ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/06 ojú ìwé 19
  • Ṣé Ọjọ́ Alẹ́ Ń Sanni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ọjọ́ Alẹ́ Ń Sanni?
  • Jí!—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Ti Ràn Mí Lọ́wọ́ Ní Ti Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Bí Àpéjọ Mẹ́ta Ṣe Yí Ìgbésí Ayé Mi Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Láti Ẹnu Àwọn Ìkókó”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nígbèésí Ayé Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 4/06 ojú ìwé 19

Ṣé Ọjọ́ Alẹ́ Ń Sanni?

ÌGBÀ òtútù ni ohun tá a fẹ́ sọ yìí ṣẹlẹ̀ ní aago mẹ́fà ààbọ̀ àárọ̀ ọjọ́ kan ní ìlú Soweto lórílẹ̀-èdè South Africa. Ó di dandan kí ìyá kan tó ń jẹ́ Evelyn, tó ń gbébẹ̀ dìde ńlẹ̀.a Àmọ́, torí pé kò sí ẹ̀rọ tó ń múlé gbóná nínú ilé tó ń gbé, wàhálà ńlá ni fún un.

Bó ṣe jí, ó rọra n sún lọ sí etí bẹ́ẹ̀dì nítorí orúnkún tó ń ro ó. Ó wá jókòó síbẹ̀ ó ń wòréré ayé. Díẹ̀díẹ̀, ìrora orúnkún tó ń ro ó yẹn bẹ̀rẹ̀ sí lọ sílẹ̀. Màmá yìí wá pa kítí mọ́ra ó sì dìde ńlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni orúnkún ọ̀hún tún sán an, wàá wàá. Ó di ìgbáròkó ẹ̀ mú, bíi ‘tata tó ń wọ́ ara rẹ̀ lọ’ díẹ̀díẹ̀, bó sì ṣe tẹ̀ kẹ́jẹ́kẹ́jẹ́ dé ilé ìwẹ̀ nìyẹn.—Oníwàásù 12:5.b

Màmá yìí yin ara ẹ̀, ó ní, ‘O káre láé!’ Kì í ṣe torí pé ọjọ́ òní ṣojú ẹ̀ nìkan ni, àmọ́ ọpẹ́ ńlá ni pé ó tún lè gbé ara tó ń ro ó nílẹ̀.

Àmọ́, nǹkan míì tún ń dà á láàmú o. Màmá tó ń jẹ́ Evelyn yìí sọ pé: “Bóyá lèmi náà ò ní máa ṣarán tó bá yá.” Ó ti dẹni tó ń gbàgbé ibi tó fi kọ́kọ́rọ́ ẹ̀ sí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ ó ṣì mọ ohun tó ń ṣe. Ó sọ pé: “Àdúrà mi ṣáà ni pé kọ́rọ̀ mi má lọ dà bíi tàwọn arúgbó kan tí wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́.”

Nígbà tí Evelyn ò tíì dàgbà tó báyìí, ọ̀rọ̀ bọ́jọ́ ogbó rẹ̀ ṣe máa rí kò kàn án. Àmọ́ kó tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ọjọ́ ogbó ti dé sí i, ìrora tó ń dà á láàmú báyìí sì máa ń rán an létí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ pé ó ti lé lọ́dún mẹ́rìnléláàádọ́rin.

Àwọn tí tiwọn sàn ju ti màmá yìí lọ tí àìsàn àti ìnira ò fi bẹ́ẹ̀ dà láàmú lè fi gbogbo ẹnu sọ pé ọjọ́ alẹ́ san àwọn ju òwúrọ̀ lọ. Bíi ti Ábúráhámù, bàbá àtijọ́ yẹn, wọ́n lè dàgbà ‘di ọjọ́ ogbó gidi gan-an, kí wọ́n darúgbó kí wọ́n sì ní ìtẹ́lọ́rùn.’ (Jẹ́nẹ́sísì 25:8) Ọjọ́ ogbó àwọn kan lè jẹ́ “ọjọ́ àti ọdún ìbànújẹ́” wọn ò sì lè rí sọ ju pé: “Mi ò gbádùn ayé.” (Oníwàásù 12:1, Today’s English Version) Nínú ìwádìí kan, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ìgbà táwọn bá fi máa tó fẹ̀yìn tì, nǹkan ò ní dáa. Kódà wọ́n yí orúkọ tí wọ́n ń pe igbà alẹ́ padà sí “Sànmánì Ojú Dúdú.”

Ojú wo lo fi ń wo ọjọ́ ogbó? Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro táwọn àgbàlagbà ń dojú kọ? Ṣé dandan ni pé béèyàn bá ti darúgbó kò ní mọ ohun tó ń ṣe mọ́? Kí lèèyàn lè ṣe láti jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ túbọ̀ máa balẹ̀ lọ́jọ́ alẹ́?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí.

b Ọjọ́ ti pẹ́ táwọn èèyàn ti ń fojú ewì wo ọ̀rọ̀ ṣùnnùkùn tó ṣàlàyé àwọn ìṣòro ọjọ́ ogbó yìí. Inú ìwé ìgbàanì kan tó ń jẹ́ ìwé Oníwàásù ni ewì ọ̀hún wà nínú Bíbélì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́