ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/07 ojú ìwé 26-29
  • Ṣó O Ti Pinnu Láti Di Ọlọ́rọ̀? Kí Ló Lè Yọrí sí fún Ẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó O Ti Pinnu Láti Di Ọlọ́rọ̀? Kí Ló Lè Yọrí sí fún Ẹ?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Ìlépa Ọrọ̀ Máa Ń Ṣe Fáwọn Ọmọ
  • Ohun Tí Ìlépa Ọrọ̀ Máa Ń Ṣe Fáwọn Àgbàlagbà?
  • Kí Lò Ń Fẹ́ Gan-an?
  • Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó
    Jí!—2015
  • Máa Fọgbọ́n Náwó
    Jí!—2009
  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 7/07 ojú ìwé 26-29

Ṣó O Ti Pinnu Láti Di Ọlọ́rọ̀? Kí Ló Lè Yọrí sí fún Ẹ?

NÍNÚ ayé táwọn èèyàn tó lé ní ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọ̀kẹ́ [850,000,000] ò ti róúnjẹ tó tó jẹ yìí, ó lè ṣòro fún èèyàn láti ronú pé àpọ̀jù ọrọ̀ lè máa fa ìṣòro. Àmọ́, ǹjẹ́ o kíyè sí i pé ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ tá a fa ọ̀rọ̀ ẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí ò sọ pé ó burú kéèyàn lówó tàbí kó lọ́rọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé ká ṣọ́ra fún ìfẹ́ owó àti ìpinnu láti di ọlọ́rọ̀? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó máa ń lépa ọrọ̀ àti ohun tí owó lè rà? Jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tó máa ń ṣe fáwọn ọmọ wọn.

Ohun Tí Ìlépa Ọrọ̀ Máa Ń Ṣe Fáwọn Ọmọ

Wọ́n ti fojú bù ú pé láàárín ọdún kan péré, ọmọ kọ̀ọ̀kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wo ìpolówó ọjà tó tó ọ̀kẹ́ méjì [40,000] lórí tẹlifíṣọ̀n. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tàwọn eré fídíò, àwọn ohun èlò ìkọrin ìgbàlódé, àwọn àwo pẹlẹbẹ tó ṣeé fi kọ̀ǹpútà lò, aṣọ òkè òkun tó ní òǹtẹ̀ àwọn tó ṣe é lára, èyí táwọn ọmọ máa ń rí láwọn ilé ìtajà àti nílé àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Kó o wá fọkàn yàwòrán bí wọ́n á ṣe máa yọ àwọn òbí wọn lẹ́nu tó pé kí wọ́n ra irú ẹ̀ fáwọn náà. Àwọn òbí kan sì rèé, gbogbo ohun táwọn ọmọ wọn bá ti ń fẹ́ ṣáá ni wọ́n máa ń ṣe fún wọn. Kí ló fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀?

Ìdí ni pé àwọn òbí kan ò rí àwọn ohun tí wọ́n ń fẹ́ lò yàlà yòlò nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé, wọn ò wá fẹ́ káwọn ọmọ tiwọn lálàṣí ohunkóhun bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Ẹ̀wẹ̀, ẹ̀rù máa ń ba àwọn òbí míì pé báwọn bá sọ pé àyè ohun táwọn ọmọ ń béèrè fún ò yọ, wọn ò ní fẹ́ràn àwọn mọ́. Obìnrin kan tó wà lára àwọn tó dá ẹgbẹ́ agbọ̀ràndùn fáwọn òbí sílẹ̀, nílùú Boulder, ní ìpínlẹ̀ Colorado, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Wọ́n fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ fáwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì rí i dájú pé wọ́n ń gbádùn ara wọn.” Àwọn òbí míì nírètí pé báwọn bá ń fáwọn ọmọ lẹ́bùn rẹpẹtẹ, ìyẹn á dípò ọ̀pọ̀ àkókò tí wọ́n fi ń dá wà nílé lẹ́yìn táwọn bá ti gba ibi iṣẹ́ lọ. Ìdí mìíràn sì tún ni pé lẹ́yìn tí òbí bá ti já lanba lọ, já lanba bọ̀ jálẹ̀ ọ̀sẹ̀, bó bá dòpin ọ̀sẹ̀ kò ní fẹ́ kọ́mọ kan tún máa wá yọ òun lẹ́nu bóun bá sọ pé: “Rárá o, mi ò lè ra ohun tó o béèrè fún ẹ.”

