Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ló Burú Nínú Mímutí Àmuyíràá?
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó wákàtí mélòó kan tá a ti wà nídìí ọtí, síbẹ̀ nígbà tí èmi àti ọ̀rẹ́ mi kúrò níbi àríyá náà láago kan òru, olúkúlùkù wa gbé ìgò wisikí tiẹ̀ dání. Bá a ṣe ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sílé, bẹ́ẹ̀ là ń mutí. Ohun tí mo kàn rántí lẹ́yìn náà ni pé oòrùn ti ń là, mo sì wá rí i pé ọ̀nà ibòmíì la mórí lé. Àṣé àárín ọ̀nà márosẹ̀ la tiẹ̀ ń rìn. Ìyanu ló jẹ́ pé ọkọ̀ ò kọ lù wá.”—Clay.a
ỌTÍ ÀMUYÍRÀÁ. Táwọn kan bá máa ṣàlàyé ẹ̀, wọ́n á ló túmọ̀ sí mímutí torí kọ́tí bàa lè pani. Ìròyìn kan láti Ilé Iṣẹ́ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà Tó Ń Rí sí Ọtí Àmupara àti Sísọ Ọtí Mímu Di Bárakú gbìyànjú láti túbọ̀ sọ ohun tó jẹ́ gan-an. Ó sọ pé mímú ọtí àmuyíràá “sábà máa ń túmọ̀ sí kí ọkùnrin mu ìgò ọtí márùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan tàbí kí obìnrin mu ìgò ọtí mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan.”
Àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé “ìṣòro ńlá kan tó ń kojú ọ̀ràn ìlera” ni mímutí àmuyíràá. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn ọmọ ilé ìwé girama tí wọ́n wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Scotland, àti nílẹ̀ Wales ṣe fi hàn, “ìdá mẹ́rin àwọn ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mẹ́rìnlá ni wọ́n sọ pé àwọn ‘gbé’ ìgò ọtí márùn-un tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ‘lura’ rí ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan.” Ìlàjì àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́rìndínlógún tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ni wọ́n sọ pé àwọn náà ti ṣe bẹ́ẹ̀ rí.
Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn méjì nínú márùn-ún lára àwọn ọmọ ilé ìwé gíga ni wọ́n ti mutí àmuyíràá, ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan
láàárín ọ̀sẹ̀ méjì ṣáájú ìwádìí yẹn. Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìlera Ilẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé “nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá, ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó [10, 400,000] àwọn ọ̀dọ́langba tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìlá sí ogún ló sọ pé àwọn máa ń mu ọtí líle. Lára àwọn wọ̀nyí, mílíọ̀nù márùn-ún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ló jẹ́ alámuyíràá nígbà tí mílíọ̀nù méjì, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [2,300,000] jẹ́ ọ̀mùtípara tó máa ń mu àmuyíràá ó kéré tán, lẹ́ẹ̀marùn-ún lóṣù.” Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Ọsirélíà fi hàn pé àwọn ọmọbìnrin ló ń mu àmuyíràá jù níbẹ̀, àní wọ́n máa ń mu tó ìgò ọtí mẹ́tàlá sí ọgbọ̀n ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo!
Ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń mu àmuyíràá máa ń mu ún nítorí pé àwọn ọ̀dọ́ bíi tiwọn ló tàn wọ́n sẹ́nu ẹ̀. Carol Falkowski, tó jẹ́ olùṣèwádìí ṣàlàyé pé: “Ńṣe làwọn ìdíje ẹńbáláyà, irú èyí tí ò sí tẹ́lẹ̀ ń jẹ yọ lọ́tùn-ún lósì: ìyẹn ìdíje tí wọ́n ń fi ọtí mímú ṣe títí wọ́n fi máa mutí yó bìnàkò. Bí àpẹẹrẹ, níbi àwọn ìdíje kan tí wọ́n ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí níbi táwọn èèyàn ti ń fọ̀rọ̀wérọ̀, wọ́n á ní káwọn tó ń kópa da gàásì kan ọtí líle sọ́fun tí wọ́n bá ti fún wọn ní àmì pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.”
