Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra Fún Wíwo Àwòrán Oníhòòhò?
“Ọmọkùnrin kan tí kọ́bọ́ọ̀dù ẹ̀ ò jìnnà sí tèmi níléèwé wa lẹ àwòrán ọmọbìnrin kan tó wà níhòòhò mọ́ ilẹ̀kùn kọ́bọ́ọ̀dù rẹ̀.”—Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Robert.a
“Ìwádìí kan tí wọ́n ní ká ṣe wá níléèwé ni mò ń ṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ṣàdédé ni mo rí àwòrán oníhòòhò tó yọ lórí kọ̀ǹpútà mi.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Annette.
NÍGBÀ táwọn òbí rẹ wà lọ́dọ̀ọ́ bíi tìẹ, àwòrán oníhòòhò kì í ṣe ohun tí wọ́n ń rí káàkiri ìgboro. Àmọ́ lóde òní, ó ti wá di mẹ́ta kọ́bọ̀. Bíi ti Robert tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan, ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti ṣèèṣì ráwọn àwòrán oníhòòhò táwọn akẹgbẹ́ ẹ mú wá síléèwé tàbí kó o ṣèèṣì rí i lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì bíi ti Annette. Ọmọbìnrin ọlọ́dún mọ́kàndínlógún kan sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà tí mo bá ń ṣe nǹkan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, bóyá ṣe ni mò ń wo ọjà tí mo lè rà tàbí tí mo fẹ́ wo iye tí mo ní ní báńkì, ńṣe làwòrán oníhòòhò kàn máa ń yọ gannboro lórí kọ̀ǹpútà mi!”b
Èyí kì í ṣe tuntun mọ́. Ìwádìí kan fi hàn pé mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá lára àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ sí mẹ́rìndínlógún ló sọ pé lọ́pọ̀ ìgbà táwọn bá ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n ní káwọn ṣe wá níléèwé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ṣe làwọ́n kàn máa ń ṣèèṣì rí àwòrán oníhòòhò lórí kọ̀ǹpútà àwọn! Òótọ́ tí ò ṣeé já ní koro ni pé àwòrán oníhòòhò ti wá pọ̀ nígboro torí pé ọ̀kẹ́ àìmọye ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló ń gbé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwòrán oníhòòhò sórí ìkànnì wọn báyìí. Kódà, wọ́n máa ń wò ó lórí fóònù alágbèéká pàápàá. Denise tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún sọ pé: “Kì í ṣe nǹkan bojúbojú mọ́ níléèwé wa. Ohun tí wọ́n sábà máa ń bi ara wọn ní gbogbo ọjọ́ Monday ni pé, ‘Àwòrán wo lo gbé sórí fóònù ẹ lópin ọ̀sẹ̀?’”
Bó o ti ṣe wá mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wo àwòrán oníhòòhò báyìí, o lè máa ronú pé, ‘Ṣé bẹ́ẹ̀ náà ló burú tó ni?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ó burú tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Mẹ́ta rèé lára àwọn nǹkan tó fi hàn pé kò yẹ ọmọlúwàbí:
◼ Àwòrán oníhòòhò ń tàbùkù sáwọn tó ń ṣe é àtàwọn tó ń wò ó.—1 Tẹsalóníkà 4:3-5.
◼ Ohun táwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí wíwo àwòrán oníhòòhò ń ṣe kò yàtọ̀ sí tàwọn áńgẹ́lì búburú tí ìbálòpọ̀ ti jàrábà wọn nígbà ayé Nóà.—Jẹ́nẹ́sísì 6:2; Júúdà 6, 7.
◼ Ó máa ń rọrùn fáwọn tó ń wo àwòrán oníhòòhò láti kó sínú ẹ̀ṣẹ̀ nípa ṣíṣèṣekúṣe.—Jákọ́bù 1:14, 15.
Àwòrán oníhòòhò máa ń ba gbogbo àwọn tó bá kó sínú páńpẹ́ ẹ̀ láyé jẹ́ ni. Gbé ìrírí àwọn ẹni méjì péré yẹ̀ wò:
“Láti kékeré ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí wo àwòrán oníhòòhò, mo sì jà fitafita kí n tó lè gba ara mi lọ́wọ́ ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó ọdún mélòó kan báyìí, síbẹ̀ àwọn àwòrán wọ̀nyẹn ṣì wà lọ́pọlọ mi. Àwọn àwòrán yẹn kì í fẹ́ kúrò lọ́kàn èèyàn, ńṣe ló sì máa ń jẹ́ kó dà bíi pé ẹ̀rí ọkàn èèyàn ò mọ́. Wíwo àwòrán oníhòòhò máa ń sọ èèyàn di alábùkù táá sì wá jẹ́ kẹ́ni náà máa wo ara rẹ̀ bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Onítọ̀hún á wá máa dá jẹ ìrora ọkàn.”—Erica.
