ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g18 No. 1 ojú ìwé 8-9
  • Ìfẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfẹ́
  • Jí!—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “ÌDÈ ÌRẸ́PỌ̀ PÍPÉ” LÓ SO WỌ́N PỌ̀
  • Ìfẹ́ (Agape)—Ohun Tí Kò jẹ́ Àti Ohun Tí Ó Jẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Ìfẹ́’
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • “Ìfẹ́ Kì Í Kùnà Láé”—Ìwọ Ńkọ́?
    Jí!—1998
  • Ìfẹ́—Ànímọ́ Kan Tó Ṣe Pàtàkì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Jí!—2018
g18 No. 1 ojú ìwé 8-9
Tọkọtaya tí wọ́n láyọ̀

OHUN TÓ Ń FÚNNI LÁYỌ̀

Ìfẹ́

GBOGBO WA LA NÍLÒ ÌFẸ́. Ìfẹ́ ló ń gbé ìgbéyàwó dúró, òun ló ń mú kí ìdílé lágbára, òun náà ló ń mú okùn ọ̀rẹ́ yi. Torí náà, ìfẹ́ ṣe pàtàkì téèyàn bá máa láyọ̀ àti pé ó máa ń jẹ́ kí ọpọlọ jí pépé, kí ìrònú èèyàn sì já geere. Àmọ́ kí ni “ìfẹ́”?

Ìfẹ́ tá à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níbí kì í ṣe ìfẹ́ táwọn olólùfẹ́ máa ń ní sí ara wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn náà ṣe pàtàkì. Ìfẹ́ tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí tún jinlẹ̀ ju ìyẹn lọ, ó máa ń mú kí èèyàn ṣoore fún àwọn ẹlòmíì látọkàn wá, ó tiẹ̀ lè mú kí èèyàn fi ìrọ̀rùn ti wọn ṣáájú ti ara rẹ̀. Àwọn ìlànà Ọlọ́run ló ń darí ìfẹ́ yìí, síbẹ̀ ẹni tó ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣì lè fi bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ hàn.

Àlàyé kan tó kún rẹ́rẹ́ nípa ìfẹ́ jẹ́ ká mọ̀ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, . . . a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.”​—1 Kọ́ríńtì 13:​4-8.

Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ “kì í kùnà láé,” torí pé ó máa wà títí láé ni. Kódà, ńṣe ló máa ń lágbára sí i bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Ìfẹ́ yìí tún jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé,” torí pé a kì í tán an ní sùúrù, ó kún fún inú rere, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn lẹ́mìí ìdáríjì. (Kólósè 3:14) Torí náà, táwọn èèyàn bá ní irú ìfẹ́ yìí, bí wọ́n tiẹ̀ láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tiwọn, àjọṣe wọn á gún régé, wọ́n á sì láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo bí irú ìfẹ́ yìí ṣe lè mú kí àárín tọkọtaya gún régé dáadáa.

“ÌDÈ ÌRẸ́PỌ̀ PÍPÉ” LÓ SO WỌ́N PỌ̀

Jésù Kristi kọ́ wa ní àwọn ìlànà pàtàkì nípa ìgbéyàwó. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “ ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’ . . . Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:​5, 6) Ó kéré tán, ìlànà pàtàkì méjì wà nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí.

“ÀWỌN MÉJÈÈJÌ YÓÒ DI ARA KAN.” Ìgbéyàwó ni àjọṣe tó sún mọ́ra jù lọ nínú àjọṣe àwa ẹ̀dá èèyàn, tí tọkọtaya bá sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kò ní sí èyíkéyìí nínú wọn tó máa fi ẹnì kejì rẹ̀ sílẹ̀, kó sì lọ di “ara kan” pẹ̀lú ẹlòmíì. (1 Kọ́ríńtì 6:16; Hébérù 13:4) Ìwà àìṣòótọ́ kì í jẹ́ kí ọkọ àti ìyàwó fọkàn tán ara wọn, ó sì lè da ìgbéyàwó rú pátápátá. Àgàgà tí ọmọ bá ti wọ̀ ọ́, ó lè dá wàhálà ńlá sílẹ̀. Torí pé ó lè mú kí àwọn ọmọ ka ara wọn sí ẹni tí kò ṣe pàtàkì, ó lè mú kí ẹ̀rù máa bà wọ́n tàbí kí wọ́n di oníbìínú èèyàn.

“OHUN TÍ ỌLỌ́RUN TI SO PỌ̀.” Ọlọ́run ka ìgbéyàwó sí àjọṣe mímọ́. Tí tọkọtaya bá ní irú èrò yìí, wọ́n á máa sapá láti mú kí ìdè ìgbéyàwó wọn túbọ̀ lágbára sí i. Tí wọ́n bá tiẹ̀ kojú ìṣòro, wọn kò ní máa wá ọ̀nà láti tú ìgbéyàwó wọn ká. Ìfẹ́ wọn á lágbára gan-an. Tọkọtaya tó bá ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ á “máa mú ohun gbogbo mọ́ra,” wọ́n á sì jọ wá ojútùú sí ìṣòro wọn, kí àláàfíà àti ìṣọ̀kan lè wà.

Àǹfààní ńlá ló máa jẹ́ fún ọmọ tó bá dàgbà sínú ìdílé tí àwọn òbí ti ní ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan sí ara wọn. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jessica sọ pé: “Bàbá mi àti ìyá mi nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Tí mo bá rí bí ìyá mi ṣe máa ń bọ̀wọ̀ fún bàbá mi, pàápàá lórí ọ̀rọ̀ àwa ọmọ, ó máa ń wú mi lórí gan-an. Èmi náà fẹ́ fìwa jọ ìyá mi.”

Ìfẹ́ ló ṣe pàtàkì jù lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run. Kódà Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Abájọ tí Jèhófà tún fi jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Àwa náà máa láyọ̀ tá a bá sapá láti fìwà jọ Ọlọ́run, pàápàá tá a bá ń gbé ìfẹ́ yọ nínú ìwà wa. Éfésù 5:​1, 2 gbà wá níyànjú pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.”

KÓKÓ PÀTÀKÌ

‘Ìfẹ́ a máa ní sùúrù àti inú rere. A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.’​—1 Kọ́ríńtì 13:​4-8.

Ìfẹ́ máa ń mú ayọ̀ wá torí pé ó máa ń . . .

  • Jẹ́ kí èèyàn ṣoore fún àwọn ẹlòmíì látọkàn wá

  • Lágbára sí i bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́

  • Jẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ yi, kí ìgbéyàwó sì lágbára

  • Jẹ́ kí ọkàn àwọn ọmọ balẹ̀ kí ara sì tù wọ́n

  • Jẹ́ ká fìwà jọ Ẹlẹ́dàá wa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́