ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g21 No. 3 ojú ìwé 14-15
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Bóyá Ẹlẹ́dàá Wà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Bóyá Ẹlẹ́dàá Wà
  • Jí!—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wàá túbọ̀ láyọ̀
  • Wàá rí ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ káyé ẹ dáa
  • Wàá rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè rẹ
  • Wàá nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa
  • Ǹjẹ́ O Gbà Pé Ọlọ́run Wà? Tó O Bá Gbà Àǹfààní Wo Ló Máa Ṣe Ẹ́?
    Jí!—2015
  • Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì
Àwọn Míì
Jí!—2021
g21 No. 3 ojú ìwé 14-15
Àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́ta ń wo ẹyẹ tó wà lórí igi.

Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ̀ Bóyá Ẹlẹ́dàá Wà

Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ̀ bóyá Ẹlẹ́dàá wà? Ìdí ni pé tó o bá ṣèwádìí, tó sì dá ẹ lójú pé Ọlọ́run Olódùmarè wà, ó máa wù ẹ́ láti wá àwọn ẹ̀rí táá jẹ́ kó o gbà pé òun náà ló mí sí Bíbélì. Tó o bá sì fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Lára àwọn àǹfààní tó o máa rí níbẹ̀ nìyí.

Wàá túbọ̀ láyọ̀

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “[Ọlọ́run] ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde, ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.”​—Ìṣe 14:17.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni gbogbo ohun tó wà láyé yìí. Wàá túbọ̀ mọyì àwọn ẹ̀bùn yìí tó o bá mọ̀ pé Ọlọ́run tó fún wa láwọn ẹ̀bùn náà nífẹ̀ẹ́ rẹ, ọ̀rọ̀ rẹ sì jẹ ẹ́ lógún gan-an.

Wàá rí ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ káyé ẹ dáa

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Wàá lóye ohun tó jẹ́ òdodo àti ẹ̀tọ́ àti àìṣègbè, gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere.”​—Òwe 2:9.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Torí pé Ọlọ́run ló dá ẹ, ó mọ ohun táá jẹ́ kó o láyọ̀. Tó o bá ka Bíbélì, wàá rí ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní káyé ẹ lè dáa.

Wàá rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè rẹ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Wàá . . . rí ìmọ̀ Ọlọ́run.”​—Òwe 2:5.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Tó o bá gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, ó máa rọrùn fún ẹ láti rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tó lè máa jẹ ọ́ lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ: Kí nìdí tá a fi wà láàyè? Kí nìdí tí ìyà fi pọ̀ tó báyìí? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú? Bíbélì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, àwọn ìdáhùn náà á sì fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀.

Wàá nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “‘Mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa,’ ni Jèhófà wí, ‘èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’”​—Jeremáyà 29:11.

Lọ wo fídíò Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì? àti Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì? lórí ìkànnì jw.org. O lè rí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò yìí tó o bá kọ “ooto Bibeli” tàbí “onsewe Bibeli” síbi téèyàn ti lè fi ọ̀rọ̀ wá nǹkan lórí ìkànnì náà.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ọlọ́run ṣèlérí pé láìpẹ́, òun máa fòpin sí ìwà ibi àti ìyà, òun á sì mú ikú kúrò. Tó bá dá ẹ lójú pé Ọlọ́run máa ṣe àwọn nǹkan rere yìí, ọkàn ẹ á balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, ìyẹn á sì jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti máa fara da àwọn ìṣòro rẹ.

Àǹfààní táwọn kan ti rí torí pé wọ́n gbà pé Ẹlẹ́dàá wà

Cyndi.

“Ó máa ń yà mí lẹ́nu tí mo bá rí bí Ọlọ́run ṣe ń ran àwa èèyàn lọ́wọ́ lóríṣiríṣi ọ̀nà. Òun ló jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa, ó tún jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn àti bá a ṣe lè di ọ̀rẹ́ òun.”​—Cyndi, Amẹ́ríkà.

Elise.

“Inú mi dùn gan-an torí mo gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, ọkàn mi sì balẹ̀. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n ronú jinlẹ̀, torí mo mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tó yẹ kí n kọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa, àwọn nǹkan tó dá, àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀.”​—Elise, Faransé.

Peter.

“Ṣe ni mo túbọ̀ ń láyọ̀ bí mo ṣe ń fi ohun tí Ẹlẹ́dàá kọ́ wa nínú Bíbélì sílò. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n wo ibi táwọn èèyàn dáa sí, kí n máa tẹ́tí sílẹ̀ táwọn èèyàn bá ń sọ̀rọ̀, kí n sì jẹ́ kí ohun tí mo ní tẹ́ mi lọ́rùn. Ó tún ti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè jẹ́ bàbá rere.”​—Peter, Netherlands.

Liz.

“Tẹ́lẹ̀, ohun tí mo máa ń ṣe ò ju pé kí n jẹun, kí n sùn, kí n sì máa lé bí màá ṣe tètè débi iṣẹ́. Gbogbo wàhálà yẹn ti pọ̀ jù fún mi! Àmọ́ ní báyìí, mo gbà pé Ọlọ́run ló jẹ́ kí n wà láàyè, ó sì fẹ́ kí n máa gbádùn ayé mi. Torí náà, ó yẹ kí n mọyì ohun tó ṣe fún mi.”​—Liz, Estonia.

Adrien.

“Mo máa ń ṣàníyàn gan-an. Àmọ́, ọkàn mi máa ń balẹ̀ bí mo ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà ibi, ìwà ìrẹ́jẹ àti ìyà.”​—Adrien, Faransé.

Wo fídíò náà Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?​—Èyí Tó Gùn kó o lè rí i pé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́