ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g21 No. 2 ojú ìwé 4-6
  • Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ìwọ Àtàwọn Ọ̀rẹ́ Ẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ìwọ Àtàwọn Ọ̀rẹ́ Ẹ?
  • Jí!—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀
  • OHUN TÓ O LÈ ṢE
  • Àkóbá Wo Ni Ìkànnì Àjọlò Lè Ṣe fún Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwọn Ọmọdé àti Ìkànnì Àjọlò—Apá 1: Ṣé Ó Yẹ Kí Ọmọ Mi Lo Ìkànnì Àjọlò?
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Táwọn Òbí Mi Bá Sọ Pé Kí N Má Lo Ìkànnì Àjọlò?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwọn Ọmọdé àti Ìkànnì Àjọlò—Apá 2: Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
Àwọn Míì
Jí!—2021
g21 No. 2 ojú ìwé 4-6
Àwọn ọ̀rẹ́ tó wà láwọn ibi tó yàtọ̀ láyé ń lo fídíò alátagbà láti bára wọn sọ̀rọ̀.

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe Fún Ìwọ Àtàwọn Ọ̀rẹ́ ẹ?

Ẹ̀rọ ìgbàlódé wúlò púpọ̀. Àwọn èèyàn máa ń fi tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ síra wọn, wọ́n fi ń kọ lẹ́tà, wọ́n lè lo ìkànnì àjọlò, wọ́n tiẹ̀ lè máa rí ara wọn bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà wọn jìn síra.

Àmọ́, àwọn kan ti sọ ọ̀rẹ́ wọn di ọ̀rẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé, ohun tó sì máa ń ṣẹlẹ̀ sí wọn ni pé . . .

  • wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ gba tàwọn ọ̀rẹ́ wọn rò.

  • wọ́n sábà máa ń dá wà, wọn kì í sì í láyọ̀.

  • wọ́n máa ń ro tara wọn nìkan.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ọ̀dọ́bìnrin kan ń wo ìkànnì àjọlò lóru. Àwọn èèyàn ti wo ohun tó ń wò yẹn ní ìgbà 723,000.

ÌGBATẸNIRÒ

Tẹ́nì kan bá fẹ́ máa gba ti ọmọnìkejì ẹ̀ rò, àfi kó fara balẹ̀, kó sì fi sùúrù ronú nípa onítọ̀hún. Àmọ́ èèyàn ò lè ráyè ṣèyẹn níbi tó ti ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, tó ń gba èsì pa dà, tó sì tún ń wo ohun tó ń lọ lórí ìkànnì àjọlò.

Tó o bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ẹ̀rọ ìgbàlódé, kó o tó mọ̀, gbogbo àkókò ẹ ni wàá máa fi fèsì àwọn ọrọ̀ tó ń wọlé látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Ohun táá wá jẹ ẹ́ lógún ni bó o ṣe máa ráyè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ náà dípò kó o wá bí wàá ṣe ran ọ̀rẹ́ ẹ kan tó níṣòro lọ́wọ́.

RÒ Ó WÒ NÁ: Báwo lo ṣe máa bá àwọn òrẹ́ ẹ “kẹ́dùn” tó bá jẹ́ pé àtẹ̀jíṣẹ́ lo fi ń bá wọn sọ̀rọ̀?​—1 PÉTÉRÙ 3:8.

ÌBÀNÚJẸ́

Ìwádìí kan fi hàn pé inú ọ̀pọ̀ èèyàn kì í dùn tí wọ́n bá ti pẹ́ jù lórí ìkànnì àjọlò; àti pé téèyàn bá kàn ṣáà ń wo fọ́tò àtàwọn nǹkan míì táwọn èèyàn gbé sórí ìkànnì, “á máa ṣèèyàn bíi pé ó kàn ń fàkókò ẹ̀ ṣòfò ni.”

Bákan náà, tẹ́nì kan bá ń wo àwọn fọ́tò tó jojú ní gbèsè táwọn kan gbé sórí ìkànnì àjọlò, inú ẹ̀ lè bà jẹ́ kó sì máa ronú pé ńṣe lòun ń jìyà níbi táwọn tó kù ti ń gbádùn ara wọn.

