Ori 18
Ijọba naa Jagunmólú!
1. (a) Ki ni idi fun níní ìgbọ́kànlé ninu ọjọ-ọla araye? (b) Ki ni Armageddoni yoo tumọsi fun awọn olupa aye run?
A Ó ha pa araye run kuro lori ilẹ̀-ayé yii bi? Ó tì o. Ijọba naa sì ni idi rẹ̀. Nitori pe “Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa,” Jesu tí a ti gbeka ori ìtẹ́, ni yoo gbégbèésẹ̀ nigba ‘dídé’ Ijọba naa lati pa eto-ajọ Satani ti ori ilẹ̀-ayé ati awọn eto-igbekalẹ rẹ̀ tí ń pọ́nnilójú run. Ní Armageddoni, awọn tí yoo jẹ́ olupa ayé run ni a ó ti parun funraawọn.—Ìfihàn 11:15, 18; 14:19, 20; 19:11-16.
2, 3. (a) Ikilọ wo ni asọtẹlẹ Sefaniah pese? (b) Ki ni a ń beere fun lilaaja?
2 Ọlọrun wa, Jehofa, ti kilọ fun wa lati wà lojufo si ohun tí oun fẹ́ ṣe aṣepari rẹ̀ ní Armageddoni.
“Nitori naa ẹ duro dè mi, ni Oluwa wi, titi di ọjọ naa ti emi o dide si ohun-ọdẹ; nitori ipinnu mi ni lati ko awọn orilẹ-ede jọ, ki emi ki o le ko awọn ilẹ̀ ọba jọ, lati da irunu mi si ori wọn, ani gbogbo ibinu mi gbigbona: nitori a o fi iná owú mi jẹ gbogbo ayé run.”
Ṣugbọn awọn olulaaja yoo wà, ọpọlọpọ wọn! Jehofa sì ti ń mura wọn silẹ lọwọlọwọ, gẹgẹ bi awọn ọ̀rọ̀ tí ń mura wọn silẹ lọwọlọwọ, gẹgẹ bi awọn ọ̀rọ̀ tí ó tẹle e wọnyi ninu asọtẹlẹ kan-naa ti wi:
“Nitori n’igba naa ni emi o yi èdè mímọ́ si awọn eniyan, ki gbogbo wọn ki o lè maa kepe orukọ [Jehofa, lati lè maa ṣiṣẹṣin in ni ifẹgbẹkẹgbẹ, NW].”—Sefaniah 3:8, 9.
3 Iwọ yoo ha jẹ́ ọ̀kan lara awọn olulaaja wọnyẹn bi? Bẹẹni, bi iwọ bá “kepe orukọ Jehofa.” Bawo ni iwọ ṣe lè ṣe eyi? Nipa yiyipada si “èdè mímọ́”—gbigba ihinrere Ijọba Ọlọrun tí ń wẹnimọ́ sí ọkàn-àyà rẹ, ati ṣíṣiṣẹ́ lé e lórí. (Marku 13:10) Ní lílò igbagbọ ninu ipese Ọlọrun nipasẹ Kristi, iwọ nilati huwa ní ibamu pẹlu ìṣílétí Peteru si awọn eniyan rẹ̀ ní ọ̀rúndún 19 sẹhin pe: “Nitori naa ẹ ronupiwada, ki ẹ sì tún yipada, ki a lè pa ẹṣẹ yin rẹ́, ki akoko itura baa lè ti iwaju Oluwa wá.”—Iṣe 3:19.
4, 5. (a) Bawo ni iwọ ṣe lè wá gbadun ibatan timọtimọ pẹlu Jehofa? (b) Bawo ni iwọ ṣe lè dahunpada si “ede mímọ́” naa?
