ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/07 ojú ìwé 12-14
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Àṣà Búburú Yìí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Àṣà Búburú Yìí?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Ṣe bí Ọkàn Ẹ Bá Ń Dá Ẹ Lẹ́bi
  • Àǹfààní Tó Wà Nínú Fífinú Han Ẹnì Kan
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Mi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbọ́kàn Mi Kúrò Lórí Ìbálòpọ̀?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Rẹ
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Mímọ́ Lójú Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Jí!—2007
g 1/07 ojú ìwé 12-14

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Àṣà Búburú Yìí?

“Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mí tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ mi. Ìgbà tí mo wá mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ọ̀ràn náà, inú mi kì í dùn ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń dáṣà yìí. Mo máa ń bi ara mi pé, ‘Ṣé inú Ọlọ́run á sì máa dùn sírú èmi yìí?’ Ohun kan tí mo mọ̀ ni pé mi ò ní lè wọnú ayé tuntun.”—Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Luiz.a

BÍI ti Luiz, ó ṣeé ṣe kí fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ti wọ ìwọ náà lẹ́wù. O ò sì ṣàìmọ̀ pé inú Jèhófà á dùn sí ẹ bo o bá lè jáwọ́ nínú àṣà yìí tó o sì lo ìkóra-ẹni-níjàánu, èyí tó jẹ́ èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Gálátíà 5:22, 23; 2 Pétérù 1:5, 6) Àmọ́, ó ṣì máa ń ṣe é lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ní gbogbo ìgbà tó o bá sì ti tún ṣe é, èrò tó máa ń wá sí ẹ lọ́kàn ni pé kò sí bó o ṣe lè jáwọ́, pé kò lè ṣeé ṣe láti pa gbogbo ìlànà òdodo Ọlọ́run mọ́.

Ohun tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Pedro ń rò gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ó ní: “Ṣe ni ìbànújẹ́ máa ń bá mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá tún ṣe é. Mo máa ń rò pé kò sí ohun tí mo lè ṣe tí Ọlọ́run á fi dárí ẹ̀ jì mí. Àtigbàdúrà gan-an wá dogun fún mi. Bí mo ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ àdúrà mi ni pé: ‘Jèhófà, mi ò mọ̀ bóyá wàá gbọ́ àdúrà yìí o, àmọ́ . . . ’” Irú èrò kan náà yìí ló wà lọ́kàn ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ André. Ó ní: “Mo máa ń rí ara mi bí alágàbàgebè. Ekukáká ni mo fi máa ń lè dìde kúrò lórí ibùsùn láràárọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Kì í rọrùn fún mi láti lọ sí ìpàdé tàbí láti kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá.”

Ṣe ni kó o fọkàn balẹ̀ bó bá ń ṣe ẹ bó ṣe ṣe Luiz, Pedro, tàbí André. Ìwọ nìkan kọ́ ló ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò sì tíì kọjá àtúnṣe! Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́, tó fi mọ́ àwọn àgbàlagbà pàápàá, ni wọ́n ti bá àṣà fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ yí ṣùgbọ́n tí wọ́n pàpà jáwọ́ nínú ẹ̀. Ó dájú pé ìwọ náà lè jáwọ́.b

Ohun Tó O Lè Ṣe bí Ọkàn Ẹ Bá Ń Dá Ẹ Lẹ́bi

Bá a ṣe sọ ṣáájú, ọkàn àwọn tó máa ń fi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ sábà máa ń dá wọn lẹ́bi. Ó dájú pé, bí àṣà yìí bá ń mú ọ ‘banú jẹ́ lọ́nà ti Ọlọ́run,’ wàá lè ṣara gírí láti borí ẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 7:11) Ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ náà ò gbọ́dọ̀ pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ kó má bàa ṣàkóbá. Àkóbá tó lè ṣe ni pé ó lè kó ìdààmú bá ẹ débi tí wàá fi jọ̀gọnù.—Òwe 24:10.

Nítorí náà, ṣe ni kó o mọ bó ṣe jẹ́ gan-an. Ọ̀kan lára ìwà àìmọ́ ni fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ. Ó lè sọ ẹ́ ‘dẹrú fún oríṣiríṣi ìfẹ́ ọkàn àti adùn,’ ó sì lè súnná sí àwọn ìwà tó lè sọ ìrònú èèyàn dìdàkudà. (Títù 3:3) Síbẹ̀, fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ kì í ṣe ọ̀kan lára ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ tó burú jáì bí àgbèrè. (Éfésù 4:19) Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé bí fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ bá ti di ìṣòro fún ẹ, kò sídìí fún ẹ láti máa rò pó o ti dẹ́ṣẹ̀ tí ò ní ìdáríjì. Àṣírí ibẹ̀ ni pé kó o má gbà fún un tó bá ti ń wù ẹ́ ṣe, kó o má sì ṣe juwọ́ sílẹ̀ láé!

