ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • sp ojú ìwé 23-27
  • Ṣiṣẹsin Jehofa, Kii Ṣe Satani

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣiṣẹsin Jehofa, Kii Ṣe Satani
  • Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jehofa Dara
  • Yẹra Fun Awọn Iṣe Aimọ
  • Sọ Ijọsin Tootọ Dàṣà
  • Darapọ Pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa
  • Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Jáwọ́ Nínú Ìsìn Èké; Máa Ṣe Ìsìn Tòótọ́
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Ohun Tó Yẹ Ká Mọ̀ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Agbára Jésù Ju Ti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lọ
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Àwọn Míì
Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?
sp ojú ìwé 23-27

Ṣiṣẹsin Jehofa, Kii Ṣe Satani

Gbogbo wa ní yíyàn kan. Yala ki a ṣiṣẹsin Jehofa tabi ki a ṣiṣẹsin Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀. Awa kò lè ṣe mejeeji. Ẹ wo bi o ti bọgbọnmu to lati ṣiṣẹsin Jehofa!

Jehofa Dara

Gẹgẹ bi a ti rí i, awọn ẹmi-eṣu gbadun ṣiṣe ipalara ati titan awọn eniyan jẹ. Jehofa kò ri bẹẹ rara. O nifẹẹ araye gẹgẹ bi baba ti nifẹẹ awọn ọmọ rẹ̀. Oun jẹ Olùfunni ni “ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pipe.” (Jakọbu 1:17) Oun kò fawọ ohunkohun ti o dara sẹhin kuro lọdọ araye, ani bi o tilẹ ná-an ni ohun pupọ gan-an paapaa.—Efesu 2:4-7.

Jésù fi ìfẹ́ hàn sí àwọn èèyàn bó ṣe la ojú afọ́jú, tó jẹ́ kí odi sọ̀rọ̀, tó sì jí òkú dìde

Jesu, Ọmọkunrin Ọlọrun, fi ifẹ hàn fun awọn eniyan nipa mimu wọn larada

Ronu nipa awọn nnkan ti Jesu Ọmọkunrin Ọlọrun ṣe lori ilẹ-aye. Oun mu ki awọn ẹni ti o yadi sọrọ ó sì pese iriran fun awọn afọju. O wo awọn adẹ́tẹ̀ sàn ati awọn arọ eniyan. O le awọn ẹmi-eṣu jade o sì wo oniruuru awọn aisan sàn. Jesu, nipasẹ agbara Ọlọrun, tilẹ ji awọn oku dide si iye paapaa.—Matiu 9:32-35; 15:30, 31; Luuku 7:11-15.

Kaka ki o purọ lati ṣì wa lọna, Ọlọrun maa nsọ otitọ nigbagbogbo. Oun kò tan ẹnikẹni jẹ ri.—Numeri 23:19.

Yẹra Fun Awọn Iṣe Aimọ

Gan-an gẹgẹ bi okùn aláǹtakùn ti nmu kokoro, ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan wà labẹ ìdè igbagbọ ninu ohun asan ati eke. Wọn bẹru awọn oku. Wọn bẹru awọn ẹmi-eṣu. Wọn ndaamu nipa awọn ègún, awọn àmì, awọn oògùn, ati awọn agbara awo. Wọn wa labẹ ìdè awọn igbagbọ ati àṣà ti a gbe kari awọn irọ́ Satani Eṣu. Awọn iranṣẹ Ọlọrun ni a kò dẹkunmu nipasẹ eyikeyii ninu awọn nnkan wọnyi.

Jehofa lagbara pupọpupọ ju Satani lọ. Bi iwọ ba nṣiṣẹsin Jehofa, oun yoo daabobo ọ kuro lọwọ awọn ẹmi-eṣu. (Jakọbu 4:7) Awọn èèdì ki yoo le mu ọ. Fun apẹẹrẹ, ni Nigeria, awọn ògbóǹkangí adáhunṣe mẹta kan fi èèdì mú Ẹlẹ́rìí Jehofa kan lati pa á nitori pe o kọ̀ lati fi ilu silẹ. Nigba ti èèdì naa kuna, ẹ̀rù ba ọkan ninu awọn adáhunṣe naa, o lọ sọdọ Ẹlẹ́rìí naa, o sì bẹbẹ fun aanu.