4 Gẹgẹ bi Jesu, iwọ nilati fi araarẹ hàn pe iwọ kii ṣe apakan ayé Satani. (Johannu 17:14, 16) Nipa yiya araarẹ si mímọ́ fun Jehofa nipasẹ Kristi kí iwọ sì ṣe baptismu ninu omi ní iṣapẹẹrẹ eyiini, iwọ lè wọ̀ inu ipo-ibatan timọtimọ kan pẹlu Jehofa Ọlọrun. (1 Peteru 3:21) Ibatan timọtimọ yii ni iwọ gbọdọ wá ọ̀nà lati mú dagba nigba gbogbo, bi iwọ ti ń ṣiṣẹsin Ọlọrun “ní ifẹgbẹkẹgbẹ” pẹlu gbogbo awọn eniyan rẹ̀ tí a ṣetojọ lori ilẹ̀-ayé. Bi anfaani rẹ ba ti yọnda to, iwọ yoo fẹ́ lati nípìn-ín papọ pẹlu awọn wọnyi ní sisọ “ihinrere ijọba yii” di mímọ̀ fun gbogbo awọn tí yoo fẹ́ lati fetisilẹ.—Matteu 24:14; Romu 10:10-18; Heberu 13:15.
5 Iwọ ha jẹ́ ẹnikan tí ó tipa bayii dahunpada si “èdè mímọ́” ti otitọ Bibeli bi? Nigba naa gbe gbogbo igbẹkẹle rẹ le Jehofa. “Gẹgẹ bi Ẹni alagbara, oun yoo gbanila.”—Sefaniah 3:17; Isaiah 12:2-5.
6. Imọran rere wo ni Johannu funni, ki ni eyi gbọdọ fun wa ní iṣiri lati ṣe?
6 Bi iwọ ti ń mú ifẹ dagba fun Jehofa ati ododo rẹ̀, iwọ tún nilati gbé ní ibamu pẹlu awọn ilana Bibeli. Aposteli Johannu funni ní imọran rere yii:
“Ẹ maṣe fẹran ayé, tabi ohun ti ń bẹ ninu ayé. Bi ẹnikẹni bá fẹran ayé, ifẹ ti Baba kò sí ninu rẹ̀. Nitori ohun gbogbo ti ń bẹ ni ayé, ifẹkufẹẹ ara, ati ifẹkufẹẹ ojú, ati irera ayé, ki iṣe ti baba bikoṣe ti ayé. Ayé si ń kọja lọ, ati ifẹkufẹẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ṣe ifẹ Ọlọrun ni yoo duro laelae.”—1 Johannu 2:15-17.
“Laelae”! Eyiini kò ha mu ki o jẹ ohun ti o niyelori lati fi itara ṣe ifẹ-inu Ọlọrun ni awọn ọjọ ikẹhin eto-igbekalẹ buruku ti Satani yii bi? Kò ha fun wa ní iṣiri ní “awọn ọjọ ikẹhin” wọnyi lati wà timọtimọ pẹlu eto-ajọ Jehofa, gẹgẹ bi a ti ń ṣoju fun un lori ilẹ̀-ayé nipasẹ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” naa bi?—Matteu 24:45-47, NW.
IṢẸ TAKUNTAKUN KAN
7. Lẹhin Armageddoni, ki ni yoo ṣì wà titilọ?
7 Bi èéfín ogun Armageddoni ti ń kásẹ̀nílẹ̀, eto-ajọ Jehofa tí a lè fojuri yoo ṣì wà níhìn-ín, ni sẹpẹ fun lílò ní ọna eyikeyii tí oun bá fẹ́. Ǹjẹ́ ki a sì kà wa si ẹni yiyẹ, pẹlu, lati wà níhìn-ín ní ẹnikọọkan!—Sefaniah 2:3; Orin Dafidi 25:8, 9, 20.
8. (a) Ki ni a ó nilo nigba naa lati ṣe aṣepari iṣẹ Ọlọrun? (b) Bawo ni yoo ti jẹ pe a ti mura awọn eniyan Ọlọrun silẹ?
