Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ẹni Gidi Ni Ọlọ́run?
ÀWỌN nǹkan àrà tó wà nínú ìṣẹ̀dá mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé ọlọ́run tàbí òrìṣà kan wà tí agbára rẹ̀ ju ti èèyàn lọ. Ṣé àwọn nǹkan àrà tó ṣòro láti lóyè ní àgbáálá ayé yìí máa ń jọ ẹ́ lójú? Ṣé ó máa n yà ẹ́ lẹ́nu bó o ṣe ń rí àwọn nǹkan àgbàyanu tó wà láyé yìí àti ọ̀nà àrà tí ara àwa èèyàn gbà ń ṣiṣẹ́?
Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí àwọn nǹkan yìí mú kí ìwọ pẹ̀lú gbà pé àwọn nǹkan àrà yìí ò ṣẹ̀yìn ọlọ́run kan. Àwọn ìsìn kan ń kọ́ni pé irú àwọn ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ń gbé inú àwọn òkè ńlá, inú àwọn igi, ojú ọ̀run àti nínú àwọn nǹkan míì. Àwọ́n míì gbà gbọ́ pé ẹ̀mí àwọn baba ńlá tó ń ṣoore àtèyí tó ń ṣèkà ló di àwọn agbára àràmàǹdà kan tí èyí sì wá para pọ̀ di Ẹni Gíga Jù Lọ, ìyẹn Ọlọ́run!
Ohun kan tó jọra nípa àwọn tó ní irú ìgbàgbọ́ méjèèjì yìí ni pé, wọ́n gbà pé agbára tó ju ti èèyàn lọ yìí kò ṣeé mọ̀ rárá. Ó ṣòro fún àwọn kan láti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ní èrò àti ìmọ̀lára, ó sì ṣòro fún wọn láti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ní àwọn nǹkan lọ́kàn tó fẹ́ ṣe, ó sì ní àwọn nǹkan tó wù ú. Ṣé ẹni gidi tó wà lóòtọ́ ni Ọlọ́run? A lè rí ìdáhùn tó ṣe kedere nínú Bíbélì tó jẹ ọ̀kan lára àwọn ìwé mímọ́ tó tíì pẹ́ jù lọ tó sì wà káàkiri lónìí.
Bí Èèyàn Ṣe Rí Jẹ́ Ká Mọ Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́
Bíbélì kọ́ni pé Ọlọ́run dá àwa èèyàn lọ́nà tá a fi lè ṣàgbéyọ àwọn ànímọ́ rẹ̀. Jẹ́nẹ́sísì 1:27 sọ pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán [ara] rẹ.”
Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí kò túmọ̀ sí pé bí Ọlọ́run ṣe rí gan-an ni àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ ṣe rí. Bíbélì sọ pé ẹ̀mí ni Ọlọ́run, a ò sì lè rí i, àmọ́ ohun tá a lè fojú rí ni Ọlọ́run fi dá èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Jòhánù 4:24) Tá a bá yọwọ́ ti ìyàtọ̀ gbòógì tó wà láàárín Ọlọ́run àti àwa èèyàn yìí, a máa mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an nípa fífara balẹ̀ kíyè sí àwọn ànímọ́ táwa èèyàn ní.
Àwa èèyàn lè lo agbára, a sì lè dìídì ṣe àwọn nǹkan tá a ti rò tẹ́lẹ̀. Àwọn ànímọ́ bí inúure, agbára láti ronú, ọgbọ́n àti ìdájọ́ òdodo ló sì máa ń mú ká ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Bí nǹkan sì ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn máa ń yàtọ̀ síra nígbà míì, a lè nífẹ̀ẹ́, a lè kórìíra, a sì lè bínú. Bí àwọn ànímọ́ yìí bá ṣe pọ̀ tó tàbí bó bá ṣe kéré tó nínú ìwà ẹnì kan ló ń mú kí ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ wà láàárín wa. Síbẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ní àwọn ànímọ́ tiẹ̀. Àwa èèyàn jẹ́ ẹni gidi.
Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu pé kí Ọlọ́run dá wa ní ẹ̀dá tó lè ṣe onírúurú nǹkan bó bá jẹ́ pé ẹ̀mí àìrí kan tó kàn ń lọ sókè sódò ni òun fúnra rẹ̀? Bó bá jẹ́ pé Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀, onírúurú ọ̀nà ni àwa èèyàn máa fi jọ Ọlọ́run. Gbé àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
Ọlọ́run ní orúkọ. Bíbélì sọ nínú ìwé Aísáyà 42:8 pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” Ọlọ́run fẹ́ ká mọ orúkọ òun. Bíbélì tún sọ pé: “Kí orúkọ Jèhófà di èyí tí a fi ìbùkún fún láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin. Láti yíyọ oòrùn títí di ìgbà wíwọ̀ rẹ̀, orúkọ Jèhófà yẹ fún ìyìn.” (Sáàmù 113:2, 3) Èyí fi hàn pé bí àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run bá ń lo orúkọ rẹ̀ déédéé, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi tó wà lóòótọ́.
Kò sí ẹni tó dà bí Ọlọ́run. Bíbélì fi kọ́ni pé kò sí ẹni tó dà bí Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 8:5, 6) Ó sọ pé: “Ìwọ . . . tóbi jọjọ, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ; nítorí kò sí ẹlòmíràn tí ó dà bí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kankan bí kò ṣe ìwọ.” (2 Sámúẹ́lì 7:22) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run tòótọ́ nínú ọ̀run lókè àti lórí ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀. Kò sí òmíràn.”—Diutarónómì 4:39.
Jèhófà Ọlọ́run kórìíra ìwà ìbàjẹ́. Ẹni gidi tó wà lóòótọ́ ló lè kórìíra nǹkan. Bíbélì sọ fún wa pé Ẹlẹ́dàá kórìíra àwọn nǹkan bí “ojú gíga fíofío, ahọ́n èké, àti ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀, ọkàn-àyà tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ àwọn ìpètepèrò tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, ẹsẹ̀ tí ń ṣe kánkán láti sáré sínú ìwà búburú, ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ, àti ẹnikẹ́ni tí ń dá asọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.” (Òwe 6:16-19) Kíyè sí i pé Ọlọ́run kórìíra ìwà àwọn èèyàn tó bá ń ṣàkóbá fún àwọn ẹlòmíì. A kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Bíbélì sọ yìí pé ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún àti pé ó kórìíra àwọn nǹkan tó bá ń ṣàkóbá fún wa.
Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa. Bíbélì ṣàlàyé pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ “aráyé” gan-an. (Jòhánù 3:16, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ó sọ pé Ọlọ́run jẹ́ baba tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tó sì fẹ́ ohun tó dáa fún wọn. (Aísáyà 64:8) Ọ̀pọ̀ àǹfààní làwa èèyàn máa jẹ tá a bá mọ Ọlọ́run sí Baba tó nífẹ̀ẹ́ wa.
O Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run
Bíbélì kọ́ni lọ́nà tó ṣe kedere pé Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ ẹnì kan tó ní orúkọ tó sì ní àwọn ànímọ́. Ó lè lo agbára, kó sì dìídì ṣe àwọn ohun tó ní lọ́kàn, àwọn ànímọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀, irú bí inú rere, ọgbọ́n àti ìdájọ́ òdodo ló sì máa ń mú kó ṣe ohun tó bá fẹ́ ṣe. Kò jìnnà sí wa, ẹni tá a sì lè sún mọ́ ni. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”—Aísáyà 41:13.
Ọlọ́run ní ohun kan lọ́kàn tó fẹ́ ṣe fún àwa èèyàn. Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Torí a mọ̀ pé kò sí ẹni tó dà bíi Jèhófà àti pé a ò lè fi wé ẹnikẹ́ni, ìyẹn jẹ́ kó máa wù wá láti ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀, ká sì fẹ́ láti gbádùn àwọn ìbùkún tó fẹ́ fún àwọn tó bá di ọ̀rẹ́ rẹ̀.—Diutarónómì 6:4, 5; 1 Pétérù 5:6, 7.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Ṣé Ọlọ́run ní orúkọ?—Aísáyà 42:8.
● Ǹjẹ́ àwọn tá a lè pè ní ọlọ́run pọ̀?—1 Kọ́ríńtì 8:5, 6.
● Ǹjẹ́ àwa èèyàn lè ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́?—1 Pétérù 5:6, 7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Bó bá jẹ́ pé ẹ̀mí àìrí kan tó kàn ń lọ sókè sódò ni Ọlọ́run, ǹjẹ́ ó lè dá àwa èèyàn ní ẹ̀dá tó lágbára láti ṣe onírúurú nǹkan?