Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Máa Ṣépè?
“Mo fẹ́ máa ṣe bíi tàwọn ọmọ iléèwé mi. Mo rò pé ohun tó fà á nìyẹn tí mo fi máa ń ṣépè.” —Melanie.a
Èmi ò ka èpè ṣíṣẹ́ sí nǹkan bàbàrà. Ojoojúmọ́ ni mò ń gbọ́ táwọn èèyàn ń ṣépè, nílé ẹ̀kọ́ àti nínú ilé.”—David.
KÍ LÓ dé tó fi jẹ́ pé táwọn àgbàlagbà bá ń ṣépè tàbí tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ rírùn, àwọn èèyàn kì í rí ohun tó burú níbẹ̀, àmọ́ táwọn ọ̀dọ́ bá wá ń ṣépè ariwo á ta? Ṣé ọjọ́ orí la fi ń mọ̀ bóyá ó tọ́ kéèyàn máa ṣépè ni? Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti máa ń pèdè tí ò dáa lẹ́nu, tó sì wá dà bíi pé ẹní bá dàgbà ló lè ṣépè, àmọ́ ọmọdé ò gbọ́dọ̀ ṣépè, o lè bi ara ẹ pé, “Kí ló burú nínú kéèyàn máa ṣépè?”
Bí Èpè Ṣíṣẹ́ Ṣe Máa Ń Mọ́ni Lára
Kò sí iyè méjì pé níbi gbogbo làwọn èèyàn ti máa ń ṣépè. Kódà, àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń sọ pé bó bá jẹ́ pé gbogbo èpè táwọn ń gbọ́ sétí níléèwé làwọn ń gbowó lé lórí, owó ọ̀hún á ti pọ̀ débi pé àwọn ò ní wáṣẹ́ mọ́, àwọn òbí àwọn sì lè fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ tiwọn. Eve, ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sọ pé: “Bá a bá ń sọ̀rọ̀ lásán, ó dà bíi pé àwọn ọmọléèwé mi ò lè ṣe kí wọ́n máà ṣépè lọ́pọ̀ ìgbà nínú gbólóhùn kọ̀ọ̀kan tó ń jáde lẹ́nu wọn. Bó o bá ń gbọ́ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀, agbára káká nìwọ náà ò fi ní di ọ̀kan lára wọn.”
Ṣé àwọn tó ń ṣépè ló yí ìwọ náà ká bíi ti Eve? Àbí ìwọ náà ti ń bá wọn ṣépè?b Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ronú díẹ̀ lórí ohun tó fà á tó o fi ń ṣépè. Bó o bá ti mọ ohun tó fà á, á rọrùn fún ẹ láti jáwọ́ ńbẹ̀.
Pẹ̀lú èyí lọ́kàn ẹ, gbìyànjú láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
Kí ló máa ń fà á tó o fi ń ṣépè?
□ Bínú bá ń bí mi tàbí tọ́rọ̀ bá ká mi lára
□ Bí mi ò bá rẹ́ni dá sí mi
□ Káwọn ẹgbẹ́ mi lè gba tèmi
□ Kí wọ́n má bàa fojú ọ̀dẹ̀ wò mí
□ Kí n lè báwọn aláṣẹ fà á
□ Àwọn ìdí míì ․․․․․
Àwọn ìgbà wo ló máa ń ṣe ẹ́ jù lọ bíi kó o ṣépè?
□ Nílé ìwé
□ Lẹ́nu iṣẹ́
□ Bí mo bá ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tàbí tí mo bá ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí tẹlifóònù alágbèéká mi
□ Bí mo bá wà lémi nìkan
Kí lo fi máa ń dá èpè tó ò ń ṣẹ́ láre?
□ Àwọn ẹgbẹ́ mi ń ṣépè
□ Àwọn òbí ń ṣépè
□ Àwọn olùkọ́ ń ṣépè
□ Ó kún ẹnu àwọn òṣèré
□ Kò sí nǹkan bàbàrà ńbẹ̀, ọ̀rọ̀ lásán ni
□ Bí mo bá wà lọ́dọ̀ àwọn tí ò ka èpè sí ni mo máa ń ṣépè
□ Àwọn ìdí míì ․․․․․
Kí nìdí tó fi yẹ kó o sapá láti borí àṣà yìí? Ṣé òótọ́ ló burú pé kéèyàn máa ṣépè? Gbé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Èpè kì í ṣe ọ̀rọ̀ lásán. Jésù sọ pé: “Ohun tí ó bá kún inú ọkàn ẹni ni ẹnu ẹni í sọ jáde.” (Lúùkù 6:45, Ìròyìn Ayọ̀) Kíyè sí i pé kì í wulẹ̀ ṣe irú ẹni tá a máa fẹ́ láti jẹ́ lọ̀rọ̀ ẹnu wa máa ń sọ, ó tún máa ń sọ irú ẹni tá a ti jẹ́. Kódà, bó o bá ń pèdè tí ò dáa lẹ́nu torí pé àwọn míì ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ṣíṣe tó ò ń ṣe bíi tiwọn á fi hàn pé ò ń “tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀,” àti pé o ò mọ̀wàá hù.—Ẹ́kísódù 23:2.