Àmọ́, ṣé àwọn òbí tó bá ń fún àwọn ọmọ wọn ní ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ni àbí wọ́n ń pa wọ́n lára? Ọ̀nà kì í sábà gba ibi táwọn òbí ń fojú sí, torí pé ohun tá à ń rí ni pé dípò kírú àwọn ọmọ tí wọ́n kẹ́ bà jẹ́ bẹ́ẹ̀ túbọ̀ máa fẹ́ràn Bàbá àti Ìyá wọn, ṣe ni wọ́n ń di aláìmoore. Wọ́n kì í tiẹ̀ mọrírì ẹ̀bùn tí wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé káwọn òbí rà fáwọn. Obìnrin kan tó jẹ́ alákòóso ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ oníwèé márùn-ún sí ọdún méjì àkọ́kọ́ nílé ẹ̀kọ́ girama sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa pé bó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tọ́mọ ń béèrè fún ṣáá làwọn òbí ń fi lé e lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kò ní ju ọ̀sẹ̀ méjì lọ tá á fi gbé nǹkan náà jù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.”

Báwọn ọmọ tí wọ́n ti kẹ́ bà jẹ́ náà bá wá dàgbà ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Newsweek ṣe sọ, ìwádìí fi hàn pé bí wọ́n bá dàgbà tán, ó “máa ń ṣòro fún wọn láti mọ ohun tí wọ́n á ṣe bí ìṣòro bá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹjú mọ́ wọn.” Níwọ̀n bí wọn ò ti mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ṣe làálàá kọ́wọ́ wọn tó ba ohun tí wọ́n ń fẹ́, ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń fìdí rẹmi nílé ìwé, wọn kì í ṣe dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ àti nígbà tí wọ́n bá gbéyàwó, lá á bá tún di pé káwọn òbí máa gbọ́ bùkátà wọn nìṣó. Irú wọn tún máa ń tètè ṣàníyàn, wọn kì í sì í pẹ́ sorí kọ́.

Nítorí náà, ìyà tí wọn ò fẹ́ kó jẹ àwọn àkẹ́bàjẹ́ ọmọ náà ló máa ń jẹ wọ́n kẹ́yìn. Wọn ò jẹ́ kí wọ́n mọyì ohun tó túmọ̀ sí láti níṣẹ́ lọ́wọ́, wọn ò mọ̀ bóyá àwọn lè dá ohunkóhun ṣe, wọn kì í sì í gbà pé àwọn náà ní ibi táwọn dáa sí. Oníṣègùn ọpọlọ, Jessie O’Neill kìlọ̀ fáwọn òbí pé: “Bẹ́ ẹ bá kọ́ àwọn ọmọ pé gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ṣáà ti fẹ́ lọwọ́ wọ́n lè tẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ẹ sí, ńṣe lẹ̀ ń fi òṣì pilẹ̀ ayé wọn.”

Ohun Tí Ìlépa Ọrọ̀ Máa Ń Ṣe Fáwọn Àgbàlagbà?

