Ìtùnú Fáwọn Tó Soríkọ́
“Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” (Róòmù 8:22) Kékeré kọ́ ni ìyà tí ń jẹ aráyé lákòókò tí kíkọ àkọsílẹ̀ yìí wáyé ní ohun tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá ọdún sẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló soríkọ́. Nítorí náà, a rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.”—1 Tẹsalóníkà 5:14.
Lónìí, ìpọ́njú aráyé tilẹ̀ tún pọ̀ ju ìyẹn lọ, àwọn èèyàn tó soríkọ́ sì pọ̀ ju tìgbàkigbà rí lọ. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ó yẹ kí ìyẹn yà wá lẹ́nu? Ó tì o, nítorí Bíbélì fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà, ó sì pè wọ́n ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1-5) Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, “làásìgbò” yóò bá “àwọn orílẹ̀-èdè” tí “àwọn ìran bíbanilẹ́rù yóò sì wà.”—Lúùkù 21:7-11; Mátíù 24:3-14.
Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn èèyàn bá ti wà nínú hílàhílo, ìbẹ̀rù, ìbànújẹ́, tàbí irú àwọn ẹ̀dùn ọkàn bẹ́ẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ ni pé wọ́n á dẹni tó soríkọ́. Ikú ẹni táa fẹ́ràn, ìkọ̀sílẹ̀, kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹni, tàbí kéèyàn lùgbàdì àìsàn lè múni soríkọ́ tàbí banú jẹ́ dé góńgó. Àwọn ènìyàn tún máa ń soríkọ́ bí wọ́n bá ro ara wọn pin, bí wọ́n bá rò pé aláṣetì làwọn àti pé àwọn ti já gbogbo èèyàn kulẹ̀. Kò sẹ́ni tọ́kàn rẹ̀ ò lè dà rú bó bá wà nínú pákáǹleke, àmọ́ béèyàn bá ti sọ̀rètí nù, tí kò mọ̀nà àbáyọ nínú ipò burúkú kan, ìyẹn lè mú un soríkọ́ gidigidi.
Irú nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìgbàanì pẹ̀lú. Àìsàn kọlu Jóòbù, àdánù tún dé bá a. Ó rò pé Ọlọ́run ti kọ òun sílẹ̀, nítorí náà, ìgbésí ayé sú u pátápátá. (Jóòbù 10:1; 29:2, 4, 5) Jékọ́bù soríkọ́ nítorí ọmọ rẹ̀ tó rò pé ó ti kú, ó kọ̀ láti gbìpẹ̀, ó sì ń rokàn pé ó kúkú sàn kí òun kú. (Jẹ́nẹ́sísì 37:33-35) Bí àbámọ̀ ṣe bá Dáfídì Ọba nítorí àṣemáṣe ńláǹlà tó ṣe, ó kédàárò pé: “Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni mo ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́. Ara mi ti kú tipiri.”—Sáàmù 38:6, 8; 2 Kọ́ríńtì 7:5, 6.
Lónìí, ọ̀pọ̀ dẹni tó soríkọ́ nítorí pé wọ́n ń lo ara wọn lálòyọ́, bí wọ́n ṣe ń fojoojúmọ́ ayé lépa ọ̀nà àtimáa ṣe àwọn nǹkan tó ré kọjá ohun tí agbára ọpọlọ wọn, ìmọ̀lára wọn, àti okunra wọn lè gbé. Dájúdájú, àìfararọ, pa pọ̀ mọ́ àwọn èrò àti ìmọ̀lára òdì lè ṣe ara ní jàǹbá, kí ó sì ṣàkóbá fún ìṣiṣẹ́ ọpọlọ, ìsoríkọ́ ló sì máa ń kẹ́yìn rẹ̀.—Fi wé Òwe 14:30.
Ìrànlọ́wọ́ Tí Wọ́n Nílò
Ẹpafíródítù, Kristẹni tó wá láti ìlú Fílípì ní ọ̀rúndún kìíní, dẹni tó “soríkọ́ nítorí [àwọn ará] gbọ́ pé ó ti dùbúlẹ̀ àìsàn.” Ó ṣeé ṣe kí Ẹpafíródítù, tí àìsàn gbé ṣánlẹ̀ nígbà tí àwọn ará rán an pé kó gbé àwọn ìpèsè kan lọ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní Róòmù, ti rò pé òun ti já àwọn ẹlẹgbẹ́ òun kulẹ̀, pé aláṣetì ni wọn ó ka òun sí. (Fílípì 2:25-27; 4:18) Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ràn án lọ́wọ́?