8 Awọn eniyan Ọlọrun yoo nilati wà ni iṣetojọ niṣo labẹ akoso Ijọba naa lati lè ṣaṣepari iṣẹ takuntakun ti sisọ ilẹ̀-ayé tí a ti fọ̀ mọ́ tónítóní di ẹlẹwa, ni yíyí agbaye wa pada si “ọgbà Ọlọrun” niti gàsíkíá. (Fiwe Esekieli 31:8.) Iwọ pẹlu ha fẹ́ jẹ́ alabaapin ninu iṣẹ naa bi? Ẹmi tí ó muratan ati okun-inu tí Ọlọrun fi funni ni a ó nilo lati ṣe iṣẹ naa—iru itara kan-naa tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fihan nisinsinyi ní ‘wiwaasu ihinrere ijọba yii ní gbogbo ayé.’ Gbogbo eniyan yoo nilati jẹ́ oṣiṣẹ gidi tí ń tẹle apẹẹrẹ Ọba naa, ẹni tí ó wi pe: “Baba mi ń ṣiṣẹ titi di isinsinyi, emi sì ń ṣiṣẹ.”—Johannu 5:17; 4:34.
9. (a) Iru iṣẹ wo ni yoo wà? (b) Ki ni ó fihan pe eyi ki yoo jẹ́ iṣẹ tí ń súni?
9 Laisi aniani awọn ìwéwèédáwọ́lé ilé-kíkọ́ yoo gbilẹ̀ jakejado ayé—kii ṣe kíkọ́ awọn ilé-gbígbé játijàti tí wọn ṣùjọ ní awọn ilu-nla, ṣugbọn fifi awọn ilé-gbígbé tí a fi awọn ọgbà ẹlẹwa yíká, tí a kọ́ fun awọn idile kún ori ilẹ̀-ayé ninu ayika paradise. Bẹẹni, iṣẹ pupọ yoo wà lati ṣe, ṣugbọn yoo jẹ́ iṣẹ onidunnu, tí ó gbadunmọni, iṣẹ tí ó kún fun èrè-ẹ̀san nipa eyi tí Ọba Solomoni wi pe: “Kò si ohun tí ó dárajù” pe ki “gbogbo eniyan jẹ nitootọ ki ó sì mu ki ó rí rere fun gbogbo iṣẹ aṣekara rẹ̀.”—Oniwasu 3:12, 13, NW; fiwe Isaiah 65:17, 21-25.
10. Ki ni Ìfihàn 21:1-4 fihan niti awọn ipò tí yoo wà nigba naa?
10 Labẹ awọn ipò wo ni “awọn agutan miiran” Oluwa yoo wà nigba tí wọn bá ń ṣiṣẹ wọn? (Johannu 10:16) Ìfihàn ori 21 sọ fun wa nipa ohun tí a lè reti. Ó ṣapejuwe “ọrun titun ati ayé titun” kan. Awọn eto-igbekalẹ ijọba eniyan oníwà-ìbàjẹ́ kò tún ní ṣakoso ẹgbẹ-awujọ mọ́, nitori pe “ọrun ti iṣaaju ati ayé ti iṣaaju” ti kọja lọ. Pẹlupẹlu, Eṣu ati agbara-idari alarekereke rẹ̀ ni a ó ti mú kuro. “Òkun” araye tí a ti dà ríborìbo, tí a ń bì síhìn-ín bì sọ́hùn-ún bi wọn ti ń lepa àìwà-bí-Ọlọrun kò ní sí mọ́. Dipo eyi, ẹgbẹ-awujọ eniyan tí ó duro deedee, “ayé titun” naa, yoo pese ipilẹ tí ó durogbọnyin fun ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun. Nibẹ iwọ lè fi pẹlu iduroṣinṣin tẹle awọn itọsọna “ọrun titun” naa, tí ó jẹ́ Ọba naa ati “iyawo” rẹ̀ tí iye wọn jẹ́ 144,000. Ninu agbara rẹ̀ gẹgẹ bi “ilu mímọ́ nì, Jerusalemu titun,” “iyawo” ọlọ́ba yii yoo ‘sọkalẹ wá lati ọrun’ niti pe yoo dari afiyesi rẹ̀ sori iṣẹ atunṣe tí a ó ṣe lori ilẹ̀-ayé. Ẹ sì wò iyọrisi alayọ tí yoo jẹ́! Gẹgẹ bi Johannu ti rohin:
Kiyesii, àgọ́ Ọlọrun wà pẹlu awọn eniyan, oun yoo sì maa bá wọn gbé, wọn yoo sì maa jẹ́ eniyan rẹ̀, ati Ọlọrun tikaraarẹ̀ yoo wà pẹlu wọn, yoo sì maa jẹ́ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yoo sì nù omije gbogbo nù kuro ní oju wọn; ki yoo sì sí iku mọ́, tabi ọ̀fọ̀, tabi ẹkún, bẹẹ ni ki yoo sí irora mọ́: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.”—Ìfihàn 21:1-4.
