Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Báwo Ni Ìjọsìn Ọlọ́run Ṣe Lè Gbádùn Mọ́ Mi?
Josh, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] nà gbalaja sórí ibùsùn rẹ̀. Màmá ẹ̀ dúró sẹ́nu ọ̀nà yàrá ẹ̀, ó sì ké mọ́ ọn pé: “Joshua, dìde ńlẹ̀! Ṣé wàá ló ò mọ̀ pé ìpàdé ti yá ni!” Wọ́n tọ́ Josh dàgbà bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun àtàwọn òbí ẹ̀ sì máa ń lọ sí ìpàdé ìjọ déédéé. Àmọ́, lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ó dà bíi pé kò wù ú láti máa lọ sípàdé mọ́.
Ó wá fún màmá ẹ̀ lésì pé: “Ẹ má yọ mí lẹ́nu o jàre, ṣé dandan ni kí n lọ ni?”
Màmá ẹ̀ náà dá a lóhùn pé: “Ẹjọ́ tó o rò yẹn tó ẹ, ṣáà lọ múra. Mi ò tún fẹ́ pẹ́ lónìí o!” Màmá ẹ̀ yí pa dà, ó sì bá tiẹ̀ lọ.
Josh ò tíì jẹ́ kí màmá ẹ̀ lọ tán tó ti gbaná jẹ. Ó sọ pé: “Ẹ wò ó, màámi, ó lè jẹ́ pé ẹ̀sìn tẹ́yin fẹ́ nìyẹn, àmọ́ ẹ ò lè fipá mú mi wọnú ẹ̀.” Ó mọ̀ pé màmá òun gbọ́ ohun tóun sọ, torí pé kò gbúròó ẹsẹ̀ rẹ̀ mọ́. Lẹ́yìn náà, láìfèsì, màmá ẹ̀ bá tirẹ̀ lọ.
Josh dára ẹ̀ lẹ́bi nítorí ohun tó ṣe yẹn. Kò wù ú kó sọ̀rọ̀ sí màmá ẹ̀ bẹ́ẹ̀ yẹn. Síbẹ̀, kò fẹ́ tọrọ àforíjì. Kí ni ì bá wá ṣe báyìí o . . .
Ó mí kanlẹ̀ hìn-ìn, ó dìde kúrò lórí ibùsùn, ó sì mẹ́wù wọ̀. Ó wá ń kùn lọ pé: “Bó pẹ́ bó yá, màá kúkú yan ẹ̀sìn tó wù mí. Tèmi yàtọ̀ sì tàwọn yòókù tá a jọ wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kò sì dá bíi pé Kristẹni ni Ọlọ́run dá mi!”
ṢÓ TI ṣèwọ náà rí bíi ti Josh tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀ tán yìí? Nígbà míì, ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé báwọn míì tiẹ̀ gbádùn àti máa lọ sípàdé, òde ẹ̀rí, kí wọ́n sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ńṣe nìwọ wulẹ̀ ń tẹ̀ lé àwọn òbí ẹ lọ, àmọ́ ọkàn rẹ ò sí níbẹ̀? Bí àpẹẹrẹ:
◼ Ṣé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń dà bí ìgbà tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ fún ẹ láti ṣe wá nílé ìwé?
◼ Ṣé kì í yá ẹ lára láti wàásù láti ilé dé ilé?
◼ Ṣé ìpàdé máa ń sú ẹ?
Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ “bẹ́ẹ̀ ni” sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè yẹn, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Bó o bá lè ṣe àwọn ìyípadà díẹ̀, o lè kọ́ nípa bí wàá ṣe máa gbádùn iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Jẹ́ ká wo àwọn ohun tó o lè ṣe.
Ìṣòro Àkọ́kọ́: Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Ìdí tí kò fi rọrùn. Bóyá o lérò pé kò mọ́ ẹ lára láti máa kẹ́kọ̀ọ́. Ó dà bíi pé ìwé kì í pẹ́ sú ẹ, ó sì máa ń ṣòro fún ẹ láti jókòó jẹ́ẹ́ kó o sì pọkàn pọ̀! Yàtọ̀ síyẹn, ṣé ohun tó ò ń kọ́ nílé ìwé ò tíì pọ̀ tó ni?
