Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Bí Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Kan Bá Ní Kí N Jẹ́ Ká Jọ Gbéra Wa Sùn Ńkọ́?
“Àwọn ọ̀dọ́ máa ń fi ìbálòpọ̀ lọ ara wọn kí wọ́n lè mọ̀ bóyá á kúkú yọrí sí gbígbé ẹni tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ sùn, àti kí wọ́n lè mọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ mélòó làwọn á lè bá sùn.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Penny.a
“Àwọn ọkùnrin kì í fọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ bò. Wọ́n máa ń buragadó pé àwọn ní ọ̀rẹ́bìnrin, síbẹ̀ wọ́n ń bá ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin míì sùn.”—Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Edward.
“Àwọn tó ké sí mi pé kí n jẹ́ ká jọ máa gbéra wa sùn ò yọ́ ọ̀rọ̀ náà sọ rárá. Bó o bá sì sọ pó ò ṣe, ìyẹn ò ní kí wọ́n fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀!”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Ida.
LÁWỌN ilẹ̀ kan, tọkùnrin tobìnrin ló ń gbéra wọn sùn. Láwọn ibòmíì sì rèé, ọ̀tọ̀ lorúkọ tí wọ́n fi ń pe irú àṣà bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọmọdébìnrin kan tó ń jẹ́ Akiko lórílẹ̀-èdè Japan sọ pé àgbéròde làwọn ń pè é. Ó tún sọ pé “ọ̀rọ̀ míì táwọn máa ń lò ni sefre, tó túmọ̀ sí ‘ọ̀rẹ́ alábàásùn.’ Ìdí kan ṣoṣo tá a fi ń bára wa ṣọ̀rẹ́ ò ju torí àtibára wa sùn lọ.”
Orúkọ yòówù kí wọ́n máa pè é, ohun kan náà ni gbogbo ẹ̀ túmọ̀ sí, ìyẹn ìṣekúṣe lásán tí ò náni ní nǹkan kan.b Àwọn ọ̀dọ́ kan tiẹ̀ tún máa ń buragadó pé àwọn láwọn ọ̀rẹ́ táwọn jọ ka ara àwọn sí “àǹfààní àdúgbò.” Ohun tó da gbogbo wọn pọ̀ ò ju pé kí wọ́n máa bára wọn lò pọ̀, kí oníkálukú sì máa lọ nílọ ẹ̀ bí wọ́n bá ṣe tán. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sọ pé: “Gbígbéra ẹni sùn ò kọjá pé kéèyàn ṣáà ti tẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn lójú ẹsẹ̀. Bó o bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, ẹnu kó o máa bá tìẹ lọ ní.”
Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, o gbọ́dọ̀ “sá fún àgbèrè.”c (1 Kọ́ríńtì 6:18) Bóyá fífi tó o bá fi èyí sọ́kàn á lè jẹ́ kó o máa sapá láti yẹra fún àwọn ipò tó lè kó ẹ sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Àmọ́, láwọn ìgbà míì, ìṣòro lè tọ̀ ẹ́ wá. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Cindy sọ pé: “Nílé ìwé, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọkùnrin ni wọ́n ti dẹnu kọ mí pé kí n jẹ́ káwọn gbé mi sùn.” Irú ẹ̀ náà tún lè ṣẹlẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Margaret sọ pé: “Ọ̀gá mi níbi iṣẹ́ fi ìbálòpọ̀ lọ̀ mí. Ó ń yọ mí lẹ́nu débi pé ṣe ni mo ní láti fi iṣẹ́ sílẹ̀!”
Lọ́wọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu bí ara ẹ bá ń wà lọ́nà fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jeremáyà 17:9) Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Lourdes rí i pé òótọ́ gbáà nìyẹn. Òun náà sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ bọ̀bọ́ tó fẹ́ láti bá mi lò pọ̀ yẹn.” Bí ọ̀ràn ti Jane náà ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Ibẹ̀ lọkàn mi ń wà ṣáá ní gbogbo ìgbà. Àtisọ pé mi ò ṣe ni ọ̀kan lára ohun tó nira jù lọ tí mo tíì ṣe rí.” Edward, tá a fa ọ̀rọ̀ ẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí pẹ̀lú gbà pé kò rọrùn láti má ṣe lọ́wọ́ sírú ẹ̀. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin ló ti fi ìbálòpọ̀ lọ̀ mí, àtisọ pé mì o ṣe nítorí pé mo jẹ́ Kristẹni lohun tó tíì ṣòro jù fún mi. Kò rọrùn láti sọ pé mi ò ṣe!”
