ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g17 No. 2 ojú ìwé 8-9
  • Nígbà Tí Òbí Ẹnì Kan Bá Kú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà Tí Òbí Ẹnì Kan Bá Kú
  • Jí!—2017
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
  • OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀
  • OHUN TÓ O LÈ ṢE
  • Tí Òbí Ọmọdé Kan Bá Kú
    Jí!—2017
  • Ṣé Bí Mo Ṣe Ń Kẹ́dùn Dáa Báyìí?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà á Bí Dádì Tàbí Mọ́mì Bá Kú?
    Jí!—2009
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Da Ẹ̀dùn Ọkàn Téèyàn Mi Bá Kú?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Jí!—2017
g17 No. 2 ojú ìwé 8-9
Ọmọdé kan di ọwọ́ àgbàlagbà kan mú ní itẹ́ òkú

Ìrànlọ́wọ́ Fún Ìdílé | Àwọn Ọ̀dọ́

Nígbà Tí Òbí Ẹnì Kan Bá Kú

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ọmọ ọdún mẹ́fà ni Dami nígbà tí àìsàn kan tí wọ́n ń pè ní aneurysm pa bàbá rẹ̀. Derrick ti pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án nígbà tí àìsàn ọkàn gbẹ̀mí bàbá tiẹ̀ náà. Àìsàn jẹjẹrẹ ló pàpà wá pa ìyá Jeannie láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí wọ́n ti ń bá a fà á, ọmọ ọdún méje ni Jeannie nígbà náà.a

Àwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣì kéré nígbà tí ẹni tí wọ́n fẹ́ràn kú. Ṣé irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ipò náà.b Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kó o mọ àwọn nǹkan kan nípa ọgbẹ́ ọkàn yìí.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Oríṣiríṣi ọ̀nà lèèyàn lè gbà fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn. Èyí fi hàn pé bí o ṣe máa fi hàn pé ohun tó ṣẹlẹ̀ dùn ẹ́ máa yàtọ̀ sí bí ẹlòmíì ṣe máa fi hàn. Ìwé Helping Teens Cope With Death sọ pé: “Kì í ṣe dandan kí gbogbo wa fi ìmọ̀lára wa hàn lọ́nà kan náà nígbà tí èèyàn wa bá kú.” Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kó o má ṣe bo ẹ̀dùn ọkàn rẹ mọ́ra. Kí nìdí? Ìdí ni pé . . .

Ó léwu tó o bá bo ẹ̀dùn ọkàn rẹ mọ́ra. Jeannie tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Mi ò fẹ́ kí àbúrò mi bara jẹ́ jù, torí náà mi ò jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn mi hàn síta. Títí dòní gan-an, mo ṣì máa ń gbé ohun tó bá ń dùn mí sára, ó sì máa ń ṣàkóbà fún ìlera mi.”

Àwọn ọ̀mọ̀wé náà gbà bẹ́ẹ̀. Ìwé The Grieving Teen sọ pé: “Téèyàn bá bo ìmọ̀lára rẹ̀ mọ́ra, bópẹ́ bóyá á tú jáde ṣáá ni. Ìgbà tí o kò retí rẹ̀ láá kàn bú jáde, o kàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í kanra òdì tàbí kó máa rẹ̀ ọ́.” O lè bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí àmuyíràá tàbí kó o máa lo oògùn ní àlòjù kó o ṣáà lè gbé ìbànújẹ́ yẹn kúrò lára.

Ìbànújẹ́ máa ń mú kéèyàn ní èrò òdì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń bínú sí ẹni tó kú torí wọ́n ronú pé ńṣe lẹni náà “fi wọ́n sílẹ̀.” Àwọn míì máa ń dá Ọlọ́run lẹ́bi pé kò yẹ kó jẹ́ kí ẹni náà kú. Ọ̀pọ̀ ló sì máa ń dá ara wọn lẹ́bi fún ohun tí wọ́n ṣe tàbí sọ sí ẹni náà kó tó kú, tí kò wá sí àyè fún wọn mọ́ láti wá nǹkan ṣe sí i.

A ti wá rí i pé ohun tó lè mú kó nira láti tètè gbé ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn pọ̀. Ibo lo ti lè rí ìtura, kó o lè máa bá ìgbésí ayé rẹ lọ?

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. Nírú àsìkò yìí, ó lè máa ṣe ẹ́ bí i kó o dá wà. Àmọ́ tó o bá sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún mọ̀lẹ́bí rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan lo tó lè túra ká, kí ìbànújẹ́ má báa sorí rẹ kodò.​—Ìlànà Bíbélì: Òwe 18:24.

