ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/08 ojú ìwé 3-4
  • Ṣóòótọ́ Ni Pé Ikú Lòpin Ohun Gbogbo?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣóòótọ́ Ni Pé Ikú Lòpin Ohun Gbogbo?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Lè Rí Ìtùnú Gbà
  • Ìdí Tá A Fi Lè Gbà Gbọ́
  • Gbígbé Àwọn Èrò Èké Nípa Ikú Yẹ̀ Wò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Kí Ni Èrò Rẹ Nípa Ikú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ibo Làwọn Òkú Wà?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Ha Ṣeé Ṣe Lóòótọ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 10/08 ojú ìwé 3-4

Ṣóòótọ́ Ni Pé Ikú Lòpin Ohun Gbogbo?

NÍ February 1987, bàbá arúgbó kan tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún [85] ní kí wọ́n yọ ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń sẹ́ ìdọ̀tí inú kíndìnrín kúrò lára òun, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rọ yẹn ló jẹ́ kó ṣì wà láàyè. Ọ̀sẹ̀ méjì péré lẹ́yìn náà ló fọwọ́ rọrí kú sínú ilé ẹ̀, ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí ló sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ nígbà tó kú.

Ìwọ̀nba àkókò tí bàbá yẹn àtọmọ ẹ̀ fi wà pa pọ̀ mú káwọn méjèèjì ro àròjinlẹ̀ lórí ìbéèrè kan tí wọ́n ti máa ń gbé yẹ̀ wò tẹ́lẹ̀, ìyẹn ni pé, Ṣóòótọ́ ni pé ikú lòpin ohun gbogbo, àbí ẹní bá ti kú lè pa dà wà láàyè? Ọ̀mọ̀wé ni bàbá náà, àmọ́ kò gba Bíbélì gbọ́. Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ló kún agbárí ẹ̀, àgàbàgebè tó wà nínú ẹ̀sìn sì ti lé e sá. Ó tiẹ̀ máa ń sọ pé kò sẹ́ni tó lè mọ ohunkóhun nípa Ọlọ́run.

Síbẹ̀, torí pé ó wu ọmọ náà láti tu bàbá rẹ̀ nínú kó má bàa sọ̀rètí nù, ó jẹ́ kó rí i pé ikú kọ́ lòpin ohun gbogbo. Kó tó di pé bàbá yìí gbẹ́mìí mì, ó gbà pé òun máa fẹ́ láti pa dà wà láàyè, kóun sì máa gbé nínú ayé kan tára òun á ti dá ṣáṣá.

A Lè Rí Ìtùnú Gbà

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló máa fẹ́ pa dà wà láàyè, bó bá ṣáà ti jẹ́ pé inú ayé tí ìlera wọn ti máa jí pépé tí àlááfíà sì ti máa jọba ni wọ́n máa pa dà sí. Àwa èèyàn ò dà bí àwọn ẹranko, “tí kì í ronú,” tí wọ́n sì jẹ́ ẹ̀dá tí “ọgbọ́n àdánidá” ń darí. (2 Pétérù 2:12; ìtumọ̀ New International Version) A máa ń sìnkú. A máa ń fẹ́ mọ bọ́jọ́ ọ̀la ṣe máa rí. A ò fẹ́ darúgbó, a ò fẹ́ ṣàìsàn, bẹ́ẹ̀ la ò sì fẹ́ kú. Síbẹ̀, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa lójoojúmọ́ nìyẹn.

Bá a bá rántí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tá ò ní í sí mọ́ tàbí tí èèyàn wa kan á kú, ńṣe lẹ̀rù máa ń bà wá. Àmọ́, Bíbélì fẹ́ ká ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀ràn náà nípa sísọ pé: “Ó sàn láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju láti lọ sí ilé àkànṣe àsè.” Ó wá fi kún un pé: “Kí alààyè fi í sí ọkàn-àyà rẹ̀.” (Oníwàásù 7:2) Kí ló dé tó fi yẹ ká ro ọ̀rọ̀ náà láròjinlẹ̀?

Ohun tí ẹ̀dá ń fẹ́ ni pé kóun wà láyé, kóun wà láàyè, kóun sì wà láàyè ara òun. Kò sẹ́ni tó fẹ́ kú. Ẹ̀dá kì í fẹ́ gbà pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tóun á sùn tóun ò sì ní í jí mọ́. Bíbélì sì jẹ́ ká mọ ìdí tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni [Ọlọ́run] ti fi sínú ọkàn-àyà wọn.” (Oníwàásù 3:11) Ńṣe la fẹ́ máa wà láàyè, a ò fẹ́ kú. Ìwọ rò ó wò ná, ṣé ìwàláàyè lè máa wù wá tó bẹ́ẹ̀ bí kì í bá ṣe pé òótọ́ ni Ẹlẹ́dàá fẹ́ ká máa gbé láyé títí láé? Ṣé àwọn tó ti kú ṣì tún lè wà láàyè kí wọ́n máa gbádùn ìlera tó jí pépé kí wọ́n sì máa láyọ̀ títí lọ gbére?

