ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/08 ojú ìwé 12-13
  • Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ogójì Òǹkọ̀wé, Òǹṣèwé Kan
  • Ọlọ́run Ló Mí sí I
  • Ọ̀nà Tí Wọ́n Gbà Kọ Ọ́ Fi Irú Ẹni Tí Wọ́n Jẹ́ Hàn
  • Bíbélì Dé!
  • Báwo ni Ọlọ́run Ṣe Mí Sí Bíbélì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ǹjẹ́ A Lè Mọ Ẹni Tó Kọ Bíbélì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • ‘Ẹ̀mí Mímọ́ Darí Wọn’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ṣé Lóòótọ́ Ni “Ọlọ́run Mí Sí” Bíbélì?
    Jí!—2017
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 1/08 ojú ìwé 12-13

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?

ORÚKỌ àwọn tó kọ Bíbélì ò fara sin. Àwọn ìwé kan nínú Bíbélì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ bí “ọ̀rọ̀ Nehemáyà,” “ìran Aísáyà” àti “ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó tọ Jóẹ́lì wá.” (Nehemáyà 1:1; Aísáyà 1:1; Jóẹ́lì 1:1) Àwọn ìtàn kan wà tó jẹ́ pé Gádì, Nátánì àti Sámúẹ́lì ló kọ wọ́n. (1 Kíróníkà 29:29) A rí orúkọ àwọn tó kọ ọ̀pọ̀ lára sáàmù nínú àkọlé sáàmù tí kálukú wọ́n kọ.—Sáàmù 79, 88, 89, 90, 103 àti 127.

Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ sọ pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn èèyàn la lò láti kọ Bíbélì, kò yàtọ̀ sáwọn ìwé míì, torí pé ìmọ̀ èèyàn náà ló máa kúnnú ẹ̀. Ṣé ọ̀rọ̀ wọn lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀?

Ogójì Òǹkọ̀wé, Òǹṣèwé Kan

Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ló sọ ohun táwọn kọ sílẹ̀, àwọn míì sọ pé òun ló ń darí àwọn tàbí pé ó rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti fáwọn nísọfúnni. (Sekaráyà 1:7, 9) Ó lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300] ìgbà táwọn wòlíì tó kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù fi sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí.” (Ámósì 1:3; Míkà 2:3; Náhúmù 1:12) Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé tí wọ́n kọ ló bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn gbólóhùn bí “ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó tọ Hóséà . . . wá.” (Hóséà 1:1; Jónà 1:1) Àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa àwọn wòlíì Ọlọ́run pé: “Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”—2 Pétérù 1:21.

Nítorí náà, a lè sọ pé Bíbélì jẹ́ àpapọ̀ àwọn ìwé tó wà níṣọ̀kan, táwọn tó kọ ọ́ sì sọ pé Ọlọ́run ni igi lẹ́yìn ọgbà àwọn. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ńṣe ni Ọlọ́run lo àwọn èèyàn láti kọ èrò rẹ̀ sílẹ̀. Báwo ló ṣe ṣe é?

Ọlọ́run Ló Mí sí I

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “Ọlọ́run mí sí” túmọ̀ sí “Ọlọ́run mí èémí sí.” Èyí wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run lo ẹ̀mí kan tá ò lè rí láti darí àwọn tó kọ Bíbélì kó lè jẹ́ pé èrò rẹ̀ ni wọ́n máa kọ sílẹ̀. Àmọ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló kọ Òfin Mẹ́wàá sára àwọn wàláà òkúta. (Ẹ́kísódù 31:18) Nígbà míì sì rèé, ṣe ni Ọlọ́run máa fẹ́ káwọn òǹkọ̀wé wọ̀nyí máa kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ bó bá ṣe ń sọ ọ́ fún wọn. Ẹ́kísódù 34:27 sọ pé: “Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé: ‘Kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀ fún ara rẹ . . . ’”

Láwọn ìgbà míì, Ọlọ́run máa ń fi ohun tó bá fẹ́ káwọn èèyàn kọ sílẹ̀ hàn wọ́n nínú ìran. Èyí ló mú kí Ìsíkíẹ́lì sọ pé: “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn ìran ti Ọlọ́run.” (Ìsíkíẹ́lì 1:1) Bákan náà, “Dáníẹ́lì fúnra rẹ̀ lá àlá, ó sì rí àwọn ìran orí rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀. Ní àkókò yẹn, ó kọ àlá náà sílẹ̀.” (Dáníẹ́lì 7:1) Inú ìran ni àpọ́sítélì Jòhánù náà ti rí ohun tó kọ sínú ìwé tó gbẹ̀yìn Bíbélì, ìyẹn ìwé Ìṣípayá. Jòhánù kọ̀wé pé: “Nípa ìmísí, mo wá wà ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn líle bí ti kàkàkí lẹ́yìn mi, tí ó wí pé: ‘Kọ ohun tí ìwọ rí sínú àkájọ ìwé.’”—Ìṣípayá 1:10, 11.

