Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ọmọ Ọlọ́run Ni Jésù Lóòótọ́?
KÒ SÍ tàbí-ṣùgbọ́n lọ́kàn àpọ́sítélì Pétérù nígbà tó sọ nípa Jésù pé: “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.” (Mátíù 16:16) Ọ̀kan péré lèyí jẹ́ lára ọ̀pọ̀ ibi tí Bíbélì ti pe Jésù ní Ọmọ Ọlọ́run. Gbólóhùn náà sì ti di ọ̀rọ̀ táwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ń gbà bí ẹní gba igbá ọtí.
Ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ àwọn tó gbà gbọ́ pé Jésù Kristi ni Ọlọ́run láti ṣàlàyé ìdí tí wọ́n tún fi ń pè é ní Ọmọ Ọlọ́run. Ẹní bá rò ó láròjinlẹ̀ á mọ̀ pé òun nìkan ò lè jẹ́ Ọlọ́run kó sì tún jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Èrò àwọn kan ni pé bá a bá yọwọ́ pé Jésù jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká, ẹni tó finú ṣọgbọ́n, tàbí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ojúlówó wòlíì Ọlọ́run, kò tún sí bó ṣe jẹ́ mọ́. Kí ni Bíbélì fi kọ́ wa nípa rẹ̀ gan-an? Ṣé ohun tó o gbà gbọ́ nípa rẹ̀ ṣe pàtàkì?
Àkọ́bí Ọlọ́run
Bíbélì ṣàlàyé pé ìgbà kan wà tí kò sí ẹlòmíràn àfi Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. Ìfẹ́ ló mú kó fẹ́ láti di baba tó fi ìwàláàyè jíǹkí ọmọ rẹ̀, lọ́nà tó yàtọ̀ sí bí àwa èèyàn ṣe ń di baba ọmọ. Ohun tí Jèhófà ṣe ni pé ó lo àwámárìídìí agbára tó fi ń ṣẹ̀dá láti dá ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó ní làákàyè. Ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ni “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run” tá a wá mọ̀ sí Jésù Kristi. (Ìṣípayá 3:14; Òwe 8:22) Nítorí pé lákòókò tí Ọlọ́run dá wà ló fọwọ́ ara rẹ̀ dá Jésù, ó bá a mu gẹ́lẹ́ láti pe Jésù ní “ọmọ bíbí kan ṣoṣo” àti “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.”—Jòhánù 1:14; Kólósè 1:15.
Ó wá ṣe kedere nígbà náà pé, gẹ́gẹ́ bí ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, kò sí bí Jésù ṣe lè jẹ́ Ẹlẹ́dàá, ìyẹn “Ọlọ́run kan ṣoṣo náà.” (1 Tímótì 1:17) Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, ọ̀pọ̀ àǹfààní ni Ọlọ́run fi jíǹkí Ọmọ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nípasẹ̀ Jésù ni Ọlọ́run fi dá “gbogbo ohun mìíràn,” tó fi mọ́ àwọn áńgẹ́lì pàápàá. Àwọn áńgẹ́lì yìí ni Bíbélì pè ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run” nítorí pé Jèhófà ló fi ìwàláàyè jíǹkí àwọn náà.—Kólósè 1:16; Jóòbù 1:6; 38:7.
Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti mú kí ayé wà ní sẹpẹ́ káwọn èèyàn lè máa gbé inú ẹ̀, ó dájú pé àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run yìí ni Ọlọ́run ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé: “Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; Òwe 8:22-31) Ó dájú nígbà náà pé ẹ̀dá ẹ̀mí tá a wá mọ̀ sí Jésù yìí ni Jèhófà lò láti ṣẹ̀dá Ádámù tí í ṣe ènìyàn àkọ́kọ́ tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.—Lúùkù 3:38.
Jésù Ọmọ Ọlọ́run Di Èèyàn
Àpọ́sítélì Jòhánù fi hàn wá pé ní àkókò tí Ọlọ́run yàn, ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run yìí “di ẹlẹ́ran ara, ó sì gbé láàárín wa.” (Jòhánù 1:14) Ká bàa lè bí Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran ara, Ọlọ́run tipasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu fi ẹ̀mí Jésù sínú ilé ọlẹ̀ ọmọbìnrin wúńdíá Júù kan tó ń jẹ́ Màríà. Nípa báyìí, Jésù ṣì ń bá a nìṣó láti máa jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti di èèyàn. Àti pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló mú kí Jésù wà láàyè, tí kì í sì í ṣe èèyàn èyíkéyìí, a bí i ní pípé láìlẹ́ṣẹ̀. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà pé: “Ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.”—Lúùkù 1:35; Hébérù 7:26.
