ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g21 No. 1 ojú ìwé 4-5
  • Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Táá Mú Kí Ìdílé Rẹ Láyọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Táá Mú Kí Ìdílé Rẹ Láyọ̀
  • Jí!—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Máa Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Aya Yín
  • Ẹ̀yin Aya, Ẹ Máa Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Ọkọ Yín
  • Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ọkọ tàbí Aya Rẹ
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Máa Tọ́ Àwọn Ọmọ Yín
  • Ẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Máa Gbọ́ràn Sí Àwọn Òbí Yín Lẹ́nu
  • Ìdílé Rẹ Lè Láyọ̀
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ìgbésí Ayé Ìdílé Tí Inú Ọlọrun Dùn Sí
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?—Apá Kìíní
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Jí!—2021
g21 No. 1 ojú ìwé 4-5
Ìdílé aláyọ̀ kan. Wọ́n wà ní ọjà.

Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Táá Mú Kí Ìdílé Rẹ Láyọ̀

Ẹ̀bùn pàtàkì ni ìgbéyàwó àti ọmọ jẹ́. Ẹlẹ́dàá wa ló sì fún wa. Ó fẹ́ kí ìdílé wa láyọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi fún wa ní ìwé àtayébáyé kan, ó sì ní ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú ẹ̀ kí ìdílé wa lè láyọ̀. Wo àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí.

Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Máa Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Aya Yín

“Kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn bí ara wọn. Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, torí pé kò sí èèyàn kankan tó jẹ́ kórìíra ara rẹ̀, àmọ́ á máa bọ́ ara rẹ̀, á sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.”​—ÉFÉSÙ 5:28, 29.

Ọkọ ni olórí ìdílé. (Éfésù 5:23) Àmọ́, ọkọ rere kì í le koko mọ́ àwọn ará ilé ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í kanra mọ́ wọn. Ó mọyì ìyàwó rẹ̀ gan-an, ó máa ń pèsè àwọn ohun tó nílò, ó sì máa ń ṣìkẹ́ rẹ̀. Ó máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti múnú ẹ̀ dùn, ó sì máa ń gba tiẹ̀ rò. (Fílípì 2:4) Ó máa ń sọ tinú ẹ̀ fún ìyàwó ẹ̀, ó sì máa ń tẹ́tí sílẹ̀ tí ìyàwó ẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀. Kì í ‘bínú sí i lọ́nà òdì,’ kì í sì í lù ú tàbí kó máa sọ̀rọ̀ burúkú gbá a lórí.​—Kólósè 3:19.

Ẹ̀yin Aya, Ẹ Máa Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Ọkọ Yín

“Kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”​—ÉFÉSÙ 5:33.

Tí aya bá ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ ẹ̀, tó sì ń tì í lẹ́yìn, ilé á tòrò. Bí ọkọ ẹ̀ bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe, kò ní kàn án lábùkù, àmọ́ á ṣì máa fi sùúrù bá a sọ̀rọ̀, á sì máa bọ̀wọ̀ fún un. (1 Pétérù 3:4) Tó bá fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan, á wá àkókò tó dáa jù láti ṣe bẹ́ẹ̀, á sì bá a sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.​—Oníwàásù 3:7.

Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ọkọ tàbí Aya Rẹ

“Ọkùnrin á . . . fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, wọ́n á sì di ara kan.”​—JẸ́NẸ́SÍSÌ 2:24.

Bí ọkùnrin àti obìnrin bá ṣègbéyàwó, àjọṣe tímọ́tímọ́ ti wà láàárín wọn nìyẹn, wọ́n ti di tọkọtaya. Torí náà, ó yẹ kí tọkọtaya máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí ìgbéyàwó wọn wà níṣọ̀kan, kí wọ́n máa bára wọn sọ̀rọ̀ látọkàn wá, kí wọ́n sì máa ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà gbogbo, kódà nínú àwọn nǹkan tó dà bíi pé kò tó nǹkan. Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn, kí wọ́n má ṣe ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì àfi ọkọ tàbí aya wọn nìkan. Ìbànújẹ́ ńlá gbáà lẹni tó bá lójú síta máa fà fún ọkọ tàbí aya rẹ̀. Kò ní jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ara wọn mọ́, ó sì lè tú ìdílé ká.​—Hébérù 13:4.

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Máa Tọ́ Àwọn Ọmọ Yín

“Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀; kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.”​—ÒWE 22:6.

Ọlọ́run gbé iṣẹ́ kan lé àwọn òbí lọ́wọ́. Ó ní kí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn. Ìyẹn sì máa gba pé kí wọ́n kọ́ wọn béèyàn ṣe ń hùwà, káwọn òbí pàápàá sì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn. (Diutarónómì 6:6, 7) Bọ́mọ kan bá tiẹ̀ ṣìwà hù, òbí tó gbọ́n ò ní bínú kọjá bó ṣe yẹ. Irú òbí bẹ́ẹ̀ á ‘yára láti gbọ́rọ̀, á lọ́ra láti sọ̀rọ̀, kò sì ní tètè máa bínú.’ (Jémíìsì 1:19) Bí òbí náà bá tiẹ̀ wá rí i pé ó yẹ kóun bá ọmọ náà wí, ìfẹ́ ló máa fi bá a wí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbínú.

Ẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Máa Gbọ́ràn Sí Àwọn Òbí Yín Lẹ́nu

“Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu . . . ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.’”​—ÉFÉSÙ 6:1, 2.

Ó yẹ káwọn ọmọ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Táwọn ọmọ bá ń bọlá fáwọn òbí wọn, á mú kí ayọ̀ wà nínú ilé, á mú kí àlàáfíà jọba, á sì mú kí ìdílé wà níṣọ̀kan. Àwọn ọmọ tó ti dàgbà náà ṣì gbọ́dọ̀ máa bọlá fáwọn òbí wọn, kí wọ́n rí i dájú pé wọ́n ń tọ́jú àwọn òbí wọn dáadáa. Ìyẹn lè gba pé kí wọ́n máa bá wọn tún ilé ṣe tàbí kí wọ́n fún wọn lówó tí wọ́n lè fi bójú tó ara wọn.​—1 Tímótì 5:3, 4.

Mo Ti Wá Di Ọkọ Rere

“Nítorí ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ mi dàgbà, mo máa ń retí pé gbogbo ohun tí mo bá sọ ni ìyàwó mi gbọ́dọ̀ ṣe. Àmọ́, nígbà tó yá, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé bí mo bá tiẹ̀ jẹ́ olórí ìdílé, ó yẹ kí n máa tẹ́tí sí ìyàwó mi, kí n má ṣe mọ tara mi nìkan, kí n má sì máa pàṣẹ lé e lórí bó ṣe wù mí. Lójú Ọlọ́run, ara kan làwa méjèèjì, mo sì gbọ́dọ̀ máa ṣìkẹ́ ìyàwó mi bí mo ṣe ń ṣìkẹ́ ara mi. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí mo rí nínú Bíbélì, mo ti wá di ọkọ rere báyìí, ìdílé mi sì ń láyọ̀.”​—Rahul.

Rahul àti ìyàwó ẹ̀.

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i:

Tó o bá fẹ́ rí àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n míì tó dá lórí bó o ṣe lè mú kí ìdílé ẹ túbọ̀ láyọ̀, lọ sórí ìkànnì jw.org, wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌGBÉYÀWÓ ÀTI ÌDÍLÉ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́