Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Ìgbà Wo Ló Yẹ Kí N Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Bá Ẹni Tí Kì Í Ṣe Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Bíi Tèmi Jáde?
“Tó o bá délé ìwé, á dà bíi pé ìwọ nìkan lo ò kì í ṣe èèyàn gidi tó ò bá tí ì lẹ́nì kan tẹ́ ẹ jọ ń bára yín jáde—ẹni yòówù tí ì báà jẹ́!”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Brittany.
“Àwọn nǹkan tó ń jẹ́ kó máa wù mí gan-an láti wá ọkùnrin tá a ó jọ máa bára wa jáde pọ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ọmọkùnrin tó rẹwà pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Whitney.
◼ Ò ń wo ọmọkùnrin kan àti ọmọbìnrin kan tí wọ́n fara wọn lọ́wọ́ tí wọ́n jọ ń rìn lọ nígbà tẹ́ ẹ parí iṣẹ́ kan níléèwé. Báwo ló ṣe rí lára ẹ?
□ Kò kàn mí
□ Á máa wù mí díẹ̀díẹ̀
□ Màá jowú wọn
◼ Ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ wà níbi tẹ́ ẹ ti ń wo sinimá lo bá dédé rí i pé gbogbo obìnrin àárín yín ló bá ọkùnrin wá, gbogbo ọkùnrin àárín yín ló sì bá obìnrin wá àfìwọ nìkan! Báwo ló ṣe rí lára ẹ?
□ Kò kàn mí
□ Á máa wù mí díẹ̀díẹ̀
□ Màá jowú wọn
◼ Ká sọ pé obìnrin ni ẹ́, ọ̀rẹ́ ẹ kan bẹ̀rẹ̀ sí í fa ojú ọmọkùnrin kan mọ́ra láìpẹ́ yìí, àwọn méjèèjì sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jáde. Báwo ló ṣe rí lára ẹ?
□ Kò kàn mí
□ Á máa wù mí díẹ̀díẹ̀
□ Màá jowú wọn
Tó bá jẹ́ pé “á máa wu mí díẹ̀díẹ̀” lo sàmì sí nígbà tó ò ń dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí, ìwọ nìkan kọ́ ló ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ilẹ̀ kan wà táwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin ti máa ń bára wọn jáde. Láwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa dáhùn pé á máa wu àwọn díẹ̀díẹ̀. Yvette, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá sọ pé: “Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ó ku nǹkan kan tọ́wọ́ ẹ ò tíì bà torí pé gbogbo ẹgbẹ́ ẹ ló ní ọ̀rẹ́kùnrin tíwọ ò sì ní.”
Tó o bá lẹ́ni tó o kà sí pàtàkì, tóun náà sì kà ẹ́ sí pàtàkì, ṣe láá máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o máa wà lọ́dọ̀ ẹni náà ní gbogbo ìgbà. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún sọ pé: “Ojoojúmọ́ ló máa ń ṣe mí bíi pé kí n ní ọ̀rẹ́bìnrin, èrò yẹn kì í sì í kúrò lọ́kàn mi bọ̀rọ̀!” Àwọn kan ò ju pínníṣín báyìí lọ ti wọ́n ti lẹ́ni tí wọ́n ń bá jáde. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Time ṣèwádìí kan tó fi hàn pé ìdámẹ́rin àwọn ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni wọ́n ti ní “ẹni tí wọ́n jọ ń jáde.” Ṣó o rò pé wọ́n ti tẹ́ni tó yẹ kó máa ṣèyẹn? Ṣé àkókò ti tó fún ìwọ náà láti ní ẹni tó yẹ kó o máa bá jáde? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yìí, ó yẹ ká kọ́kọ́ dáhùn ìbéèrè pàtàkì kan.
Kí Ní ‘Bíbára Ẹni Jáde’ Túmọ̀ Sí?
◼ Lemọ́lemọ́ ni ìwọ àtẹni kan tí kì í ṣe ọkùnrin bíi tiẹ̀ jọ máa ń jáde.
Ṣé bíbá èèyàn jáde ti bẹ̀rẹ̀ náà nìyẹn? □ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ́
◼ Ọ̀rẹ́ ẹ kan wà tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà lóòjọ́ lo máa ń fi fóònù alágbèéká kọ̀wé ránṣẹ́ sí i tàbí kó o fi pè é.