Ó fi lẹ́tà rán Ẹpafíródítù sí àwọn ará ní Fílípì, lẹ́tà náà sọ pé: “Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ [gba Ẹpafíródítù] gẹ́gẹ́ bí àṣà nínú Olúwa pẹ̀lú ìdùnnú gbogbo; ẹ sì máa ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n.” (Fílípì 2:28-30) Ó dájú pé pípọ́n tí Pọ́ọ̀lù pọ́n Ẹpafíródítù lé, tí àwọn ará Fílípì sì tún fi ọ̀yàyà àti ìfẹ́ kí i káàbọ̀, yóò tù ú nínú, yóò sì tún ràn án lọ́wọ́ láti mú kí ìsoríkọ́ rẹ̀ lọ kúrò.
Láìsí àní-àní, ìmọ̀ràn Bíbélì náà pé “ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́” ló dára jù lọ. Obìnrin kan tí ìsoríkọ́ ti bá fínra sọ pé: “Pàápàá jù lọ, ìwọ yóò fẹ́ láti mọ̀ pé àwọn ènìyàn kà ọ́ sí. Ìwọ yóò fẹ́ láti gbọ́ kẹ́nì kan sọ pé, ‘Ọ̀rọ̀ ẹ yé mi; ara ẹ á kúkú yá.’”
Lọ́pọ̀ ìgbà ó máa ń béèrè pé kí ẹni tó soríkọ́ náà fúnra rẹ̀ lo ìdánúṣe láti wá agbọ̀ràndùn tó lè finú tán lọ. Kí onítọ̀hún jẹ́ ẹni tí ń gbọ́ni yé, tó jẹ́ onísùúrù gidigidi. Kẹ́ni náà yẹra fún rírọ̀jò ọ̀rọ̀ lu ẹni tó soríkọ́ náà, kó sì yẹra fún ọ̀rọ̀ tí ń dáni lẹ́bi, bíi ‘Kò yẹ kóo máa ronú báyẹn’ tàbí, ‘Ìrònú òdì pátápátá gbáà nìyẹn.’ Ẹni tó soríkọ́ máa ń tètè gba nǹkan sódì, irú àwọn ọ̀rọ̀ líle bẹ́ẹ̀ á wulẹ̀ mú kó túbọ̀ banújẹ́ sí i ni.
Ẹni tó soríkọ́ lè ro ara rẹ̀ pin. (Jónà 4:3) Síbẹ̀, ó yẹ kéèyàn rántí pé irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo òun ló ṣe pàtàkì jù. Àwọn èèyàn ka Jésù Kristi “sí aláìjámọ́ nǹkan kan,” ṣùgbọ́n ìyẹn ò yí irú ẹni tó jẹ́ lójú Ọlọ́run padà. (Aísáyà 53:3) Mọ̀ dájú pé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ló ṣe fẹ́ràn ìwọ náà.—Jòhánù 3:16.
Jésù káàánú àwọn tí wàhálà bá, ó sì sapá láti mú kí wọ́n rí i pé àwọn jẹ́ ẹni iyì. (Mátíù 9:36; 11:28-30; 14:14) Ó ṣàlàyé pé àwọn ológoṣẹ́ kéékèèké, tí kò já mọ́ nǹkan kan pàápàá, níye lórí lójú Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Kò sí ọ̀kan nínú wọn tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run.” Mélòómélòó wá ni yóò ka àwọn èèyàn tí ń gbìyànjú láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ sí iyebíye jù bẹ́ẹ̀ lọ! Jésù sọ nípa àwọn wọ̀nyí pé: “Irun orí yín pàápàá ni a ti ka iye gbogbo wọn.”—Lúùkù 12:6, 7.
Lóòótọ́, ó lè ṣòro fún ẹni tí ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò gidigidi, tí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ àti àbùkù rẹ̀ bà lọ́kàn jẹ́, láti gbà gbọ́ pé òun ṣeyebíye gan-an lójú Ọlọ́run. Ó lè máa rò ó pé òun kò yẹ lẹ́ni tí Ọlọ́run ń fi ìfẹ́ hàn sí, tó sì ń bójú tó. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà pé: “Ọkàn-àyà wa . . . lè dá wa lẹ́bi.” Ṣùgbọ́n ṣé ohun tí ń pinnu bọ́ràn ṣe máa rí nìyẹn? Rárá, òun kọ́. Ọlọ́run mọ̀ pé àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè ní èrò òdì, kí wọ́n tilẹ̀ dá ara wọn lẹ́bi. Nítorí náà Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tù wọ́n nínú pé: “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.”—1 Jòhánù 3:19, 20.
Dájúdájú, ohun tí Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ń wò ré kọjá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àṣìṣe wa. Ó mọ àwọn ipò tí a ti lè ní àwíjàre, gbogbo bí ìgbésí ayé wa ṣe rí, ohun tó sún wá ṣe nǹkan kan àti ète ọkàn wa. Ó mọ̀ pé a jogún ẹ̀ṣẹ̀, àìsàn, àti ikú, pé ìyẹn sì jẹ́ ìkálọ́wọ́kò gidi fún wa. Pé a kàn tilẹ̀ kẹ́dùn tí a sì bínú sí ara wa jẹ́ ẹ̀rí pé a kò fẹ́ láti dẹ́ṣẹ̀, pé ọ̀ràn wa kò tí ì ré kọjá àtúnṣe. Bíbélì sọ pé ńṣe ni “a tẹ̀” wá “lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo,” kì í ṣe pé a fẹ́ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, Ọlọ́run ń bá wa kẹ́dùn nínú gbogbo bí a ṣe ń ráre, ó sì ń fi ìyọ́nú gba ti àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa rò.—Róòmù 5:12; 8:20.
