ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/07 ojú ìwé 18-20
  • Ṣé Ẹni Tó Yẹ Kí N Fẹ́ Nìyí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ẹni Tó Yẹ Kí N Fẹ́ Nìyí?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ẹnikẹ́ni Ni Mo Lè Fẹ́?
  • Ṣé Àwa Méjèèjì Á Lè Bára Wa Jìnnà?
  • Ṣó Yẹ Kẹ́ Ẹ Fòpin sí Àjọṣe Yín?
  • Ṣé Ẹni Tó Yẹ Kí N Fẹ́ Nìyí?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Pétérù Sẹ́ Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 7/07 ojú ìwé 18-20

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ṣé Ẹni Tó Yẹ Kí N Fẹ́ Nìyí?

Kọ́kọ́ wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:

Àwọn ànímọ́ wo ló ṣe pàtàkì lójú ẹ báyìí pé kẹ́ni tó o máa fẹ́ ní? Nínú àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí, fi àmì ✔ síwájú àwọn ànímọ́ mẹ́rin tó o gbà pó ṣe pàtàkì jù lọ.

․․․․․ ó fani mọ́ra

․․․․․ ó máa ń fi Ìwé Mímọ́ sílò

․․․․․ ó ń kóni mọ́ra

․․․․․ ó ṣeé gbíyè lé

․․․․․ ó gbajúmọ̀

․․․․․ kì í hùwàkiwà3

․․․․․ ó máa ń ṣàwàdà

․․․․․ kì í fìwàǹwára ṣe nǹkan

Nígbà tó o ṣì kéré, ṣé ẹnì kan wà tọ́kàn ẹ ṣáà ń fà mọ́ ṣáá? Nínú àlàfo tó wà lókè yìí, fi àmì ✔ síwájú ànímọ́ tó wù ẹ́ jù lọ lára onítọ̀hún nígbà yẹn.

Kò sóhun tó burú nínú èyíkéyìí nínú àwọn ànímọ́ tá a tò sókè àpilẹ̀kọ yìí. Gbogbo wọ́n ní ibi tí wọ́n dáa sí. Àmọ́, ǹjẹ́ o kíyè sí i pé nígbà tó o ṣì kéré, tọ́kàn ẹ ṣì máa ń fà mọ́ ẹnì kan ṣáá, àwọn ànímọ́ tó jẹ mọ́ ẹwà ara lásán bí àwọn tá a tò sápá òsì nínú àlàfo yẹn ló sábà máa ń gbà ẹ́ lọ́kàn?

Àmọ́, bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń yé ẹ sí i, o bẹ̀rẹ̀ sí í lo agbára ìmòye rẹ láti ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀ràn tó túbọ̀ ṣe pàtàkì, bí àwọn tá a tò sápá ọ̀tún nínú àlàfo yẹn. Bí àpẹẹrẹ, o lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í lóye pé ọmọbìnrin tó nẹgba jù lọ ládùúgbò yẹn lè má ṣeé gbára lé rárá tàbí kó jẹ́ pé oníwàkiwà lọmọkùnrin tó gbajúmọ̀ jù lọ ní kíláàsì yín. Bó o bá ti kọjá “ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” ìyẹn ìgbà tí ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ kọ́kọ́ máa ń lágbára gan-an, ó ṣeé ṣe kó o wò ré kọjá àwọn ànímọ́ ti ara lásán kó o tó dáhùn ìbéèrè bíi, Ṣé ẹni tó yẹ kí n fẹ́ nìyí?—1 Kọ́ríńtì 7:36.

Ṣé Ẹnikẹ́ni Ni Mo Lè Fẹ́?

Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ó ṣeé ṣe káwọn obìnrin tàbí ọkùnrin púpọ̀ sí i túbọ̀ máa wọ̀ ẹ́ lójú. Ìyẹn ò wá sọ pé ẹni tó o bá ṣáà ti rí ni kó o bá lọ o. Ó ṣe tán, ẹni tẹ́ ẹ jọ máa bára yín kalẹ́ lò ń wá, ẹni tó máa mọyì irú ẹni tó o jẹ́, tíwọ náà á sì mọyì ẹ̀. (Mátíù 19:4-6) Ta nirú ẹni yẹn ì bá jẹ́ ná o? Kó o tó lè dáhùn ìbéèrè yẹn, o gbọ́dọ̀ ‘wo ara ẹ nínú dígí’ kó o má sì fi bíwọ alára ṣe rí gan-an bò fúnra ẹ.—Jákọ́bù 1:23-25.

Kó o bàa lè mọ púpọ̀ sí i nípa ara ẹ, dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:

Ibo ni mo dáa sí?

․․․․․

Ibo ni mo kù sí?

․․․․․

Kí lẹ̀dùn ọkàn mi, àwọn nǹkan wo ló yẹ kí n ṣiṣẹ́ lé lórí nínú ìjọsìn mi?

