Apa 8
Ete Ọlọrun Ń Sún Síhà Imuṣẹ
1, 2. Bawo ni Ọlọrun ti ṣe ń ṣe ipese lati mu ijiya kuro?
IṢAKOSO ti awọn ọlọ̀tẹ̀ eniyan ati ti awọn ẹmi eṣu ti ń fa idile eniyan sisalẹ fun ọpọlọpọ ọrundun. Sibẹ, Ọlọrun kò tíì ṣaika awọn ijiya wa si. Kàkà bẹẹ, ninu gbogbo awọn ọrundun, oun ti ń ṣe ipese lati tú awọn eniyan silẹ kuro lọwọ ìdìmú iwa buburu ati ijiya.
2 Nigba ìṣọ̀tẹ̀ ni Edeni, Ọlọrun bẹrẹ sii ń ṣipaya awọn ete rẹ̀ lati gbe ijọba kan kalẹ ti yoo sọ ilẹ̀-ayé yii di paradise ibugbe fun awọn eniyan. (Genesisi 3:15) Lẹhin naa, gẹgẹ bi olori agbẹnusọ fun Ọlọrun, Jesu sọ ijọba Ọlọrun ti ń bọ̀ yii di ẹṣin-ọ̀rọ̀ ikọnilẹkọọ rẹ̀. O sọ pe oun ni yoo jẹ ireti kanṣoṣo fun araye.—Danieli 2:44; Matteu 6:9, 10; 12:21.
3. Ki ni Jesu pe ijọba ti ń bọ lọna naa fun ilẹ̀-ayé, eesitiṣe?
3 Jesu pe ijọba Ọlọrun ti ń bọ̀ naa ni “ijọba ọrun,” niwọn bi yoo ti ṣakoso latọrunwa. (Matteu 4:17) O tun pe e ni “ijọba Ọlọrun,” niwọn bi Ọlọrun yoo ti jẹ Oludasilẹ rẹ̀. (Luku 17:20) La awọn ọrundun kọja Ọlọrun misi awọn akọwe rẹ̀ lati ṣakọsilẹ awọn asọtẹlẹ nipa awọn ti yoo parapọ jẹ ijọba naa ati ohun ti yoo ṣaṣepari rẹ̀.
Ọba Titun ti Ilẹ̀-Ayé
4, 5. Bawo ni Ọlọrun ṣe fihan pe Jesu ni Ọba rẹ̀ ti oun fọwọsi?
4 Jesu ni ẹni ti, ni ohun ti o fẹrẹẹ to ẹgbẹrun ọdun meji sẹhin, o mu ọpọlọpọ asọtẹlẹ nipa ẹni naa ti yoo jẹ́ Ọba Ijọba Ọlọrun ṣẹ. Oun ni o wá jẹ ààyò Ọlọrun fun Oluṣakoso ijọba ọrun yẹn lori araye. Lẹhin iku rẹ̀, Ọlọrun jí Jesu dide si iwalaaye ni ọrun gẹgẹ bi ẹda ẹmi alaileeku, alagbara kan. Ọpọlọpọ awọn ẹlẹ́rìí si ajinde rẹ̀ ni wọn wà.—Iṣe 4:10; 9:1-9; Romu 1:1-4; 1 Korinti 15:3-8.
5 Jesu nigba naa wá “jokoo ni ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.” (Heberu 10:12) Nibẹ ni o ti ń duro de ìgbà ti Ọlọrun yoo fun un ni agbara lati gbe igbesẹ gẹgẹ bi Ọba Ijọba Ọlọrun ti ọrun. Eyi mu asọtẹlẹ Orin Dafidi 110:1 ṣẹ, nibi ti Ọlọrun ti sọ fun un pe: “Jokoo ni ọwọ́ ọ̀tún mi, titi emi o fi sọ awọn ọta rẹ di apoti-itisẹ rẹ.”
