Ori 2
Ọba Ayeraye Naa
1. Eeṣe tí a fi nilati ní ìgbọ́kànlé ninu Ọlọrun gẹgẹ bi Baba gidi kan?
JESU bẹrẹ “Adura Oluwa” nipa pípe Ọlọrun ní “Baba wa.” Rárá, kii wulẹ ṣe Baba Jesu Kristi nikan, ṣugbọn ní àsẹ̀hìnwá àsẹ̀hìnbọ̀ Baba gbogbo araye tí ń fi pẹlu igbọran jọsin Ẹni ti “ń gbọ́ adura” onifẹẹ yii. (Orin Dafidi 65:2) Gẹgẹ bi “Ọba ayeraye” oun ń fi ojúlówó àníyàn tí ó wà pẹtiti hàn si awọn ẹ̀dá rẹ̀, àní gẹgẹ bi eniyan kan tí ó jẹ́ baba rere ti ń ṣe fun awọn ọmọ rẹ̀. (1 Timoteu 1:17) Awa gbọdọ ní ìgbọ́kànlé ninu “Baba wa” gẹgẹ bi Ẹni gidi kan tí ó bikita fun wa. Ohun yoowu ki ede, àwọ̀ ara tabi ipò ìdúró wa ninu igbesi-aye jẹ́, awa gbọdọ ní imọlara ominira lati sunmọ ọn, nitori pe “Ọlọrun kii ṣe ojúsàájú eniyan: ṣugbọn ní gbogbo orilẹ-ede, ẹni tí ó bá bẹru rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ̀.”—Iṣe 10:34, 35.
2, 3. Bawo ni Baba wa ṣe fi araarẹ̀ hàn pe oun jẹ Olùfúnni-ní-Ìyè ati Olùpèsè Atobilọla? (Genesisi 1:1, 2, 31)
2 “Baba wa tí ń bẹ ní ọrun” ni Ẹlẹ́dàá, Ẹni naa tí ó fi ìyè fun araye. (Matteu 6:9; Orin Dafidi 36:9) Ṣugbọn oun pọ̀ pupọ ju jijẹ kiki Olùfúnni-ní-Ìyè lọ; oun tún jẹ Olùpèsè Atobilọla wa pẹlu. Awa yoo reti pe ki baba ti o jẹ eniyan kan tí ó mọṣẹ́níṣẹ́ pèsè ile ati ohun ìgbẹ́mìíró fun awọn ọmọ rẹ̀, kódà laika bi akoko ati isapa tí yoo ná a yoo ti pọ̀ tó. Baba wa ọrun ti ṣe eyi, ati jù bẹẹ lọ, lọna ọ̀làwọ́ julọ.
3 Rò ó wò ná bi “Ọba ayeraye” yii ti fi ifẹ pèsè ilẹ̀-ayé lati jẹ́ ile wa. Ó fi i si ibi tí ó tọ́ gan-an ní ofuurufu awọn ọrun, ati nipa agbara rẹ̀ ti o galọla julọ oun mú ki ohun gbogbo tí ó pọndandan fun mimu ki gbigbe awọn eniyan ninu ayé jẹ alayọ hù jade lori ilẹ̀-ayé. Nigba naa ni oun dá ọkunrin ati obinrin, ó sì fi wọn sinu ile ẹlẹwa yii—ẹ̀bùn titobilọla kan, nitootọ, “fun awọn ọmọ eniyan”!—Orin Dafidi 115:16; 19:1, 2.
4. (a) Oye oninuure wo nipa ọjọ iwaju ni Baba wa fihan ní mimura ile wa silẹ? (b) Ki ni mú un dá wa lójú pe oun fẹ́ ki a layọ?