․․․․․

Wàá rí i pé iṣẹ́ kékeré kọ́ ni fún èèyàn láti mọ irú ẹni tóun jẹ́ gan-an, àmọ́ irú àwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí náà ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀.a Bí ohun tó o mọ̀ nípa ara ẹ bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà lá á ṣe rọrùn fún ẹ tó láti wá ẹni tó máa mọyì ibi tó o dáa sí tá á sì lè fara da ibi tó o kù sí. Àmọ́, bó o bá wá rò pó o ti rẹ́ni tó yẹ kó o fẹ́ ńkọ́?

Ṣé Àwa Méjèèjì Á Lè Bára Wa Jìnnà?

Láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, fara balẹ̀ ronú nípa ẹni tó o ní lọ́kàn láti fẹ́. Àmọ́ kó o ṣọ́ra o! Kó má lọ jẹ́ pé ohun tó o fẹ́ rí nìkan ni wàá máa rí. Torí náà, fara ẹ balẹ̀. Gbìyànjú láti mọ̀wà ẹni náà dáadáa.

Ànímọ́ tó fara hàn lóréfèé lásán lọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n jọ máa fẹ́ra máa ń wò. Wọ́n máa ń yára tọ́ka sí àwọn ibi tí wọ́n ti bára mu, bí: ‘Irú orin kan náà ló máa ń wù wá gbọ́.’ ‘Irú eré kan náà ló máa ń wù wá ṣe.’ ‘Gbogbo nǹkan lohùn wa jọ máa ń ṣọ̀kan lé lórí!’ Àmọ́, bá a ṣe sọ ṣáájú, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo ti kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe, wàá máa wò ré kọjá àwọn ànímọ́ tó fara hàn lóréfèé. Ó yẹ kó o fòye mọ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.”—1 Pétérù 3:4; Éfésù 3:16.

Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi máa pọkàn pọ̀ sórí bẹ́ ẹ ṣe jọ ń fara mọ́ ohun kan náà tó, fífiyè sí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ bí ẹ kò bá fara mọ́ ohun kan náà ló máa jẹ́ kó o mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an. Ìyẹn ni pé bó ṣe máa ń ṣe bí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀. Ṣó máa ń rin kinkin pé òun lòun tọ̀nà, bóyá nípa ‘bíbínú fùfù’ tàbí kó máa ‘sọ̀rọ̀ èébú’? (Gálátíà 5:19, 20; Kólósè 3:8) Àbí ó máa ń fi òye hàn, tó máa ń múra tán láti jáwọ́ nítorí àtipa àlàáfíà mọ́ bí kì í bá ṣe pé ọ̀ràn èyí tọ́ èyí ò tọ́ là ń sọ?—Jákọ́bù 3:17.

Ohun míì tó tún yẹ kó o gbé yẹ̀ wò nìyí: Ṣé ẹni tó máa ń dọ́gbọ́n darí ẹlòmíì ṣe nǹkan tó fẹ́ ni àbí òjòwú? Ṣó máa ń fẹ́ láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ gbogbo ibi tó o bá ń rìn sí? Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nicole sọ pé: “Ewu wà ńbẹ̀ bí ẹnì kan kì í bá fẹ́ rí ọ̀rẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn míì tàbí tó ń jowú. Mo máa ń gbọ́ táwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ń bára wọn jà nítorí pé ọ̀kan lára wọn ò máa pe èkejì lemọ́lemọ́ lórí fóònù láti máa sọ gbogbo bóun ṣe ń rìn fún un. Lójú tèmi, àpẹẹrẹ burúkú nìyẹn.”

Ojú wo làwọn míì fi ń wo ọkùnrin tàbí obìnrin tẹ́ ẹ jọ ń bára yín jáde? O kúkú lè bá àwọn tó ti ṣe díẹ̀ tí wọ́n ti mọ onítọ̀hún sọ̀rọ̀, irú bí àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ní ìjọ tó ń dara pọ̀ mọ́. Wọ́n á jẹ́ kó o mọ̀ báwọn èèyàn bá ń “ròyìn rẹ̀ dáadáa.”—Ìṣe 16:1, 2.b

Ṣó Yẹ Kẹ́ Ẹ Fòpin sí Àjọṣe Yín?

Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ẹni tẹ́ ẹ jọ ń bára yín jáde ò yẹ lẹ́ni tẹ́ ẹ lè jọ fẹ́ra yín ńkọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ì bá kúkú dáa kẹ́ ẹ fòpin sírú àjọṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.”—Òwe 22:3.c

Bó bá tún yá, wàá rẹ́ni tẹ́ ẹ ó jọ máa bára yín jáde. Bó bá sì ti dà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o yáa fọgbọ́n tó o ti kọ́ látinú èyí tó o ti ṣe kọjá wo bí onítọ̀hún ṣe rí gan-an. Ó ṣeé ṣe nígbà yẹn kí ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè náà, “Ṣé ẹni tó yẹ kí n fẹ́ nìyí?” jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni!