11. (a) Ifojusọna titobilọla wo ni ó ń durode araadọta ọkẹ awọn olulaaja? (b) Bawo ni Ọlọrun yoo ṣe fi eniyan kún ilẹ̀-ayé?
11 Ṣakiyesi pe lara ohun tí a ṣeleri ni ifojusọna atobilọla naa wa pe “kò ní sí iku mọ́.” Ireti wà pe araadọta ọkẹ eniyan yoo rí igbala la “ipọnju nla” naa já lati wọ̀ inu awọn ibukun “ayé titun.” (Ìfihàn 7:9, 14) Sibẹ ẹgbẹẹgbẹrun lọna araadọta ọkẹ, ani awọn billion eniyan, ni yoo gbadun ìyè níhìn-ín labẹ Ijọba naa lẹ́hìn-ọ̀-rẹ̀hìn. Eeṣe tí a fi wi pe “awọn billion”? Lẹhin ikun-omi ọjọ Noa, Jehofa fun awọn olulaaja olododo naa ní aṣẹ kan, ní wiwi pe: “Ẹ maa bisii, ẹ sì maa rẹ̀, ki ẹ sì gbilẹ.” Eyi ronúdábàá ifojusọna onidunnu nipa igbeyawo eniyan ati mímú awọn ọmọ jade ninu ododo fun akoko kan, ó keretan, lẹhin Armageddoni. (Genesisi 9:1, 7; 10:1-32; Matteu 24:37) Bi ó ti wù ki ó rí, eyiini kò ní jẹ olori ọna Ọlọrun fun ‘kíkún ilẹ̀-ayé’ pẹlu eniyan ní akoko naa. Bawo, nigba naa, ni Ọlọrun yoo ṣe fi eniyan kún ilẹ̀-ayé wa, ki ó sì tipa bayii ṣaṣepari ete rẹ̀ ip
“ỌLỌRUN . . . LAAYE”
12. Ẹkọ Jesu wo ni ó ṣe awọn ogunlọgọ eniyan ní hàá?
12 Ní akoko-iṣẹlẹ kan, Jesu dá awọn alatako rẹ̀ lóhùn pe:
“Niti ajinde oku, ẹyin kò ti kà eyi tí a sọ fun yin lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, wi pe, Emi ni Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu? Ọlọrun kii ṣe Ọlọrun awọn oku, bikoṣe ti awọn alaaye.”
Ni oju-iwoye Ọlọrun, awọn eniyan oloootọ wọnni dabi ẹni tí ó walaaye, a ó sì jí wọn dide. Háà ṣe awọn ogunlọgọ eniyan naa nipa ẹkọ yẹn.—Matteu 22:31-33; Luku 20:37, 38.