6. Bawo ni Jesu ṣe fihan pe oun tootun lati jẹ Ọba Ijọba Ọlọrun?
6 Ni ìgbà ti o wà lori ilẹ̀-ayé, Jesu fihan pe oun tootun fun iru ipo bẹẹ. Laika inunibini si, o yàn lati pa iwatitọ rẹ̀ si Ọlọrun mọ. Nipa ṣiṣe bẹẹ, oun fihan pe irọ́ ni Satani pa nigba ti o sọ pe kò si eniyan ti yoo jẹ oluṣotitọ si Ọlọrun labẹ idanwo. Jesu, ọkunrin pipe kan, ‘Adamu ikeji,’ fihan pe Ọlọrun kò ṣe aṣiṣe ni dida awọn eniyan pipe.—1 Korinti 15:22, 45; Matteu 4:1-11.
7, 8. Awọn ohun rere wo ni Jesu ṣe nigba ti o wà nihin in lori ilẹ̀-ayé, ki sì ni oun ṣaṣefihan rẹ̀?
7 Ọba wo ni o tíì ṣaṣeyọri iṣẹ rere pupọ to bi Jesu ti ṣe ni iwọnba ọdun melookan ti iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀? Bi ẹmi Ọlọrun ti fun un ni agbara, Jesu mu alaisan, arọ, afọju, aditi, odi larada. O tilẹ ji oku dide! O ṣaṣefihan ni iwọn ranpẹ ohun ti oun yoo ṣe fun araye ni iwọn ti o kárí-ayé nigba ti oun bá gba agbara Ijọba.—Matteu 15:30, 31; Luku 7:11-16.
8 Jesu ṣe ọpọlọpọ iṣẹ rere nigba ti o wà nihin in lori ilẹ̀-ayé tobẹẹ gẹẹ ti ọmọ-ẹhin rẹ̀ Johannu fi wi pe: “Ọpọlọpọ ohun miiran pẹlu ni Jesu ṣe, eyi ti bi a bá kọwe wọn ni ọkọọkan, mo rò pe ayé paapaa kò lè gba iwe naa ti a bá kọ.”—Johannu 21:25.a
9. Eeṣe ti awọn eniyan olotiitọ-ọkan fi wọ tọ Jesu lọ?
9 Jesu jẹ oninuure ati oniyọọnu, ti o ni ifẹ ńláǹlà fun awọn eniyan. O ṣeranlọwọ fun awọn talaka ati awọn ti a tẹloriba, ṣugbọn oun kò pààlà iyatọ ni ilodisi awọn ọlọrọ tabi onipo giga. Awọn eniyan olotiitọ-ọkan dahunpada si ikesini onifẹẹ ti Jesu nigba ti o wi pe: “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹyin ti ń ṣiṣẹẹ, ti a si di ẹru wuwo le lori, emi o si fi isimi fun yin. Ẹ gba ajaga mi si ọrùn yin, ki ẹ si maa kọ́ ẹkọ́ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan ni emi; ẹyin o si ri isimi fun ọkan yin. Nitori ajaga mi rọrun, ẹrù mi si fuyẹ.” (Matteu 11:28-30) Awọn eniyan olubẹru-Ọlọrun wọ́ tọ ọ tí wọn si wọna fun iṣakoso rẹ̀.—Johannu 12:19.
Awọn Alajumọ-Ṣakoso
10, 11. Ta ni yoo nipin-in pẹlu Jesu ninu ṣiṣakoso lori ilẹ̀-ayé?
10 Gan an gẹgẹ bi awọn ijọba eniyan ti ní awọn oludari alajumọ-ṣakoso, bẹẹ naa ni Ijọba Ọlọrun ti ọrun ní. Awọn ẹlomiran yatọ si Jesu yoo ni ipin ninu ṣiṣakoso lori ilẹ̀-ayé, nitori Jesu ṣeleri fun awọn alabaakẹgbẹpọ timọtimọ rẹ̀ pe wọn yoo ṣakoso pẹlu oun gẹgẹ bi awọn ọba lori araye.—Johannu 14:2, 3; Ìfihàn 5:10; 20:6.