Ìwé ìròyìn Psychology Today sọ pé bẹ́ẹ bá tiẹ̀ ti ṣègbéyàwó, “bó ti wù kó ti pẹ́ tó tẹ ẹ ti jọ wà tàbí kówó tẹ́ ẹ ní lọ́wọ́ ṣe pọ̀ tó, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé owó náà lẹ ó ṣì máa jiyàn lé lórí.” Ìwé ìròyìn náà tún sọ pé “ọwọ́ táwọn tọkọtaya bá fi ń mú èdè àìyedè nítorí owó àti ohun tí wọ́n máa ń ṣe bí ọ̀nà ò bá gba ibi tí wọ́n fojú sí, lè jẹ́ kí wọ́n tètè mọ̀ bóyá ìgbéyàwó wọn á tọ́jọ́ tàbí ó máa forí ṣánpọ́n.” Bí tọkọtaya bá ń ka owó àti nǹkan ìní sí bàbàrà ju bó ṣe yẹ lọ, ó dájú pé wọ́n ń fi ìgbéyàwó wọn wewu nìyẹn. Àwọn òǹṣèwádìí tiẹ̀ ti fojú bù ú pé iyàn jíjà lórí owó ló máa ń fà á tí mẹ́sàn-án fi ń tú ká lára ìgbéyàwó mẹ́wàá.

Ká tiẹ̀ wá sọ pé tọkọtaya tó ní ìṣòro owó ṣì ń gbé pa pọ̀, mìmì ṣì lè máa mi ìgbéyàwó wọn bó bá jẹ́ pé wọn ò wá ohun méjì ju owó àtáwọn nǹkan mèremère tówó lè rà lọ. Bí àpẹẹrẹ, bí tọkọtaya kan bá jẹ gbèsè sọ́rùn, kò ní pẹ́ tí wọ́n á fi dẹni tó ń kanra, inú á máa tètè bí wọn, ọ̀tún á sì máa dá òsì lẹ́bi pé òun ló kó àwọn sínú ìṣòro àìlówó lọ́wọ́. Ìgbà míì sì máa ń wà tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó máa gba tọkọ taya lọ́kàn ni bí tọ̀tún tòsì wọn á ṣe kó dúkìá jọ débi pé wọn ò ní ráyè fúnra wọn mọ́. Bó bá wa ṣẹlẹ̀ pé ọkọ tàbí aya ra nǹkan olówó gegere tó sì wá gbé e pa mọ́ fún ẹnì kejì rẹ̀ ńkọ́? Irú ohun tó máa ń fa kí tọkọtaya máa fọ̀rọ̀ bò fúnra wọn nìyẹn, ọkàn wọn á máa dá wọn lẹ́bi, wọ́n á máa fura síra wọn, bó pẹ́ bó yá ìgbéyàwó wọn á tú ká.

Àwọn àgbà mélòó kan tún wà tí wọ́n ti fi ara wọn fún ìfẹ́ ọrọ̀ yálà wọn ti ṣègbéyàwó tàbí wọn ò tíì ṣe. Àwọn kan tiẹ̀ wà lórílẹ̀-èdè South Africa tí wọ́n fẹ́ fọwọ́ ara wọn para wọn nígbà tí gbígbé tí wọ́n fẹ́ máa gbé ìgbé ayé bíi tàwọn òyìnbó rọ́rí mọ́ wọn lọ́wọ́. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọkùnrin kan pa ìyàwó rẹ̀, ó pa ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá, ó sì para ẹ̀ náà, gbogbo ẹ̀ ò sì ṣẹ̀yìn ìṣòro ìṣúnná owó.

Lóòótọ́ o, ọ̀pọ̀ èèyàn wà tó jẹ́ pé kì í ṣe ìlépa ọrọ̀ ló ń ṣekú pa wọ́n. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé ńṣe nirú wọn wulẹ̀ wà láyé bí aláìsí láyé níbi tí wọ́n ti ń lépa ọrọ̀. Wọ́n sì tún lè máà rójú ráyè bó bá di pé wàhálà iṣẹ́ tàbí àìríná àìrílò ti mú kí àwọn àìlera tó lè pani láìtọ́jọ́ máa ṣe wọ́n, ìyẹn àwọn bí àìróorunsùn tó, kí orí máa fọ́ni lákọlákọ tàbí ọgbẹ́ inú. Bá a bá sì wá rẹ́ni tó pe orí ara ẹ̀ wálé tó sì fẹ́ yí ohun tó fi sípò àkọ́kọ́ padà, ó lè ti pẹ́ jù fún un. Ọkọ tàbí aya ẹ̀ lè má gbà á gbọ́ mọ́, ìdààmú ọkàn lè ti sọ àwọn ọmọ ẹ̀ dìdàkudà, kí ròkè rodò sì ti sọ òun náà di aláìlera. Bóyá ó ṣeé ṣe kéèyàn rí nǹkan ṣe sí díẹ̀ lára irú àwọn ìṣòro yìí, àmọ́ ó máa gba ìsapá ńláǹlà. Ìdí sì ni pé irú àwọn bẹ́ẹ̀ ti “fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:10.