“Ọdún mẹ́wàá gbáko ni mo fi wo àwòrán oníhòòhò léraléra, ó sì ti tó ọdún mẹ́rìnlá báyìí tí mo ti gbara mi lọ́wọ́ ẹ̀. Síbẹ̀, ojoojúmọ́ ló ṣì máa ń ṣe mí bíi kí n wò ó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í wù mí wò bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, síbẹ̀, kò tíì tán lára. Ó ṣì máa ń wù mí wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn àwòrán náà ò kúrò lọ́kàn mi. Kò bá ti dáa jù ká ní mi ò bẹ̀rẹ̀ sí í wo ìwòkuwò yìí. Ńṣe ló kọ́kọ́ ń dùn mọ́ mi, àmọ́ ní báyìí mo ti wá rí i pé ó léwu. Wíwo àwòrán oníhòòhò ń bayé ẹni jẹ́, ohun ìríra ni, ó ń tàbùkù sáwọn tó ń ṣe é, ọmọlúwàbí kan kì í sì í wò ó. Ká sòótọ́, irọ́ funfun báláú làwọn tó ń gbé àwòrán oníhòòhò jáde ń pa tí wọ́n bá sọ pé ó dáa kéèyàn máa wò ó. Kò sí nǹkan kan bó ti wù kó mọ tó dáa nínú wíwò ó.”—Jeff.
Ṣàyẹ̀wò Ara Rẹ
Kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa ṣèèṣì fojú kan àwòrán oníhòòhò rárá? Kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò bó o ṣe máa ń rí i.
Báwo lo ṣe máa ń ṣèèṣì rí àwọn àwòrán oníhòòhò tó?
□ Mi ò rí i rí □ Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan
□ Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ □ Ojoojúmọ́
Ibo lo ti sábà máa ń rí i?
□ Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì □ Ilé ìwé
□ Orí tẹlifíṣọ̀n □ Ibòmíì
Ṣé ọ̀nà kan wà tó sábà máa ń gbà yọjú?
Gbé àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí yẹ̀ wò:
Ṣó o rò pé àwọn kan lára àwọn ọmọ ilé ìwé rẹ lè fi àwòrán oníhòòhò kún ohun tí wọ́n bá fi ránṣẹ́ sórí tẹlifóònù alágbèéká rẹ tàbí sí àdírẹ́sì tó o fi ń gba lẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Tó o bá ti mọ̀ bẹ́ẹ̀ á dáa kó o tètè pa á rẹ́ láìwulẹ̀ wò ó.
Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tó o fi ń wá ìsọfúnni lórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì tó máa ń gbé àwòrán oníhòòhò wá pẹ̀lú ìsọfúnni tó o nílò? Tó o bá ti mọ̀ pé irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀, á dáa kó o mọ irú ọ̀rọ̀ tí wàá máa fi wá ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
Kọ àwọn nǹkan tó ti mú kó o rí àwòrán oníhòòhò rí sísàlẹ̀ yìí.
․․․․․
Nígbà tó o ti wá mọ àwọn nǹkan tó máa ń jẹ́ kó o rí àwòrán oníhòòhò báyìí, kí lo rò pé o lè ṣe láti dín iye ìgbà tó o máa ń ṣèèṣì rí àwòrán oníhòòhò kù? (Kọ àwọn ohun tó o rò pé o lè ṣe síbí yìí.)
․․․․․
Kí lo máa ń ṣe nígbà tó o bá ṣèèṣì rí àwòrán oníhòòhò?
□ Mo máa ń yára gbójú kúrò níbẹ̀.
□ Mo máa ń wò ó díẹ̀ kí n lè mohun tó jẹ́.
□ Mo máa ń wò ó lọ nítèmi ni, mo tún máa ń wá sí i pàápàá.
Tó bá jẹ́ pé gbólóhùn kejì tàbí ìkẹta lo sàmì sí, kí ló yẹ kó o ṣe?
․․․․․
Bó O Ṣe Lè Jáwọ́ Ńbẹ̀
Àwọn kan tó ṣèèṣì rí àwòrán oníhòòhò máa ń fẹ́ wò ó díẹ̀ sí i, nígbà tó bá sì yá, á wá di bárakú. Kò rọrùn láti jáwọ́ nínú àṣà yẹn tó bá ti mọ́ra. Jeff, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Kó tó di pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí oògùn olóró tó lókìkí tí mi ò tíì bá wọn lò rí. Àmọ́ kò séyìí tó di bárakú fún mi tó wíwo àwòrán oníhòòhò.”
Tí wíwo àwòrán oníhòòhò bá ti di bárakú fún ẹ, má bọkàn jẹ́ jù. O ṣì lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Lọ́nà wo?