11 Nipa bayii, papọ pẹlu Jesu, a jí iwọnba kereje awọn eniyan dide bakan naa si iwalaaye ti ọrun. Wọn parapọ di Ijọba Ọlọrun ti yoo mu awọn ibukun ayeraye wa fun araye. (2 Korinti 4:14; Ìfihàn 14:1-3) Nitori naa jalẹ atọdunmọdun, Jehofa ti ṣe imurasilẹ fun iṣakoso ti yoo mu awọn ibukun ainipẹkun wá fun idile eniyan.
Akoso Olominira Yoo Dopin
12, 13. Ki ni Ijọba Ọlọrun ti wà ni sẹpẹ́ nisinsinyi lati ṣe?
12 Ninu ọrundun yii Ọlọrun ti lọwọ ni taarata ninu awọn àlámọ̀rí ilẹ̀-ayé. Bi Apa 9 ninu iwe pẹlẹbẹ yii yoo ti jiroro rẹ̀, asọtẹlẹ Bibeli fihan pe Ijọba Ọlọrun labẹ Kristi ni a ti fidi rẹ̀ mulẹ ni ọdun 1914 o si ti wà ni sẹpẹ́ nisinsinyi lati tẹ gbogbo eto-igbekalẹ Satani ni àtẹ̀rẹ́. Ijọba yẹn ti ṣetan lati lọ maa “jọba laaarin awọn ọta [Kristi].”—Orin Dafidi 110:2.
13 Nipa eyi asọtẹlẹ inu Danieli 2:44 sọ pe: “Ni ọjọ awọn ọba wọnyẹn [ti wọn wà nisinsinyi] ni Ọlọrun ọrun yoo gbe ijọba kan kalẹ [ni ọrun] eyi ti a ki yoo parun laelae, a ki yoo si fi ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀ le awọn eniyan miiran lọwọ [a ki yoo tun gba iṣakoso eniyan láàyè mọ lae]. Oun [Ijọba Ọlọrun] yoo fọ́ gbogbo ijọba wọnyii tuutu yoo si mu wọn wá si opin, oun yoo si duro titi lae.”—Revised Standard Version.
14. Awọn anfaani diẹ wo ni yoo wá nitori opin ti o deba iṣakoso eniyan?
14 Pẹlu imukuro lọna ti gbogbo iṣakoso ti kò gbarale Ọlorun, iṣakoso Ijọba Ọlọrun lori gbogbo ilẹ̀-ayé yoo jẹ patapata. Ati nitori pe Ijọba naa ń ṣakoso latọrunwa, awọn eniyan kò lè sọ ọ dibajẹ lae. Agbara iṣakoso yoo wà ni ibi ti o wà ni akọkọ pàá, ni ọrun, pẹlu Ọlọrun. Ati niwọn bi akoso Ọlọrun yoo ti ṣakoso gbogbo ilẹ̀-ayé, awọn isin eke tabi awọn àbá ero-ori ati awọn imọ-ọran iṣelu ti kò tẹnilọrun kò tun ni ṣi ẹnikẹni lọna mọ. Kò si eyikeyii lara awọn nǹkan wọnyẹn ti a o tun gbà láàyè lati wà mọ.—Matteu 7:15-23; Ìfihàn, ori 17 titi de 19.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun isọfunni kikun nipa igbesi-aye Jesu, wo iwe naa Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, ti a tẹjade ni 1991 lati ọwọ Watchtower Society.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Nigba ti o wà lori ilẹ̀-ayé Jesu mu awọn alaisan larada o si jí awọn oku dide lati fi ohun ti oun yoo ṣe ninu aye titun han
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ijọba Ọlọrun ti ọrun yoo tẹ gbogbo oniruuru akoso ti kò gbara le e ni àtẹ̀rẹ́