AYÉ DOJÚ RÚ
1 | Tọ́jú Ara Rẹ
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ
Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ tàbí tí wàhálà bá wà nílùú, onírúurú ọ̀nà nìyẹn máa ń gbà ṣàkóbá fún ìlera àwọn èèyàn.
Bí àpẹẹrẹ, àyà àwọn èèyàn sábà máa ń já tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀, tí wọn ò bá sì tètè gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ìyẹn lè mú kí wọ́n ṣàìsàn.
Tí nǹkan ò bá rí bó ṣe yẹ kó rí nílùú, ìyẹn lè ṣàkóbá fún ètò ìlera débi pé kò ní rọrùn láti tọ́jú àwọn aláìsàn.
Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ìyẹn lè má jẹ́ káwọn èèyàn rówó ra oúnjẹ aṣaralóore, oògùn àtàwọn nǹkan pàtàkì míì.
Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀
Tẹ́nì kan bá ń ṣàìsàn tó le gan-an tàbí tí ọkàn ẹ̀ ò balẹ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò ní lè ronú bó ṣe tọ́, ó sì lè máa ṣe àwọn nǹkan táá ṣàkóbá fún ìlera ẹ̀. Ìyẹn sì lè mú kí àìsàn tó ń ṣe é burú sí i.
Tẹ́nì kan bá ń ṣàìsàn tí kò sì tọ́jú ara ẹ̀, ńṣe ni àìsàn náà á máa burú sí i, ó sì lè gbẹ̀mí ẹ̀.
Tára ẹ bá le dáadáa, wàá lè ronú lọ́nà tó tọ́, wàá sì lè ṣèpinnu tó dáa nígbà ìṣòro.
Tó ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe láti tọ́jú ara ẹ.
Ohun To O Lè Ṣe Ní Báyìí
Tí ọlọ́gbọ́n bá rí ohun kan tó lè pa á lára, á tètè wá nǹkan ṣe sí i. Ohun tó yẹ ká ṣe nìyẹn tó bá kan ọ̀rọ̀ ìlera wa. Tá a bá ń ṣe ìmọ́tótó bó ṣe yẹ, a ò ní tètè máa ṣàìsàn, tá a bá sì ṣàìsàn, kò ní le jù. Ó ṣe tán, wọ́n sọ pé ìmọ́tótó borí àrùn mọ́lẹ̀.
“A máa ń tọ́jú ara wa dáadáa a sì máa ń jẹ́ kí àyíká wa wà ní mímọ́ tónítóní. Ìyẹn jẹ́ ká dín iye tá à ń ná lórí ọ̀rọ̀ ìtọ́jú ara wa kù.”—Andreas.a
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú ìwé yìí.