Bó bá ti ṣe ìwọ náà rí bíi ti Lourdes, Jane àti Edward àmọ́ tó o ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run, ó yẹ ká lù ọ́ lọ́gọ ẹnu pé o káre láé. Ara tiẹ̀ lè tù ẹ́ bó o bá mọ̀ pé irú èròkerò bẹ́ẹ̀ yọ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà lẹ́nu.—Róòmù 7:21-24.
Ìlànà inú Bíbélì wo lo ò gbọ́dọ̀ gbàgbé bí ẹnì kan bá ní kó o jẹ́ kí ìwọ àtòun jọ gbéra yín sùn?
Rí I Pé O Mọ Ìdí Tí Gbígbéra Ẹni Sùn Fi Burú
Bíbélì dẹ́bi fún bíbára ẹni lò pọ̀ láìṣe ìgbéyàwó. Àní àgbèrè jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ táwọn tó bá ń ṣe é ò fi ní “jogún ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Kó bàa lè ṣeé ṣe fún ẹ láti má ṣe lọ́wọ́ sí gbígbéra ẹni sùn, ojú tí Jèhófà fi ń wo àgbèrè ni ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa fi wò ó. Ìwà funfun ni kó o yàn láàyò.
“Ó dá mi lójú hán-únhán-ún pé ọ̀nà Jèhófà lọ̀nà tó dára jù lọ láti máa tọ̀.”—Karen, ọmọbìnrin kan láti orílẹ̀-èdè Kánádà.
“Béèyàn bá tìtorí àtitẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ́rùn fún ìṣẹ́jú díẹ̀, tó wá ré òfin Jèhófà nípa ìwà tó yẹ ká máa hù kọjá, ọ̀pọ̀ nǹkan lèèyàn máa pàdánù.”—Vivian, ọmọbìnrin kan láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.
“Rántí pé èèyàn ló bí ẹ o, o ní ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́rẹ̀ẹ́, ara ìjọ Ọlọ́run sì ni ẹ́. Gbogbo àwọn èèyàn yìí lo máa ṣẹ̀ bó o bá gba ìbálòpọ̀ láyè!”—Peter, láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.” (Éfésù 5:10) Bó o bá kórìíra àgbèrè bí Jèhófà ṣe kórìíra ẹ̀, á ṣeé ṣe fún ẹ láti “kórìíra ohun búburú,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máa wu ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ́ aláìpé.—Sáàmù 97:10.
◼ Ẹsẹ Bíbélì tá a dábàá pé kó o kà: Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9. Bó o ṣe ń kà á, kíyè sí ohun tó mú kí Jósẹ́fù fìgboyà dúró sórí ohun tó tọ́ nígbà tó dojú kọ ìdẹwò láti ṣàgbèrè àti ohun tí ò jẹ́ kó juwọ́ sílẹ̀.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohun Tó O Gbà Gbọ́ Tì Ẹ́ Lójú
Kì í ṣe ohun tí kò wọ́pọ̀ fáwọn ọ̀dọ́ láti dúró lórí òtítọ́ kí wọ́n sì gbèjà ìgbàgbọ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, àǹfààní ló jẹ́ fún ẹ láti máa gbèjà orúkọ Ọlọ́run nípa híhùwà ọmọlúwàbí. Má ṣe jẹ́ kójú tì ẹ́ nítorí pé o ò fi ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó báni dọ́rẹ̀ẹ́.
“Tètè jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o ò ní gbàgbàkugbà láyè.”—Allen, láti orílẹ̀-èdè Jámánì.
“Má máa ṣe mẹin-mẹin nípa ohun tó o gbà gbọ́.”—Esther, láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
“Bó o bá sọ pé, ‘Àwọn òbí mi ò ní jẹ́ kí n máa báa yín jáde,’ àwọn ojúgbà ẹ ò ní kà á sí pàtàkì pé lóòótọ́ lo ò nífẹ̀ẹ́ sọ́ràn gbígbéra ẹni sùn. O gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ojúgbà ẹ mọ̀ pé ìwọ gan-an lo ò fẹ́ láti máa bá wọn jáde.”—Janet, láti orílẹ̀-èdè South Africa.