Ọ̀nà Tí Wọ́n Gbà Kọ Ọ́ Fi Irú Ẹni Tí Wọ́n Jẹ́ Hàn

Pé Ọlọ́run mí sí àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ kò ní kí wọ́n má kọ ọ́ lọ́nà tí wọ́n ń gbà kọ̀wé. Kódà, iṣẹ́ ribiribi làwọn tó kọ Bíbélì ṣe kí wọ́n tó lè kọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó kọ ìwé Oníwàásù sọ pé ńṣe lòun ní láti “wá ọ̀nà àtirí àwọn ọ̀rọ̀ dídùn àti àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.” (Oníwàásù 12:10) Ó kéré tán ìwé mẹ́rìnlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ẹ́sírà kà kó tó lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìtàn tó wà nínú ìwé tó kọ, lára àwọn ìwé tó kà ni ìwé “ìròyìn àwọn àlámọ̀rí àwọn ọjọ́ Dáfídì Ọba” àti “Ìwé Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì.” (1 Kíróníkà 27:24; 2 Kíróníkà 16:11) Lúùkù, tó kọ ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere, “tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye, láti kọ̀wé wọn . . . ní ìṣètò tí ó bọ́gbọ́n mu.”—Lúùkù 1:3.

Tó o bá ka àwọn ìwé Bíbélì kan, wàá rí díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ táwọn tó kọ wọ́n ní. Bí àpẹẹrẹ, bí Mátíù, tí wọ́n tún ń pè ní Léfì, tó jẹ́ agbowó orí kó tó di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ṣe kọ ìwé rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ sí ìṣirò. Òun nìkan lára àwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere ló sọ pé “ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà” ni Júdásì gbà kó tó fi Jésù han àwọn tó fẹ́ mú un. (Mátíù 27:3; Máàkù 2:14) Lúùkù tó jẹ́ oníṣègùn náà sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìtọ́jú ìṣègùn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń ṣàlàyé ohun tó ń ṣe àwọn tí Jésù mú lára dá, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “akọ ibà” àti “kún fún ẹ̀tẹ̀.” (Lúùkù 4:38; 5:12; Kólósè 4:14) Èyí fi hàn pé Jèhófà jẹ́ káwọn tó kọ Bíbélì lo ọ̀rọ̀ ara wọn kí wọ́n sì kọ ọ́ lọ́nà tó máa gbà yéèyàn; síbẹ̀, ó rí i dájú pé èrò òun gẹ́lẹ́ ni wọ́n kọ sílẹ̀.—Òwe 16:9.

Bíbélì Dé!

Ẹ kíyè sí i pé ogójì ọkùnrin ló kọ ìwé kan ṣoṣo yìí, ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún ni wọ́n sì fi kọ ọ́. Àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti àgbègbè tó yàtọ̀ síra ni wọ́n ti kọ ọ́, síbẹ̀ àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ò ta kora, gbogbo wọ́n sì ní àkòrí kan náà tó fani lọ́kàn mọ́ra. Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu gbáà lèyí! Ó dájú pé irú èyí ò lè rí bẹ́ẹ̀ bí kì í bá ṣe pé Òǹṣèwé kan náà ló darí gbogbo wọn.

Ṣé dandan ni pé kí Jèhófà lo èèyàn láti kọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀? Rárá o. Ṣùgbọ́n lílò tó lo èèyàn fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn. Ká sòótọ́, ọ̀kan lára ohun tó jẹ́ kí ọ̀pọ̀ máa ka Bíbélì lónìí ni pé àwọn tó kọ ọ́ fi onírúurú ìmọ̀lára tí ẹ̀dá èèyàn ń ní hàn. Bí Dáfídì Ọba ṣe kọ ìwé ẹ̀ jẹ́ ká mọ ọgbẹ́ tó máa ń wà lọ́kàn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ń fẹ́ kí Ọlọ́run fàánú hàn sóun lẹ́yìn tó ti ronú pìwà dà.—Sáàmù 51:2-4, 13, 17, àkọlé.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn bíi tiwa ni Jèhófà lò láti kọ Bíbélì, a lè gbẹ́kẹ̀ lé ohun tí wọ́n kọ, bíi tàwọn Kristẹni ìgbàanì, tí wọn ò wo Ìwé Mímọ́ “bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—1 Tẹsalóníkà 2:13.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Ta ni Òǹṣèwé “gbogbo Ìwé Mímọ́”?—2 Tímótì 3:16.

◼ Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà Ọlọ́run gbà fi èrò rẹ̀ sọ́kàn àwọn tó kọ Bíbélì? —Ẹ́kísódù 31:18; 34:27; Ìsíkíẹ́lì 1:1; Dáníẹ́lì 7:1.

◼ Báwo ni ànímọ́ àtohun táwọn tó kọ Bíbélì nífẹ̀ẹ́ sí ṣe hàn nínú ohun tí wọ́n kọ?—Mátíù 27:3; Lúùkù 4:38.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́