Ìdí tó fi yẹ kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kì í wulẹ̀ ṣe pé Ọlọ́run mí sí Bíbélì nìkan ni, àmọ́ ó tún “wúlò fún kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àti ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti fún títọ́ wọn sọ́nà àti fún fífi báa ṣe lè gbélé ayé hàn wọ́n.” (2 Tímótì 3:16, ìtumọ̀ Contemporary English Version) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tó o bá kà lè jẹ́ kí ojú rẹ là sí ọ̀pọ̀ nǹkan tó ò tíì mọ̀. Ibi tọ́rọ̀ náà tiẹ̀ wà ni pé kò sí ohun rere kankan tọ́wọ́ èèyàn lè tẹ̀ láyé yìí láìjẹ́ pé ó fara ṣiṣẹ́ fún un. Bó o bá fẹ́ mọ eré ìdárayá kan ṣe dáadáa, o gbọ́dọ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe eré náà, kó o sì máa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. Bó o bá fẹ́ kára ẹ jí pépé, o gbọ́dọ̀ máa ṣeré ìmárale. Bó o bá fẹ́ mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá rẹ, o gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Ohun tí díẹ̀ lára àwọn ojúgbà rẹ máa ń sọ. “Ìgbà tí mo délé ìwé gíga ni mo tó mọ̀ pé ìpinnu pàtàkì kan wà tó yẹ kí n ṣe. Gbogbo nǹkan tí kò dáa ló kún ọwọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé wa, torí náà, mo ní láti ṣe àwọn ìpinnu tó dá lórí àwọn ìbéèrè bíi, ‘Ṣé ohun tí mo fẹ́ láti ṣe nìyẹn? Ṣé ojúlówó òtítọ́ làwọn òbí mi ń kọ́ mi?’ Àfi kí èmi fúnra mi wádìí ọ̀ràn náà wò.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Tshedza.
“Mo mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ mi, ohun tó wá kù ni pé kí n mú un dá ara mi lójú. Mo gbọ́dọ̀ sọ ọ́ di ìsìn mi, kó má wulẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi ló ń sún mi ṣe é.”—Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nelisa.
Ohun tó o lè ṣe. Ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí wàá lè máa lò fún dídá kẹ́kọ̀ọ́. Kó o wá yan àwọn ohun tí wàá fẹ́ láti ṣèwádìí lé lórí. Ibo lo ti lè bẹ̀rẹ̀? O ò ṣe walẹ̀ jìn nínú Bíbélì rẹ kó o sì ṣàyẹ̀wò ohun tó o gbà gbọ́ fínnífínní, bóyá nípa lílo ìwé bíi Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?a
Ohun tí màá ṣe. Láti bẹ̀rẹ̀, fàmì sí méjì tàbí mẹ́ta lára àwọn àkòrí Bíbélì tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa wọn lára àwọn tá a tò sísàlẹ̀ yìí, o sì lè kọ díẹ̀ lára tìẹ náà síbẹ̀, bó o bá fẹ́.
□ Ṣé Ọlọ́run wà?
□ Báwo ló ṣe lè dá mi lójú pé Ọlọ́run mí sí àwọn tó kọ Bíbélì?
□ Kí nìdí tó fi yẹ kí n gba Bíbélì gbọ́ dípò ẹfolúṣọ̀n?
□ Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, báwo ni mo sì ṣe lè ṣàlàyé pé ó wà lóòótọ́?
□ Báwo ni mo ṣe lè ṣàlàyé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn téèyàn bá ti kú?
□ Kí nìdí tó fi gbọ́dọ̀ dá mi lójú pé àjíǹde máa wà?
□ Báwo ni mo ṣe lè mọ ìsìn tòótọ́ yàtọ̀?
□ ․․․․․
Ìṣòro Kejì: Lílọ Sóde Ẹ̀rí
Ìdí tí kò fi rọrùn. Fífi ọ̀rọ̀ inú Bíbélì kọ́ àwọn ẹlòmíràn tàbí bíbá ọmọ ilé ìwé ẹni pàdé lóde ẹ̀rí, máa ń bani lẹ́rù nígbà míì.
Ìdí tó fi yẹ kó o wàásù. Jésù fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni pé: “Ẹ . . . sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìdí tún wà tó fi yẹ kó o máa wàásù. Ìwádìí fi hàn pé láwọn ibì kan, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló gba Ọlọ́run gbọ́ tí wọ́n sì ń lo Bíbélì. Síbẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ kan náà yẹn ò gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Látinú ẹ̀kọ́ tó o ti kọ́ nínú Bíbélì, o ti mọ àwọn nǹkan tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ojúgbà ẹ ń wá kiri, tó sì jẹ́ kòṣeémáàní fún wọn!
Ohun tí díẹ̀ lára àwọn ojúgbà ẹ sọ. “Èmi àti ọ̀rẹ́ mi múra ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó gbéṣẹ́, a sì kọ́ bá a ṣe lè borí àtakò àti bá a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò. Látìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi, ni mo ti túbọ̀ ń gbádùn ẹ̀.”—Nelisa.
“Ìrànlọ́wọ́ tí arábìnrin kan ṣe fún mi kúrò ní kékeré! Ọdún mẹ́fà ló gbà lọ́wọ́ mi, ó máa ń mú mi lọ sóde ẹ̀rí, ó sì máa ń fún mi lóúnjẹ àárọ̀ nígbà míì. Ó fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ń gbéni ró hàn mí. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà sì ràn mí lọ́wọ́ láti tún èrò mi pa. Àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀ fún mi ti wá mú kó ṣeé ṣe fún èmi náà láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́. Ó ti ṣe bẹbẹ fún mi!”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Shontay.
