ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • T-19 ojú ìwé 2-6
  • Ayé Yìí Yóò Ha Là á Já Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayé Yìí Yóò Ha Là á Já Bí?
  • Ayé Yìí Yóò Ha Là Á Já Bí?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ayé Kan Dópin—Òmíràn Rọ́pò Rẹ̀
  • Ọjọ́ Ọ̀la Ayé Yìí
  • ‘Àmì’ Náà
  • Omi Pa Ayé Kan Run—Ǹjẹ́ Irú Ẹ̀ Tún Lè Ṣẹlẹ̀ Mọ́?
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Àkókò Yìí Gan-an Ló Yẹ Ká Máa Ṣọ́nà Ju Ti Tẹ́lẹ̀ Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ṣé Òpin Ayé Ti Sún Mọ́lé?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Aye Titun Kan Ti Sunmọle!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ayé Yìí Yóò Ha Là Á Já Bí?
T-19 ojú ìwé 2-6

Ayé Yìí Yóò Ha Là á Já Bí?

Kò sí ìran mìíràn tó tíì gbọ́ ọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa òpin ayé tó báyìí rí. Ọ̀pọ̀ ń bẹ̀rù pé ìpakúpa ogun átọ́míìkì ni yóò fòpin sí ayé yìí. Àwọn mìíràn rò pé ó ṣeé ṣe kí ìbàyíkájẹ́ pa ayé run. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mìíràn ń dààmú pé yánpọnyánrin ọrọ̀ ajé ló máa sún àwùjọ ènìyàn láti gbéjà ko ara wọn.

Ṣé ayé yìí lè dópin lóòótọ́? Bó bá dópin, kí ni yóò túmọ̀ sí? Ǹjẹ́ ayé kankan tíì dópin rí?

Ayé Kan Dópin—Òmíràn Rọ́pò Rẹ̀

Bẹ́ẹ̀ ni, ayé kan dópin rí lóòótọ́. Gbé ayé tó di èyí tó burú gan-an lọ́jọ́ Nóà yẹ̀ wò. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.” Bíbélì tún sọ pé: “[Ọlọ́run] kò sì fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ ayé ìgbàanì, ṣùgbọ́n ó pa Nóà, oníwàásù òdodo mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 2:5; 3:6.

Ṣàkíyèsí ohun tí òpin ayé yẹn túmọ̀ sí àti ohun tí kò túmọ̀ sí. Kò túmọ̀ sí òpin ìran ènìyàn. Nóà àti ìdílé rẹ̀ la Ìkún Omi kárí ayé náà já. Ilẹ̀ Ayé àti ọ̀run ẹlẹ́wà tó kún fún àwọn ìràwọ̀ là á já bákan náà. “Ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run,” ìyẹn ètò àwọn nǹkan burúkú, ló pa run.

Nígbà tó yá, bí àwọn àtọmọdọ́mọ Nóà ṣe ń pọ̀ sí i, ayé mìíràn tún gbèrú. Ayé kejì yẹn, tàbí ètò àwọn nǹkan yẹn, ló wà títí dọjọ́ tiwa yìí. Ogun, ìwà ọ̀daràn, àti ìwà ipá ló sì kún inú ìtàn rẹ̀. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ayé yìí? Ṣé yóò là á já?

Ọjọ́ Ọ̀la Ayé Yìí

Lẹ́yìn tí Bíbélì sọ pé ayé Nóà pa run, àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Nípa ọ̀rọ̀ kan náà, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná.” (2 Pétérù 3:7) Ní tòótọ́, bí òǹkọ̀wé Bíbélì mìíràn ṣe ṣàlàyé: “Ayé [èyí tó wà lónìí] ń kọjá lọ.”—1 Jòhánù 2:17.