Àmọ́, kò wá mọ síbẹ̀ yẹn o. Ọkùnrin pèdèpèdè kan tó ń jẹ́ James V. O’Connor sọ pé: “Àwọn tó máa ń ṣépè sábà máa ń jẹ́ oníjà, wọ́n máa ń le koko, wọ́n máa ń fàwọn èèyàn ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n máa ń bínú, wọ́n máa ń jiyàn, gbogbo nǹkan ni wọ́n sì máa ń ráhùn lé lórí.” Bí àpẹẹrẹ, lójú àwọn tó máa ń ṣépè bí nǹkan ò bá rí bí wọ́n ṣe rò, ṣe ló máa ń dà bíi pé kí nǹkan máa lọ déédéé ṣáá. Torí wọn ò rí ara gba àṣìṣe sí. Àmọ́, ní ti àwọn tí kì í ṣépè, O’Connor sọ pé “ara wọn sábà máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, . . . wọ́n dàgbà, wọ́n danú, inú kì í sì í bí wọn sódì.” Irú èèyàn wo ló wá yẹ kó o jẹ́ o?
Bó o bá ń ṣépè, wàá sọ ara ẹ lórúkọ. Bíi ti ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́, ó dájú pé kì í wù ẹ́ kó o múra wúruwùru. O fẹ́ kí ìrísí ẹ máa fa àwọn èèyàn mọ́ra. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o mọ̀ pé irú ọ̀rọ̀ tó ò ń sọ máa ń nípa tó pọ̀ gan-an lórí àwọn míì ju ìmúra rẹ lọ? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀rọ̀ tó ò ń sọ lè pinnu
◼ Ẹni tó máa fẹ́ láti bá ẹ ṣọ̀rẹ́.
◼ Bóyá wọ́n á gbà ẹ́ síṣẹ́ kan tàbí wọn ò ní gbà ẹ́.
◼ Báwọn èèyàn á ṣe máa bọ̀wọ̀ fún ẹ tó.
Òótọ́ ni, irú ojú yòówù káwọn èèyàn máa fi wò wá máa yí padà gbàrà tí wọ́n bá gbọ́rọ̀ ẹnu wa. O’Connor sọ pé: “O ò ní mọ iye àwọn tí ì bá ti bá ẹ ṣọ̀rẹ́ àmọ́ tí wọ́n ń sá fún ẹ, tàbí bó o ṣe ń lé àwọn èèyàn sá kúrò lọ́dọ̀ ara ẹ lemọ́lemọ́ tó tàbí bó o ṣe ń dẹni ẹ̀tẹ́ nítorí pé èdè ẹnu ẹ ò dáa.” Ẹ̀kọ́ wo lèyí wá kọ́ ẹ? Bó o bá ń pèdè tí ò dáa lẹ́nu, ara ẹ lò ń ṣe o.
Èpè ṣíṣẹ́ ò fọ̀wọ̀ hàn fún Ẹlẹ́dàá tó fún wa lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ. Ká sọ pé o fún ọ̀rẹ́ rẹ ní ṣẹ́ẹ̀tì tàbí bíláòsì kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ bí ọ̀rẹ́ ẹ bá sọ aṣọ tó o fún un di ìnulẹ̀? Nígbà náà, wá ronú nípa bó ṣe máa rí lára Ẹlẹ́dàá wa bá a bá ṣi ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ lò. Abájọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi sọ pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.”—Éfésù 4:31.
Wàá ti wá rí i báyìí pé, ọ̀pọ̀ ìdí rere ló wà tí kò fi yẹ ká máa ṣépè. Àmọ́, bó bá ti mọ́ ẹ lára pé kó o máa ṣépè, báwo lo ṣe lè ṣẹ́pá rẹ̀?
Àkọ́kọ́: Rí i pé ó yẹ kó o yíwà padà. Torí kò dájú pé wàá fẹ́ láti dẹ́kun èpè ṣíṣẹ́, àyàfi tó o bá mọ àǹfààní tó wà nínú pé kó o yí èdè tó ò ń pè padà. Èwo lára àwọn kókó tá a tò sísàlẹ̀ yìí ló máa mú kó o dẹ́kun èpè ṣíṣẹ́?