Láwọn ìgbà míì, ó rọrùn láti sorí kọ́ lẹ́yìn téèyàn bá tún ṣe é. Nígbà tíyẹn bá wáyé, má ṣe gbà gbé ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 24:16, tó sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú; ṣùgbọ́n àwọn ẹni burúkú ni a óò mú kọsẹ̀ nípasẹ̀ ìyọnu àjálù.” Torí pé o padà tún ṣe é ò túmọ̀ sí pé o ti dèèyàn burúkú. Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o fẹ̀sọ̀ ronú lé ohun tó mú kó o padà sídìí ẹ̀ kó o sì gbìyànjú láti rí i pé o ò tún ṣe nǹkan yẹn mọ́.

Dípò tí wàá fi jẹ́ kí ìṣòro yìí mú kó o máa sọ ohun tí ò yẹ síra ẹ, ṣe ni kó o máa ṣàṣàrò nípa ìfẹ́ àti àánú Ọlọ́run. Onísáàmù nì, Dáfídì, tóun náà ti ṣàṣìṣe rí, sọ pé: “Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, Ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:13, 14) Ó dájú pé Jèhófà máa ń ro ti àìpé mọ́ wa lára ó sì “ṣe tán láti dárí jini” nígbà tá a bá ṣẹ̀. (Sáàmù 86:5) Síbẹ̀, ó fẹ́ ká sapá láti ṣàtúnṣe.

Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ṣe kó o bàa lè gba ara ẹ lọ́wọ́ àṣà yìí, kó o má sì tún ṣe é mọ́?

Àǹfààní Tó Wà Nínú Fífinú Han Ẹnì Kan

Láìka bí ọ̀rọ̀ nípa ìbálópọ̀ ṣe gbòde kan lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè sí, kì í rọrùn fáwọn èèyàn kan láti sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ lọ́nà tó bétí mu. Ó lè jẹ́ pé ìtìjú ló mú kó nira fún ẹ láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ kódà fún ẹni tó o rò pé ó yẹ kó o finú hàn. Kristẹni kan tó tó bí ọdún mélòó kan tó fi sapá láti jáwọ́ nínú àṣà fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ sọ pé: “Ká ni mo mọ̀ ni, ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́ ni mi ò bá ti gbé ìtìjú tà tí ǹ bá sì ti sọ fẹ́nì kan! Ọ̀pọ̀ọdún ni ẹ̀rí ọkàn mi fi dà mí láàmú, kékeré sì kọ́ ni àkóbá tó ṣe fún àjọṣe èmi àtàwọn ẹlòmíì, èyí tó tiẹ̀ burú jù ni bó ṣe kó bá àjọṣe èmi àti Jèhófà.”

Ta ló yẹ kó o sọ fún? Ẹni tó dáa jù lẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ dáadáa, ó dáa jù kẹ́ni náà jẹ́ òbí. O lè bẹ̀rẹ̀ báyìí: “Ẹ jọ̀ọ́ mo ní ìṣòro kan tó ń dà mí láàmù, ǹjẹ́ mo lè fi tó yín létí?”

Mário pinnu láti sọ fún bàbá ẹ̀. Nígbà tí bàbá yìí sì gbọ́ ohun tọ́mọ ẹ̀ sọ, ó káàánú púpọ̀, ọ̀rọ̀ ọ̀hún sì yé e dáadáa. Ó jẹ́ kí Mário mọ̀ pé òun alára níṣòro náà nígbà tóun wà lọ́dọ̀ọ́. Mário ni: “Ìṣírí ńlá ni òótọ́ inú àti àìṣẹ̀tàn bàbá mi jẹ́ fún mi. Mo pinnu pé bí bàbá mi bá lè jáwọ́ nínú àṣà náà, a jẹ́ pé èmi náà lè jáwọ́ nìyẹn. Ànímọ́ bàbá mi wú mi lórí débi tí mi ò fi mọ̀gbà tí mo bú sẹ́kún.”

André náà ṣọkàn akin, ó fi tó Kristẹni alàgbà kan létí, inú rẹ̀ sì dùn pé òun ṣe bẹ́ẹ̀.c Ó ní: “Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yẹn lọ, ṣe ni ojú alàgbà yẹn lé ròrò fómijé. Nígbà tí mo gúnlẹ̀, ó jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi. Ó ní ìṣòro tó wọ́pọ̀ ni ìṣòro tí mo ní. Ó ní kí ń máa fi bí nǹkan bá ṣe ń lọ sí fún mi lórí ọ̀ràn náà tó òun létí, ó sì ṣèlérí pé òun á bá mi mú àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa wá. Lẹ́yìn tí mo ti sọ fún un, mo pinnu láti rí i pé èmi ni màá borí, kódà bó bá ń wá sí mi lọ́kàn jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

Bíi ti Mário àti André, ìrànlọ́wọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó fúnwọ náà bó o ṣe ń sapá láti jáwọ́ nínú àṣà fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ. Tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú àpótí náà “Má Gbà fún Un!” Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé wàá borí!