“Àwọn ọmọkùnrin tá a jọ lọ sílé ẹ̀kọ́ girama mọ irú ẹni tí mo jẹ́, wọ́n sì mọ̀ pé pàbó ni gbogbo ìgbìdánwò wọ́n máa já sí.”—Vicky, ọmọbìnrin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Bó o bá dúró lórí ìgbàgbọ́ rẹ, ìyẹn ló máa fi hàn pé ìwọ náà ti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 14:20.
◼ Ẹsẹ Bíbélì tá a dábàá pé kó o kà: Òwe 27:11. Kíyè sí i pé ohun tó o bá hù níwà lè mú kó o gbèjà Ọlọ́run lórí ọ̀ràn kan tó kan gbogbo aráyé, ìyẹn ni ọ̀ràn sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́!
Dúró Gbọn-in!
Ó ṣe pàtàkì kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ò ní lọ́wọ́ sí ìwàkiwà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn míì lè rò pé ṣe lo wúlẹ̀ ń díbọ́n bó o bá sọ bẹ́ẹ̀.
“Ẹni tó fẹ́ kẹ́ ẹ jọ gbéra yín sùn lè máa ronú pé ṣe lòun ń gbé ẹ lẹ́mìí gbóná, pé wàhálà tó máa ṣòro fún ẹ láti dojú kọ lòun gbé síwájú ẹ, ìyẹn á sì mú kó túbọ̀ máa fínná mọ́ ẹ bóyá wàá jẹ́ gbà.”—Lauren, láti orílẹ̀-èdè Kánádà.
“Nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe, ì báà jẹ́ bó o ṣe ń múra ni o, bó o ṣe ń sọ̀rọ̀, ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ àti bó o ṣe ń báwọn èèyàn lò, o gbọ́dọ̀ fi hàn pé àyè à-ń-gbéra ẹni sùn ò yọ.”—Joy, láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
“Dúró lórí ìpinnu tó o ṣe láti má ṣe gbà, kó o sì jẹ́ kó ṣe kedere pé kò sáyè à-ń-gbéra ẹni sùn.”—Daniel, láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà.
“Má gbàgbàkugbà láyè! Nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin kan gbọ́wọ́ ẹ̀ lé mi lára tó wá ń sọ pé ṣe màá jẹ́ kóun gbé mi sùn, ṣe ni mo sọ fún un pé, ‘Ó pẹ́ kó o tó gbọ́wọ́ ẹ kúrò léjìká mi!’ mo tún kó o lójú mọ́lẹ̀, mo sì fibẹ̀ sílẹ̀.”—Ellen, láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
“Má ṣe gbojú bọ̀rọ̀, ṣe ni kó o sọ pé o ò ṣe àti pé o ò ní gba irú ẹ̀ láyè láé. Irú ìgbà yẹn kọ́ ló yẹ kéèyàn máa tijú akika!”—Jean, láti orílẹ̀-èdè Scotland.
“Ọmọkùnrin kan ò yé yọ̀ mi lẹ́nu ṣáá, bó ṣe ń fi ìbálòpọ̀ lọ̀ mí bẹ́ẹ̀ náà ló ń fi mí ṣẹlẹ́yà. Ìgbà tó yá lèmi náà bá sọ ojú abẹ níkòó fún un. Ìgbà yẹn gan-an ló sì tó fi mi lọ́rùn sílẹ̀.”—Juanita, láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.
“Ó yẹ kó o jẹ́ kó ṣe kedere pé o ò ní í gbarú ẹ̀ láyè. Má ṣe gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n bá ń wá bí wọ́n ṣe máa gbé ẹ sùn. Bó bá yá, wọ́n lè ní kó o wá pọ ohun tó o jẹ́ nípa bíbá àwọn lò pọ̀.”—Lara, láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o bá dúró ṣinṣin lórí òtítọ́. Látinú ìrírí tí Dáfídì, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù, fúnra rẹ̀ ní ó sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.”—Sáàmù 18:25.
