Ṣé Aráyé Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ohun Tó Ń Fa Ìbẹ̀rù?
ǸJẸ́ ẹnikẹ́ni wà láyé eléwu yìí tó lè fi gbogbo ẹnu sọ pé kò sóhun tó ń ba òun lẹ́rù? Kò dájú. Àwọn èèyàn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run pàápàá ń dojú kọ ewu tó ń mú kí wọ́n bẹ̀rù. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó rìnrìn-àjò débi tó pọ̀ sọ pé ọkọ̀ ojú omi tóun wọ̀ rì, ó tún sọ nípa ewu odò, ewu àwọn dánàdánà, àti ewu nínú ìlú. (2 Kọ́ríńtì 11:25-28) Bákan náà lọ̀ràn rí lónìí, ọ̀pọ̀ nínú wa lewu máa ń wu.
Àmọ́ ṣá o, a lè máa wá ọ̀nà láti dáàbò bo ara wa. Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó máa dín ewu tó ń wu wá kù, a ó sì lè dín ẹ̀rù tó ń bà wá kù. Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) Kí làwọn nǹkan díẹ̀ tó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a lè ṣe?
Bá A Ó Ṣe Máa Ṣọ́ra Wa
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ti pẹ́ tí wọ́n ti kọ Bíbélì, ọpẹ́ ni pé lọ́jọ́ tòní, ọ̀pọ̀ ìlànà tá a lè mú lò tá a ò fi ní kó séwu, ṣì wà nínú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Ní ti ọlọ́gbọ́n, ojú rẹ̀ wà ní orí rẹ̀; ṣùgbọ́n arìndìn ń rìn lọ nínú ògédé òkùnkùn.” (Oníwàásù 2:14) Ó bọ́gbọ́n mu kó o mọ̀ béèyàn bá wà ní sàkáání rẹ, bó bá sì ṣeé ṣe, má máa rìn ní àyíká ibi tó ṣókùnkùn. Bó bá ṣeé ṣe, o lè máa gba àdúgbò tí iná ti pọ̀ lójú pópó, bó bá tiẹ̀ máa mú kí ìrìn ẹ gùn sí i. Bíbélì tún sọ pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan . . . Bí ẹnì kan bá sì lè borí ẹni tí ó dá wà, ẹni méjì tí ó wà pa pọ̀ lè mú ìdúró wọn láti dojú kọ ọ́.” (Oníwàásù 4:9, 12) Bó o bá ń gbé níbi tó léwu, o ò ṣe kúkú máa wá ẹni tẹ́ ẹ ó jọ máa rìn lọ sílé?
Bó o bá bọ́ sọ́wọ́ dánàdánà, ó máa dára kó o rántí pé ẹ̀mí ẹ ṣe pàtàkì púpọ̀ ju ohun ìní lọ. (Mátíù 16:26) Ó tún dáa kó o rántí pé báwọn èèyàn bá kóra jọ láti fẹ̀hónú hàn, wọn ò ṣeé kò lójú, wọ́n sì lè dán mẹ́wàá wò.—Ẹ́kísódù 23:2.
Bí ẹnì kan bá ń yọ ọ́ lẹ́nu nípa fífi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ẹ́, tàbí nípa fífi ọ̀rọ̀ rírùn ṣẹ̀fẹ̀, tàbí nípa gbígbìyànjú láti fọwọ́ kàn ọ́ níbi tí kò yẹ, òun tó dára jù ni pé kó o kọ̀ fún un jálẹ̀. O tiẹ̀ lè fibẹ̀ sílẹ̀ bí Jósẹ́fù ṣe ṣe nígbà tí obìnrin oníwà pálapàla kan di ẹ̀wù rẹ̀ mú. Ó “fẹsẹ̀ fẹ, ó sì bọ́ síta.” (Jẹ́nẹ́sísì 39:12) Bí kò bá ṣeé ṣe láti fẹsẹ̀ fẹ, o lè sọ pé: “Mi ò gbarú ẹ̀ rárá!” tàbí “Má fọwọ́ ẹ kàn mí mọ́ láé!” tàbí “Mi ò fẹ́ kéèyàn máa sọ irú ọ̀rọ̀ rírùn yẹn sí mi.” Bó bá ṣeé ṣe, má máa lọ síbi táwọn èèyàn ti lè máa yọ ẹ́ lẹ́nu.