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ìbéèrè míì tó o lè bira ẹ wà lójú ìwé 18 nínú Jí! January–March 2007

b Tún wo àwọn ìbéèrè inú àpótí tó wà lójú ìwé 19 sí 20.

c Bó o bá fẹ́ mọ̀ síwájú sí i nípa bó o ṣe lè sọ fẹ́nì kan pé o ò ṣe mọ́, wo ojú ìwé 12 sí 14 nínú Jí! April 8, 2001.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Àwọn ànímọ́ dáadáa wo ló máa mú kó o jẹ́ ọkọ tàbí aya rere?

◼ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ tí wàá fẹ́ kẹ́ni tó o máa fẹ́ ní?

◼ Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà mọ púpọ̀ sí i nípa ìṣesí, ìwà àtohun táwọn èèyàn ń sọ nípa ẹni tẹ́ ẹ jọ ń bára yín jáde?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

Ṣé á ṣeé fi ṣọkọ?

KÒṢEÉMÁÀNÍ

▪ Báwo ló ṣe máa ń lo àṣẹ tí wọ́n bá gbé lé e lọ́wọ́?—Mátíù 20:25, 26.

▪ Kí làwọn àfojúsùn rẹ̀?—1 Tímótì 4:15.

▪ Ṣó ti ń sapá láti lé àwọn àfojúsùn yẹn bá?—1 Kọ́ríńtì 9:26, 27.

▪ Àwọn wo lọ̀rẹ́ ẹ̀?—Òwe 13:20.

▪ Báwo lọ̀ràn owó ṣe máa ń rí lára ẹ̀?—Hébérù 13:5, 6.

▪ Irú eré ìnàjú wo ló fẹ́ràn láti máa ṣe?—Sáàmù 97:10.

▪ Irú èèyàn wo laṣọ tó ń wọ̀ fi hàn pó jẹ́?—2 Kọ́ríńtì 6:3.

▪ Kí ni ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà máa ń sún un láti ṣe?—1 Jòhánù 5:3.

IRÚ ẸNI TÓ YẸ KÓ JẸ́

▪ Ṣé òṣìṣẹ́ kára ni?—Òwe 6:9-11.

▪ Ṣé kì í náwó nínàákúnàá?—Lúùkù 14:28.

▪ Ṣé wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ ní rere?—Ìṣe 16:1, 2.

▪ Ṣó máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí ẹ̀?—Ẹ́kísódù 20:12.

▪ Ṣó máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò?—Fílípì 2:4.

IBI TÍ ÌṢÒRO TI LÈ JẸ YỌ

▪ Ṣé kì í pẹ́ bínú?—Òwe 22:24.

▪ Ṣó máa ń fẹ́ bá ẹ ṣèṣekúṣe?—Gálátíà 5:19.

▪ Ṣé oníjà ni àbí ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ èébú?—Éfésù 4:31.

▪ Ṣé bí ò bá tíì rọ́tí líle kò lè gbádùn ara ẹ̀?—Òwe 20:1.

▪ Ṣé òjòwú àti anìkànjọpọ́n ni?—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]

Ṣé á ṣeé fi ṣaya?

KÒṢEÉMÁÀNÍ

▪ Báwo ló ṣe ń tẹrí bá nínú ilé àti nínú ìjọ?—Éfésù 5:21, 22.

▪ Irú èèyàn wo laṣọ tó ń wọ̀ fi hàn pó jẹ́?—1 Pétérù 3:3, 4.

▪ Àwọn wo lọ̀rẹ́ ẹ̀?—Òwe 13:20.

▪ Báwo lọ̀ràn owó ṣe máa ń rí lára ẹ̀?—1 Jòhánù 2:15-17.

▪ Kí làwọn àfojúsùn rẹ̀?—1 Tímótì 4:15.

▪ Ṣó ti ń sapá láti lé àwọn àfojúsùn yẹn bá?—1 Kọ́ríńtì 9:26, 27.

▪ Irú eré ìnàjú wo ló fẹ́ràn láti máa ṣe?—Sáàmù 97:10.

▪ Kí ni ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà máa ń sún un láti ṣe?—1 Jòhánù 5:3.

IRÚ ẸNI TÓ YẸ KÓ JẸ́

▪ Ṣé òṣìṣẹ́ kára ni?—Òwe 31:17, 19, 21, 22, 27.

▪ Ṣé kì í náwó nínàákúnàá?—Òwe 31:16, 18.

▪ Ṣé wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ ní rere?—Rúùtù 4:11.

▪ Ṣó máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí ẹ̀?—Ẹ́kísódù 20:12.

▪ Ṣó máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò?—Òwe 31:20.

IBI TÍ ÌṢÒRO TI LÈ JẸ YỌ

▪ Ṣé alásọ̀ ni?—Òwe 21:19.

▪ Ṣó máa ń fẹ́ kó o bá òun ṣèṣekúṣe?—Gálátíà 5:19.

▪ Ṣé ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ èébú ni àbí oníjà?—Éfésù 4:31.

▪ Ṣé bí ò bá tíì rọ́tí líle kò lè gbádùn ara ẹ̀?—Òwe 20:1.

▪ Ṣé òjòwú àti anìkànjọpọ́n ni?—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́