Awọn ara Efesu sun awọn iwe idán wọn

Awọn ara Efesu sun awọn iwe idán wọn

Bi awọn ẹmi-eṣu ba gbejako ọ, iwọ lè ke pe orukọ Jehofa oun yoo sì daabobo ọ. (Owe 18:10) Ṣugbọn ki iwọ baa le ni aabo Ọlọrun, o nilati ja araàrẹ gbà patapata kuro lọwọ ibaṣepọ eyikeyii ti o niiṣe pẹlu ibẹmiilo ati ijọsin ẹmi-eṣu. Awọn olujọsin Ọlọrun ni Efesu igbaani ṣe bẹẹ. Wọn kó gbogbo iwe wọn lori idán jọ wọn sì sun wọn níná. (Iṣe 19:19, 20) Awọn iranṣẹ Ọlọrun lonii gbọdọ ṣe ohun kan naa. Gba ara rẹ lọwọ oògùn, ìgbàdí, awọn okùn “aabo,” agbara awo, awọn ìwé idán, ati ohunkohun ti o nii ṣe pẹlu àṣà ibẹmiilo.

Sọ Ijọsin Tootọ Dàṣà

Bi iwọ ba fẹ lati wu Ọlọrun, kò tó lati wulẹ fi ijọsin eke silẹ ki o sì dawọ ṣiṣe awọn ohun ti o buru duro. Iwọ gbọdọ fi taratara sọ ijọsin mimọgaara dàṣà. Bibeli fi ohun ti o nilo hàn:

Ìjọsìn tòótọ́ ní nínú kí èèyàn máa wá sí ìpàdé, kó sì máa ka Bíbélì

Pésẹ̀ si awọn ipade Kristẹni.—Heberu 10:24, 25

Kẹkọọ Bibeli.—Johanu 17:3

Ìjọsìn tòótọ́ ní nínú kí èèyàn máa wàásù fún àwọn míì, kó máa gbàdúrà sí Jèhófà, kó sì ṣèrìbọmi

Waasu fun awọn ẹlomiran.—Matiu 24:14

Gbadura si Jehofa.—Filipi 4:6, 7

Ṣe baptism.—Iṣe 2:41

Darapọ Pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa

Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ ní awọn eniyan lori ilẹ-aye ti nkọni ti wọn sì nṣe awọn ohun ti kò tọna. Ṣugbọn Jehofa ni awọn eniyan pẹlu. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. (Aisaya 43:10) Eyi ti o ju million mẹrin awọn Ẹlẹ́rìí ni o wa jakejado ilẹ-aye. Gbogbo wọn ngbiyanju lati ṣe ohun ti o dara ati lati kọ awọn eniyan ni otitọ. Ni ọpọlọpọ ilẹ, iwọ le pade wọn ni Gbọngan Ijọba, nibi ti wọn yoo ti fi tọyayatọyaya ki ọ kaabọ.

Iṣẹ wọn ni lati ran awọn eniyan lọwọ lati ṣiṣẹsin Ọlọrun. Wọn yoo kẹkọọ Bibeli pẹlu rẹ ninu ile rẹ, ni riran ọ lọwọ lati kẹkọọ bi iwọ ṣe le ṣiṣẹsin Jehofa ni ọna ti o tọ. Iwọ kò nilati sanwo fun eyi. Awọn Ẹlẹ́rìí layọ lati kọni ni otitọ nitori pe wọn nifẹẹ awọn eniyan wọn sì nifẹẹ Jehofa Ọlọrun.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kí àwọn èèyàn káàbọ̀ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì

Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo ran ọ lọwọ lati ṣiṣẹsin Ọlọrun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́