Ohun tó o lè ṣe. Báwọn òbí ẹ bá yọ̀ǹda fún ẹ, wá ẹnì kan tó jù ẹ́ lọ nínú ìjọ yín tẹ́ ẹ lè jọ máa lọ sóde ẹ̀rí. (Ìṣe 16:1-3) Bíbélì sọ pé: “Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.” (Òwe 27:17) Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn máa báwọn àgbàlagbà tó nírìírí kẹ́gbẹ́ pọ̀. Alexis, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé: “Ó tiẹ̀ máa ń rọrùn láti wà pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà.”
Ohun tí màá ṣe. Nísàlẹ̀, kọ orúkọ ẹnì kan nínú ìjọ yín, yàtọ̀ sáwọn òbí rẹ, tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lóde ẹ̀rí.
․․․․․
Ìṣòro Kẹta: Lílọ sí Ìpàdé Ìjọ
Ìdí tí kò fi rọrùn. Lẹ́yìn tó o bá ti jókòó fún àkókò gígùn nínú kíláàsì, títẹ́tí sí àsọyé tá a gbé karí Bíbélì fún wákàtí kan tàbí méjì lè dà bí ohun tí kò ní tán mọ́.
Ìdí tó fi yẹ kó o ṣe é. Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”—Hébérù 10:24, 25.
Ohun tí díẹ̀ lára àwọn ojúgbà rẹ sọ. “Dandan ni kéèyàn múra ìpàdé ìjọ sílẹ̀. Ìgbà míì tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé àfi kó o múra ẹ lọ́ranyàn. Bó o bá sì múra ìpàdé sílẹ̀, wàá gbádùn ìpàdé náà torí pé ohun tí wọ́n ń jíròrò máa yé ẹ, wàá sì lè dáhùn nípàdé.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Elda.
“Nígbà tó ṣe, mo bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí i pé ìpàdé tí mo bá lóhùn sí gan-an ló máa ń gbádùn mọ́ mi jù lọ.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jessica.
Ohun tó o lè ṣe. Wá àyè láti máa múra ìpàdé sílẹ̀, kó o sì dáhùn bí ìbéèrè bá jẹ yọ. Èyí ò ní jẹ́ kó dà bíi pé ńṣe lo kàn lọ mú ìjókòó gbóná lásán.
Àpẹẹrẹ kan rèé: Èwo ló máa ń gbádùn mọ́ni jù lọ nínú kéèyàn wo eré ìdárayá lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí kó lọ gbá bọ́ọ̀lù lórí pápá? Dájúdájú, ó ṣàǹfààní kéèyàn lọ gbá bọ́ọ̀lù lórí pápá ju kéèyàn jẹ́ òǹwòran lásán lọ. O ò kúkú ṣe máa fi ojú kan náà wo lílọ sáwọn ìpàdé ìjọ?
Ohun tí màá ṣe. Nínú àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí, ṣe àkọsílẹ̀ ìgbà tí wàá lè lo ọgbọ̀n ìṣẹ́jú péré lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti máa fi múra ìpàdé ìjọ sílẹ̀.
․․․․․
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti wá ń rí i báyìí pé òtítọ́ lọ̀rọ̀ inú Sáàmù 34:8, èyí tó sọ pé: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.” Àbí, ṣé ọ̀nà ọ̀fun tìẹ kì í dá tòlótòló tó o bá gbọ́ nípa oúnjẹ aládùn kan? Ṣé kó wà ní dáa kó o fẹnu ara ẹ tọ́ oúnjẹ náà wò? Bí ọ̀rọ̀ ìjọsìn Ọlọ́run náà ṣe rí nìyẹn. Tọ́ ọ wò fúnra ẹ, kó o sì rí bí lílọ sípàdé, kíkẹ́kọ̀ọ́, àti wíwàásù ti ṣàǹfààní tó. Bíbélì sọ pé ẹni tó jẹ́ olùṣe ọ̀rọ̀ náà, tí kì í wulẹ̀ ṣe olùgbọ́ nìkan “yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.”—Jákọ́bù 1:25.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Kí ló lè mú kó máa sú ọ̀dọ́ kan láti máa lọ sípàdé, kó máa kẹ́kọ̀ọ́, kó sì máa wàásù?
◼ Lára apá mẹ́ta tí ìjọsìn pín sí tá a jíròrò nínú àpilẹkọ yìí, èwo ni wàá fẹ́ láti ṣiṣẹ́ lé lórí, báwo lo sì ṣe máa ṣe é?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Bó o bá fẹ́ kára ẹ jí pépé, o gbọ́dọ̀ máa ṣeré ìmárale. Bó o bá fẹ́ kára ẹ jí pépé nípa tẹ̀mí, o gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run