ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/06 ojú ìwé 30-31
  • Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú sí Lóòótọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú sí Lóòótọ́?
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Wọ́n Ń Lo Àgbélébùú Fún?
  • “Ẹ Máa Ṣọ́ra fún Àwọn Òrìṣà”
  • Ṣé Òótọ́ Ni Jésù Kú Lórí Àgbélébùú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Fi Í Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú Sí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì í Fi Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 4/06 ojú ìwé 30-31

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú sí Lóòótọ́?

Ọ̀KAN lára ohun ìjọsìn táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó ni àgbélébùú. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń bọ̀wọ̀ fún un torí wọn kà á sí ohun mímọ́ tí wọ́n kan Jésù mọ́. Òǹkọ̀wé onísìn Roman Kátólíìkì tó tún jẹ́ awalẹ̀pìtàn nì, Adolphe-Napoleon Didron, sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé, ọ̀wọ̀ kan náà táwọn èèyàn ń fún Kristi ni wọ́n ń fún àgbélébùú; kódà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sì ìyàtọ̀ nínú báwọn èèyàn ṣe ń jọ́sìn Ọlọ́run Fúnra Rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn igi mímọ́ yìí.”

Àwọn kan sọ pé ṣe ní àgbélébùú máa ń jẹ́ káwọn túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run lásìkò táwọn bá ń gbàdúrà. Àwọn mìíràn ń lò ó bí àjẹsára, lérò pé yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ aburú. Ṣùgbọ́n ṣó yẹ káwọn Kristẹni máa lo àgbélébùú bí ohun ìjọsìn? Àní, ṣé lóòótọ́ ni pé orí àgbélébùú ni Jésù kú sí? Kí ni Bíbélì fi kọ́ni lórí kókó yìí?

Kí Ni Wọ́n Ń Lo Àgbélébùú Fún?

Láìmọye ọdún kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé làwọn ará Bábílónì ìgbàanì ti ń lo àgbélébùú láti jọ́sìn ọlọ́run ìbímọlémọ, ìyẹn Támúsì. Lílo àgbélébùú tàn kálẹ̀ dé Íjíbítì, Íńdíà, Síríà àti Ṣáínà. Ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ìjọsìn ọlọ́run èké náà, Támúsì wọnú ìjọsìn Jèhófà. Bíbélì sì sọ pé ‘ohun ìṣe-họ̀ọ́-sí’ nirú ìjọsìn bẹ́ẹ̀.—Ìsíkíẹ́lì 8:13, 14.

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà stau·rosʹ ni àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà, Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù lò nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n kan Jésù mọ́. (Mátíù 27:40; Máàkù 15:30; Lúùkù 23:26) Ọ̀rọ̀ náà stau·rosʹ tọ́ka sí igi tó wà ní ìnàró ṣánṣán tàbí òpó. Ọ̀gbẹ́ni J. D. Parsons sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní, The Non-Christian Cross, pé: “Kò sí gbólóhùn èyíkéyìí nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ àwọn ìwé tó para pọ̀ di Májẹ̀mú Tuntun tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé stauros tí wọ́n kan Jésù mọ́ yàtọ̀ sí stauros tí gbogbo ayé mọ̀; ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ bí kò ṣe sí ẹ̀rí pé stauros náà jẹ́ igi méjì tí wọ́n kàn mọ́ ara wọn bí àgbélébùú.”

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Ìṣe 5:30, àpọ́sítélì Pétérù lo ọ̀rọ̀ náà xyʹlon tó túmọ̀ sí “igi,” èyí tó jẹ́ ọ̀rọ̀ míì tí wọ́n máa ń pe stau·rosʹ, ìyẹn ò sì túmọ̀ sí òpó méjì tó dábùú ara wọn bí kò ṣe ẹyọ igi kan ṣoṣo tó dúró ṣánṣán. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀ọ́dúnrún ọdún lẹ́yìn ikú Jésù káwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni kan tó bẹ̀rẹ̀ sí tan èrò náà kálẹ̀ pé orí igi méjì tó dábùú ara wọn ni wọ́n kan Jésù mọ́. Ṣùgbọ́n, àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ló mú wọn ní irú èrò yìí, kò sì tún ṣẹ̀yìn bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà stau·rosʹ nílòkulò. A ò wá ní gbójú fò ó dá pé àwọn àwòrán ayé ìgbàanì kan ṣàfihàn igi tàbí òpó kan ṣoṣo dípò àgbélébùú gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn ará Róòmù máa ń lò láti fi pani.