13. Ki ni a lè reti niti “awọn agutan miiran” oloootọ tí wọn ti kú?
13 Ó lọgbọn-ninu lati reti pe irú awọn eniyan oloootọ bẹẹ tí wọn farada inunibini “ki wọn ki ó lè rí ajinde tí ó daraju gbà,” papọ pẹlu awọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́ ninu “awọn agutan miiran” tí wọn lè kú lonii ṣaaju Armageddoni, yoo niriiri didi awọn ti a kọkọ ji dide sinu “ayé titun.” Boya iwọ funraarẹ ti padanu awọn ẹni ọ̀wọ́n ninu iku, àní awọn iranṣẹ Ọlọrun oloootọ. Wò iru idunnu tí yoo jẹ́ lati kí awọn wọnyi káàbọ̀ lati inu ipo-oku, ati lati sọ fun wọn nipa iṣe ìdáláre nla ti Jehofa!—Heberu 11:35.
14. Ireti yiyanilẹnu wo ni a ṣapejuwe rẹ̀ ninu Johannu 5:28, 29 ati Ìfihàn 20:11-13?
14 Bi o ti wu ki o ri, ki ni nipa awọn miiran ninu araye ti wọn ti ku la nǹkan bi 6,000 ọdun itan já? Jesu wi pe: “Ki eyi ki ó maṣe yà yin lẹnu, nitori wakati ń bọ̀ ninu eyi tí gbogbo awọn tí ó wà ní isa-oku yoo gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yoo sì jade wá.” (Johannu 5:28, 29) “Awọn oku, ati ẹni kekere ati ẹni nla,” yoo jade wá lati isa-oku lati duro niwaju ìtẹ́ idajọ Ọlọrun.—Ìfihàn 20:11-13.
15. Eeṣe tí akoko idajọ kò fi ní banilẹru?
15 Eyiini yoo ha jẹ́ akoko bibanilẹru fun awọn tí a jí dide bi? Laika awọn aworan isin nipa Idajọ Ikẹhin si, yoo jẹ́ akoko onidunnu julọ. Nitori pe awọn tí a jí dide wọnni ni a kò ní dajọ fun gẹgẹ bi iṣẹ buburu tí wọn ti ṣe nigba tí ó ti kọja, ṣugbọn, kàkà bẹẹ, yoo jẹ́ ní ibamu pẹlu ifẹ-inu wọn lati gbé ní ibamu pẹlu awọn ohun àbèèrè fún ododo fun ìyè ninu ilẹ-akoso Ijọba Ọlọrun. (Fiwe Romu 6:7.) Gbogbo isapa ni a ó sì ṣe lati ràn wọn lọwọ si ipa-ọna lati ṣe ìlàjà ní kíkún pẹlu Ọlọrun. Itolẹsẹẹsẹ ikọnilẹkọọ titobijulọ ti gbogbo igba ni a ó mú tẹsiwaju labẹ iṣetojọ Ijọba naa.
16. (a) Ki ni “awọn àkájọ-ìwé” naa jẹ́? (b) Eeṣe tí imọ-ẹkọ yoo fi lọ́lá jù ninu “ayé titun”?
16 “Awọn ìwé” ni a ó ṣísílẹ̀. Awọn wọnyi yoo jẹ́ awọn itọni tí a tẹjade lati ṣeranwọ fun awọn eniyan tí a jí dide lati ṣe ‘awọn iṣẹ’ wọnni tí yoo mú ki wọn yẹ fun ìyè ainipẹkun. (Ìfihàn 20:12) Awọn ohun-eelo itolẹsẹẹsẹ ati ikọnilẹkọọ ninu “ayé titun” naa, tí Jehofa ati Messia Ọba rẹ̀ ń darísọ́nà, yoo fi jàn-ànràn jan-anran jinlẹ ní ifiwera ju ohunkohun tí ayé Satani tíì fi funni rí.