Ṣé bíbá èèyàn jáde ti bẹ̀rẹ̀ náà nìyẹn? □ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ́
◼ Ìwọ àtẹnì kan tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ jọ ń ṣọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀. Àwọn òbí ẹ ò mọ̀ nípa ẹ̀. O ò tíì sọ fún wọn torí o mọ̀ pé wọn ò ní fọwọ́ sí i.
Ṣé bíbá èèyàn jáde ti bẹ̀rẹ̀ náà nìyẹn? □ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ́
◼ Gbogbo ìgbà tó o bá wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ ẹ, o ò lẹ́ni méjì tó máa ń wù ẹ́ láti bá tò ju ẹni kan báyìí ṣáá tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ.
Ṣé bíbá èèyàn jáde ti bẹ̀rẹ̀ náà nìyẹn? □ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ́
Ó lè má ṣòro fún ẹ láti dáhùn ìbéèrè àkọ́kọ́ yẹn, àmọ́ o lè ní láti dúró díẹ̀ kó o tó lè dáhùn àwọn tó kù. Ohun wo gan-an la wá lè sọ pé bíbá ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni jáde jẹ́? Nínú ìjíròrò yìí, a ó pè é ní àjọṣe kan tó wà láàárín ìwọ àtẹni kan pàtó, tó jẹ́ pé ẹni náà ń dá ẹ lọ́rùn tó tún jẹ́ pé ìwọ nìkan ṣoṣo lò ń dá a lọ́rùn. Ó lè jẹ́ nígbà tẹ́ ẹ bá wà láàárín àwọn míì tàbí lẹ́yin nìkan, ó lè jẹ́ lórí fóònù tàbí lójúkojú, ó lè jẹ́ ní gbangba tàbí ní kọ̀rọ̀ tó bá fi lè jẹ́ pé ìwọ àtẹni náà jọ ní ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ síra yín, bíbára ẹni jáde ti fẹ́ wọ̀ ọ́ nìyẹn o.
Àmọ́ ṣó yẹ kó o dáwọ́ lé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lásìkò yìí? Lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò ìbéèrè mẹ́ta yìí, wàá lè mọ̀ bó bá yẹ bẹ́ẹ̀ tàbí kò yẹ bẹ́ẹ̀.
Kí Lo Ní Lọ́kàn?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni àṣà ìlú wọn ò ka bíbá ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn jáde léèwọ̀. Ṣe ni wọ́n kà á sí ọ̀nà tẹ́ni méjì lè gbà mọwọ́ ara wọn. Ìdí pàtàkì kan ṣoṣo tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tó fi yẹ kí ọkùnrin àti obìnrin máa bára wọn jáde ni láti lè fi mọ̀ bóyá àwọn méjèèjì yẹ lẹ́ni tó lè fẹ́ra kí ìgbéyàwó wọn sì ládùn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
Bíbélì fi ọ̀rọ̀ náà “ìgbà ìtànná òdòdó èwe” ṣàpèjúwe ìgbà tí òòfà ìfẹ́ ìbálòpọ̀ máa ń lágbára lọ́kàn èèyàn. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Tó o bá wá ń bá ẹnì kan tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ jáde lásìkò tó o ṣì wà ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” ó lè mú kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lágbára lọ́kàn ẹ kó sì mú kó o jẹ̀ka àbámọ̀ nígbà tó o bá ṣe nǹkan táá já jó ẹ lójú gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Gálátíà 6:7 pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.”
Lóòótọ́ o, àwọn ojúgbà ẹ kan lè máa bá ẹlòmíì jáde láìní in lọ́kàn láti ṣègbéyàwó. Ó lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n ń wo níní táwọn ni ọ̀rẹ́bìnrin tàbí ọ̀rẹ́kùnrin gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń fi hàn pé àwọn ti tóó ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe tàbí kí wọ́n máa wò ó bí ẹni àbágbafẹ́ tó lè mú káwọn èèyàn máa ka àwọn sí ẹni pàtàkì. Ìwà ìkà ni pé kéèyàn jẹ́ kí ọkàn ẹlòmíì máa fà sí òun tó sì jẹ́ pé eré ló fi ń ṣe, abájọ tọ́rọ̀ àwọn méjì bẹ́ẹ̀ kì í fi í pẹ́ kó tó dà rú. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Heather sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń ya ara wọn lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jáde. “Wọ́n á wá máa wo àjọṣe wọn bí èyí táwọn lè pa tì nígbà tó bá wù wọ́n, wọ́n á wá tipa bẹ́ẹ̀ máa fi ìkọ̀sílẹ̀ kọ́ra dípò kí wọ́n fi irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó.”
