ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g16 No. 4 ojú ìwé 16
  • Bí Kòkòrò Periodical Cicada Ṣe Ń Gbé Ìgbé Ayé Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Kòkòrò Periodical Cicada Ṣe Ń Gbé Ìgbé Ayé Rẹ̀
  • Jí!—2016
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2016
  • Kí Ló Dé Tí Wọ́n Tún Fi Ń Padà Wá?
    Jí!—2003
  • Àwọn Àrùn Tí Kòkòrò Ń gbé Kiri Ìṣòro Tí Ń Gbilẹ̀
    Jí!—2003
Jí!—2016
g16 No. 4 ojú ìwé 16

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Kòkòrò Periodical Cicada Ṣe Ń Gbé Ìgbé Ayé Rẹ̀

KÒKÒRÒ, cicada máa ń jọ kòkòrò eéṣú. Kò síbi téèyàn ò ti lè rí kòkòrò yìí lórí-ilẹ̀ ayé, àyàfi ní apá ibi tó tutù jù lọ láyé, tá a mọ̀ sí Antarctica. Àríwá ìlà oòrùn ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ni wọ́n ti sábà máa ń rí èyí tí wọ́n ń pè ní periodical cicada, ó sì ti pẹ́ gan-an tí àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè ti ń ṣèwádìí nípa kòkòrò yìí.

Kòkòrò cicada

Rò ó wò ná: Ẹgbẹẹgbẹ̀rún kòkòrò periodical cicadas máa ń fara hàn lójijì lákòókò ìrúwé, wọn kì í sì í lò ju ọ̀sẹ̀ mélòó kan lọ. Láàárín àkókò yẹn, wọ́n máa ń bó awọ ara wọn, wọ́n máa ń pariwo gan-an, wọ́n á fò, wọ́n á bímọ, wọ́n á sì kú. Ohun tó wá yani lẹ́nu ni pé ó máa ń tó ọdún mẹ́tàlá (13) sí mẹ́tàdínlógún (17) kí ìran míì tó tún yọjú, èyí sinmi lórí irú èyí tí wọ́n jẹ́. Ibo ni àwọn kòkòrò yìí máa ń wà ní gbogbo àkókò yẹn, kí sì ni wọ́n ń ṣe?

Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ó yẹ ká mọ bí kòkòrò periodical cicada ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ̀. Lẹ́yìn nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan táwọn kòkòrò yìí bá fara hàn, wọ́n máa ń gun ara wọn, àwọn abo á sì yé ẹyin tó pọ̀ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] sí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] sínú ẹ̀ka igi. Kété lẹ́yìn náà ni wọ́n máa ń kú. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ẹyin náà á di ọmọ, àwọn ọmọ náà á sì jábọ́ sílẹ̀, wọ́n á wọnú ilẹ̀ lọ, wọ́n á sì máa gbébẹ̀. Omi tó wà lára ìtàkùn igi ni wọ́n máa ń fà mu fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá sí mẹ́tàdínlógún lẹ́yìn náà, wọ́n á ti dàgbà, wọ́n á sì rú jáde láti inú ilẹ̀ láti wá bímọ.

Ìwé ìròyìn Nature sọ pé ọ̀nà tó díjú tí kòkòrò cicada ń gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ “ti rú àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lójú fún ọ̀pọ̀ ọdún. . . . Kódà, títí di báyìí, àwọn onímọ̀ nípa kòkòrò ṣì ń wá bí wọ́n ṣe máa mọ ibi tí kòkòrò tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí ti ṣẹ̀ wá.” Ohun ìyàlẹ́nu gbáà lèyí jẹ́ lágbo àwọn ẹranko.

Kí lèrò rẹ? Ṣé bí periodical cicada ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́