Ohun Tó O Lè Ṣe Nípa Ìbẹ̀rù Nínú Ilé
Kí lo lè ṣe bí ẹ̀rù ọkọ rẹ tó ń fìyà jẹ ọ́ bá ń bà ọ́? Ì bá dáa bó o bá ní ibi tí wàá sá gbà lọ́kàn bí ọkọ rẹ bá ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí hùwà tó lè pa ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ lára, tàbí tó tiẹ̀ lè gbẹ̀mí yín.a Bíbélì sọ bí Jékọ́bù ṣe fara balẹ̀ ronú nípa ohun tó máa ṣe bó bá ṣẹlẹ̀ pé Ísọ̀ fẹ́ ta á ní jàǹbá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ò wá rí bó ṣe rò, ọgbọ́n wà nínú bó ṣe lo ìṣọ́ra. (Jẹ́nẹ́sísì 32:6-8) Lára ọ̀nà tó o lè gbà dọ́gbọ́n ara ẹ ni pé kó o wá ẹnì kan tó lè gbà ọ́ sílé bí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. O ti lè ṣàlàyé àwọn ọ̀nà tí onítọ̀hún lè gbà ràn ọ́ lọ́wọ́ fún un kó tó di pé o sá tọ̀ ọ́ lọ. Á sì tún dáa káwọn ìwé ẹ̀rí àtàwọn nǹkan pàtàkì míì wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ.
Lára ohun tó o tún lè ṣe ni pé kó o jẹ́ káwọn agbófinró mọ̀ nípa lílù tí ọkọ rẹ máa ń lù ọ́, kó o sì máa wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ wọn.b Bíbélì kọ́ni pé olúkúlùkù ló máa dáhùn fún gbogbo ìwà tó bá hù. (Gálátíà 6:7) Bíbélì sọ nípa àwọn agbófinró pé: “Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni ó jẹ́ sí ọ fún ire rẹ. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń ṣe ohun tí ó burú, kí o máa bẹ̀rù.” (Róòmù 13:4) Ìwà ọ̀daràn ni gbígbéjàkoni lójú pópó, ìwà ọ̀daràn náà sì ni nínú ilé. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ìwà ọ̀daràn tún ni kéèyàn máa dọdẹ ẹlòmíì.
Bó o bá ń ṣe àwọn ohun tá a sọ yìí, ó lè dín ìbẹ̀rù kù débì kan. Ṣùgbọ́n ohun tí Bíbélì ń ṣe ò mọ sórí fífúnni ní ìmọ̀ràn tó wúlò o. Kì í ṣe ìwé abánigbọ́ṣòro kan lásán. Ìwé táwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀ kì í kùnà, tó ń jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run ń ṣe báyìí àti ohun tó ń bọ̀ wá ṣe lọ́jọ́ iwájú ló jẹ́. Ìròyìn ayọ̀ wo ló wà nínú Bíbélì fáwọn tí ìbẹ̀rù ò tíì kúrò lọ́rọ̀ wọn?
Ohun Tó Fà Á Tí Ìbẹ̀rù Fi Gbòde Kan
Ní pàtàkì jù lọ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere.” (2 Tímótì 3:1-3) Ọ̀rọ̀ kàbìtì mà nìyẹn jẹ́ nípa bí àkókò wa ṣe máa kún fún ìbẹ̀rù tó o!
Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó ní: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba; ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ láti ibì kan dé ibòmíràn; àwọn ìran bíbanilẹ́rù yóò sì wà àti àwọn àmì ńláǹlà láti ọ̀run.” (Mátíù 24:3, 7, 8; Lúùkù 21:10, 11) Nítorí náà, “àwọn ìran bíbanilẹ́rù” tá a ti rí, tí wọ́n sì wà lára àwọn nǹkan tó jẹ́ kí ìbẹ̀rù gbayé kan, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wa. Àmọ́, kí ló fà á tí wọ́n fi ń ṣẹlẹ̀ gan-an?
Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:31) Lákòókò tá à ń gbé yìí, a lè retí pé kí ìjọba kan láti ọwọ́ Ọlọ́run máa ṣàkóso aráyé látọ̀run wá. (Dáníẹ́lì 2:44) Báwo ni ayé á ṣe rí nígbà yẹn?
Kò Sí Ìbẹ̀rù Mọ́!
Bíbélì ṣàlàyé nípa ọjọ́ iwájú tí àlàáfíà yóò wà, tí kò ní sí ogun mọ́, tí àwọn aṣebi ò ní sí mọ́, tí ayé á sì kún fáwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Pétérù, àpọ́sítélì Jésù, kọ̀wé nípa “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run,” tó ń bọ̀ lọ́nà. Kò ní sí olubi kankan téèyàn á máa bẹ̀rù mọ́ nítorí pé ‘òdodo yóò máa gbé’ lórí ilẹ̀ ayé. (2 Pétérù 3:7, 9, 13) Wo bó ṣe máa tuni lára tó béèyàn bá ń gbé láàárín àwọn tó ṣeé fọkàn tán, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú! Àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ yìí á ràn wá lọ́wọ́ láti máa fojú tó yàtọ̀ wo ewu tó wà lákòókò wa yìí. Ewu yẹn ò ní máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí ayé.—Sáàmù 37:9-11.
Nítorí tàwọn tó ń ṣàníyàn, Jèhófà sọ fún wòlíì rẹ̀ pé: “Sọ fún àwọn tí ń ṣàníyàn nínú ọkàn-àyà pé: ‘Ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ má fòyà. Ẹ wò ó! Ọlọ́run yín yóò wá tòun ti ẹ̀san, Ọlọ́run yóò wá, àní tòun ti ìsanpadà. Òun fúnra rẹ̀ yóò wá, yóò sì gbà yín là.’” (Aísáyà 35:4) Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run òtítọ́ lè máa fi ìdánilójú wọ̀nà fún ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. (Fílípì 4:6, 7) Ìtùnú gbáà ló jẹ́ fáwọn tẹ́rù ń bà láti mọ̀ pé Jèhófà ò tíì pa ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ tì, ó ṣì fẹ́ kí ilẹ̀ ayé kún fún àwọn èèyàn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tí wọ́n sì ń fi àwọn ànímọ́ onífẹ̀ẹ́ bíi tiẹ̀ hàn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; Aísáyà 11:9.
A mọ̀ pé kó sóhun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti fìfẹ́ ṣe ohun tó wù ú fún aráyé. (Aísáyà 55:10, 11; Róòmù 8:35-39) Bá a bá mọ̀ bẹ́ẹ̀, ohun tó wà nínú Sáàmù kan, tá a mọ̀ bí-ẹní-mowó nínú Bíbélì á nítumọ̀ gidi sí wa. A kà níbẹ̀ pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. . . . Ó ń tu ọkàn mi lára. Ó ń ṣamọ̀nà mi ní àwọn òpó ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi.” (Sáàmù 23:1-4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ń mú kẹ́rù bani nínú ayé lè pọ̀ sí i, ó dájú hán-ún hán-ún pé ayé kan tẹ́rù ò ti ní bani mọ́ ti sún mọ́lé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó o bá fẹ́ mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí àwọn tó lè mú kí tọkọtaya pínyà, wo Jí! February 8, 2002, ojú ìwé 10.
b Bó o bá fẹ́ kà nípa àwọn tí wọ́n ń lù ní àlùbami nínú ilé, wo Jí! November 8, 2001, ojú ìwé 3 sí 12, àti Jí! February 8, 1993, ojú ìwé 3 sí 14.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọlọ́run máa tó mú ayé tẹ́rù ò ti ní bani mọ́ wá