AWỌN IBUKUN FUN “OGUNLỌGỌ NLA ENIYAN”
17. Ní lilaaja sinu “ayé titun” naa, ki ni iwọ yoo nilati ṣe?
17 Bi ó ti wù ki ó rí, bi iwọ bá jẹ́ ọ̀kan lara “ogunlọgọ nla eniyan” tí yoo là Armageddoni já, nibo ni iwọ yoo ti baamu ninu aworan yii? Aposteli Paulu wi pe: “Nitori bi gbogbo eniyan ti kú ninu Adamu, bẹẹ ni a ó sì sọ gbogbo eniyan di alaaye ninu Kristi.” (1 Korinti 15:22) Iwọ, pẹlu, yoo nilo anfaani ẹbọ irapada Kristi, eyi tí oun yoo lò lati gbé araye ga si ijẹpipe nigba 1,000 ọdun ijọba rẹ̀. Iwọ, pẹlu, ni yoo pọndandan fun lati mu araarẹ wa larọọwọto fun idanilẹkọọ ti o wa ninu ‘àkájọ ìwé’ ẹlẹgbẹrun ọdun naa, ki o baa lè fi pẹlu iduroṣinṣin ṣe ‘awọn iṣẹ’ tí yoo yọrisi kíkọ tí a ó kọ orukọ rẹ sinu “iwe ìyè.”
18. Itolẹsẹẹsẹ Ijọba wo ni yoo mú akanṣe idunnu wá?
18 Lonii, ọpọlọ eniyan aláìpé tirẹ lagbara lati gbà ki ó sì fi nǹkan pamọ dé kìkì iwọn bín-ín-tín ẹkunrẹrẹ agbara rẹ̀. Boya iwọ ti ṣe sáàfúlà rí pe, ‘Ká ní mo lè ranti ni!’ Ẹ wo bi o ti yẹ ki o dupẹ tó fun ẹbọ Kristi! Nitori pe, gẹgẹ bi apakan ninu itolẹsẹẹsẹ Ijọba naa fun gbígbé araye ga, kii ṣe kìkì pe awọn irora ati ki ara maa dunni yoo di àwátì nikan ni ṣugbọn pe iṣẹda yiyanilẹnu yẹn—ero-inu eniyan tirẹ—ni a ó sọ di pípé fun kikẹkọọ ati riranti isọfunni, ríronú lori rẹ̀ ati, lékè gbogbo rẹ̀, nini imọriri ọlọ́wọ̀ jijinlẹ fun awọn animọ titobilọla ti Ọlọrun wa, Jehofa. Awọn idena tí ede ń mú wá, eyi tí ó jẹyọ lati inu idarudapọ ede nibi ile-iṣọ Babeli, ni a ó mú kuro, a ó sì kọ́ gbogbo araye ní ede kanṣoṣo ki wọn baa lè ṣiṣẹsin Jehofa papọ ní iṣọkan, gẹgẹ bi a ti dábàá ninu Sefaniah 3:9.
19. Ninu idunnu wo ni awọn ọmọ-abẹ Ijọba yoo ṣajọpin?
19 Ọkàn-àyà eniyan pípé, pẹlu, ni a ó súnṣiṣẹ́ nipasẹ ifẹ fun Ọlọrun ati aladuugbo. Abajọ tí Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ fi dari awọn ọ̀rọ̀ wọnyi si awọn eniyan rẹ̀ onimọriri pe:
“Sá wò ó, emi dá awọn ọrun titun ati ayé titun: a ki yoo sì ranti awọn ti iṣaaju, bẹẹ ni wọn ki yoo wá sí àyà. Ṣugbọn ki ẹyin ki ó yọ̀, ki inu yin ki ó sì dùn titilae ninu eyi tí emi dá: nitori kiyesii, emi dá Jerusalemu [Titun] ní inudidun, ati awọn eniyan rẹ̀ ní ayọ. Emi yoo sì ṣe àríyá ní Jerusalemu, emi yoo sì yọ̀ ninu awọn eniyan mi: a ki yoo sì tún gbọ́ ohùn ẹkún mọ́ ninu rẹ̀, tabi ohùn igbe.” (Isaiah 65:17-19)
Idunnu ati ayọ aṣeyọri rírànyòò ti awọn 144,000 alajumọ ṣakoso pẹlu Kristi ninu Ijọba rẹ̀ ni a ó fihàn lara awọn billion awọn ọmọ-abẹ Ijọba naa lori ilẹ̀ayé bi awọn wọnyi ti ń tẹsiwaju sí ìjẹ́pípé eniyan.