Téèyàn bá ń bá ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ jáde láti fi ṣe ṣeréṣeré tàbí torí pé èèyàn kàn fẹ́ ní ọ̀rẹ́kùnrin tàbí ọ̀rẹ́bìnrin, ó lè mú kéèyàn ba ẹlòmíì lọ́kàn jẹ́. Wo àpẹẹrẹ ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Eric. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún ó ń bá ọmọbìnrin kan ṣe ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, eré ló sì rò pé àwọn jọ ń ṣe lójú ara ẹ̀. Nígbà tó yá ló rí i pé nǹkan míì ti ń wọ ọ̀rọ̀ àárín àwọn. Eric sọ pé: “Káì! Ó yà mí lẹ́nu nígbà tí mo rí i tó ti yáa gba ọ̀rọ̀ ọ̀hún sóòótọ́. Ọ̀rẹ́ lásán lèmi rò pé a jọ ń ṣe o!”
Kì í ṣe pó burú kó o máa wà pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ níbi tójú àwọn ẹlòmíràn ti lè máa tó yín o. Àmọ́, tó bá dọ̀rọ̀ kó o máa bá ẹnì kan jáde, ì bá dáa jù tó o bá dúró dìgbà tóo ti kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe, lákòókò tí wàá ti dẹni táá lè ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Ohun tí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Chelsea mọ̀ nìyẹn nígbà tó yá. Ó sọ pé: “Ọkàn kan ń sọ fún mi pé ọ̀rọ̀ eré lásán ni kémi àti ọmọkùnrin kan jọ máa bára wa jáde, àmọ́ kì í tún ṣe ọ̀rọ̀ eré mọ́ bí ẹni téèyàn ń bá ṣeré bá gbà á sí òótọ́ tí olùwá rẹ̀ ò sì rí i bẹ́ẹ̀.”
Ọmọ Ọdún Mélòó Ni Ẹ́?
◼ Ọmọ ọdún mélòó lo rò pé ó yẹ kí ọ̀dọ́ kan jẹ́ kó tó máa bá ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ jáde? ․․․․․․․․․․
◼ Wá béèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ àwọn òbí ẹ méjèèjì tàbí lọ́wọ́ ọ̀kan nínú wọ́n, kó o sì kọ ìdáhùn wọn síbí yìí. ․․․․․
Ó ṣeé ṣe kí ọjọ́ orí tí ìwọ rò pé ó yẹ kó o jẹ́ kéré sí èyí táwọn òbí ẹ kọ sílẹ̀. Ó sì lè máà rí bẹ́ẹ̀! O sì lè wà lára àwọn ọ̀dọ́ tó gbọ́n tí wọ́n fẹ́ kó dìgbà táwọn bá dàgbà tó táwọn á sì ti mọ ara àwọn díẹ̀ sí i káwọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹlòmíì jáde. Ohun tí ọ̀dọ́bìnrin kan nínú ìjọ tó ń jẹ́ Sondra ti pinnu láti ṣe nìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ orí ẹ̀ ti tó tẹni tí òfin sọ pé ó lè ṣègbéyàwó. Sondra sọ ohun tó ń rò, ó ní: “Ohun tó ń mú kéèyàn bá ẹlòmíì jáde ni pé kẹ́ni náà lè mọ irú ẹni téèyàn jẹ́. Àmọ́ béèyàn ò bá mọ ara ẹ, báwo ló ṣe fẹ́ kẹ́lòmíì mọ irú ẹni tóun jẹ́?”
Ohun tí ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan tó ń jẹ́ Danielle náà rò nìyẹn. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wo bó ṣe ń ṣe mí ní bí ọdún kan sẹ́yìn, mo rí i pé irú ẹni tí mi ò bá fẹ́ nígbà yẹn á yàtọ̀ sí irú ẹni táá wù mí láti fẹ́ ní báyìí. Nísinsìnyí gan-an, kò tíì dá mi lójú pé mo lè ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Nígbà tí mo bá tó dẹni tó níwà ọmọlúwàbí ni màá tó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú ẹni tí màá máa bá jáde.”
Ṣó O Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó?
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé téèyàn bá ti ń bá ẹlòmíì jáde, ó ti ń múra ìgbéyàwó nìyẹn, ì bá dáa kó o bi ara ẹ bóyá o ti ṣe tán láti bójú tó iṣẹ́ ọkọ tàbí ti baba tàbí ti aya tàbí ti ìyá. Báwo lo ṣe lè mọ̀ tó o bá ti tẹ́ni tó ń ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀? Kíyè sí ohun tó tẹ̀ lé e yìí.