4 Ẹ wo iru ilé gbígbámúṣé tí Baba wa ọrun pèsè fun awọn ọmọ rẹ̀ níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé! Oun ṣeto rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pe awọn òru tí ó tutù, tí ń mú isinmi wá lè tẹle awọn ọ̀sán mímọ́lẹ̀yòò tí ó kún fun igbokegbodo. Ó ṣètò awọn asiko tí ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ fun ire ati igbadun wa. (Genesisi 8:22) O pèsè ọpọ yanturu ohun kò-ṣeé-màní naa, omi, tí ó sì ṣe ìpínfúnni rẹ̀ káàkiri ilẹ̀-ayé ki a baa lè maa rí i lò nibikibi tí a bá ti nilo rẹ̀. Oun tẹ́ awọn eweko atunilára silẹ bii kápẹ́ẹ̀tì—eyi ti araadọta ọkẹ ibusọ níbùú-lóròó rẹ̀ wà—kaakiri ile ori ilẹ̀-ayé wa. O ti ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹlu awọn òdòdó aláràbárà tí ó kọyọyọ. O ti sọ oju ilẹ di ẹlẹwa laaarin awọn ẹgàn, adágún omi ati awọn òkè-ńlá tí ó wuni. Ninu “yàrá-abẹ́-ilẹ̀” ilẹ̀-ayé ni oun ti fi ọpọlọpọ èédú-ilẹ̀, epo ati awọn ohun ọrọ̀ àmúṣagbára miiran pamọ sí. O ń báa lọ lati maa fi ounjẹ kún inu “yàrá ounjẹ” ayé ní àkúnwọ́sílẹ̀ pẹlu awọn hóró, eso, ewébẹ̀ ati awọn oúnjẹ adùnyùngbà miiran. Ẹ wo iru Olùpèsè ọlọgbọn, olugbatẹniro ti Baba wa ọrun jẹ́! Bibeli pè é ní “Ọlọrun alayọ.” Dajudaju, oun fẹ́ ki a jẹ́ alayọ, pẹlu.—1 Timoteu 1:11, NW; Isaiah 25:6-8.
“ORUKỌ” BABA WA
5. Ki ni ó gbọdọ jẹ́ ifẹ ọkàn-àyà wa ní fifi awọn ọ̀rọ̀ iṣaaju inu adura àwòṣe Jesu gbadura?
5 Baba wa ọrun onifẹẹ ní “orukọ rere kan,” ìfùsì rere kan gẹgẹ bi Olùpèsè Atobilọla. Oun tun ní orukọ ara-ẹni kan, gan-an gẹgẹ bi baba eniyan eyikeyii ti ní. Bi awa bá ní baba ẹlẹ́ran ara kan tí ó tóyeyẹ, awa nilati koriira lati rí ki a pẹ̀gàn orukọ ati ìfùsì rẹ̀. Awa gbọdọ fẹ́ lati ríi pe a bọ̀wọ̀ fun orukọ rẹ̀. Àní jù bẹẹ lọ paapaa, ó gbọdọ jẹ́ ifẹ ọkan wa lati ríi pe a bọla fun orukọ Baba wa ọrun. Nitori naa, lati inu ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkàn-àyà wa, o yẹ ki awa lè gbadura pẹlu awọn ọ̀rọ̀ tí Jesu fi ṣaaju ninu Adura Àwòṣe rẹ̀: “Baba wa ninu awọn ọ̀run, jẹ́ kí orukọ rẹ di sísọdimímọ́.”—Matteu 6:9, NW; Owe 22:1, àlàyé isalẹ ìwé.
6. Niti orukọ Ọlọrun, ki ni iwọ yoo fẹ́ lati rí?
6 Nitootọ, ó gbọdọ figba gbogbo jẹ́ adura onígbòóná-ọkàn wa pe ki a gbé orukọ atobilọla Ẹlẹ́dàá ọrun ati ayé ga, ki a gbé e ga soke jù gbogbo orukọ miiran lọ, ki a sì fi i hàn pe ó jẹ́ orukọ tí ó ṣeyebíye, tí ó kún fun itumọ julọ, tí ó si fanimọ́ra julọ ní agbaye. Ohun tí ó ṣe pataki lọpọlọpọ ju igbala awa funraawa lọ ni ìsọdimímọ́ orukọ mímọ́ Ọlọrun. Orukọ ati ìfùsì rẹ̀ ni a gbọdọ sọ di mímọ́—ki a dá a láre lodisi gbogbo ẹ̀gàn tí awọn ẹ̀dá olórúkọ-búburú ti kójọ lé e lórí.
7. Ki ni Bibeli fihan pe ó jẹ́ orukọ àdáni ti Ọlọrun ń jẹ́?
7 Ki ni orukọ àdáni ti Baba wa ọrun ń jẹ́? A ṣí i paya ninu ayika ọ̀rọ̀ eyi ti ó fihan pe Ẹni ti o ni orukọ titobilọla yẹn ní awọn ọ̀tá. Ní ṣiṣapejuwe eyi, Orin Dafidi 83, ẹsẹ 17 ati 18, ninu Bibeli Mimọ ni ede Yoruba, kà pe: “Ki wọn ki ó daamu ki a sì pọ́n wọn lójú laelae; nitootọ, ki a dojuti wọn, ki wọn ki ó ṣègbé. Ki awọn eniyan ki ó lè mọ̀ pe iwọ orukọ ẹnikanṣoṣo tí ń jẹ́ Jehofa, iwọ ni Ọga-ogo lori ayé gbogbo.”—Tún wo Orin Dafidi 100:3.
