ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g22 No. 1 ojú ìwé 13-15
  • 4 | Gbà Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 4 | Gbà Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
  • Jí!—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ
  • Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Ní Báyìí
  • Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ̀ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
  • Kí Ló Lè Fún Mi Ní Ìrètí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì
  • Ohun Tó Lè Fi Wá Lọ́kàn Balẹ̀ Lọ́dún 2024—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Jí!—2022
g22 No. 1 ojú ìwé 13-15
Wọ́n ṣí Bíbélì kan sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwo kan tí òdòdó wà nínú ẹ̀.

AYÉ DOJÚ RÚ

4 | Gbà Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Àníyàn nípa bí nǹkan ṣe ń dojú rú láyé yìí lè mú kí nǹkan tojú sú àwọn èèyàn, kó sì ṣàkóbá fún ìlera wọn. Kódà, ó lè mú káwọn kan gbà pé kò sọ́nà àbáyọ mọ́. Kí làwọn èèyàn sábà máa ń ṣe tí nǹkan bá dojú rú?

  • Àwọn kan ò ní fẹ́ ronú nípa ọjọ́ iwájú mọ́.

  • Àwọn míì máa ń fi ọtí àbí oògùn olóró pàrònú rẹ́.

  • Àwọn míì gbà pé ikú yá ju ẹ̀sín, torí náà wọ́n á gbìyànjú láti para wọn.

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀

  • Nǹkan lè yí pa dà nígbàkigbà kó o sì rí ojútùú sí díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó ò ń kojú báyìí.

  • Tí ìṣòro náà ò bá tiẹ̀ yanjú, àwọn nǹkan kan ṣì wà tó o lè ṣe láti máa fara dà á.

  • Bíbélì sọ fún wa pé Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìṣòro tó wà láyé yìí.

Ohun Tó O Lè Ṣe Ní Báyìí

Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.”​—Mátíù 6:34.

Má ṣe jẹ́ kí àníyàn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la dẹ́rù bà ẹ́, débi tó ò fi ní lè bójú tó àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe lónìí.

Tó o bá ń ṣàníyàn jù nípa àwọn nǹkan burúkú tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀, ńṣe ni wàá máa gbọ́kàn sókè, ìyẹn á sì mú kí nǹkan túbọ̀ tojú sú ẹ.

KÍ LỌ̀NÀ ÀBÁYỌ?​—Ohun Tó O Lè Ṣe

GBỌ́KÀN KÚRÒ LÓRÍ ÀWỌN ÌṢÒRO TÓ O NÍ

Obìnrin kan ń wo ìta látojú wíńdò.

Bíbélì sọ pé: “Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìyà ń jẹ, àmọ́ ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn máa ń jẹ àsè nígbà gbogbo.” (Òwe 15:15) Tó o bá ń ronú ṣáá nípa ìṣòro tó o ní, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o tètè wá nǹkan ṣe sí i. Àmọ́, tó o bá gbà pé nǹkan ṣì lè dáa, ó máa rọrùn fún ẹ láti ronú nípa ohun tó o lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà.

  • Dín iye àkókò tó ò ń lò láti gbọ́ ìròyìn kù.

  • Lópin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, máa ronú nípa àwọn nǹkan méjì tàbí mẹ́ta tí Ọlọ́run ṣe fún ẹ, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀.

  • Kọ ohun tó o gbà pé o lè ṣe tán lójúmọ́ sílẹ̀. Wá gbìyànjú láti pín àwọn iṣẹ́ ńláńlá sí kéékèèké, kó lè rọrùn fún ẹ láti mọ ohun tó o ṣe lọ́jọ́ kan.

JẸ́ KÍ ÀWỌN ÈÈYÀN RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

Bàbá àgbàlagbà kan ń bá ọ̀dọ́kùnrin kan sọ̀rọ̀, ó sì ń fi ọ̀dọ́kùnrin náà lọ́kàn balẹ̀.

Bíbélì sọ pé: ‘Ẹni tó bá ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa kọ ọgbọ́n tó gbéṣẹ́.’ (Òwe 18:1) Ká sọ pé o já sínú kòtò tó jìn gan-an, ó dájú pé ìwọ fúnra ẹ ò ní lè jáde. Àmọ́ tẹ́nì kan bá wá ràn ẹ́ lọ́wọ́, kíá ló máa fà ẹ́ jáde.

  • Ní káwọn mọ̀lẹ́bí ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́.

  • Máa ronú nípa ohun tí ìwọ náà lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Tó o bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, o ò ní máa gbé ìṣòro ẹ sọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ.

  • Tó o bá ti ro ara ẹ pin débi pé ayé ti sú ẹ, á dáa kó o lọ rí dókítà. Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé àìlera ló ń mú kẹ́nì kan máa sorí kọ́ tàbí kó máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí ojútùú sí ìṣòro wọn lẹ́yìn tí wọ́n lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.a

a Ìwé yìí ò sọ irú ìtọ́jú pàtó tó yẹ kẹ́nì kan gbà.

Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ̀ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa

Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, onísáàmù kan gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ fún ọ̀nà mi.” (Sáàmù 119:105) Jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ lohun tí onísáàmù yẹn sọ.

Tẹ́nì kan bá ń rìn nínú òkùnkùn lálẹ́, ọkàn ẹ̀ máa balẹ̀ tó bá tan tọ́ọ̀ṣì torí ìyẹn á jẹ́ kó mọ ibi tó yẹ kó gbà. Bákan náà, ṣe ni Bíbélì dà bí ìmọ́lẹ̀ torí ó láwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó máa tọ́ wa sọ́nà, táá sì ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́.

Tẹ́nì kan bá tanná nínú òkùnkùn, ìyẹn lè jẹ́ kó rí ohun tó wà lọ́nà jíjìn. Bákan náà, Bíbélì lè jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.

Torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá, ó jẹ́ ká mọ báwa èèyàn ṣe dé ayé, ó sì tún jẹ́ kó dá wa lójú pé nǹkan ṣì máa dáa lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan yìí:

1

Bí ìyà ṣe bẹ̀rẹ̀: Bíbélì sọ pé “bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe tipasẹ̀ ẹnì kan wọ ayé, tí ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn torí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”​—Róòmù 5:12.

2

Ìdí tí ìjọba èèyàn ò fi lè yanjú ìṣòro wa: Bíbélì sọ pé “kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé lónìí fi hàn pé òótọ́ lohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ.

3

Bí Ọlọ́run ṣe máa tún ayé yìí ṣe: Bíbélì sọ pé “ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”​—Ìfihàn 21:4.

Àwòrán apá kan látinú fídíò “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Obìnrin kan ń fi ohun tó kà nínú Bíbélì han ọkọ rẹ̀.

KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I. Wo fídíò náà Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́