◼ Àwọn ìbátan ẹ Báwo lo ṣe ń ṣe sáwọn òbí ẹ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ọmọ ìyá? Ṣé orí ẹ sábà máa ń gbóná sí wọn, bóyá tí wàá wá máa fi èdè tó le tàbí ọ̀rọ̀ rírùn sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ? Kí ni wọ́n lè sọ nípa ẹ lórí ọ̀ràn yìí? Bó o bá ṣe ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ lò á pinnu bí wàá ṣe máa ṣe sẹ́ni tó o bá fẹ́.—Éfésù 4:31, 32.
◼ Bó o ṣe ń náwó Báwo lo ṣe ń bójú tó owó ọwọ́ ẹ? Ṣé gbogbo ìgbà lo máa ń ní gbèsè lọ́rùn? Ṣé tó o bá ríṣẹ́ kì í tètè bọ́ lọ́wọ́ ẹ? Tí iṣẹ́ bá máa ń bọ́ lọ́wọ́ ẹ, kí ló máa ń fà á? Ṣé iṣẹ́ yẹn ò dáa tó ni àbí àwọn tó gbà ẹ́ síṣẹ́ ni ò ṣe ẹ́ dáadáa? Àbí ìwà ẹ kan ló ń mú kí iṣẹ́ máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ? Bó ò bá lè bójú tó owó ẹ bó ṣe yẹ, báwo lo ṣe máa lè bójú tó ìdílé ẹ?—1 Tímótì 5:8.
◼ Ipò tẹ̀mí Bó o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ànímọ́ tẹ̀mí wo lo ní? Ṣó o máa ń wáyè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣé kò dìgbà tí wọ́n bá tó ní kó o lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ kó o tó lọ, ṣé bẹ́ẹ̀ náà ni ti ìpàdé ìjọ? Tí o kì í bá fún ara ẹ lókun nípa tẹ̀mí, báwo lo ṣe lè fún ẹnì kejì nínú ìgbéyàwó lókun nípa tẹ̀mí?—2 Kọ́ríńtì 13:5.
Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó yẹ kó o gbé yẹ̀ wò rèé tó o bá ń ronú nípa àtimáa bá ẹnì kan jáde tó o sì tún ń ronú nípa ìgbéyàwó. Àmọ́ kó tó dìgbà tó o máa bẹ̀rẹ̀ èyí, kò sóhun tó burú nínú kó o wà pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ níbi tó bá ti bójú mu. Tó bá sì wá di ọjọ́ iwájú tó o bá fẹ́ máa bá ẹnì kan jáde, wàá ti mọ irú ẹni tó o jẹ́ àtirú ẹni tó wù ẹ́ láti fẹ́.
Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Wàá rí àlàyé púpọ̀ sí i lórí èyí lójú ìwé 13 sí 26 nínú ìwé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde yìí.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé. . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Ibo ló máa bójú mu fún ẹ láti wà pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ?
◼ Àwọn ànímọ́ wo ló ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ kó o ní, kó o bàa lè dẹni tó yẹ láti fi ṣe ọkọ tàbí aya?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ohun Táwọn Ojúgbà Ẹ Kan Sọ
“Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé àwọn tó ń bá ara wọn jáde yẹn ń gbádùn jù mí lọ, mo tiẹ̀ máa ń jowú àwọn tó ti gbéyàwó pàápàá. Àmọ́ ọ̀rọ̀ eré kọ́ lọ̀rọ̀ kí ọkùnrin àti obìnrin máa bára wọn jáde. Bó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ eré lo kà á sí, ọ̀rọ̀ tó wà lórí ẹ̀mí ẹlòmíì lo fi ń ṣeré yẹn o. Mo rò pé ohun tí bíbá ẹlòmíì jáde wà fún ni láti fi wò ó wò bóyá ẹ̀yin méjèèjì á lè di tọkọtaya.”—Blaine, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún.
“Èmi ò rò pó yẹ kó o máa bá àwọn ọmọkùnrin kan jáde láti fi ‘dánra wò’ títí dìgbà tó o máa rẹ́ni tó wù ẹ́. Ẹ lè tibẹ̀ ṣẹra yín.”—Chelsea, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún.