8. Ki ni awọn ọ̀tá Ọlọrun ti gbiyanju lati ṣe sí orukọ rẹ̀, pẹlu iyọrisi wo sì ni?
8 Nitori naa, JEHOFA ni orukọ Ọlọrun. Ṣugbọn ọpọlọpọ eniyan tí wọn sọ pe awọn ń jọsin Ọlọrun ni wọn ti fi àìlọ́wọ̀ tí ó gadabú hàn si orukọ naa. Awọn kan tilẹ ti yọ orukọ rẹ̀ dànù kuro ninu awọn itumọ Bibeli wọn, tí wọn sì fi awọn ọ̀rọ̀ bii “OLUWA” ati “ỌLỌRUN” ninu awọn lẹta gàdàgbà-gàdàgbà dipo rẹ̀. Kii ṣe kiki pe aṣa yii ti fi orukọ Ọlọrun olokiki pamọ́ nikan ni, ṣugbọn ó tún ṣe àmúlùmalà Oluwa Jehofa pẹlu Oluwa Jesu Kristi ati pẹlu awọn “oluwa” ati “ọlọrun” miiran tí a sọrọ nipa wọn ninu Bibeli. (Orin Dafidi 110:1; Deuteronomi 10:17; Romu 1:4; 1 Korinti 8:5, 6) Bawo ni awọn kan ṣe lè fi àìlábòsí gbadura pe ki a bọ̀wọ̀, tabi ya, orukọ Baba naa si mímọ́, nigba tí wọn ń wá ọ̀nà lati bo orukọ naa mọ́lẹ̀?
9. (a) Ọ̀nà wo ni a gbà ń kọ orukọ Ọlọrun ní ede Heberu, ati ní awọn èdè miiran? (b) Bibeli fihan pe Ọlọrun jẹ́ ẹni meloo?
9 Orukọ Ọlọrun ti o tayọ gbogbo orukọ ni a ṣojú fun lédè Heberu, èdè akọkọ tí a lò lati fi kọ Bibeli, pẹlu awọn àmì-ìkọ̀wé yii יהוה, eyi tí awọn kan ń pè ní Yahʹweh. Ọ̀nà pípè orukọ naa tí gbogbogboo tẹwọgba lédè Yoruba ni “Jehofa,” orukọ naa ni a sì ṣojú fun lọna kan-naa ninu awọn èdè miiran. Nipa lilo orukọ naa “Jehofa” ó ṣeeṣe fun wa lati fihan ní kedere ẹni tí a ní lọ́kàn. ‘Jehofa kan’ ni. Oun kii ṣe Jesu Kristi, nitori pe aduroṣinṣin Ọmọkunrin Ọlọrun ni Jesu jẹ́, “aworan Ọlọrun tí a kò rí, akọbi gbogbo ẹ̀dá.”—Kolosse 1:15; Marku 12:29; Deuteronomi 6:4.
10. Ki ni orukọ Ọlọrun tumọsi, bawo ni oun sì ṣe fi eyi han?
10 Orukọ naa “Jehofa” ní itumọ alagbara. Ó tumọsi: “Oun Mú Ki Ó Wà (tabi, Jásí).” Eyi nii ṣe pẹlu Oun fúnraarẹ̀, kii ṣe pẹlu dídá tí Oun dá awọn nǹkan. Nipa bayii, o polongo pe “Jehofa” ni orukọ “iranti” oun nigba tí ó ṣetan lati di Oludande oníṣẹ́ ìyanu fun awọn eniyan rẹ̀ Israeli kuro lọ́wọ́ Farao ti Egipti. (Eksodu 3:13-15) Lẹhin naa, nigba tí wolii Jeremiah jẹ́wọ́ Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ gẹgẹ bi Olùṣẹ̀dá ọrun ati ayé ‘nipa agbara nla rẹ̀ ati nínà apá rẹ̀,’ ati gẹgẹ bi ẹni “titobi ní igbimọ, ati alagbara ní iṣe,” Jehofa mú un dá wolii rẹ̀ lójú pe, ní akoko yiyẹ Tirẹ̀, Oun yoo mú iṣe kan tí o jọ bi eyi ti kò lè ṣẹlẹ ṣe nipa didi Ẹni ti o mu awọn eniyan Rẹ̀ padàbọ̀sípò lati oko òǹdè Ilẹ-ọba Babiloni. O sì ṣe bẹẹ!—Jeremiah 32:17-19, 27, 44; 2 Kronika 36:15-23.
