Ojú Ìwòye Bíbélì
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ọ̀ràn Àtúnṣe Ilẹ̀ Ayé?
OHUN táwọn èèyàn ń ṣe lórí ilẹ̀ yìí ń ṣàkóbá tó pọ̀ gan-an, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé àkókò tá a wà yìí ni àkóbá táwọn èèyàn ń ṣe fún ilẹ̀ ayé yìí tíì pọ̀ jù lọ. Nítorí oríṣiríṣi ìbàjẹ́ tó ń bá ilẹ̀ ayé báyìí, tó fi mọ́ ooru tó ń pọ̀ lápọ̀jù, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, àwọn ìjọba àtàwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ń sapá ní gbogbo ọ̀nà láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá.
Ǹjẹ́ nǹkan kan tiẹ̀ wà tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe lórí títún àyíká wa ṣe? Bí ohun kan bá wà tá a lè ṣe, ibo la lè ṣe é dé? Bíbélì mẹ́nu ba àwọn ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa ṣe ohun tí kò ní máa ṣàkóbá fún orí ilẹ̀ ayé yìí. Ó tún jẹ́ ká mọ ọ̀nà tá a lè gbà ṣe é tá à fi ní kọjá àyè wa.
Bá A Ṣe Lè Máa Ṣe Ohun Tó Bá Ìfẹ́ Ẹlẹ́dàá Wa Mu
Jèhófà Ọlọ́run dá orí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ọgbà ẹlẹ̀wá fún aráyé láti máa gbénú ẹ̀. Ó sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ pé “ó dára gan-an ni,” ó sì ní kí aráyé “máa ro [ilẹ̀ ayé]” kí wọ́n sì “máa bójú tó o.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28, 31; 2:15) Báwo ni ipò tí ayé yìí wà báyìí ṣe rí lójú Ọlọ́run? Ó dájú pé ọwọ́ táwọn èèyàn fi mú orí ilẹ̀ ayé ò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú rárá àti rárá, nítorí pé Ìṣípayá 11:18 sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run á “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” Fún ìdí yìí, kò yẹ ká máa dágunlá sí ipò tí orí ilẹ̀ ayé yìí wà.
Bíbélì mú kó dá wa lójú pé gbogbo ìbàjẹ́ yòówù kí aráyé ti ṣe lórí ilẹ̀ ayé yìí ni Ọlọ́run máa mú kúrò nígbà tó bá ń “sọ ohun gbogbo di tuntun.” (Ìṣípayá 21:5) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ máa ronú pé ohun tó bá wù wá la lè máa ṣe torí pé Ọlọ́run máa tó tún ilẹ̀ ayé yìí ṣe. Kékeré kọ́ ni àkóbá tí irú èrò bẹ́ẹ̀ lè ṣe fún orí ilẹ̀ ayé yìí. Ọ̀nà wo la wá lè gbà fi hàn pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ayé yìí làwa náà fi ń wò ó, báwo la sì ṣe lè máa ṣe ohun tó máa fi hàn pé a fẹ́ kí ayé yìí di Párádísè bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí?
Bá A Ṣe Lè Máa Mú Kí Ilẹ̀ Ayé Wà Ní Mímọ́
Àwọn ohun tẹ́dàá èèyàn ń ṣe ò lè ṣàì máa dá pàǹtírí sílẹ̀. Jèhófà ti fọgbọ́n dá ayé lọ́nà táwọn ìdọ̀tí wọ̀nyí ò fi ní máa dà wá láàmú, táfẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ á máa mọ́, tómi á máa mọ́ lóló, tí orí ilẹ̀ ò sì ní di àkìtàn. (Òwe 3:19) Ó yẹ kí ọ̀nà tá à ń gbà ṣe nǹkan bá àwọn ètò tí Jèhófà ti ṣe wọ̀nyí mu. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra ṣe kó má lọ jẹ́ pé ńṣe la tún ń pa kún àkóbá tí ìdọ̀tí ń ṣe fún ilẹ̀ ayé yìí. Tá a bá ń tọ́jú àyíká wa, ńṣe ló ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa. (Máàkù 12:31) Wo àpẹẹrẹ kan látinú ìtàn Bíbélì.
Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ẹ̀yìn “òde ibùdó” ni kí wọ́n máa bo ìgbọ̀nsẹ̀ wọn mọ́. (Diutarónómì 23:12, 13) Èyí jẹ́ kí ibi tí wọ́n pàgọ́ sí wà ní mímọ́; kò sáwọn kòkòrò tó ń fa àrùn, ó sì ń jẹ́ kí ìgbọ̀nsẹ̀ tètè jẹrà. Bákan náà lónìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń gbìyànjú láti tètè da àwọn ìdọ̀tí àtàwọn nǹkan ẹlẹ́gbin míì nù. Àmọ́, a ní láti máa ṣọ́ra ṣe tá a bá ń da àwọn nǹkan tó ní májèlé nù.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ohun tá a kà sí ìdọ̀tí wọ̀nyí ló ṣì ṣeé tún lò lọ́nà míì. Tí àwọn òfin kan bá wà lórílẹ̀ èdè rẹ tó dá lórí sísọ ìdọ̀tí di ohun tó wúlò, pípa irú òfin bẹ́ẹ̀ mọ́ á fi hàn pé ò ń fi ‘àwọn ohun ti Késárì fún Késárì.’ (Mátíù 22:21) Sísọ ìdọ̀tí dohun tó wúlò lè gba ìsapá o, àmọ́ ṣe ló ń fi hàn pé à ń wọ̀nà fún ìgbà tí ilẹ̀ ayé máa wà ní mímọ́ tónítóní.