“Ẹ Máa Ṣọ́ra fún Àwọn Òrìṣà”

Ohun tó tún ṣe pàtàkì táwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ kíyè sí ni bóyá ó bójú mu láti máa jọ́sìn ohun tí wọ́n fi pa Jésù. Kódà kó jẹ́ òpó igi ìdálóró tó tọ́ sangbọndan, àgbélébùú, ọfà, aṣóró, tàbí ọ̀bẹ ni wọ́n fi pa Jésù, ṣó yẹ ká máa jọ́sìn irú nǹkan bẹ́ẹ̀?

Jẹ́ ká sọ pé ilé ẹjọ́ rí ohun ìjà táwọn kan fi pa èèyàn rẹ kan gbà lọ́wọ́ àwọn tó ṣiṣẹ́ ibi náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí. Ṣé wàá gba ohun ìjà yẹn dání láti ya fọ́tò rẹ̀ kó o sì ṣe ẹ̀dà rẹ̀ rẹpẹtẹ kó o lè máa pín in káàkiri? Ṣé wàá ṣe onírúurú ohun ìjà yẹn jáde gan-an bó ṣe rí? Ṣé wàá wá fi díẹ̀ lára àwọn ohun ìjà yẹn ṣe ohun ọ̀ṣọ́? Tàbí kẹ̀, ṣé wàá bẹ ilé iṣẹ́ kan lọ́wẹ̀ pé kí wọ́n ṣe é jáde lọ́pọ̀ kó o lè máa tà á fún tẹbí tọ̀rẹ́ kí wọ́n lè máa jọ́sìn rẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó o máà fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀! Àmọ́, àwọn ohun tá a sọ yìí làwọn èèyàn ń fi àgbélébùú ṣe!

Yàtọ̀ síyẹn, lílo àgbélébùú nínú ìjọsìn kò yàtọ̀ sígbà téèyàn ń jọ́sìn ère, èyí tí Bíbélì kà léèwọ̀. (Ẹ́kísódù 20:2-5; Diutarónómì 4:25, 26) Àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tòótọ́ tí ẹ̀sìn Kristẹni fi kọ́ni ṣe kedere nínú ìmọ̀ràn tó gba àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.” (1 Jòhánù 5:21) Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́, kódà nígbà tí ìyẹn yọrí sí ikú látọwọ́ ìjọba Róòmù ní gbàgede ìwòran orílẹ̀-èdè náà.

Àmọ́, ojú pàtàkì làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi wo ikú ìrúbọ Kristi. Bákan náà, lóde òní, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tẹ́nikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn ni ohun tí wọ́n kan Jésù mọ́ títí tó fi joró kú, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń ṣèrántí ikú Jésù gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà lànà ìgbàlà sílẹ̀ fáwọn ẹ̀dá èèyàn aláìpé. (Mátíù 20:28) Ìbùkún tí kò ṣeé fẹnu sọ làwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ máa gbádùn látàrí ìfẹ́ títayọlọ́lá tí Ọlọ́run fi hàn sí wa. Lára rẹ̀ ni ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 17:3; Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àwòrán ìgbàaní tá à ń wò yìí jẹ́ ká rí i pé igi tàbí òpó kan ṣoṣo làwọn ará Róòmù máa ń lò láti fi pa ọ̀daràn

[Credit Line]

Rare Books Division, The New York Public Library, Astor, Lenox and Tilden Foundations

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́