“Lójú tèmi ó dà bíi pé o yẹ kó o dàgbà tẹ́ni tó ń gbéyàwó kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹnì kan jáde. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa dà bíi pé o lọ síbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nígbà tó o ṣì wà níléèwé tó ò tíì ráàyè gbaṣẹ́.”—Sondra, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]
OHUN KAN TÓ YẸ KÁWỌN ÒBÍ KÍYÈ SÍ
Ó dájú pé bópẹ́ bóyá wọ́n ń bọ̀ wá máa ké sáwọn ọmọ tìẹ náà pé kí wọ́n jẹ́ káwọn jọ máa jáde. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Phillip sọ pé: “Jẹ́jẹ́ ara mi ni mo wà! Ṣe làwọn ọmọbìnrin máa ń wá bá mi pé ká jọ máa jáde tí màá sì dúró síbẹ̀ tí màá máa ronú pé ‘Kí ni kí n wá ṣe báyìí o?’ Ó ṣòro fún mi láti sọ pé mi ò ṣe torí pé òrékelẹ́wà làwọn kan lára wọn.”
Ohun tó dáa jù tíwọ gẹ́gẹ́ bí òbí lè ṣe ni pé bó o bá lọ́mọ tí kò tíì pé ogún ọdún, kó o máa bá a sọ̀rọ̀ nípa bíbá ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ jáde. O ò ṣe kúkú lo àpilẹ̀kọ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun tó o fi máa jíròrò kókó náà? Béèrè ohun tí ọmọkùnrin ẹ tàbí ọmọbìnrin ẹ ń rò nípa àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ ọ́ níléèwé àti nínú ìjọ Kristẹni pàápàá. Nígbà míì o lè dá ìjíròrò náà sílẹ̀ láìṣe pé o dìídì pè é pé ọ̀rọ̀ wà, bíi “nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà.” (Diutarónómì 6:6, 7) Ìgbà yòówù kó o dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀, rántí pé ó yẹ kó o “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”—Jákọ́bù 1:19.
Tọ́mọ ẹ bá sọ pé ẹnì kan tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ wu òun, máà jẹ́ kó já ẹ láyà. Ọmọbìnrin kan tí kò tíì pé ogún ọdún sọ pé: “Nígbà tí dádì mi mọ̀ pé mo ti ní ọ̀rẹ́kùnrin, wọ́n fara ya! Wọ́n fẹ́ máa fàwọn ìbéèrè irọ́ kan halẹ̀ mọ́ mi, wọ́n lọ ń bi mí bóyá mo ti ṣe tán láti ṣègbéyàwó, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ṣe làwọn ìbéèrè yẹn máa ń mú káwa ọmọdé fẹ́ máa bá irú ìfẹ́ yẹn lọ láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ yẹn ò yé àwọn òbí wa dáadáa!”
Tọ́mọ yín tí kò tíì pé ogún ọdún bá mọ̀ pé ẹ kì í sábàá sọ̀rọ̀ nípa kí ọkùnrin àti obìnrin máa bára wọn jáde, nǹkan míì tí ò dáa lè yí wọ̀ ọ́: Ó lè máa bá ẹnì kan jáde ní bòókẹ́lẹ́, tẹ́ ò sì ní mọ̀. Ọmọbìnrin kan sọ pé: “Táwọn òbí bá ti le mọ́ ọmọ jù, ṣe làwọn ọmọ á túbọ̀ fẹ́ má yọ́ ọ ṣe lábẹ́lẹ̀. Wọn ò ní jáwọ́ nínú ẹ̀. Wọ́n á túbọ̀ máa ṣe é ní bòókẹ́lẹ́ ni.”
Tó o bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nǹkan á túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Obìnrin kan tó jẹ́ ẹni ogún ọdún sọ pé: “Àwọn òbí mi kì í fi nǹkan kan pa mọ́ fún mi lórí ọ̀ràn bíbá ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tèmi jáde. Ó ṣe pàtàkì lójú wọn pé kí n jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tó wù mí, mo sì rò pé ìyẹn dáa! Bàbá mi á pe ẹni náà jókòó láti bá a sọ̀rọ̀. Bí ohunkóhun bá sì wà táwọn òbí mi á fẹ́ kí n mọ̀, wọ́n á sọ fún mi. Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo ti máa ń pinnu pé mi ò ṣe, kódà kó tó di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í bára wa jáde.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Kò burú bó o bá wà láàárín àwọn tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ níbi táwọn èèyàn pọ̀ sí, ó sì láǹfààní tiẹ̀