Bá A Ṣe Lè Fọgbọ́n Lo Àwọn Nǹkan Tí Ọlọ́run Dá Sórí Ilẹ̀ Ayé
Ká tó lè máa rí oúnjẹ, ibùgbé àtàwọn nǹkan àmúṣagbára tó máa máyé dẹrùn fún wa, a nílò àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sórí ilẹ̀ ayé. Bá a ṣe ń lo àwọn nǹkan wọ̀nyí á fi hàn bóyá a mọyì wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tí ẹran ń wu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ láginjù, Jèhófà pèsè àparò fún wọn lọ́pọ̀ yanturu. Ìwọra àti ojúkòkòrò tí wọ́n ní mú kí wọ́n fi ohun tí Ọlọ́run pèsè fún wọn ṣòfò, èyí sì bí Jèhófà Ọlọ́run nínú gan-an. (Númérì 11:31-33) Ọlọ́run ò tíì yí padà o. Àwọn Kristẹni tó mọ̀wà hù kì í ṣe oníwọra, torí náà wọn kì í fàwọn ohun tí Jèhófà pèsè ṣòfò.
Àwọn kan lè máa ronú pé bó bá ṣe wu àwọn làwọ́n ṣe lè lo àwọn ohun àmúṣagbára tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ lo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run pèsè ní ìlò àpà torí pé a lówó ẹ̀ lọ́wọ́ tàbí torí pé ó pọ̀ lápọ̀jù. Nígbà tí Jésù bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà ìyanu, ó ní káwọn ọmọlẹ́yìn òun kó èébù búrẹ́dì àti ẹja tó ṣẹ́ kù jọ. (Jòhánù 6:12) Ó rí i dájú pé òun ò fi ohun tí Bàbá òun pèsè ṣòfò.
Bá Ò Ṣe Ní Kọjá Àyè Wa
Àwọn ìpinnu tá à ń ṣe lójoojúmọ́ máa ń nípa lórí àyíká ibi tá à ń gbé. Ṣó wá yẹ ká ta kété sí gbogbo àwọn nǹkan tó wà láyé torí pé a ò fẹ́ ba àyíká wa jẹ́? Kò síbi tí Bíbélì ti gbà wá nírú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù. Nígbà tó wà láyé, ó ṣe ohun gbogbo níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ìyẹn ló sì jẹ́ kó ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́. (Lúùkù 4:43) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù ò jẹ́ bá wọn lọ́wọ́ nínú ìṣèlú láti yanjú àwọn ìṣòro tó wà láwùjọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n-sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.”—Jòhánù 18:36.
Síbẹ̀, tá a bá ń pinnu ohun tá a fẹ́ tó bá dọ̀ràn ilé gbígbé, mọ́tò tàbí eré ìnàjú, ó yẹ ká máa ronú lórí ipa tí ìpinnu wa máa ní lórí àyíká wa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń fẹ́ ra àwọn ohun èlò tí ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe wọ́n àti ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà lò wọ́n ò ní máa ba àyíká jẹ́. Àwọn kan máa ń ṣọ́ra láti má máa ṣe ohunkóhun tó máa ba afẹ́fẹ́ jẹ́ tàbí táá máa mú kí wọ́n fi àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè ṣòfò.
A ò ní máa fi dandan mú káwọn ẹlòmíì ṣe bíi tiwa tó bá dọ̀ràn títún àyíká ṣe, torí pé àyíká àti ipò kálukú wa yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, olúkúlùkù ló máa dáhùn fún ìpinnu tó bá ṣe. Bí Bíbélì ṣe sọ, “olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ara rẹ̀.”—Gálátíà 6:5.
Àwa èèyàn ni Ẹlẹ́dàá gbé iṣẹ́ bíbójútó ilẹ̀ ayé lé lọ́wọ́. Tá a bá mọrírì iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ yìí, tá à ń bọ̀wọ̀ fún Un, tá a sì fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ohun tó dá, èyí á jẹ́ ká máa ronú jinlẹ̀ tá a bá fẹ́ ṣèpinnu tó máa nípa lórí bá a ṣe ń bójú tó ilẹ̀ ayé.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Ṣé Ọlọ́run máa tún ilẹ̀ ayé tó dà bí àkìtàn yìí ṣe?—Ìṣípayá 11:18.
◼ Kí ni ojúṣe àwa èèyàn tó bá dọ̀ràn títún ilẹ̀ ayé ṣe?—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15.
◼ Kí la rí kọ́ lára Jésù Kristi nípa fífọgbọ́n lo àwọn ohun tí Ọlọ́run pèsè?—Jòhánù 6:12.