Kí Lò Ń Fẹ́ Gan-an?

Ohun táwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ ń fẹ́ ni ilé aláyọ̀, ara dídá ṣáṣá, iṣẹ́ tó ní láárí, àti owó tó pọ̀ tó tí wọ́n fi lè máa gbé ìgbé ayé tó tù wọ́n lára. Ó gba pé kéèyàn wà níwọ̀ntúnwọ̀nsí kọ́wọ́ ẹ̀ tó lè tẹ àwọn nǹkan mẹ́rin wọ̀nyí. Bó bá sì wá lọ jẹ́ pé owó ṣáá lèèyàn fẹ́ máa lépa, kò sí béèyàn ṣe lè wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé kí wọ́n tó lè padà sí ẹsẹ àárọ̀, àfi kí wọ́n wáṣẹ́ olówó pọ́ọ́kú ṣe, kí wọ́n máa gbénú ilé tó mọ níwọ̀n tàbí kí wọ́n máa gbé ìgbésí ayé tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Mélòó lára wọn ló múra tán láti jáwọ́ nínú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ kí wọ́n bàa lè lo àkókò wọn sórí àwọn nǹkan tó sàn jù? Ṣe ló dà bí obìnrin kan tó sọ pé: ‘Mo gbà pé mi ò nílò ọ̀pọ̀ dúkìá, àmọ́ òjú mi ò gbà á láti jáwọ́ nínú kíkó wọn jọ!’ Ó lè má wu àwọn kan láti máa kó dúkìá jọ, àmọ́ wọn ò fẹ́ kó jẹ́ àwọn lẹni àkọ́kọ́ tó máa bẹ̀rẹ̀ sí í dín in kù.

Ìwọ ńkọ́? Bó o ba ti mọ ọ̀nà tó o lè gbà fi owó àtàwọn nǹkan ìní sí àyè tó yẹ kí wọ́n wà, ó yẹ ká lù ọ́ lọ́gọ ẹnu pé o káre láé. Ẹ̀wẹ̀, ṣé kì í ṣe pé ìkánjú lo fi ń ka àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí torí pé iṣẹ́ ti máa ń gbà ẹ́ lákòókò jù? Ṣó ò sì sí lára àwọn tó di dandan fún pé kí wọ́n dín ohun tó ń gbọ́n wọn lówó lọ kù kí wọ́n lè ní àlàáfíà ara àti ìbàlẹ̀ ọkàn? Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe jáfara, ṣe ni kó o tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá kí ìfẹ́ ọrọ̀ tóó da ilé àtọ̀nà ẹ rú. Àwọn ìmọ̀ràn díẹ̀ tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dín ohun tó ń gbọ́n ẹ lówó lọ kù wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé yìí.

Béèyàn ò bá ṣe jura ẹ̀ lọ lórí ọ̀ràn àwọn ohun ìní, àlàáfíà ara á wà fún táya tọmọ, ohunkóhun ò sì ní máa kó wọn láyà sókè. Tàwọn Kristẹni tiẹ̀ tún jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọn kì í fẹ́ kí kíkó dúkìá jọ fara gbá àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Báwo ni ìfẹ́ ọrọ̀ ṣe lè mú ká di aláìṣedéédéé nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run, kí la sì lè ṣe láti kòòré irú ẹ̀? Ohun tí àpilẹ̀kọ tó kàn dá lé lórí gan-an nìyẹn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

Aláìmoore làwọn ọmọ tí wọ́n bá kẹ́ bà jẹ́ sábà máa ń yà, wọ́n kì í sì í pẹ́ gbé ohun tí wọ́n bá rà fún wọn jù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Wíwà ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì

Dídín owó téèyàn ń ná sórí ohun ìní kù gba ìpinnu àti ètò téèyàn fẹ̀sọ̀ ṣe. Àwọn àbá díẹ̀ tó ti ran àwọn kan lọ́wọ́ rèé.