Bàbá Jésù fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé nígbà tí Jésù ṣì wà nínú ẹran ara, ọmọ òun ni. Nígbà tí Jésù ń ṣe ìrìbọmi, Jòhánù Oníbatisí fojú ara rẹ̀ rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, ó sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá tó wí pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:16, 17) Abájọ tí Jòhánù fi sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Mo sì ti rí i, mo sì ti jẹ́rìí pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.”—Jòhánù 1:34.
Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, kò máa pariwo kiri pé òun ni Mèsáyà náà, tí í ṣe Ọmọ Ọlọ́run. (Máàkù 8:29, 30) Ó sábà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn gbà lọ́kàn ara wọn pé ọmọ Ọlọ́run lòun lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fetí sí ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ wọn, tí wọ́n bá ti kíyè sí bó ṣe ń gbé ìgbé ayé ẹ̀, àti lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fojú ara wọn rí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tó ń ṣe. Ọ̀pọ̀ irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe lójútáyé. Bí àpẹẹrẹ, ó wo “gbogbo àwọn tí nǹkan kò sàn fún . . . tí onírúurú òkùnrùn àti ìjoró ń wàhálà.” (Mátíù 4:24, 25; 7:28, 29; 12:15) Àwọn afọ́jú, àwọn adití, àwọn arọ, àtàwọn olókùnrùn, gbogbo wọn ni wọ́n tọ Jésù wá, ó sì wo gbogbo wọn sàn. Kódà, ó jí òkú dìde! (Mátíù 11:4-6) Kòrókòró lójú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni Jésù tipasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu rìn lórí omi, ó mú kí ẹ̀fúùfù àti omi tí ń ru gùdù nígbà tí ìjì líle ń jà rọlẹ̀. Bó ṣe lo agbára lọ́nà àràmàǹdà yìí mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ jẹ́ ní ti tòótọ́.”—Mátíù 14:24-33.
Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Lára Ọmọ Ọlọ́run
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo láti ọ̀run wá sáyé, tó sì jẹ́ pé ṣe ló máa kú ikú oró níbẹ̀? “Kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Òdodo ọ̀rọ̀, nípasẹ̀ ikú Jésù nìkan ló fi lè “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Òótọ́ sì ni pé látọjọ́ táláyé ti dáyé, bá a bá yọwọ́ Jèhófà àti àkọ́bí Ọmọ rẹ̀, kò sẹ́ni tó tíì fi ìfẹ́ tó tóbi ju èyí lọ hàn.—Róòmù 8:32.
Lẹ́yìn ikú Jésù, “a polongo [rẹ̀] ní Ọmọ Ọlọ́run” lọ́nà àkànṣe tí ẹnikẹ́ni kò lè sẹ́, “nípasẹ̀ àjíǹde láti inú òkú” àti pípadà tó padà sí ìyè lókè ọ̀run gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí. (Róòmù 1:4; 1 Pétérù 3:18) Lẹ́yìn ìyẹn ni Jésù fi sùúrù dúró ti Baba rẹ̀ fún nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà mọ́kàndínlógún, kó tó gbé e gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba tá a fìdí rẹ̀ kalẹ̀ lókè ọ̀run, èyí tó máa tó ṣàkóso lé gbogbo ayé pátá lórí láìpẹ́.—Sáàmù 2:7, 8; Dáníẹ́lì 7:13, 14.
Ṣé wàá fẹ́ láti rí ojúure Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ alágbára ńlá yìí? Bó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, a rọ̀ ọ́ pé kó o yẹ àwọn ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni wò kó o sì máa fi wọ́n ṣèwà hù nínú ìgbésí ayé rẹ. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Kò sírọ́ ńbẹ̀, ohun tí ẹnì kan bá gbà gbọ́ nípa Ọmọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an ni!— Jòhánù 3:18; 14:6; 1 Tímótì 6:19.
ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?
◼ Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run?—Jòhánù 1:3, 14; Ìṣípayá 3:14.
◼ Kí nìdí tó o fi lè gbà gbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù?—Mátíù 3:16, 17.
◼ Àǹfààní wo lo lè tìdí ẹ̀ wá, bó o bá gbà gbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù?—Jòhánù 3:16; Jòhánù 14:6; 17:3.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn ẹ̀kọ́ tó mọ́gbọ́n dání tí Jésù fi kọ́ni àtàwọn iṣẹ́ ìyanu ńláǹlà tó ṣe ló fi hàn pé kì í ṣe èèyàn kan lásán