A YA ORUKỌ JEHOFA SI MÍMỌ́ TITILAE
20. (a) Eese tí 1,000 ọdun naa yoo fi kọja lọ kánkán? (b) Bawo ni Dafidi ṣe bukun Jehofa? (c) A ha sún ọ lati sọ iru isọjade ọ̀rọ̀ ìyìn ti o farajọ eyi bi?
20 Ẹgbẹrun ọdun yoo kọja, gan-an gẹgẹ bi ọjọ kan loju Jehofa, ẹ sì wò bi yoo ti dabi akoko ráńpẹ́ kan fun iran eniyan pẹlu, tí ọwọ́ wọn dí tobẹẹ fun awọn iṣẹ atunṣe! (2 Peteru 3:8) Awa lè fojusọna, pẹlu, pe akoko itura yoo wà fun ikẹgbẹpọ alayọ ati eré-idaraya onilera, igbadun ohùn-orin ati awọn iṣẹ́-ọnà ti o niyelori miiran, ati awọn iṣeto fun ijọsin Ẹlẹ́dàá Atobilọla wa nigba gbogbo. Gbogbo eniyan ni yoo fẹ́ lati bukun Jehofa gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe ní ṣiṣeto fun ijọsin ninu tẹmpili, nigba tí ó wi pe:
“Tirẹ, Oluwa, ni titobi, ati agbara, ati ògo, ati iṣẹgun, ati ọláńlá: nitori ohun gbogbo ní ọrun ati ní ayé tirẹ ni; ijọba ni tirẹ, Oluwa, a sì gbé ọ lékè ní ori fun ohun gbogbo. Ọrọ̀ ati ọlá ọ̀dọ̀ rẹ ni ó ti ń wá, iwọ sì jọba lori ohun gbogbo; ní ọwọ́ rẹ ni agbara ati ipá wà; ati ní ọwọ́ rẹ ni sisọnidi nla wà, ati fifi agbara fun ohun gbogbo. Ǹjẹ́ nisinsinyi, Ọlọrun wa, awa dupẹ lọwọ rẹ, a sì yìn orukọ ògo rẹ.”—1 Kronika 29:11-13.
21. (a) Bawo ni Kristi yoo ṣe kádìí iṣakoso ẹlẹgbẹrun ọdun rẹ̀? (b) Ki ni Ijọba naa yoo ti ṣe aṣepari rẹ̀?
21 Ní ibamu pẹlu isọjade ìyìn titobilọla yii, Ẹni naa tí ó tobiju Dafidi lọ, Kristi Jesu, yoo pari iṣakoso ẹlẹgbẹrun ọdun alalaafia ati alatunṣe rẹ̀ nipa ṣiṣe ohun tí aposteli Paulu sọtẹlẹ pe:
“Nigba naa ni opin yoo dé, nigba tí ó bá ti fi ijọba fun Ọlọrun àní Baba; nigba tí ó bá ti mú gbogbo aṣẹ ati gbogbo ọlá ati agbara [tí ń ṣatako] kuro.”