Ewu Tó Wà Nínú Mímutí Àmuyíràá
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè ka mímutí lámuyíràá sí ìdíje, àmọ́ ìdíje tó léwu gan an ni! Tí èèyàn bá ti mu ọtí lámujù, kì í jẹ́ kí ọpọlọ rí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn gbà, tó bá sì wá rí bẹ́ẹ̀, ara lè má ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ kó ṣiṣẹ́ mọ́. Ara àwọn nǹkan tó lè máa tìdí ẹ̀ yọjú ni pé kéèyàn máa bì, kó má mọ ohun tó ń ṣe mọ́, èémí ẹ̀ sì lè máà já gaara tàbí kó máa mí ní ìdákúrekú. A ti rí ẹni tó gbabẹ̀ kú. Ní nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn tí Kim, ọmọbìnrin, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún jáde ilé ìwé gíga, ó lọ síbi àríyá kan níbi téèyàn ti lè rí ọtí mu débi tó bá lè mu ún dé. Kim mu ìgò ọtí mẹ́tàdínlógún kó tó di pé ó yó débi tí kò fi mọ ohun tó ń ṣe mọ́. Àǹtí ẹ̀ wá mú un lọ sílé. Nígbà tó dàárọ̀ ọjọ́ kejì tí màmá Kim lọ wò ó, òkú ẹ̀ ló bá.
Àwọn tí wọ́n kú nítorí pé wọ́n mu ọtí púpọ̀ jù lè má pọ̀ o, síbẹ̀, ọtí àmujù ṣì lè ṣàkóbá fún ìlera. Jerome Levin ògbógi kan nínú ìtọ́jú ọpọlọ sọ pé: “Ọtí líle lè ba ẹ̀yà ara èyíkéyìí jẹ́ nínú àgọ́ ara rẹ. Àwọn ẹ̀yà ara tí ọtí sábà máa ń bà jẹ́ ni agbára ìmọ̀lára, ẹ̀dọ̀, àti ọkàn.” Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Discover sọ pé: “Àwọn ìwádìí tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi han pé ńṣe làwọn ọmọ kéékèèké tó ń mutí ń forí ọká họmú. Títí di ìgbà tí wọ́n fi máa pé ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni ọpọlọ wọn á ṣì máa dàgbà sí i, nítorí náà àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún tí wọ́n ń mutí lámujù wulẹ̀ ń ba agbára tó yẹ kí ọpọlọ wọn ní jẹ́ díẹ̀díẹ̀ ni.” Ọtí àmuyíràá wà lára àwọn nǹkan tó ń fa rorẹ́, ara híhun jọ láìtọ́jọ́, kí èèyàn máa sanra, ó tún ń ba àwọn ẹ̀yà inú ara jẹ́, ó sì tún wà lára àwọn nǹkan tó máa ń sọ èèyàn di ẹni tí ọtí àti jíjẹ oògùn ti di bárakú fún.
Àwọn ewu mìíràn tún wà tó lè tara mímutí lámujù wá. Tó o bá ti yó, àwọn èèyàn lè fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ẹ́. Wọ́n lè lù ẹ́ tàbí kí wọ́n fipá bá ẹ lò pọ̀. Bákan náà, o lè bẹ̀rẹ̀ sí wu àwọn mìíràn léwu, nígbà tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé o ò lè darí ara ẹ mọ́, èyí tó ò jẹ́ dán wò ká ní o mọ ohun tó ò ń ṣe. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi kìlọ̀ pé tó o bá mu ọtí jù, “ojú ìwọ fúnra rẹ yóò rí àwọn ohun àjèjì, ọkàn-àyà rẹ yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà.” (Òwe 23:33) Lára àwọn nǹkan ìbànújẹ́ tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ wá ni pé àárín ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ lè dà rú, o lè máa jó àjórẹ̀yìn nínú ẹ̀kọ́ àti lẹ́nu iṣẹ́ rẹ, o lè lórúkọ lọ́dọ̀ ìjọba bí ọ̀daràn, o sì lè di akúṣẹ̀ẹ́.b—Òwe 23:21.
Nǹkan Tó Lè Sọ Ẹ́ Di Ọ̀mùtí
Pẹ̀lú gbogbo ewu tó wà nídìí ẹ̀ yí náà, àwọn èèyàn ṣì ń polówó ọtí gan an, ọtí sì pọ̀ yamùrá ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Kódà, ńṣe ni wọ́n ń pọ́n ọtí bí ohun tó gbajúmọ̀ nínú ìpolówó ọjà orí tẹlifíṣọ̀n àti tàwọn ìwé ìròyìn. Àmọ́, ohun tó sábà máa ń sọ ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ di alámuyíràá ni pé wọ́n fẹ́ ṣe ohun tẹ́gbẹ́ wọn ń ṣe.