Ohun tí Bíbélì ń sọ kọ́ ni pé ilẹ̀yílẹ̀ tàbí ọ̀run tó kún fún àwọn ìràwọ̀ yóò kọjá lọ, àní gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀nyí kò ti kọjá lọ lọ́jọ́ Nóà. (Sáàmù 104:5) Kàkà bẹ́ẹ̀, ayé yìí, tòun ti “àwọn ọ̀run” rẹ̀, tàbí àwọn alákòóso tí ń ṣèjọba lábẹ́ ìdarí Sátánì, àti “ayé” rẹ̀, tàbí àwùjọ ènìyàn, ni a óò pa run bíi pé nípasẹ̀ iná. (Jòhánù 14:30; 2 Kọ́ríńtì 4:4) Ó dájú pé ayé yìí, tàbí ètò àwọn nǹkan yìí, yóò pa run gan-an gẹ́gẹ́ bí ayé tó wà ṣáájú Ìkún Omi ṣe pa run. Jésù Kristi pàápàá sọ nípa bí ipò àwọn nǹkan ṣe rí ní “àwọn ọjọ́ Nóà” pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ kété ṣáájú òpin ayé yìí.—Mátíù 24:37-39.

Ní pàtàkì, nìgbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọjọ́ Nóà ńṣe ló ń dáhùn ìbéèrè tí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ béèrè pé: “Kini yio si ṣe àmi wíwa rẹ, ati ti opin aiye?” (Mátíù 24:3, Bíbélì Mímọ́) Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ̀ pé ayé yìí yóò dópin. Ǹjẹ́ ìrètí pé èyí máa ṣẹlẹ̀ kó ìpayà bá wọn?

Dípò kí ìyẹn ṣẹlẹ̀, nígbà tí Jésù ń ṣàpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò ṣẹlẹ̀ ṣááju òpin ayé yìí, ó fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n yọ̀ ‘nítorí pé ìdáǹdè wọn ń sún mọ́lé.’ (Lúùkù 21:28) Bẹ́ẹ̀ ni, ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Sátánì àti ètò àwọn nǹkan burúkú rẹ̀, bọ́ sínú ayé tuntun alálàáfíà!—2 Pétérù 3:13.

Ṣùgbọ́n ìgbà wo ni ayé yìí yóò dópin? ‘Àmì’ wo ni Jésù fúnni nípa ‘wíwa rẹ̀ ati ti opin aiye’?

‘Àmì’ Náà

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí ‘wíwá’ níhìn-ín ni pa·rou·siʹa, ó sì túmọ̀ sí “wíwà níhìn-ín,” ìyẹn ni, wíwà lárọ̀ọ́wọ́tó ní ti gidi. Nítorí náà, nígbà tí a bá rí ‘àmì’ náà, kò ní túmọ̀ sí pé Kristi yóò dé láìpẹ́, ṣùgbọ́n pé ó ti padà wá, ó sì ti wà níhìn-ín. Yóò túmọ̀ sí pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso láìṣeéfojúrí gẹ́gẹ́ bí ọba ọ̀run àti pé yóò fòpin sí àwọn ọ̀tá rẹ̀ láìpẹ́.—Ìṣípayá 12:7-12; Sáàmù 110:1, 2.

Ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣoṣo péré kọ́ ni Jésù fi fúnni gẹ́gẹ́ bí ‘àmì.’ Ó ṣàpèjúwe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àti ipò nǹkan nínú ayé. Gbogbo ìwọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1-5; 2 Pétérù 3:3, 4) Gbé mélòó kan lára àwọn nǹkan tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò máa ṣẹlẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yẹ̀ wò.

“Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” (Mátíù 24:7) Ogun tòdé òní kàmàmà ju tìgbàkigbà rí lọ. Òpìtàn kan sọ pé: “Ogun Àgbáyé Kìíní [tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914] ni ogun ‘àrúnpá-rúnsẹ̀sí’ àkọ́kọ́.” Síbẹ̀, ìparun tí ogun àgbáyé kejì ṣe tún pọ̀ gidigidi ju ìyẹn lọ. Ogun sì ń bá a lọ láti run ayé. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ti nímùúṣẹ lọ́nà tó bùáyà!

