ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g18 No. 2 ojú ìwé 9
  • 6 Ìbáwí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 6 Ìbáwí
  • Jí!—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ
  • ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ
  • OHUN TÓ O LÈ ṢE
  • Bí O Ṣe Lè Bá Àwọn Ọmọ Rẹ Wí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Mímọrírì Ìdí Tá A Fi Ń Báni Wí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Máa Gbọ́ràn
    Jí!—2015
Àwọn Míì
Jí!—2018
g18 No. 2 ojú ìwé 9
Ìdílé kan wà nínú ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n ń fi ìtọ́kọ̀ darí

Bí ìtọ́kọ̀ ṣe ń darí ọkọ̀ ojú omi náà ni ìbáwí ṣe máa ń tọ́ ọmọ sọ́nà

ÒBÍ

6 Ìbáwí

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ

Ìbáwí lè túmọ̀ sí pé ká tọ́ni sọ́nà tàbí ká kọ́ni. Ó máa ń gba pé kí àwọn òbí ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà míì tí ọmọ bá hùwà àìtọ́. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń túmọ̀ sí kí àwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ ní ìwà rere kí wọ́n lè máa ṣe dáadáa.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, àwọn òbí kan kì í bá ọmọ wọn wí bó ṣe yẹ, tóri wọ́n rò pé táwọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọmọ náà lè má níyì lójú ara rẹ̀ mọ́. Àmọ́, àwọn òbí tó gbọ́n máa ń fún àwọn ọmọ wọn ní àwọn òfin tó bọ́gbọ́n mu, wọ́n á sì kọ́ wọn láti jẹ́ onígbọràn.

“Tó bá jẹ́ pé láti kékeré ni áwọn òbí ti ń kọ́ ọmọ wọn ní ohun tó yẹ kó ṣe àti ohun tí kò gbọ́dọ̀ ṣe, tó bá dàgbà, á máa hùwà ọmọlúwàbí. Àmọ́ tí wọn ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọmọ náà máa dà bí ọkọ̀ ojú omi tí kò ní ìtọ́kọ̀. Bó pẹ́ bó yá, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ á máa hùwàkíwà.”​—Pamela.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Máa dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Tí ọmọ rẹ bá rú òfin, rí i dájú pé o bá a wí. Àmọ́ tó bá ṣègbọràn, gbóríyìn fún un.

“Mo máa ń gbóríyìn fún àwọn ọmọ mi dáadáa fún bí wọ́n ṣe jẹ́ onígbọràn, torí pé lásìkò tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ ọmọ ni kì í gbọ́rọ̀ sáwọn òbí wọn lẹ́nu. Tí àwọn òbí bá ń gbóríyìn fún àwọn ọmọ, ó máa ń jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti gba ìbáwí.”​—Christine.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.”​—Gálátíà 6:7.

Ìbáwí tó yẹ. Ìbáwí tó bá ọjọ́ orí ọmọ rẹ mu, tó bá ohun tó ṣe mu tí kò sì pọ̀ jù ló yẹ kó o fún ọmọ rẹ, má sì máa bínú ju bó ṣe yẹ lọ lórí ọ̀rọ̀ kékeré. Tó o bá fún ọmọ rẹ ní ìbáwí tó bá ohun tó ṣe mu, ìbáwí yẹn máa nítumọ̀. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ rẹ bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù lórí fóònù, tó ń wo ìwòkuwò lórí rẹ̀ tàbí tó fi ń ṣe nǹkan míì tí kò dáa, o lè gba fóònù yẹn lọ́wọ́ rẹ̀ fún àwọn àkókò kan.

“Mo máa ń sapá láti mọ̀ bóyá ọmọ mi mòọ́mọ̀ ṣe àìgbọràn ni àbí àṣìṣe ni. Ìyàtọ̀ wà nínú kéèyàn ṣe àṣìṣe àti kéèyàn ní ìwà kan tí kò dáa tó yẹ kéèyàn ṣe nǹkan sí. Tó bá jẹ́ pé ó ṣe àṣìṣe ni, ó lè má gbà ju pé kó o jẹ́ kó mọ àṣìṣe rẹ̀.”​—Wendell.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.”​—Kólósè 3:21.

Fi ìfẹ́ bá wọn wí. Táwọn òbí bá ń jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn, ó máa rọrùn fáwọn ọmọ wọn láti máa gba ìbáwí.

“Tí ọmọ wa bá ṣe àṣìṣe, a máa ń jẹ́ kó mọ̀ pé a mọyì àwọn nǹkan dáadáa tó ti ṣe tẹ́lẹ̀. Àá wá jẹ́ kó mọ̀ pé tó bá lè ṣàtúnṣe, àṣìṣe tó ṣe yẹn kò ní bà á lórúkọ jẹ́. Àá sì tún jẹ́ kó mọ̀ pé a máa ràn án lọ́wọ́ kó lè ṣe àtúnṣe tó yẹ.”​—Daniel.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere.”​—1 Kọ́ríńtì 13:4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́