Nígbà tí wọ́n ṣèwádìí kúlẹ̀kúlẹ̀ lórí ọtí mímu lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, ìpín mẹ́rìndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n wádìí lẹ́nu wọn ló sọ pé nítorí “káwọn má bàa dá yàtọ̀ láàárín ẹgbẹ́ àwọn làwọn ṣe ń mutí.” Lójú ọlọ́mọ-ò-to, níbi àríyá tí “bíà ti ń pe bíà rán níṣẹ́,” ẹni tó jẹ́ onítìjú èèyàn lè wá di amúlùúdùn lójú agbo nígbà táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ bá ń rọ̀ ọ́ pé kó ṣáà máa mutí nìṣó. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Katie mutí yó lọ́nà yẹn, ńṣe ni wọ́n gbé e wálé nígbà tó dá kú. “Ọ̀rẹ́” rẹ̀ kan ló rọ ọ́ yó, ohun tíyẹn ń sọ fún un ni pé: “O dẹ̀ ń ṣe bí ọmọdé, o ti di obìnrin kẹ̀. Ó yẹ kó o ti mọ bí wọ́n ṣe ń gbé e dà sọ́fun.”
Ìfẹ́ láti jayé orí ẹni kéèyàn sì fẹ́ láti bẹ́gbẹ́ pé lágbára débi pé bí ẹ̀rí àrídájú tiẹ̀ wà pé àmuyíràá léwu, síbẹ̀ àwọn tó ń mutí yó bìnàkò túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni.
Èwo Ni Ìwọ Máa Ṣe Níbẹ̀?
Ìbéèrè tó dojú kọ ẹ́ rèé o: Tọ́rọ̀ bá dọ̀rọ̀ mímutí èwo ni ìwọ máa ṣe? Ṣé nǹkan táwọn ẹgbẹ́ ẹ bá ti ṣe nìwọ náà máa bá wọn ṣe? Rántí ohun tí Bíbélì sọ nínú Róòmù 6:16 pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé bí ẹ bá ń jọ̀wọ́ ara yín fún ẹnikẹ́ni bí ẹrú láti ṣègbọràn sí i, ẹ̀yin jẹ́ ẹrú rẹ̀ nítorí ẹ ń ṣègbọràn sí i?” Bó o bá ń jẹ́ káwọn ẹgbẹ́ ẹ máa darí gbogbo ohun tí wàá máa ṣe, a jẹ́ pé ẹrú lásánlàsàn lo jẹ́ sí wọn yẹn. Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé kó o dánú rò. (Òwe 1:4) Ó tún láwọn àmọ̀ràn tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe àṣìṣe tó lágbára. Ronú lórí ohun tó sọ nípa ọtí líle.
Lóòótọ́, Bíbélì ò ní kéèyàn má mutí o, kò sì ní káwọn ọ̀dọ́ máà gbádùn ara wọn. Ohun tó sọ ni pé ká má mu àmupara. Òwe 20:1 sọ pé: “Afiniṣẹ̀sín ni wáìnì, aláriwo líle ni ọtí tí ń pani, olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣáko lọ kò gbọ́n.” Bẹ́ẹ̀ gan an ló rí, ọtí líle lè sọ èèyàn di ẹni ẹ̀sín àti aláriwo! Òótọ́ ni pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè fún ọ ní ìgbádùn, ṣùgbọ́n tó o bá ṣàṣejù nídìí ẹ̀, á ‘bù ẹ́ ṣán gẹ́gẹ́ bí ejò,’ nígbà tójú ẹ bá dá, wàá wá rí bí ìpalára tó ṣe fún ẹ ti ṣe pọ̀ tó, àti bó ti ṣe bà ẹ́ nínú jẹ́ tó.—Òwe 23:32.
Ohun mìíràn tó tún yẹ kó o kíyè sí ni pé láwọn orílẹ̀-èdè kan, ó níbi téèyàn gbọ́dọ̀ dàgbà dé kó tó lè mutí. Àwa Kristẹni máa ń ṣègbọràn sírú àwọn òfin bẹ́ẹ̀. (Títù 3:1) Nítorí àtidáàbò bò ẹ́ làwọn òfin yẹn ṣe wà.