“Àìtó oúnjẹ . . . yóò sì wà.” (Mátíù 24:7) Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, ìyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé òun ló le jù lọ láyé yìí bẹ́ sílẹ̀. Ìyàn tó burú jáì tún bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì pẹ̀lú. Ìyọnu àìjẹunre-kánú ń kọlu ohun tí ó tó ìdámárùn-ún àwọn olùgbé ayé, tó sì ń ṣekú pa nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rìnlá ọmọ lọ́dọọdún. “Àìtó oúnjẹ” wà lóòótọ́!

“Ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà.” (Lúùkù 21:11) Ní ìpíndọ́gba, iye àwọn tí ń tipasẹ̀ ìsẹ̀lẹ̀ kú lọ́dọọdún láti ọdún 1914 wá jẹ́ ìlọ́po mẹ́wàá ti àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá. Gbé mélòó kan péré nínú àwọn tó ṣe pàtàkì-pàtàkì yẹ̀ wò: Lọ́dún 1920, ní China, 200,000 ló kú; lọ́dún 1923, ní Japan, 99,300 ṣègbé; lọ́dùn 1939, ní Turkey, 32,700 ló run; lọ́dún 1970, ní Peru, 66,800 ló kú; àti lọ́dún 1976, ní China, nǹkan bí 240,000 (tàbí, bí àwọn kan ṣe sọ, 800,000) ṣègbé. Dájúdájú, “ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà” ni!

“Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn . . . láti ibì kan dé ibòmíràn.” (Lúùkù 21:11) Kété lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, nǹkan bíi mílíọ̀nù mọ́kànlélógún ènìyàn ni àjàkálẹ̀ àrùn gágá pa. Ìwé Science Digest ròyìn pé: “Látayébáyé, kò tíì sí àgbákò ikú kíkorò tó sì yára kánkán tó bẹ́ẹ̀ rí.” Láti ìgbà yẹn wá, àrùn ọkàn, àrùn jẹjẹrẹ, àrùn éèdì, àti ọ̀pọ̀ ìyọnu mìíràn ló ti ń pa ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù ènìyàn.

“Pípọ̀ sí i ìwà àìlófin.” (Mátíù 24:12) Láti ọdún 1914, ayé wa ti dayé oníwà ọ̀daràn àti ìwà ipá. Ní ibi púpọ̀, kò sẹ́ni tí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ lójú pópó, àní lójú mọmọ pàápàá. Ní alẹ́, ńṣe làwọn ènìyàn ń jókòó sílé, wọn a sì tilẹ̀kùn pa tòun ti ohun ìdènà, bí ẹ̀rù ti ń bà wọ́n láti jáde síta.

Ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn ni a sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, gbogbo ìwọ̀nyí sì ti ń nímùúṣẹ. Èyí túmọ̀ sí pé òpin ayé ti sún mọ́lé. Àmọ́ o, ó dùn mọ́ni pé àwọn olùlàájá yóò wà. Lẹ́yìn tí Bíbélì sọ pé “ayé ń kọjá lọ,” ó ṣèlérí pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.

Nítorí náà, a ní láti kọ́ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run kí a sì ṣe é. Nígbà náà, a ó lè la òpin ayé yìí já láti lè gbádùn àwọn ìbùkún ayé tuntun Ọlọ́run. Bíbélì ṣèlérí pé ní ìgbà náà: “Ọlọ́run . . . yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [àwọn ènìyàn], ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

Bí a kò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí a fà yọ wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]

Orísun Àwọn Fọ́tò: Ọkọ̀ òfuurufú: Fọ́tò USAF. Ọmọ kékeré: Fọ́tò WHO látọwọ́ W. Cutting. Ìsẹ̀lẹ̀: Y. Ishiyama, Yunifásítì Hokkaido, ní Japan.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́