◼ YẸ Ọ̀RÀN ARA Ẹ WÒ. Kí ló yẹ kó o má rà mọ́? Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o jáwọ́ nínú ẹ̀? Kíkó àwo orin tí wọ́n ṣe sórí CD jọ ńkọ́? Kíkó àwọn aṣọ olówó iyebíye àtàwọn bàtà ìgbàlódé jọ ńkọ́?

◼ DÍN ÀWỌN NǸKAN TÓ Ò Ń KÓ JỌ KÙ FÚNGBÀ DÍẸ̀. Bí kò bá dá ẹ lójú pé o lè mú kí ìgbésí ayé ẹ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, o ò kúkú ṣe gbìyànjú ẹ̀ wò fún oṣù mẹ́fà tàbí fún ọdún kan. Mú un dá ara ẹ lójú bóyá lóòótọ́ lò ń láyọ̀ bó o ṣe ń fi gbogbo àkókò ẹ wá owó àtàwọn nǹkan ìní tàbí ńṣe ni ayọ̀ ẹ ń pẹ̀dín.

◼ KẸ́YIN ÀTÀWỌN ỌMỌ JÍRÒRÒ BẸ́ Ẹ ṢE MÁA DÍN NǸKAN TẸ́ Ẹ̀ Ń KÓ JỌ KÙ. Èyí lè mú káwọn ọmọ túbọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú yín, ẹ ó sì rí i pé kò ní ṣòro fún yín láti sọ pé agbára yín ò gbé e bí wọn bá ní kẹ́ ẹ ṣe ohun kan tápá yín ò ká fáwọn.

◼ Ẹ RÒ Ó WÒ BÓYÁ Ẹ LÈ MÁA FÁWỌN ỌMỌ YÍN NÍ OWO TÁṢẸ́RẸ́ LÁTI FI RA NǸKAN. Yálà wọ́n á pinnu pé àwọn á máa fowó pa mọ́ láti fi ra ohun tí wọ́n bá fẹ́ tàbí pé àwọn á kúkú gbàgbé nípa ohun náà, ohun tó dájú ni pé wọ́n á mọyì béèyàn ṣe ń ní sùúrù kọ́wọ́ ẹ̀ tó tẹ nǹkan tó nílò àti béèyàn ṣe máa ń mọrírì ohun tó bá ní. Wọ́n á tún kọ́ béèyàn ṣe máa ń ṣèpinnu.

◼ MỌ ONÍRÚURÚ Ọ̀NÀ TÉÈYÀN GBÀ Ń ṢỌ́WÓ NÁ. Máa lọ síbi tí wọn ti ń tajà lọ́pọ̀. Ṣètò bí wàá ṣe máa náwó. Máa pín ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lò pẹ̀lú àwọn míì. Má máa tan iná tó ò lò sílẹ̀. Dípò tí wàá fi ra fíìmù, máa yá a níbi tí wọ́n ti ń fi rẹ́ǹtì.

◼ FÍ ÀKÓKÒ TỌ́WỌ́ BÁ DILẸ̀ WÁ NǸKAN GIDI ṢE. Rántí pé kì í ṣe nítorí kó o má bàa ní ohun tó pọ̀ mọ́ lo ṣe fẹ́ dín nǹkan tó ò ń kó jọ kù, bí kò ṣe nítorí kó o lè ráyè fún àwọn nǹkan tó túbọ̀ ṣe pàtàkì láfiyèsí, ìyẹn ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Ṣé ohun tó ò ń ṣe nìyẹn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ìpinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń kó wàhálà bá ìgbéyàwó

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́