ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/11 ojú ìwé 28-29
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Fọwọ́ sí Fífi Èèyàn Ṣe Ẹrú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Bíbélì Fọwọ́ sí Fífi Èèyàn Ṣe Ẹrú?
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà Táwọn Èèyàn Ń Gbà Ṣe Nǹkan Ta Ko Àwọn Ìlànà Bíbélì
  • Ṣíṣe Ẹrú Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì
  • Ìfiniṣẹrú Máa Dópin
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fara Mọ́ Ṣíṣe Òwò Ẹrú?
    Jí!—2001
  • Ọjọ́ Pẹ́ Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣakitiyan Láti Fòpin Sí Ìfiniṣẹrú
    Jí!—2002
  • Òwò Ẹrú​—Láyé Àtijọ́ àti Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • “A Ti Rà Yín Ní Iye Kan”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 10/11 ojú ìwé 28-29

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Bíbélì Fọwọ́ sí Fífi Èèyàn Ṣe Ẹrú?

Ọ̀KAN lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Bíbélì kọ́ni ni pé ká fẹ́ràn àwọn aládùúgbò wa. Àmọ́, bí èèyàn bá ní ìfẹ́ kò ní máa fi àwọn èèyàn bíi tiẹ̀ ṣe ẹrú lọ́nà rírorò. Torí náà, ó máa ń ṣe àwọn èèyàn ní kàyéfì pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa fífi èèyàn ṣe ẹrú.

Nígbà àtijọ́, Ọlọ́run gba àwọn èèyàn rẹ̀ láyè pé kí wọ́n ní àwọn ẹrú. (Jẹ́nẹ́sísì 14:14, 15) Kódà, nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, àwọn Kristẹni kan ní ẹrú, àwọn Kristẹni míì sì jẹ́ ẹrú. (Fílémónì 15, 16) Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé Bíbélì fọwọ́ sí fífi èèyàn ṣe ẹrú lọ́nà rírorò?

Ọ̀nà Táwọn Èèyàn Ń Gbà Ṣe Nǹkan Ta Ko Àwọn Ìlànà Bíbélì

Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ Bíbélì, àwọn èèyàn ti gbé àwọn ọ̀nà kan kalẹ̀ tí wọ́n ń gbà ṣe nǹkan, wọ́n sì tún ní àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣòwò lọ́nà tí kò bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu. Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún wọn, ó dẹ́bi fún àwọn kan lára ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà ṣe nǹkan, àmọ́ ó fàyè gba àwọn míì, irú bíi fífi èèyàn ṣe ẹrú.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The International Standard Bible Encyclopedia sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà táwọn èèyàn máa ń gbà ṣe nǹkan ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, ó ní: “Ó jẹ́ láti mú kí àwọn èèyàn kó ara wọn jọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìyá, bó sì ṣe máa ń rí ni pé, kò sí pé àwọn kan jẹ́ tálákà, [kò sì sí pé] wọ́n ń kó àwọn opó nífà, kò sí pé àwọn kan wà tí kò nílé lórí, tàbí ọmọ aláìlóbìí.” Torí náà, kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn fàyè gba fífi èèyàn ṣe ẹrú torí pé àwọn èèyàn kúkú ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀ láti fi ṣòwò, àmọ́ Òfin Ọlọ́run fi àwọn ìlànà kan sílẹ̀ fún àwọn tó ní ẹrú, tó jẹ́ pé tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé e, ńṣe ni wọ́n á máa ṣàánú àwọn ẹrú, tí wọ́n á sì máa fìfẹ́ bá wọn lò.

Ṣíṣe Ẹrú Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì

Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìlànà kan tí Ọlọ́run fi sínú Òfin nípasẹ̀ Mósè:

● Bí ẹnì kan bá jí èèyàn gbé tó sì tà á, ńṣe ni wọ́n máa pa ajínigbé náà. (Ẹ́kísódù 21:16) Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ètò tí wọ́n ṣe láti dènà ipò òṣì, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọmọ Ísírẹ́lì kan jẹ gbèsè tó pọ̀ gan-an, bóyá torí pé ó ṣe òwò kan láìronú jinlẹ̀ dáadáa tó sì wá jẹ gbèsè, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ta ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹrú. Ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míì pé onítọ̀hún lè wá jẹ èrè tó pọ̀ gan-an débi tó fi máa lè sanwó láti gba òmìnira rẹ̀ pa dà.—Léfítíkù 25:47-52.

● Èyí yàtọ̀ pátápátá sí bí wọ́n ṣe máa ń ni àwọn ẹrú lára, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè láti ọdúnmọ́dún. Léfítíkù 25:39, 40 sọ pé: “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin rẹ di òtòṣì nítòsí rẹ, tí ó sì ní láti ta ara rẹ̀ fún ọ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ lò ó gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìnrú. Kí ó wà pẹ̀lú rẹ bí lébìrà tí a háyà, bí olùtẹ̀dó.” Ètò tí Ọlọ́run fìfẹ́ ṣe fáwọn tó bá di tálákà paraku ni èyí.