11. Bawo ni a ṣe lè so orukọ Ọlọrun pọ̀ mọ́ Ijọba rẹ̀ lonii?
11 Lonii, pẹlu, Jehofa ni Ọlọrun nla tí “ó mú ki ó wà.” Oun gẹgẹ bi ẹnikan lè mu araarẹ̀ yẹ fun ohun yoowu ti o ba pọndandan, lati kún oju ila ipa iṣẹ eyikeyii tí aini wà fun, lati lè mú awọn ohun agbayanu ṣe nipasẹ Ijọba rẹ̀, ní sisọ orukọ rẹ̀ di mímọ́ ati fun anfaani awọn eniyan rẹ̀. Ohun yoowu tí ó bá pete lati ṣe ń di ṣiṣe, pẹlu iyọrisirere.—Isaiah 48:17; 55:11.
A HA TI YA ORUKỌ ỌLỌRUN SÍ MÍMỌ́ BI?
12. Bawo ni araye ti ṣe kà Ọlọrun sí?
12 Araye ha ti fi imọriri, ọ̀wọ̀ ati ifẹ hàn fun Ọlọrun olokiki yii, ẹni tí ó jẹ́ adúróṣánṣán tí ó sì ti pèsè lọna iyanu tobẹẹ fun awọn ẹ̀dá rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé bi? Wò yika òbíríkítí ilé-ayé yii, iwọ yoo sì rí idahun naa. Wò bi awọn orilẹ-ede tí a fi ẹnu lasan pè ní Kristian ṣe ṣojú fun Ọlọrun lọna òdì! Ọpọ lara awọn orilẹ-ede wọnyi ti rí i gẹgẹ bi Ọlọrun kan tí ń ṣègbè, wọn sì ti gbadura si i lati ràn wọn lọwọ ninu ogun jíjà wọn lodisi awọn eniyan ẹlẹgbẹ wọn. Awọn miiran ti kà á sí Ọlọrun onroro, tí ń fi “awọn ọkàn tí ó jade lọ” ranṣẹ si awọn ọwọ́-iná tí ń muni jẹ̀rora oró ayeraye. Sibẹ awọn miiran ti rẹ̀ ẹ́ silẹ nipa fifi i wé awọn ère alailẹmii tí a fi igi tabi okuta ṣe. Pupọ ti dìídì rú awọn ofin ododo rẹ̀, tí wọn ń wi pe Ọlọrun kò ríran tabi bikita mọ́.—Ṣe ifiwera Iṣe 10:34, 35; Jeremiah 7:31; Isaiah 42:8 ati 1 Peteru 5:7.
13. Ki ni yoo jẹ́ iyọrisi ikẹhin bi a bá gbà awọn eniyan ti a ṣìlọ́nà láàyè lati lépa awọn ọna àìnífẹ̀ẹ́ wọn?
13 Bi ó ti wù ki ó rí, bi awọn eniyan tí a ṣìlọ́nà kò bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun ki wọn sì ya orukọ rẹ̀ sí mímọ́, bawo ni wọn yoo ṣe nífẹ̀ẹ́ eniyan ẹlẹgbẹ́ wọn? (1 Johannu 4:20, 21; 5:3) Ayafi bi a bá mú ifẹ padabọ sinu idile araye, bikoṣe bẹẹ nikẹhin ayé yoo di agbegbe ti o kun fun idarudapọ ti àìsíṣọ̀kan, ìwà-ipá ati rúgúdù. O ti rí bẹẹ, ní awọn ibi kan nisinsinyi. Pẹlu ìtànkálẹ̀ ohun-ija alágbára atọmiki laaarin awọn orilẹ-ede, ní ọjọ kan ṣáá awọn eniyan arógunyọ̀ lè pa gbogbo iran eniyan rẹ́ ráúráú. Ṣugbọn eyi jẹ́ ohun kan tí Baba wa onifẹẹ kò ní gbà láàyè lae!—Orin Dafidi 104:5; 119:90; Isaiah 45:18.
BI ỌLỌRUN ṢE YA ORUKỌ RẸ̀ SI MÍMỌ́
14, 15. Ta ni ó mú ipò iwaju nínú yiya orukọ Ọlọrun si mímọ́, bawo sì ni?