A mú kó dá wa lójú pé: “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́. . . . Bí yíyọ oòrùn ti jìnnà réré sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ìrélànàkọjá wa jìnnà réré sí wa. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:8, 12, 14) Dájúdájú, Jèhófà ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.”—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.
Ìrànlọ́wọ́ tí àwọn tó soríkọ́ nílò jù lọ ń wá nípasẹ̀ sísún mọ́ Ọlọ́run wọn tí ó jẹ́ aláàánú kí wọ́n sì gbà láti ṣe bó ṣe sọ, pé kí wọ́n ‘ju ẹrù ìnira wọn sọ́dọ̀ òun.’ Dájúdájú, òun lè “mú ọkàn-àyà àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.” (Sáàmù 55:22; Aísáyà 57:15) Nítorí náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ká máa gbàdúrà, ó wí pé: “[Ẹ] kó gbogbo àníyàn yín lé [Jèhófà], nítorí ó bìkítà fún yín.” (1 Pétérù 5:7) Bẹ́ẹ̀ ni, nípasẹ̀ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ àwa ènìyàn lè sún mọ́ Ọlọ́run kí á sì gbádùn “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”—Fílípì 4:6, 7; Sáàmù 16:8, 9.
Ṣíṣe àyípadà tó gbéṣẹ́ nínú ìgbésí ayé ẹni sì tún lè ṣèrànwọ́ fún ẹni tó soríkọ́ láti borí ipò yẹn. Ṣíṣe eré ìmárale, jíjẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, gbígba atẹ́gùn tó jíire sára, kí a fún ara ní ìsinmi tó pọ̀ tó, ká sì yẹra fún wíwo tẹlifíṣàn láwòjù, gbogbo rẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Obìnrin kan tí ran àwọn tó soríkọ́ lọ́wọ́ nípa mímú kí wọ́n rìn kárakára. Nígbà tí omidan kan tó soríkọ́ sọ pé: “Mi ò fẹ́ rìn káàkiri,” obìnrin yìí fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ láìṣàwàdà pé: “Ní tìyẹn, o máa rìn o.” Obìnrin náà ròyìn pé: ‘A rin ìrìn kìlómítà mẹ́fà. Nígbà tí a padà dé, ó ti rẹ̀ ẹ́, ṣùgbọ́n ara rẹ̀ túbọ̀ mókun sí i. O kò lè mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni eré ìmárale àṣekára ṣe wúlò tó àfìgbà tóo bá tó dán an wò.’
Àmọ́ ṣá o, nígbà míì, kì í ṣeé ṣe láti borí ìsoríkọ́ pátápátá, àní lẹ́yìn lílo gbogbo ohun táa mọ̀ pàápàá, títí kan àwọn oògùn. Obìnrin kan tí ó ti lé ní ogójì ọdún sọ pé: “Gbogbo nǹkan ni mo ti lò wò, síbẹ̀ mo ṣì ń soríkọ́.” Bọ́ràn ṣe rí gan-an ní lọ́ọ́lọ́ọ́ nìyẹn, kì í sábà ṣeé ṣe láti wo afọ́jú, adití, tàbí arọ sàn. Ṣùgbọ́n àwọn tó soríkọ́ lè rí ìtùnú àti ìrètí nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, èyí tí ń fúnni ní ìrètí ìtura pípẹ́ títí tí ó sì dájú, kúrò nínú gbogbo àìlera àráyé.—Róòmù 12:12; 15:4.
Ìgbà Tí Ẹnikẹ́ni Kò Ní Soríkọ́ Mọ́
Nígbà tí Jésù ń ṣàpèjúwe àwọn nǹkan ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí yóò dé bá ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó sọ síwájú sí i pé: “Bí nǹkan wọ̀nyí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:28) Ìdáǹdè bọ́ sínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run ni Jésù ń sọ, ibẹ̀ la ó ti “dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.
Ìtura gbáà ni yóò mà jẹ́ o fún aráyé láti bọ́ lọ́wọ́ ìnira àtẹ̀yìnwá, kéèyàn máa jí lójoojúmọ́ láìsí ìṣòro tí ń páni láyà, téèyàn ó sì máa hára gàgà láti bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò ẹni lójúmọ́! Kò sẹ́nikẹ́ni tóhunkóhun yóò tún mú soríkọ́ mọ́. Ìlérí tó dájú, tí Ọlọ́run ṣe fáráyé ni pé òun yóò “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Bí a kò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí a fà yọ wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.