Ṣe àkọsílẹ̀. Kọ ohun tó o rántí nípa òbí rẹ tó kú yìí. Bí àpẹẹrẹ, kí ni ohun tó o fẹ́ràn jù nípa rẹ̀? Kọ àwọn ìwà rẹ̀ tó dáa sílẹ̀, kó o sì mú èyí tó wù ẹ́ láti tẹ̀ lé ní ìgbésí ayé rẹ.

Tí èrò òdì bá ń wá sí ẹ lọ́kàn ṣáá, bóyá tó o ṣì ń rántí bó o ṣe jágbe mọ́ òbí rẹ kó tó kú, o lè kọ bó ṣe ká ẹ lára sí àti ìdí tó fi ká ẹ lára bẹ́ẹ̀ sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Ó dùn mí pé mo jágbe mọ́ dádì mí ní ó ku ọ̀la kí wọ́n kú.”

Lẹ́yìn náà, wá rò ó dáadáa bóyá o jẹ̀bi lóòótọ́. Ìwé The Grieving Teen sọ pé: “Oò lè dá ara rẹ lẹ́bi torí kò sí bó o ṣe fẹ́ mọ̀ pé kò ní sáyè fún ẹ láti tọrọ àforíjì. Kò sì mọ́gbọ́n dání pé ká máa ṣọ́ ohun tá a fẹ́ sọ tàbí ìṣesí wà sí àwọn míì torí wọ́n lè kú nígbà kigbà.”​—Ìlànà Bíbélì: Jóòbù 10:1.

Tọ́jú ara rẹ. Máa sinmi dáadáa, ṣeré ìmárale, kó o sì máa jẹun tó dáa. Tí oúnjẹ ò bá wù ẹ́ jẹ, o lè máa jẹ ìpápánu látìgbàdégbà, títí dìgbà tí oúnjẹ gidi á fi wù ẹ́ jẹ. Àmọ́ yẹra fún jíjẹ àwọn oúnjẹ midinmíìdìn tàbí mímú ọ̀tí líle, torí pé ńṣe nìyẹn máa mú kí ìbànújẹ́ rẹ pọ̀ sí i.

Gbàdúrà sí Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, Òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sáàmù 55:22) Àdúrà kì í ṣe ohun téèyàn ń gbà kára ṣáá lè tù ú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń lo àdúrà láti bá Ọlọ́run tó ń “tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa” sọ̀rọ̀.​—2 Kọ́ríńtì 1:​3, 4.

Ọlọ́run máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti tu àwọn èèyàn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú. O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ipò tí àwọn tó ti kú wà àti ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa jí wọn dìde.c​—Ìlànà Bíbélì: Sáàmù 94:19.

a O tún lè kà nípa ọ̀rọ̀ Dami, Derrick àti Jeannie nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ nípa ikú òbí, a tún lè lo ìmọ̀ràn tó wà níbẹ̀ tí mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ ẹni bá kú.

c Wo orí 16 nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní. O tún lè wà á jáde lọ́fẹ̀ẹ́ lórí ìkànnì www.jw.org/yo. Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE.

FI ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ YÌÍ SỌ́KÀN

  • “Ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.”​—Òwe 18:24.

  • “Èmi yóò sọ̀rọ̀ nínú ìkorò ọkàn mi!”​—Jóòbù 10:1.

  • “Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú [Ọlọ́run] ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.”​—Sáàmù 94:19.

RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́

“Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá ní ìdílé wa. Lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, àrùn jẹjẹrẹ pa ìyá àwọn ọmọdékùnrin méjì kan tá a mọ̀ dáadáa. Ìkan jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà, èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta, ó fẹ́ẹ̀ jẹ́ iye ọdún tí èmi àti àbúrò mi obínrin wà nìyẹn nígbà tí dádì wa kú lọ́dún mẹ́tàdínlógún [17] sẹ́yìn.

“Èmí, àbúrò mi àti mọ́mì mi ti pinnu pe a máa dúró tì wọ́n. A máa ń pè wọ́n wá sílé wa. A máa n tẹ́tí sí wọn. A tún máa lọ bá wọn ṣeré tàbí ká fún wọn nímọ̀ràn, ká ṣáà lè rí i pé a ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ lásìkò tí wọ́n nílò rẹ̀.

“Ohun tí kò bára dé ni kí èèyàn pàdánù òbí ẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn náà kì í sì kúrò lọ́kàn bọ̀rọ̀. Ó máa fúyẹ́ lọ́kàn tó bá yá o, àmọ́ kò sí kéèyàn má máa rántí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Mo mọ ohun tó túmọ̀ sí láti pàdánù òbí ẹni, ìdí sì nìyẹn tí inú mi fi dùn pé a ṣe ohun tá a lè ṣe láti tù wọ́n nínú. Èyí ti wá mú kí ìdílé àwa méjèèjì túbọ̀ sún mọ́ra dáadáa.”​—Dami.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́