OHUN TÓ Ń FÚNNI LÁYỌ̀
Bó O Ṣe Lè Máa Gbé Ìgbé Ayé Aláyọ̀
ṢÉ O MÁA Ń LÁYỌ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan wo ló máa ń fún ẹ láyọ̀? Ṣé ìdílé rẹ ni, iṣẹ́ rẹ tàbí ẹ̀sìn tó ò ń ṣe? Ó sì lè jẹ́ ohun kan tó ò ń retí ló ń fún ẹ láyọ̀, bóyá ìgbà tó o máa parí ilé ìwé rẹ, ìgbà tó o máa ríṣẹ́ gidi tàbí ìgbà tó o máa ra ọkọ̀ tuntun.
Ọ̀pọ̀ èèyan máa ń láyọ̀ nígbà tọ́wọ́ wọn bá tẹ ohun kan tí wọ́n ń wá tàbí tí wọ́n bá ní ohun kan tó ti ń wù wọ́n tipẹ́tipẹ́. Àmọ́ ṣé irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń tọ́jọ́? Lọ́pọ̀ ìgbà, irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ kì í tọ́jọ́, ó sì máa ń dunni gan-an.
Ayọ̀ túmọ̀ sí pé kí ara èèyàn máa yá gágá nígbà gbogbo, kí ọkàn èèyàn balẹ̀, kí inú rẹ̀ sì máa dùn gan-an, kó sì máa wuni pé kí nǹkan máa rí bẹ́ẹ̀ lọ.
Àwọn èèyàn tiẹ̀ máa ń sọ pé ayọ̀ kì í ṣe ibì kan tí èèyàn ń lọ tó wá débẹ̀, àmọ́ ńṣe ló dà bí ìrìn àjò tí kò lópin. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé téèyàn bá ní ojúlówó ayọ̀, ìgbà gbogbo ni ara èèyàn á máa yá gágá. Torí náà, téèyàn bá sọ pé, “Tí mo bá ní tibí tàbí tọ̀hún, màá láyọ̀,” onítọ̀hún ò tíì láyọ̀ nìyẹn, ó ṣì dìgbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá tẹ nǹkan yẹn kó tó láyọ̀.
Ẹ jẹ́ ká fi ohun tá a máa ṣe ká lè láyọ̀ wéra pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ara líle. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí ara wa máa le dáadáa? A gbọ́dọ̀ máa jẹ ounjẹ aṣaralóore, ká máa ṣe eré ìmárale, ká sì máa ṣe àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì fún ìlera wa. Bákan náà, tá a bá fẹ́ láyọ̀, àwọn ìlànà pàtàkì kan wà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé.
Àwọn ìlànà wo la gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé tá a bá fẹ́ láyọ̀? Àwọn kókó tá a fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí yìí ṣe pàtàkì gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pe àwọn kan nínú wọn lè ṣe pàtàkì ju àwọn míì lọ:
ÌTẸ́LỌ́RÙN ÀTI ÌWÀ Ọ̀LÀWỌ́
ÌLERA ÀTI ÌFARADÀ
ÌFẸ́
ÌDÁRÍJÌ
ÌGBÉ AYÉ TÓ NÍTUMỌ̀
ÌRÈTÍ
Ìwé ọgbọ́n kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn bọ̀wọ̀ fún sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn aláìní-àléébù ní ọ̀nà wọn.” (Sáàmù 119:1) Ẹ jẹ́ ká wá wo ọ̀nà yẹn.