Ẹni tó máa ń ṣiṣẹ́ kára dà bí ẹni tó ń ṣe eré ìmárale. Ó máa jàǹfààní nísìnyí àti lọ́jọ́ iwájú
ÀWỌN Ọ̀DỌ́
11 Máa Ṣiṣẹ́ Kára
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ
Ẹni tó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára kì í sá fún iṣẹ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè pèsè fún ara wọn àti fáwọn ẹlòmíì, kódà tí iṣẹ́ wọn kò bá fi bẹ́ẹ̀ gbayì.
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ
Òótọ́ kan ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe, ọ̀pọ̀ ló sì ń sá fún iṣẹ́ lóde òní, torí náà tó o bá jẹ́ òṣìṣẹ́ kára, wàá rọ́wọ́ mú.—Oníwàásù 3:13.
“Mo ti wá rí i pé tí èèyàn bá ń ṣiṣẹ́ kára, inú rẹ̀ máa dùn, á sì mọyì ara rẹ̀. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń fẹ́ kínú mi máa dùn, torí náà mo ti fi kọ́ra láti máa ṣiṣẹ́ kára. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn máa ń mọyì ẹni tó máa ń ṣiṣẹ́ kára.”—Reyon.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Nípasẹ̀ onírúurú làálàá gbogbo ni àǹfààní fi máa ń wà.”—Òwe 14:23.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Àwọn àbá tó wà níbí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ òṣìṣẹ́ kára.
Fi kọ́ra láti máa ṣe nǹkan dáadáa. Bóyá iṣẹ́ ilé lò ń ṣe, iṣẹ́ tí wọ́n fún ẹ nílé ìwé, àbí o wà níbi iṣẹ́, fọkàn sí nǹkan tó ò ń ṣe. Tó o bá ti mọ iṣẹ́ kan ṣe, sapá láti túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní máa pẹ́ nídìí iṣẹ́ yẹn bíi ti tẹ́lẹ̀, wà á tún mọ̀ ọ́ ṣe dáadáa. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni wà á túbọ̀ máa gbádùn iṣẹ́ rẹ.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ìwọ ha ti rí ọkùnrin tí ó jáfáfá nínú iṣẹ́ rẹ̀? Iwájú àwọn ọba ni ibi tí yóò dúró sí; kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ.”—Òwe 22:29.
Má ṣe ro tara ẹ nìkan. Lọ́pọ̀ ìgbà, tó o bá ṣe ojúṣe rẹ bó ṣe yẹ, àwọn míì náà máa jàǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí wọ́n fún ẹ nílé, wàá mú nǹkan rọrùn fáwọn ará ilé rẹ.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Ṣe kọjá nǹkan táwọn èèyàn ń retí. Dípò kó o kàn fọwọ́ ra iṣẹ́ lórí, gbìyànjú láti ṣe kọjá nǹkan tí wọ́n ń retí pé kó o ṣe. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé ìwọ fúnra rẹ lò ń darí ara rẹ, torí pé kì í ṣe ẹnì kan ló tì ẹ́ láti ṣiṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀, ìwọ fúnra rẹ lo yàn láti ṣe é.—Mátíù 5:41.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Kí ìṣe rẹ dídára má bàa jẹ́ bí ẹni pé lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe láti inú ìfẹ́ àtinúwá ti ìwọ fúnra rẹ.”—Fílémónì 14.
Wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Òṣìṣẹ́ kára kì í ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó, kì í sì ṣe ọ̀lẹ. Òṣìṣẹ́ kára kì í ṣe àṣejù, ó máa ń ṣiṣẹ́ dáadáa, o sì máa ń wáyè sinmi.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 4:6.