Èyí tó gbẹ̀yìn tó sì ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kó o ronú lórí ipa tí ọtí àmujù á ní lórí ipò tẹ̀mí rẹ. Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kó o sin òun pẹ̀lú “gbogbo èrò inú rẹ,” kì í ṣe pẹ̀lú ọkàn tó ti díbàjẹ́ látàrí ọtí àmujù! (Mátíù 22:37) Kì í ṣe “àṣejù nídìí wáìnì” nìkan ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dẹ́bi fún, àmọ́ ó tún dẹ́bi fún “ìfagagbága ọtí mímu.” (1 Pétérù 4:3) Gbogbo èyí fi hàn pé mímu ọtí àmuyíràá ta ko ìfẹ́ inú Ẹlẹ́dàá wa. Téèyàn bá ń ṣe báyìí mutí àmujù, ó lè dí èèyàn lọ́wọ́ àtisún mọ́ Ọlọ́run kéèyàn sí máà rí ojú rere rẹ̀.
Kí ló yẹ kó o ṣe bí ọtí àmuyíràá bá ti jàrábà ẹ? Láìjáfara, wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ òbí rẹ tàbí Kristẹni kan tó dàgbà dénú.c Tọ Jèhófà Ọlọ́run lọ nínú àdúrà kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Òun ṣáà ni “ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.” (Sáàmù 46:1) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ojúgbà èèyàn ló sábà ń kó mímutí àmuyíràá àti mímutí láti kékeré ran èèyàn, á dáa kó o ṣèyípadà tó lágbára lórí àwọn tó ò ń bá ṣọ̀rẹ́ àti irú eré ìnàjú tó ò ń ṣe. Kò ní rọrùn láti ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ o, àmọ́ Jèhófà, lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Amẹ́ríkà fi hàn pé, “àwọn tí wọ́n máa ń mu àmuyíràá wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ló ṣeé ṣe fún jù ní ìlọ́po mẹ́jọ pé kí wọ́n máa pa kíláàsì jẹ, kí wọ́n máa ru póò lẹ́nu iṣẹ́ ilé ìwé, kí wọ́n máa bínú tàbí kí wọ́n ṣèṣe, àwọn náà ló sì ṣeé ṣe fún jù lọ pé kí wọ́n di bàsèjẹ́.”
c Nínú àwọn ọ̀ràn míì, ó lè gba pé kó o lọ sọ́dọ̀ oníṣègùn kan tó kọ́ṣẹ́mọṣẹ́.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Iye Àjálù Tí Mímutí Àmuyíràá Ti Fà
Ìsọfúnni tá a rí látinú ìṣirò, èyí tá a kọ síbí yìí ló ṣàlàyé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó tẹ̀yìn mímutí àmuyíràá wá láàárín àwọn ọmọ ilé ìwé girama lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà:
Ikú: Lọ́dọọdún, egbèje [1,400] àwọn ọmọ ilé ìwé girama tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìdínlógún sí mẹ́rìnlélógún ló ń kú látàrí ṣíṣèèṣì ṣe ara wọn léṣe nígbà tí wọ́n mutí yó, títí tó fi mọ́ ìjàǹbá mọ́tò
Ṣíṣèṣe: Ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] akẹ́kọ̀ọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìdínlógún sí mẹ́rìnlélógún ló ti ṣèṣe láìmọ̀ọ́mọ̀ nígbà tọ́rọ̀ ọtí ti wọ̀ ọ́
Bíbára Ẹni Jà: Ó ju akẹ́kọ̀ọ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000] tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìdínlógún sí mẹ́rìnlélógún lọ tí akẹ́kọ̀ọ́ míì bíi tiwọn, tó mutí yó ti dojú ìjà kọ
Ìbálòpọ̀ Tí Ò Tinú Ẹni Wá: Ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́ta àbọ̀ [70,000] akẹ́kọ̀ọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìdínlógún sí mẹ́rìnlélógún tẹ́nì kan tó yó ti fi ìbálòpọ̀ lọ̀ tàbí kó jẹ́ pé nígbà tóun gan-an yó tán ló ṣẹlẹ̀, ó sì tún lè jẹ́ pé ẹni kan tó mọ̀ rí tàbí tó ń bá jáde ló fipá bá ọmọbìnrin ọ̀hún lò pọ̀
[Credit Line]
Orísun ìsọfúnni: Ilé Iṣẹ́ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà Tó Ń Rí sí Ọtí Àmupara àti Sísọ Ọtí Mímu Di Bárakú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn ojúgbà rẹ lè rọ̀ ọ́ pé kó o mutí àmuyíràá