14 Ta ni ẹni naa tí ó ń mú ipò iwaju nínú yiya orukọ Ọlọrun si mímọ́? Họwu, Jehofa fúnraarẹ̀ ni! Eyi ni oun ń ṣe nipa gbígbé igbesẹ si ìdáláre awọn ọpa idiwọn ododo rẹ̀. Oun yoo mú idajọ ṣẹ ní kíkún sori gbogbo awọn tí ń ṣàyàgbàǹgbà pé ifẹ-inu rẹ̀ mímọ́ níjà, titi kan awọn tí ń ni awọn eniyan ẹlẹgbẹ́ wọn lára ati awọn tí ń fi eke kọni nipa Ọlọrun. (Orin Dafidi 140:12, 13; Jeremiah 25:29-31) Jehofa kò lè sẹ́ araarẹ̀. Oun ni Ọlọrun tootọ naa, ẹni tí ó lẹ́tọ̀ọ́ si ijọsin tí a yàsọ́tọ̀ gédégbé lati ọ̀dọ̀ gbogbo awọn ẹ̀dá rẹ̀. Oun ni Ọba-aláṣẹ Agbaye, ẹni tí gbogbo ẹ̀dá jẹ ní gbèsè igbọran.—Romu 3:4; Eksodu 34:14; Orin Dafidi 86:9.
15 Ní yiya orukọ rẹ̀ si mímọ́, Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ yoo mú gbogbo eniyan tí ń gbégbèésẹ̀ lọna ìpanirun, ní ilodisi ifẹ-inu rẹ̀ kuro lori ilẹ̀-ayé yii. Eyi jẹ́ nitori pe o koriira ìwà-buburu ó sì nífẹ̀ẹ́ ododo. (Orin Dafidi 11:5-7) Gẹgẹ bi oun fúnraarẹ̀ ti wi: “Emi o gbé araami lékè, emi o sì ya araami sí mímọ́; emi yoo sì di mímọ̀ loju ọpọlọpọ orilẹ-ede, wọn yoo sì mọ̀ pe emi ni [Jehofa, NW].” (Esekieli 38:23) Ní kedere, nigba naa, bi awa bá fẹ́ gbadun itẹwọgba Jehofa, awa pẹlu gbọdọ ya orukọ rẹ̀ si mímọ́, ki a kà á sí mímọ́ ati eyi tí ó yẹ fun ọ̀wọ̀ kíkún, ki a sì maa gbé ní ibamu pẹlu ifẹ-inu rẹ̀.
16. Ipa wo ni ìwà wa ń kó ninu yiya orukọ Ọlọrun si mímọ́?
16 Iwa gbogbo awọn tí ń jọsin Jehofa ń bọla fun orukọ Ọlọrun tabi tàbùkù si i. Ǹjẹ́ ki gbogbo wa dari araawa ní ọna tí yoo mú ki awọn ẹlomiran sọrọ rere nipa Ọlọrun atobilọla tí a ń jọsin, ati ni ọna ti yoo mú ìdùnnú wá bá ọkàn-àyà Jehofa fúnraarẹ̀. (1 Peteru 2:12; Owe 27:11) Gẹgẹ bi awọn ọmọ onigbọran, awa nilati fẹ́ lati fi ọpẹ́ hàn sí Baba wa fun gbogbo awọn ẹ̀bùn rẹ̀, titi kan ile wa ẹlẹwa—ilẹ̀-ayé—eyi tí a ó mu padabọ sinu ògo titobiju paapaa labẹ iṣakoso Ijọba Ọmọkunrin rẹ̀.—Isaiah 6:3; 29:22, 23.
17. Pẹlu iṣarasihuwa wo ni awa nilati fi tọ “Ọba ayeraye” naa lọ ninu adura?
17 Ẹ wo bi o ti fanilọkanmọra tó lati wá sinu ipò ibatan tí o ni itẹwọgba pẹlu “Ọba ayeraye” yii! Bi o ti wu ki o ri, awa kò lè ṣe eyi lori ìtóye awa funraawa, nitori pe a lóyún gbogbo wa lati ọ̀dọ̀ awọn obi ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a sì bí wa ninu àìpé. Ṣugbọn awa lè gbadura si Ọlọrun gẹgẹ bi Ọba Dafidi ti ṣe pe: “Pa oju rẹ mọ́ kuro lara ẹ̀ṣẹ̀ mi, ki iwọ ki o sì nù gbogbo aiṣedeedee mi nù kuro. Dá àyà titun sinu mi, Ọlọrun; ki ó si tún ọkàn diduro-ṣinṣin ṣe sinu mi.” (Orin Dafidi 51:5-10) Bi a ti ń kẹkọọ nipa ohun tí “Baba wa tí ń bẹ ní ọrun” ń beere lọwọ wa, awa lè gbadura fun ṣiṣajọpin ninu awọn ibukun ayeraye tí Ijọba rẹ̀ yoo mú wá. Bẹẹni, pẹlu ìgbọ́kànlé awa lè gbadura pe ki Ijọba Ọlọrun dé. Ki ni Ijọba yẹn yoo tumọsi fun araye níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé? Ẹ jẹ́ ki a wò ó.