◼ Mọ̀ pé ohun tó burú ni wíwo àwòrán oníhòòhò jẹ́. Ó dájú pé Sátánì ló ń lò ó láti sọ ẹ̀yà ara ìbímọ tí Jèhófà dá gẹ́gẹ́ bí ohun pàtàkì di yẹpẹrẹ. Tó bá jẹ́ pé ojú tíwọ náà fi ń wo àwòrán oníhòòhò nìyẹn, wàá máa “kórìíra ohun búburú.”—Sáàmù 97:10.
◼ Ronú nípa ohun tó máa ń tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. Àwòrán oníhòòhò máa ń da àárín tọkọtaya rú. Kì í jẹ́ ká mọyì ara wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ohun àbùkù ló sì jẹ́ fẹ́ni tó ń wò ó. Ṣó o wá rí ìdí tí Bíbélì fi sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Kọ àkóbá tí sísọ wíwo àwòrán oníhòòhò dàṣà lè ṣe fún ẹ.
․․․․․
◼ Ṣèpinnu. Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ yẹn sọ pé: “Mo ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti má ṣe fi ojú àgbèrè wo ọmọbìnrin.” (Jóòbù 31:1, ìtumọ̀ Today’s English Version) Àwọn “ẹ̀jẹ́” mélòó kan tó o lè jẹ́ rèé:
□ Mi ò ní máa lọ sídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí kò bá ti séèyàn lọ́dọ̀ mi.
□ Tí àwòrán oníhòòhò bá ṣèèṣì yọ lójú kọ̀ǹpútà nígbà tí mo bá wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kíá ni màá gbé e kúrò ńbẹ̀.
□ Màá sọ fún àgbàlagbà kan tó sún mọ́ mi nígbà tí mo bá tún ti wo àwòrán oníhòòhò.
Ṣó o lè ronú nípa ohun kan tàbí méjì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú wíwo àwòrán oníhòòhò? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kọ wọ́n síbí yìí.
․․․․․
◼ Fọ̀ràn náà sínú àdúrà. Onísáàmù náà gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.” (Sáàmù 119:37) Ká sòótọ́, kò rọrùn láti gba ara ẹni lọ́wọ́ ohun tó máa ń dùn mọ́ ẹran ara ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí. Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kó o bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì máa fún ẹ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” kó o bàa lè máa ṣohun tó tọ́!—2 Kọ́ríńtì 4:7.
◼ Fọ̀rọ̀ lọ ẹnì kan. Àbí ojú ń tì ẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni? Ó ṣeé ṣe! Síbẹ̀, wo bí ara ṣe máa tù ẹ́ tó bó o bá rẹ́ni fọ̀rọ̀ lọ̀. Ẹni tó o fọ̀rọ̀ lọ̀ yẹn lè wá dà bí “arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Ọ̀nà pàtàkì kan téèyàn lè gbà jáwọ́ nínú irú ìwà bẹ́ẹ̀ ni pé kó wá ẹni táá máa fọ̀rọ̀ lọ̀.
Tí wíwo àwòrán oníhòòhò bá ti wọ̀ ẹ́ lẹ́wù, kọ orúkọ ẹnì kan tó lóye, tó o rò pé á rọrùn fún ẹ láti fọ̀rọ̀ náà lọ̀ síbí yìí.
․․․․․
Mọ̀ dájú pé á ṣeé ṣe fún ẹ láti gbara ẹ lọ́wọ́ àṣà wíwo àwòrán oníhòòhò. Àní sẹ́, ní gbogbo ìgbà tó o bá ti ń lè gbójú kúrò níbẹ̀, o ti ṣẹ́gun ẹ̀ débì kan. Sọ fún Jèhófà nípa àṣeyọrí tó o ṣe yẹn, kó o wá dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ fún okun tó fún ẹ. Máa rántí pé bó o bá ṣe ń yẹra fún wíwo àwòrán oníhòòhò tó ń bani láyé jẹ́ yìí, ńṣe lò ń múnú Jèhófà dùn!—Òwe 27:11.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí padà.
b Àwòrán oníhòòhò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń rùmọ̀lára ẹni sókè láti ní ìbálòpọ̀. Orin tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tá a gbọ́ tàbí tá a kà nínú ìwé pàápàá lè rùmọ̀lára ẹni sókè láti ní ìbálòpọ̀.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Báwo ni àwòrán oníhòòhò ṣe ń sọ nǹkan pàtàkì di yẹpẹrẹ?
◼ Kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe tó lè mú kó o bọ́ lọ́wọ́ wíwo àwòrán oníhòòhò?
◼ Báwo lo ṣe lè ran ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ tó bá ń wo àwòrán oníhòòhò lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Ṣó o rò pé àwọn kan lára àwọn ọmọ ilé ìwé rẹ lè fi àwòrán oníhòòhò kún ohun tí wọ́n bá fi ránṣẹ́ sórí tẹlifóònù alágbèéká rẹ?