Ìdí Tá A Fi Lè Gbà Gbọ́

Lọ́dún tó kọjá, ìwé ìròyìn AARP The Magazine, ti Àjọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà Tó Ń Rí Sọ́ràn Àwọn Òṣìṣẹ́ Tó Ti Fẹ̀yìn Tì, gbé àpilẹ̀kọ tó ní àkọlé náà, “Òkú Lè Pa Dà Wà Láàyè” jáde. Nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn tó ti lé lọ́mọ àádọ́ta [50] ọdún tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, ẹ̀rí fi hàn pé “bá a bá kó ẹni mẹ́rin jọ, ẹni bíi mẹ́ta ló máa sọ pé, ‘Mo gbà gbọ́ pé òkú lè pa dà wà láàyè.’” Ìwé ìròyìn náà tún wá sọ pé ó tó nǹkan bí ìdá kan nínú mẹ́rin tó fara mọ́ gbólóhùn náà pé, “Mo gbà gbọ́ pé ikú lòpin ohun gbogbo.” Àmọ́, ṣóòótọ́ ni pé ohun táwọn èèyàn fẹ́ gbà gbọ́ nìyẹn?

Nínú àpilẹ̀kọ kan náà yẹn, wọ́n ní Tom, tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì látìlúu New York, sọ pé: “Ṣebí ẹ̀yin náà mọ̀ pé wọ́n máa ń wàásù pé ẹní bá ti kù lè pa dà wà láàyè? Bí mo bá gbọ́ bẹ́ẹ̀, ohun témi máa ń sọ ni pé, àkíìkà, kò tiẹ̀ sóhun táwọn oníwàásù yìí ò ní sọ tán. Àfi kóníkálukú yáa pinnu ohun tó máa gbà gbọ́ o jàre. Mo máa ń lọ síbi ààtò jíjẹ ara Olúwa ní Ṣọ́ọ̀ṣì. Bí mo ṣe ń gbé ìgbé ayé mi máa ń mú káwọn èèyàn rò pé mo gbà gbọ́ pé ẹni bá ti kú lè pa dà wà láàyè, àmọ́ mi ò gba ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ gbọ́. Bó bá jóòótọ́ ni bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́, ìfà lèmi kà á sí ńtèmi.”

Bíi ti Tom, ọ̀pọ̀ ni ò gbà pé ikú kọ́ lòpin ohun gbogbo tàbí pé ẹní bá ti kú lè pa dà wà láàyè. Bàbá arúgbó tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sábà máa ń sọ fọ́mọ ẹ̀ ọkùnrin pé: “Kò sóhun tó burú níbẹ̀ táwọn tó ń bẹ̀rù ikú bá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn.” Síbẹ̀, òun àtàwọn míì tí ò gba Ọlọ́run gbọ́ ti wá gbà pé, ìgbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá, tó jẹ́ alágbára gbogbo, máa ń mú kéèyàn lóye àwọn ohun àgbàyanu míì tí ì bá ti ṣòro jù láti lóye.

Bí àpẹẹrẹ, lọ́sẹ̀ mẹ́ta péré lẹ́yìn tí obìnrin bá lóyún, àwọn sẹ́ẹ̀lì tó máa di ọpọlọ á ti bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà nínú ẹ̀. Àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí máa ń yára pọ̀ sí i. Nígbà míì, sẹ́ẹ̀lì tó tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta-lé-nírínwó lè jáde wá láàárín ìṣẹ́jú kan ṣoṣo! Lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn-án, aboyún náà á bí ọmọ jòjòló kan tó ní ọpọlọ tó dáńgájíá láti kẹ́kọ̀ọ́. Abájọ tí onímọ̀ nípa àwọn ohun tín-tìn-tín inú ara, James Watson, fi sọ pé ọpọlọ èèyàn ni “ohun tó ṣòroó lóye jù lọ lára àwọn ohun tá a tíì ṣàwárí lágbàáyé.”

Bí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ń ronú nípa irú àwọn ohun àgbàyanu bẹ́ẹ̀, ìyàlẹ́nu gbáà ló máa ń jẹ́ fún wọn. Ṣé bó ṣe máa ń ṣèwọ náà nìyẹn? Ǹjẹ́ bó o ṣe ń ronú lórí àwọn ohun àgbàyanu yìí ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè tí ọkùnrin kan béèrè nígbà pípẹ́ sẹ́yìn pé: “Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?” Pẹ̀lú ìdánilójú ni ọkùnrin náà fi dá Ọlọ́run lóhùn pé: “Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”—Jóòbù 14:14, 15.

Dájúdájú, ó máa dáa ká ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó lè mú ká gbà pé ikú kọ́ lòpin ohun gbogbo.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́