RÒ Ó WÒ NÁ: Tó o bá ń lo ìkànnì àjọlò, kí lo lè ṣe kó o má bàa fi ara ẹ wé àwọn èèyàn kan débi tí wàá fi ro ara ẹ pin?​—GÁLÁTÍÀ 6:4.

ÌMỌTARA-ẸNI-NÌKAN

Olùkọ́ kan kíyè sí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ kan máa ń ṣohun tó fi hàn pé “àwọn tí wọ́n bá lè rí jẹ lọ́dọ̀ wọn nìkan ni wọ́n máa ń bá ṣọ̀rẹ́.”a Ńṣe làwọn tó bá nírú ìwà yìí máa ń wo àwọn ọ̀rẹ́ wọn bíi fóònù téèyàn ń tẹ̀ nígbà tó bá nílò ẹ̀, táá sì pa á tì síbì kan nígbà tí kò bá nílò ẹ̀.

RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé ohun tó ò ń gbé sórí ìkànnì ò fi hàn pé kárími lò ń ṣe, tàbí pé ò ń fi ohun tó o ní ṣe fọ́rífọ́rí? ​—GÁLÁTÍÀ 5:26.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

MÁA FỌGBỌ́N LO Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDÉ

Tó o bá ń fọgbọ́n lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, wàá máa ráyè fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ, ọ̀rẹ́ yín á sì túbọ̀ máa lágbára.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ìfẹ́ . . . kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.”​—1 KỌ́RÍŃTÌ 13:​4, 5.

Sàmì sí àwọn tí wàá fẹ́ tẹ̀ lé lára àwọn àbá yìí tàbí kó o kọ èyí tíwọ fúnra ẹ ronú kàn.

  • Túbọ̀ máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú (dípò kó o máa lo àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí lẹ́tà orí ẹ̀rọ nìkan)

  • Wá ibì kan fi fóònù ẹ sí (tàbí kó o yí i sílẹ̀) tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀

  • Dín àkókò tó o fi ń wo ohun táwọn èèyàn gbé sórí ìkànnì àjọlò kù

  • Túbọ̀ máa tẹ́tí sílẹ̀ táwọn èèyàn bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀

  • Lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ ẹ kan tó níṣòro kó o lè ràn án lọ́wọ́

a Ìwé Reclaiming Conversation ló sọ ọ́.

BI ARA Ẹ PÉ . . .

  • Ṣé ọ̀rẹ́ gidi lèmi àtàwọn tí mò ń bá ṣọ̀rẹ́ àbí ọ̀rẹ́ ojú lásán?

  • Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà témi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi bá ń sọ̀rọ̀ lójúkojú ni ọ̀rọ̀ àti ìpè máa ń wọlé sórí fóònù mi, tí mi ò sì ní lè tẹ́tí gbọ́rọ̀ wọn mọ́?

  • Ṣé ọ̀rọ̀ àti fọ́tò tí mò ń gbé sórí ìkànnì àjọlò kì í fi hàn pé fọ́rífọ́rí ni mò ń ṣe?

  • Lẹ́yìn tí mo bá lo àkókò tó pọ̀ lórí ìkànnì àjọlò, ṣé kì í ṣe mí bíi pé ńṣe ni mo kàn fi àkókò mi ṣòfò?

  • Kí ni mo lè ṣe tí mi ò fi ní máa lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ẹ̀rọ ìgbàlódé, kí n lè túbọ̀ máa ráyè gbọ́ tàwọn ọ̀rẹ́ mi?

    ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: Ẹ máa “wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.”​—FÍLÍPÌ 2:4.

Emily.

“Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn tó bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ gidi máa ń ṣe. Torí náà, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ díẹ̀ lo lè ní. Ó sàn kó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ díẹ̀ lo ní ju kó o kàn kó ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ jọ. Ire ẹ làwọn ọ̀rẹ́ gidi máa ń wá, ìwọ náà á sì máa wá ire wọn.”​—EMILY

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́