ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀
Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí: Ìrànlọ́wọ́ Fún Àwọn Tó ń ṣọ̀fọ̀
ÌBÀNÚJẸ́ ŃLÁ NI IKÚ ÈÈYÀN ẸNI MÁA Ń FÀ
Báwo ló ṣe máa ń rí tí èèyàn bá ń ṣọ̀fọ̀? Kí nìdí táwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ fi nílò ìtùnú?
OHUN TÓ LÈ ṢẸLẸ̀
Àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn èrò tí kò tọ́ táwọn kan ní nípa ọ̀fọ̀ àti ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n bá ń ṣọ̀fọ̀. Tó o bá ń ṣọ̀fọ̀, kà nípa oríṣiríṣi nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, tó jẹ́ pé kì í ṣohun àjèjì.
OHUN TÓ LÈ RAN ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀ LỌ́WỌ́—OHUN TÓ O LÈ ṢE
Àwọn nǹkan pàtó wo ni àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lè ṣe tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́? Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn àbá tó dá lé ọgbọ́n àtayébáyé tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́.
ÌRÀNLỌ́WỌ́ TÓ DÁRA JÙ LỌ FÚN ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀
Àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ nípa ibi tí àwọn kan ti rí ìtùnú nígbà tí ìbànújẹ́ ńlá sorí wọn kodò. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe lè ran ìwọ náà lọ́wọ́.