Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
January–March 2009
Kí Ló Ń Mú Káyé Yẹni?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń rò pé níní òkìkí, ọrọ̀, tàbí agbára ló ń mú káyé yẹni. Àmọ́, ṣóòótọ́ ni pé àwọn nǹkan wọ̀nyí la lè fi mọ ẹni táyé yẹ? Ka àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí kó o lè rí i pé kò sẹ́ni táyé ò lè yẹ bó bá gbélé ayé ṣe ohun tó dáa, èyí tó yàtọ̀ sí pé kéèyàn wulẹ̀ rí towó ṣe.
6 Ohun Mẹ́fà Tó Lè Mú Káyé Yẹni
25 Wíwo Ayé
32 Ó Ń Jẹ́ Kí Wọ́n Gbé Ìgbé Ayé Lọ́nà Tó Nítumọ̀
Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Àwọn Ohun Táwọn Èèyàn Fi Ń Jọ́sìn? 10
Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó pera wọn ní Kristẹni àtàwọn ẹlẹ́sìn míì ni wọ́n máa ń lo ìlẹ̀kẹ̀ àtàwọn nǹkan míì tó ṣeé rí bí wọ́n bá ń gbàdúrà tàbí nígbà ààtò ìjọsìn wọn. Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn ohun táwọn èèyàn fi ń jọ́sìn?