◼ Ẹsẹ Bíbélì tá a dábàá pé kó o kà: 2 Kíróníkà 16:9. Kíyè sí bí Jèhófà kì í ṣe é jáfara láti ran àwọn tó ń fi tọkàntọkàn sìn ín lọ́wọ́.
Máa Ro Ìgbẹ̀yìn Ọ̀rọ̀
Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ara ẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn? Nípa ríro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ ni!
“Má máa bá àwọn tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kẹ́gbẹ́ lọ́nà èyíkéyìí.”—Naomi, láti orílẹ̀-èdè Japan.
“Máa sá fáwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ipò tó bá léwu. Bí àpẹẹrẹ, mo mọ àwọn kan tí wọ́n juwọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti mutí yó.”—Isha, láti orílẹ̀-èdè Brazil.
“Má máa sọ gbogbo nǹkan nípa ara ẹ fáwọn èèyàn, ìyẹn àwọn nǹkan bí àdírẹ́sì tàbí nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ.”—Diana, láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
“Má ṣe jẹ́ kó yá ẹ lára láti máa gbá àwọn ọmọ kíláàsì ẹ mọ́ra.”—Esther, láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
“Mọ bí wàá ṣe máa múra. Má ṣe máa wọṣọ tá máa fara ẹ hàn.”—Heidi, láti orílẹ̀-èdè Jámánì.
“Ọ̀nà tó o tún lè gbà rí ààbò tó nípọn ni pé kí ìwọ àtàwọn òbí ẹ jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ ara yín, kẹ́ ẹ sì máa sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ipò tó lè yọjú.”—Akiko, láti orílẹ̀-èdè Japan.
Ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó o máa ń sọ, ìwà tó ò ń hù, àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàwọn ibi tó o máa ń lò sí. Lẹ́yìn náà ni kó o wá bi ara ẹ pé, ‘Ṣé èmi ni mò ń polówó ara mi àbí ṣe ni mo wulẹ̀ ń ṣe nǹkan lọ́nà táá mú káwọn èèyàn rò pé mo fẹ́ kí wọ́n fi ìbásùn lọ̀ mí?’
◼ Ẹsẹ Bíbélì tá a dábàá pé kó o kà: Jẹ́nẹ́sísì 34:1, 2. Kíyè sí bí bíbá tí Dínà bára ẹ̀ níbi tí ò yẹ ṣe kó wàhálà bá a.
Má ṣe gbàgbé pé gbígbéra ẹni sùn kì í ṣe ọ̀ràn kékeré lójú Jèhófà Ọlọ́run; kò yẹ kó jẹ́ ọ̀ràn kékeré lójú tìẹ náà. Bíbélì sọ pé: “Kò sí àgbèrè kankan tàbí aláìmọ́ . . . tí ó ní ogún èyíkéyìí nínú ìjọba Kristi àti ti Ọlọ́run.” (Éfésù 5:5) Bó o bá ń dúró lórí ohun tó tọ́, ohunkóhun ò ní ba ẹ̀rí ọkàn rere tó o ní jẹ́, àwọn èèyàn á sì máa bọ̀wọ̀ fún ẹ. Ṣe ló rí bí ọmọdébìnrin kan tó ń jẹ́ Carly ṣe sọ ọ́, ó ní: “Kí ló fà á tí wàá fi jẹ́ kí ẹlòmíì fi ẹ́ wá ìtura ojú ẹsẹ̀ fúnra ẹ̀? O ti ṣiṣẹ́ ribiribi láti ní ìdúró rere níwájú Ọlọ́run, má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbùkù sí ìdúró rere rẹ o!”
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí padà.
b Wọ́n tún máa ń lo èdè náà fún àjọṣe tímọ́tímọ́ bíi fífọwọ́ pani lára àti fífẹnu koni lẹ́nu lọ́nà tí ń ru ìbálòpọ̀ sókè.
c Lára àwọn nǹkan tá a lè pè ní àgbèrè ni ìbálòpọ̀ tá a gba ẹnu tàbí ihò ìdí ṣe, ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti ọkùnrin, fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbálòpọ̀ ẹlòmíì àti irú eré míì láàárín àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya tó sì dájú pé wọ́n lo ẹ̀yà ìbálòpọ̀ wọn lọ́nà tí kò tọ́.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbálòpọ̀ tí kò bófin mu lè máa fa ara aláìpé yìí mọ́ra, kí nìdí tí kò fi dára?
