ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 11/14 ojú ìwé 3
  • KÍ LO KÀ SÍ OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • KÍ LO KÀ SÍ OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ?
  • Jí!—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àníyàn Nípa Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Jèhófà Ń Gbọ́ Igbe Àwọn Ẹni Rírẹlẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ẹ̀mí Mímọ́ Ń fún Wa Lágbára Ká Lè Borí Àdánwò Èyíkéyìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • “Mo Ti Ń Gbádùn Iṣẹ́ Ìwàásù Báyìí!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Jí!—2014
g 11/14 ojú ìwé 3

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ?

KÍ LO KÀ SÍ OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ?

Kí ni ìwọ fúnra rẹ kà sí àṣeyọrí? Ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ yìí ná, kó o lè mọ̀.

Èwo nínú àwọn mẹ́rin yìí lo lè so pé ó ṣàṣeyọrí ní ti gidi?

  • ADÉ

    Oníṣòwò ni Adé. Ọmọlúwàbí ni, kì í ṣe ọ̀lẹ, ó sì mọyì àwọn èèyàn. Òwò tó ń ṣe ti búrẹ́kẹ́, torí náà, nǹkan ṣẹnuure fún òun àti ­ìdílé rẹ̀.

  • BÁYỌ̀

    Oníṣòwò lòun náà, àmọ́ ó rí towó ṣe ju Adé lọ. Ó kàn jẹ́ pé Báyọ̀ ti di ẹrú iṣẹ́ kó bàa lè yọrí ọlá ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ, èyí sì ti dá onírúurú ­àìsàn sí i lára.

  • KẸ́MI

    Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ girama ni Kẹ́mi. Ó já fáfá, ó sì kúndùn kó máa kàwé. Torí náà, ó máa ń yege nínú ìdánwò rẹ̀.

  • MOPÉ

    Mopé máa ń gba máàkì tó pọ̀ ju ti Kẹ́mi lọ, gbogbo ìgbà sì lorúkọ rẹ̀ máa ń wà lára àwọn to fakọyọ ní kíláàsì. Ṣùgbọ́n ó máa ń jíwèé wò nínú ìdánwò, kò sì fi gbogbo ara gbádùn kó máa kàwé.

    Àwọn wo lò rò pé ó ṣàṣeyọrí ní ti gidi? Tó bá jẹ́ pé Báyọ̀ àti Mopé lo mú àbí àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, a jẹ́ pé bí wọ́n ṣe lowó tó tàbí bí máàkì wọn ṣe pọ̀ tó lo fi ­díwọ̀n àṣeyọrí wọn láìka ọ̀nà tí wọ́n gbé e gbà.

Àmọ́ bó bá jẹ́ pé Adé àti Kẹ́mi lo yàn, èrò rẹ tọ̀nà, torí pé ìwà wọn àti ọwọ́ tí wọ́n fi mú iṣẹ́ lo fi díwọ̀n àṣeyọrí wọn. Ó ṣe tán, gbogbo ohun tó ń dán kọ́ ni wúrà. Tá a bá wo ọ̀rọ̀ yìí dáadáa, àá rídìí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ:

  • Èwo lo rò pé ó máa ṣe Kẹ́mi làǹfààní títí dọjọ́ alẹ́? Kó gba máàkì tó pọ̀ ni àbí kó mọ̀wé rẹ̀ dójú àmì?

  • Kí lo rò pé ó máa ṣe àwọn ọmọ Adé láǹfààní jù? Kí wọ́n ní gbogbo nǹkan amáyédẹrùn ni àbí kí bàbá wọn máa lo ojúlówó àkókó pẹ̀lú wọn?

Kókó ọ̀rọ̀ ni pé: Gbogbo ohun tó ń dán lọmọ aráyé kà sí àṣeyọrí; àmọ́ ­ojúlówó àṣeyọrí ju bẹ́ẹ̀ lọ, ó sábà máa ń dá lé àwọn ìwà àtàtà tó ń fini lọ́kàn balẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́