□ Ṣíṣe ohun tó wu Ẹlẹ́dàá tó dá wa láti máa sọ̀rọ̀
□ Jíjèrè ọ̀wọ̀ tó pọ̀ sí i látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíì
□ Wíwá ọ̀rọ̀ tó dáa sọ
□ Mímú irú ẹni tí mo jẹ́ sunwọ̀n sí i
Ìkejì: Ronú lórí ohun tó fà á tó o fi máa ń ṣépè. Melanie sọ pé: “Èpè ṣíṣẹ́ ni kì í jẹ́ kí wọ́n máa fojú ọ̀dẹ̀ wò mí. Mi ò kí ń fẹ́ káwọn èèyàn máa dà mí ríborìbo. Mo máa ń fẹ́ kí n máa kó àwọn èèyàn jẹ̀, kí n sì máa láálí wọn bí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe máa ń ṣe.”
Ìwọ ńkọ́? Ṣe ni kó o mọ ohun tó máa ń fà á tó o fi ń ṣépè, ìyẹn á sì jẹ́ kó o mọ bó o ṣe máa yanjú ìṣòro náà. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé torí pé gbogbo èèyàn ń ṣépè nìwọ náà fi ń ṣépè, ó yẹ kí ìwọ náà mọ bó o ṣe lè dá ṣe ohun tó tọ́. Ṣíṣe ohun tó o bá mọ̀ pó tọ́ jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó máa fi hàn pé ìwọ náà ti ń dàgbà, ìrànlọ́wọ́ ńlá sì nìyẹn máa jẹ́ fún ẹ láti dẹ́kun èpè ṣíṣẹ́.
Ìkẹta: Wá àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà máa sọ ohun tó bá wà lọ́kàn ẹ. Kì í wulẹ̀ ṣe pé kára máa ta ẹ́. Lára ohun tó tún lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fòpin sí èpè ṣíṣẹ́ ni pé kó o gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.” (Éfésù 4:22-24) Èyí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa kóra ẹ níjàánu kó o sì máa ka ara ẹ kún, á sì tún jẹ́ kó o máa bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíì.
Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, kí ìwà náà má sì ṣe fi ẹ́ sílẹ̀.
Kólósè 3:2: “Ẹ máa gbé èrò inú yín ka àwọn nǹkan ti òkè.”
Bó ṣe kàn ẹ́: Kọ́ ara ẹ lọ́nà tí wàá fi lè máa ronú lórí àwọn ohun tó tọ́, torí pé èrò rẹ máa ń nípa lórí ohun tó o bá ń sọ.
Òwe 13:20: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”
Bó ṣe kàn ẹ́: O lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ bíi tàwọn ọ̀rẹ́ ẹ.
Sáàmù 19:14: “Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà.”
Bó ṣe kàn ẹ́: Jèhófà máa ń tẹ́tí sí bá a ṣe ń lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ.
Ṣó o ṣì nílò ìrànlọ́wọ́? O ò kúkú ṣe lo àtẹ tó wà nísàlẹ̀ yìí láti wo bó o ṣe máa ń ṣépè sí? Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu pé kò ní pẹ́ tó ò fi ní ṣépè mọ́!
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.
b Àwọn Kristẹni ní ìdí tó ṣe gúnmọ́ tí wọn ò fi gbọ́dọ̀ máa pèdè tí ò dáa lẹ́nu, torí Bíbélì sọ pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde.” “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.”—Éfésù 4:29; Kólósè 4:6.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
Báwo ni èpè ṣíṣẹ́ ṣe lè nípa lórí
◼ irú àwọn tó máa fẹ́ láti bá ẹ ṣọ̀rẹ́?
◼ bóyá àwọn èèyàn á fẹ́ láti gbà ẹ́ síṣẹ́ tàbí wọn ò ní fẹ́?
◼ ojú táwọn míì á fi máa wò ẹ́?
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 21]
WO BÓ O ṢE Ń ṢE DÁADÁA SÍ
Monday Tuesday Wednesday Thursday Friday Saturday Sunday
Ọ̀sẹ̀ 1 ․․․․․․ ․․․․․․․ ․․․․․․․․․ ․․․․․․․․ ․․․․․․ ․․․․․․․․ ․․․․․․
Ọ̀sẹ̀ 2 ․․․․․․ ․․․․․․․ ․․․․․․․․․ ․․․․․․․․ ․․․․․․ ․․․․․․․․ ․․․․․․
Ọ̀sẹ̀ 3 ․․․․․․ ․․․․․․․ ․․․․․․․․․ ․․․․․․․․ ․․․․․․ ․․․․․․․․ ․․․․․․
Ọ̀sẹ̀ 4 ․․․․․․ ․․․․․․․ ․․․․․․․․․ ․․․․․․․․ ․․․․․․ ․․․․․․․․ ․․․․․․
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
O ò ní fẹ́ ṣi ẹ̀bùn tó ṣeyebíye lò. Kí lo wá fẹ́ máa lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ lọ́nà tí kò tọ́ fún?