● Bí ẹnì kan bá jalè, tí kò sì lè san ohun tó jí pa dà, ohun tí Òfin sọ ni pé kí wọ́n tà á fi ṣe ẹrú kí ó bàa lè san gbèsè rẹ̀. (Ẹ́kísódù 22:3) Tó bá ti ṣe iṣẹ́ tí ó kájú ohun tó jí náà, wọ́n á wá dá a sílẹ̀ lómìnira.

● Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fàyè gba híhùwà ìkà sí àwọn ẹrú tàbí kí wọ́n máa lò wọ́n nílòkulò. Àwọn tó ní ẹrú lè bá àwọn ẹrú wọn wí, àmọ́ wọn kò gbọ́dọ̀ ki àṣejù bọ̀ ọ́. Bí ẹnì kan bá pa ẹrú rẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ gbẹ̀san lára ọ̀gá náà. (Ẹ́kísódù 21:20) Bí wọ́n bá ṣe ẹrú kan léṣe, bóyá tí eyín rẹ̀ kan yọ, tàbí tí ojú rẹ̀ fọ́, wọ́n ní láti dá a sílẹ̀ lómìnira.—Ẹ́kísódù 21:26, 27.

● Ìgbà tí ọmọ Ísírẹ́lì kan lè fi ṣe ẹrú kò gbọ́dọ̀ ju ọdún mẹ́fà lọ. (Ẹ́kísódù 21:2) Ọdún keje ni wọ́n máa ń dá àwọn ẹrú tí ó jẹ́ Hébérù sílẹ̀. Òfin tún sọ pé, ní gbogbo àádọ́ta ọdún, wọ́n ní láti dá gbogbo àwọn ẹrú sílẹ̀ lómìnira, láìka ìgbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan di ẹrú sí.—Léfítíkù 25:40, 41.

● Bí ẹnì kan bá dá ẹrú kan sílẹ̀, ó gbọ́dọ̀ fún un ní nǹkan nígbà tó bá ń lọ. Diutarónómì 15:13, 14 sọ pé: “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé o rán an jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ ní ẹni tí a dá sílẹ̀ lómìnira, ìwọ kò gbọ́dọ̀ rán an jáde lọ́wọ́ òfo. Dájúdájú, kí o fi ohun kan láti inú agbo ẹran rẹ àti ilẹ̀ ìpakà rẹ àti ibi ìfún-òróró àti ìfúntí wáìnì rẹ mú un gbára dì.”

Nígbà ayé Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀, fífi èèyàn ṣe ẹrú jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ gan-an ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe ń tàn kálẹ̀, àwọn tó jẹ́ ẹrú àtàwọn tó ní ẹrú wà lára àwọn tó gbọ́ ìhìn rere tí wọ́n sì di Kristẹni. Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kò wàásù nípa bí àwọn èèyàn á ṣe di òmìnira lọ́wọ́ àwọn ètò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí àwọn èèyàn dá sílẹ̀, láti mú àyípadà bá ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà ṣe nǹkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n gba àwọn ẹrú àtàwọn tó ní ẹrú níyànjú láti máa fẹ́ràn ara wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìyá tí wọ́n jọ ń jọ́sìn Ọlọ́run.—Kólósè 4:1; 1 Tímótì 6:2.

Ìfiniṣẹrú Máa Dópin

Gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí pẹ̀lú gbogbo àwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì, ọ̀rọ̀ nípa fífi èèyàn ṣe ẹrú sinmi lórí nǹkan tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Tá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́, a ó rí i pé Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ sí ká máa hùwà ìkà sí àwọn èèyàn bíi tiwa.

Tá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ dáadáa, a ó rí i pé bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń lo ẹrú láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì yàtọ̀ sí èrò tí àwọn èèyàn ní lóde òní pé, ńṣe ni wọ́n máa ń hùwà ìkà sí wọn, tí wọ́n sì ń lò wọ́n nílòkulò. Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa gbà wá lọ́wọ́ gbogbo onírúurú ìfiniṣẹrú nígbà tí àkókó bá tó lójú rẹ̀. Ní àkókò yẹn, gbogbo èèyàn pátá ló máa ní òmìnira tòótọ́.—Aísáyà 65:21, 22.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ǹjẹ́ Bíbélì fọwọ́ sí híhùwà ìkà sí àwọn ẹrú?—Léfítíkù 25:39, 40.

● Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni máa ṣe sí àwọn ẹrú?—Kólósè 4:1.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]

Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ sí ká máa hùwà ìkà sí àwọn èèyàn bíi tiwa

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]

© G.M.B. Akash/Panos Pictures

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́