◼ Kí ni wàá ṣe bí ẹnì kan bá ní kó o jẹ́ kẹ́ ẹ jọ gbéra yín sùn?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]
◼ Bíbélì sọ pé ẹni tó bá ń ṣe àgbèrè “ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Wò ó bóyá o lè ronú nípa àwọn
․․․․․
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Tó o bá ń fẹ́ ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, wo ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà, ojú ìwé 47, ìpínrọ̀ 12, àti ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, ojú ìwé 182 sí 183. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé méjèèjì.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
LẸ́TÀ KAN SÍ Ẹ̀YIN ÒBÍ
“Ọmọkùnrin kan ní kíláàsì wá ní kí n jẹ́ kóun gbé mi sùn. Mi ò tiẹ̀ tètè lóye ohun tó ń sọ. Bẹ́ẹ̀, mi ò ju ọmọ ọdún mọ́kànlá lọ.”—Leah.
Àwọn ọmọ fẹ́rẹ̀ẹ́ má tíì kúrò nínú oyún báyìí tí wọ́n ti ń fọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ lọ̀ wọ́n. Ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà” nítorí pé àwọn èèyàn á jẹ́ “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu” àti “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1, 3, 4) Fífẹ́ táwọn ọ̀dọ́ ń fẹ́ láti máa gbéra wọn sùn gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a fi lè mọ̀ pé ẹsẹ Bíbélì yìí ń nímùúṣẹ.
Ayé òde òní yàtọ̀ sí ayé ìgbà tiyín. Ó kàn jẹ́ pé láwọn ọ̀nà kan, a lè sọ pé bí ìṣòro ṣe wà nígbà náà lọ́hùn-ún ló ṣe wà lóde tòní pẹ̀lú. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kó sú yín, ẹ má sì ṣe fòyà nítorí pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè mú àwọn ọmọ yín ṣìwà hù ló yí wọn ká. Ńṣe ni kẹ́ ẹ pinnu lọ́kàn ara yín láti ràn wọ́n lọ́wọ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:11) Òótọ́ inú ọ̀rọ̀ náà ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọ̀dọ́ ni wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti rí i pé àwọn ṣe ohun tó tọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tó lè mú wọn ṣìwà hù ló yí wọn ká. Báwo lẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ káwọn náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀?
Ọ̀nà kan tẹ́ ẹ lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé kẹ́ ẹ lo àpilẹ̀kọ yìí láti jíròrò ọ̀rọ̀ tá à ń sọ yìí pẹ̀lú àwọn ọmọ yín ọkùnrin tàbí obìnrin. Lábẹ́ àwọn “ẹsẹ Bíbélì tá a dábàá fún kíkà” ẹ máa rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ní àwọn ìbéèrè tó lè múni ronú jinlẹ̀. Àwọn kan dá lórí àpẹẹrẹ àwọn tó dúró lórí òtítọ́ tí wọ́n sì rí ìbùkún gbà àtàwọn tí wọn ò kọbi ara sí àwọn òfin Ọlọ́run tí wọ́n sì jìyà ẹ̀. Ẹ tún máa rí àwọn ìlànà tó máa ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì tó wà lábẹ́ “ẹsẹ Bíbélì tá a dábàá fún kíkà.” Á jẹ́ kí ẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín mọ̀ pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti máa gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọ́run. Ẹ ò ṣe kúkú jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú wọn báyìí?
Kò sígbà tá a gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run tí kò ní ṣe wá láǹfààní. (Aísáyà 48:17, 18) Béèyàn bá sì kọ̀ tí ò tẹ̀ lé e, á bá a ńbẹ̀. Àdúrà àwa tá a kọ ìwé ìròyìn Jí! yìí ni pé kí Jèhófà máa rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí ẹ̀yin òbí bẹ́ ẹ ṣe ń sapá láti gbin àwọn òfin Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀ sọ́kàn àwọn ọmọ yín.—Diutarónómì 6:6, 7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
O gbọ́dọ̀ jẹ́ kó ṣe kedere pé o ò ní gba irú ẹ̀ láyè láé