ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 9/8 ojú ìwé 28-29
  • Ṣé Ìkọ̀sílẹ̀ Ló Máa Yanjú Ìṣòro Yín?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ìkọ̀sílẹ̀ Ló Máa Yanjú Ìṣòro Yín?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Wọn Yóò Sì Di Ara Kan”
  • Ṣó Bọ́gbọ́n Mu Pé Kẹ́ Ẹ Kọra Yín Sílẹ̀?
  • Àwọn Ohun Tó Lè Ràn Yín Lọ́wọ́
  • Àwọn Ànímọ́ Bíi Ti Ọlọ́run Ṣe Pàtàkì
  • Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Máa Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Yíyan Ìkọ̀sílẹ̀
    Jí!—1999
  • Ohun Mẹ́rin Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀
    Jí!—2010
  • Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú “Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 9/8 ojú ìwé 28-29

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ìkọ̀sílẹ̀ Ló Máa Yanjú Ìṣòro Yín?

NÍLẸ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àlùfáà kan ń kí àwọn tó wà níkàlẹ̀ káàbọ̀ síbi ayẹyẹ kan. Àwọn tó dúró síwájú àlùfáà náà ni tọkọtaya kan, àwùjọ àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, àtàwọn ọmọ. Ṣé wọ́n wá báwọn tó ń ṣègbéyàwó dáwọ̀ọ́ ìdùnnú ni? Rárá o! Wọ́n wá ṣayẹyẹ títú ìgbéyàwó wọn ká ni. Bẹ́ẹ̀ ni o, ìkọ̀sílẹ̀ ti wọ́pọ̀ débi pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan ti ń ṣe ayẹyẹ ìkọ̀sílẹ̀ báyìí!

Ṣé ẹ̀yin náà ti fẹ́ kọ ara yín sílẹ̀? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ṣé lóòótọ́ ni títú tí ìgbéyàwó yín bá tú ká máa mú kí ìgbésí ayé yín túbọ̀ láyọ̀? Ǹjẹ́ àwọn ohun kan tó lè ràn yín lọ́wọ́ wà tẹ́ ẹ lè ṣe kí ẹ̀yin méjèèjì bàa lè máa láyọ̀?

“Wọn Yóò Sì Di Ara Kan”

Nígbà tí Ọlọ́run fa ìyàwó àkọ́kọ́ lé ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sọ pé ọkùnrin “yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Nítorí náà, kò wu Ọlọ́run pé kí àwọn tó bá ti ṣègbéyàwó ya ara wọn. Ìyẹn ni Jésù fi sọ lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà pé lórí “ìpìlẹ̀ àgbèrè” nìkan ni ìkọ̀sílẹ̀ fi bá Ìwé Mímọ́ mu kéèyàn sì gbé ẹlòmíràn níyàwó.—Mátíù 19:3-9.a

Èyí tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí tọkọtaya máa wà fúnra wọn lọ́jọ́ gbogbo. Èwo ni ṣíṣe bí ìṣòro tó ń bá ìgbéyàwó rẹ fínra bá le gan-an?

Ṣó Bọ́gbọ́n Mu Pé Kẹ́ Ẹ Kọra Yín Sílẹ̀?

Jésù fún wa ní ìlànà tá a fi lè mọ àbájáde ìgbésẹ̀ tá a bá gbé nígbà tó sọ pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Kí ni àbájáde àwọn ìkọ̀sílẹ̀ yàlà-yòlò tó ń wáyé lóde òní jẹ́ ká lóye rẹ̀?

Onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Chicago, Ọ̀jọ̀gbọ́n Linda Waite, tó jẹ́ aṣáájú fún ọ̀wọ́ àwọn ògbógi tí wọ́n ṣèwádìí nípa àwọn ìgbéyàwó tí kò láyọ̀, sọ pé: “Àwọn èèyàn ti ki àsọdùn bọ àwọn àǹfààní tí wọ́n ń sọ pó wà nínú ìkọ̀sílẹ̀.” Bákan náà, lẹ́yìn tó ti fi ọdún mọ́kànlá ṣe àrúnkúnná ohun tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn sọ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Michael Argyle, ti Yunifásítì Oxford rí i pé “àwọn tí kì í láyọ̀ láwùjọ ẹ̀dá èèyàn làwọn tó kọ́ra wọn sílẹ̀ tàbí tí wọ́n pínyà.” Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkọ̀sílẹ̀ lè bá ọ yanjú àwọn ìṣòro kan, ó tún lè hú ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìṣẹ̀lẹ̀ bíbanilẹ́rù tí apá ẹ ò ní lè ká sóde. Kódà, ìwádìí fi hàn pé ìkọ̀sílẹ̀ kì í sábà dín àárẹ̀ ọkàn tó bá fẹ́ ṣeni kù, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í sọni dẹni àríkí àríyọ̀.