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin nìkan làwọn tá a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ló ń tiraka láti lè jáwọ́ nínú fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ. Nítorí náà, tọkùnrin tobìnrin ni ìmọ̀ràn yìí wà fún. Tún rántí pé ohun tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé ni fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ara ẹni. Fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì tí kì í ṣe ẹni téèyàn bá ṣègbéyàwó wà lára ohun tí Bíbélì pè ní àgbèrè, ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì lójú Ọlọ́run sì ni.—Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Ní Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?” bó ṣe wà nínú ìtẹ̀jáde wa ti August 8, 2004, ojú ìwé 14 sí 16.

c Ọ̀dọ́bìnrin kan lè sọ fún mọ́mì ẹ̀ tàbí arábìnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ nínú ìjọ.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa rántí pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini”?—Sáàmù 86:5.

◼ Àwọn nǹkan wo lo máa ṣe kó o bàa lè borí àṣà fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ?

◼ Kí nìdí tí ò fi yẹ kó o jẹ́ kí ìtìjú dí ẹ lọ́wọ́ àtiwá ìrànlọ́wọ́?

◼ Ọ̀nà tó dáa jù wo lo lè gbà mú kó jẹ́ pé àwọn nǹkan tó bójú mu nìkan ni wàá máa ronú lé lórí?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Pé O Tún Ṣe É Kò Túmọ̀ Sí Pé Ọ̀rọ̀ Ẹ Ti Kọjá Àtúnṣe!

Ó rọrùn púpọ̀ láti rò pé: ‘Kò sí ohun tí mo lè ṣe sí í mọ́ o jàre, bóyá kí n kúkú gba kámú.’ Má ṣe gba irú èrò yẹn láàyè láé. Má ṣe gbà kí títún tó o tún ṣe é fúngbà díẹ̀ tàbí fúngbà mélòó kan mú kó o rẹ̀wẹ̀sì.

Ìwọ gbé àpèjúwe yìí yẹ̀ wò ná: Ká ní o fẹsẹ̀ kọ nígbà tó ò ń rìn lórí àtẹ̀gùn lọ sókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì tí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ bọ́ sórí àtẹ̀gùn kan tàbí méjì lẹ́yìn, ṣé wàá pinnu pé, ‘Mo ni láti padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá kí n sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀’? Ó dájú pó ò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Kí ló wá dé tí wàá ṣerú ìpinnu yẹn nínú ọ̀rọ̀ jíjáwọ́ nínú àṣà burúkú yìí?

Ẹ̀rí ọkàn sábà máa ń da èèyàn láàmú lẹ́yìn téèyàn bá tún ṣe é. Àmọ́, kò ní dáa tó o bá wáá lọ gbé e karí ju bó ṣe yẹ lọ nípa ríronú pé o ò já mọ́ ohunkóhun, pé o ò lágbára láti borí àṣà náà àti pé o ò tọ́ sẹ́ni tó yẹ kí wọ́n fojú èèyàn gidi wo. Má ṣe gba irú ìdálẹ́bi tó pàpọ̀jù bẹ́ẹ̀ láyè. Ṣe ló máa tán ẹ lókun tó yẹ kó o fi jàjàbọ́. Sì máa rántí pé: Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni Jésù Kristi tó jẹ́ ọkùnrin títóbi jù lọ tó tíì gbé láyé rí wáá rà padà kì í ṣe àwọn tí kì í dẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó lè ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tó pé pérépéré lákòókò tá a wà yìí.—Látinú Jí!, April 8, 1991, ojú ìwé 15.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Má Gbà fún Un!

◼ Gbé ìrònú ẹ lọ sórí àwọn nǹkan míì.—Fílípì 4:8.

◼ Yé wo àwọn ohun táá mú kó o máa ro ìròkurò.—Sáàmù 119:37.

◼ Gbàdúrà fún “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”—2 Kọ́ríńtì 4:7.

◼ Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ dí lẹ́nu àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni.—1 Kọ́ríńtì 15:58.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ìrànlọ́wọ́ Síwájú Sí I

Fún àlàyé síwájú sí i lórí béèyàn ṣe lè jáwọ́ nínú fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ, wo orí 25 àti 26 nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè . . . Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, èyí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́