Lẹẹkan ati titilae, iṣakoso Ọlọrun ni a ó ti fihan gẹgẹ bi ijọba naa tí ó tọ́, tí ó lagbara títótẹ́rùn lati mú anfaani pipẹtiti wá fun awọn olujọsin Jehofa. Labẹ iṣakoso onifẹrere ti Ijọba naa, a ó ti mú iku ti Adamu ṣokunfa rẹ̀ kuro, tí a ó sì ti sọ gbogbo araye di alaaye “ninu Kristi.” Nipa bayii, awọn billion tí yoo walaaye nigba naa lori ilẹ̀-ayé ni a ó ti “sọ di ominira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si ominira ògo awọn ọmọ Ọlọrun.”—Romu 8:21; 1 Korinti 15:22-28.
22. (a) Akoko idanwo kukuru wo ni yoo tẹle e? (b) Iṣẹ ìdáláre ikẹhin wo ni Jesu yoo múṣe?
22 Fun akoko kukuru kan, a ó tú Satani silẹ kuro ninu ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, lati dán ayé araye tí a ti sọ di pípé wò niti iduroṣinṣin rẹ̀ si ipo-ọba Jehofa. Iye kan tí a kò mọ̀ ní pàtó lè yàn lati tẹle Eṣu, ṣugbọn a ó mú idajọ ṣẹ sori wọn ní wàrà-ǹwéré. “Iru-ọmọ” “obinrin” Ọlọrun naa, Kristi Jesu, yoo ṣe iṣẹ ìdáláre rẹ̀ ikẹhin nipa fífọ́ ori Ejo laelae nì, pipa oun ati awọn iru-ọmọ rẹ̀ run patapata gẹgẹ bi nipasẹ iná tí ń jó “ní ọ̀sán ati ní òru lae ati laelae.” Ọran ariyanjiyan nla naa tí a gbé dide ní Edeni niti ipò ọba-aláṣẹ ti ó jẹ ẹ̀tọ́ Jehofa lori awọn ẹda rẹ̀ ni a ó ti dajọ rẹ̀ tí a ó sì ti yanju titilae!—Ìfihàn 20:7-10; Genesisi 3:15.
23. (a) Ríronúsíwá-sẹ́hìn lori awọn ileri Ọlọrun yẹ ki ó mú wa ṣe ki ni? (b) Eeṣe tí ó fi yẹ ki a fẹ́ lati ríi ‘kí ijọba Ọlọrun dé’?
23 Nigba tí a bá ronúsíwá-sẹ́hìn lori awọn ileri agbayanu “Ọba ayeraye” naa, Ẹlẹ́dàá Atobilọla wa, Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ, a kò ha sún wa ninu ọpẹ́ lati yìn orukọ rẹ̀ bi? A kò ha sún wa, gẹgẹ bi a ti sún awọn kan ní ọjọ Pentekosti, lati sọrọ nipa “iṣẹ-iyanu nla Ọlọrun,” nipa “Ọba awọn ọba” rẹ̀ ati Ijọba Messia naa bi? (Iṣe 2:11; Ìfihàn 15:3; 19:16) A kò ha sún wa lati gbadura si Baba wa ọrun pe, “JẸ́ KÍ IJỌBA RẸ DÉ”? (Matteu 6:9, 10, NW) Bẹẹni, “DÉ,” lati wá pa awọn iṣẹ Satani ati eto-ajọ rẹ̀ run kuro lori ilẹ̀-ayé! Bẹẹni, “DÉ,” lati wa pese ijọba ti o tọ́ fun gbogbo araye! Bẹẹni, “DÉ,” lati mú ijọba ẹlẹgbẹrun ọdun ológo wá fun imupadabọsipo paradise, jíjí awọn oku dide ati gbígbé gbogbo eniyan tí wọn fẹ́ bẹẹ ga si ijẹpipe eniyan! Bẹẹni, “DÉ,” ki orukọ Jehofa alailẹgbẹ lè di eyi tí a yasimimọ titilae fáàbàdà!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 180, 181]
Ninu ayé titun, awọn ọmọ tí a tọ́ dagba ninu ododo kò ní ní iriri eyikeyii lara awọn iṣoro tí ń yọ awọn idile lẹnu lonii