Kódà bí ìgbéyàwó rẹ kì í bá ṣe irú èyí tá a ti lè sọ pé “gẹ́gẹ́ ṣe gẹ́gẹ́,” àìkọra yín sílẹ̀ lè mú ọ̀pọ̀ àǹfààní wá. Ọ̀pọ̀ tọkọtaya tó pinnu pé èkùrọ́ ni alábàákú ẹ̀wà ló ń láyọ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Waite sọ pé: “Bó pẹ́ bó yá, ọ̀pọ̀ ìṣòro tó bá wà nílẹ̀ á yanjú, tọkọtaya á sì wá láyọ̀ púpọ̀ sí i.” Kódà, ìwádìí kan fi hàn pé nǹkan bí ẹni mẹ́jọ nínú ẹni mẹ́wàá tí ìgbéyàwó wọn ò fún wọn “láyọ̀ rárá,” síbẹ̀ náà, tí wọn ò kọra wọn sílẹ̀, ni wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí “láyọ̀ nínú ìgbéyàwó” wọn lọ́dún márùn-ún lẹ́yìn náà. Nígbà táwọn ìṣòro tó le bá tilẹ̀ yọjú pàápàá, ó sàn kí tọkọtaya máà kánjú kọra wọn sílẹ̀.

Àwọn Ohun Tó Lè Ràn Yín Lọ́wọ́

Ṣe ló yẹ káwọn tí wọ́n bá ń gbèrò láti kọra wọn sílẹ̀ máa bi ara wọn bóyá wọn ò ti máa retí ohun tó pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ nínú ìgbéyàwó wọn. Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ti ṣagbátẹrù àwọn ìtàn àròsọ nípa báwọn méjì ṣe ń fẹ́ra wọn tí wọ́n sì ṣègbéyàwó níṣu lọ́kà, tí tọkọtaya sì ń gbé láyọ̀ àti àlàáfíà títí lọ lẹ́yìn náà. Lẹ́yìn ìgbéyàwó, nígbà tí ọ̀nà ò bá gba ibi tí tọkọtaya fojú sí, ìjákulẹ̀ tó máa tìdí ẹ̀ yọ lè dá rúgúdù sílẹ̀. Bí gbún-gbùn-gbún tó wà láàárín àwọn méjèèjì bá ṣe ń pọ̀ sí i, á wá di pé kí ìbínú tó ti sẹ̀gẹ̀dẹ̀ sínú àwọn méjèèjì máà jẹ́ kí wọ́n gbọ́ra wọn yé mọ́. Ìfẹ́ á ṣá, bó bá sì yá, ìbínú àti ìkórìíra á rọ́pò rẹ̀. Bọ́rọ̀ bá ti dà bẹ́ẹ̀, àwọn kan lè ronú pé kò sí ṣíṣe kò sí àìṣe ju pé káwọn kọra àwọn.—Òwe 13:12.

Dípò jíjẹ́ kí ìbínú ru bò ọ́ lójú tó ò fi ní rí nǹkan bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, kúkú máa bá àwọn tọkọtaya tí wọ́n wà fúnra wọn lọ́jọ́ gbogbo ṣọ̀rẹ́. Ìwé Mímọ́ rọ àwọn Kristẹni láti ‘máa tu ara wọn nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí wọ́n sì máa gbé ara wọn ró lẹ́nì kìíní-kejì.’ (1 Tẹsalóníkà 5:11) Dájúdájú, àwọn tí ìgbéyàwó wọn ò fara rọ nílò ìṣírí látọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́.

Àwọn Ànímọ́ Bíi Ti Ọlọ́run Ṣe Pàtàkì

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” (Kólósè 3:12) Àwọn ànímọ́ bíi ti Ọlọ́run lè pa ìṣọ̀kan ìgbéyàwó mọ́ láwọn àkókò tí nǹkan ò bá fara rọ.

Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.” (Kólósè 3:13) Afìṣemọ̀rònú kan ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Michigan, Christopher Peterson sọ pé: “Ìdáríjì àti ayọ̀ jọ ń rìn pọ̀ ni.”

Inú rere, ìwà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti ìdáríjì ló máa ń yọrí sí ìfẹ́, tí í ṣe “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Kò sí iyèméjì pé ìgbà kan wà tẹ́ ẹ ti fi tayọ̀tayọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín. Ṣẹ́ ẹ lè pe orí ìfẹ́ yẹn padà wálé? Bó ti wù kí ipò tẹ́ ẹ bára yín le tó, ẹ mọ́kàn. Ìrètí ń bẹ. Àní, wíwà pẹ̀lú ara yín àti fífi àwọn ìlànà inú Bíbélì sílò lè mú kẹ́ ẹ ní ayọ̀ tó túbọ̀ pọ̀ sí i ju bí ẹ ti rò lọ. Dájúdájú, gbogbo ipá tí ẹ bá sà lọ́nà yìí, á mú kí inú Jèhófà Ọlọ́run, tó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, dùn.—Òwe 15:20.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìjọ àwa Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí ọkọ tàbí aya ẹni tó ṣàgbèrè ní láti pinnu yálà láti kọ alágbèrè náà sílẹ̀ tàbí kó máa bá a gbé nìṣó. Wo Jí!, May 8, 1999, ojú ìwé 5 sí 9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́