Ta Ní ń Ṣàkóso Ayé Ní Ti Tòótọ́?
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò fi ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo dáhùn ìbéèrè tí ó wà lókè yìí, wọn á sọ pé Ọlọ́run ni. Ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó gba àfiyèsí, kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti sọ pé Jésù Kristi tàbí Baba rẹ̀ ni olùṣàkóso ayé yìí ní tòótọ́. Lódì kejì ẹ̀wẹ̀, Jésù sọ pé: “Olùṣàkóso ayé yìí ni a óò lé jáde.” Ó sì fi kún un pé: “Olùṣàkóso ayé ń bọ̀. Kò sì ní ìdìmú kankan lórí mi.”—Jòhánù 12:31; 14:30; 16:11.
Nítorí náà olùṣàkóso ayé yìí ń ta ko Jésù. Ta ni èyí lè jẹ́?
Àwọn Ipò Ayé Pèsè Ojútùú Kan fún Wa
Láìka ìsapá àwọn ènìyàn afẹ́nifẹ́re sí, ayé ti jìyà lọ́nà tí ó burú jáì jálẹ̀ gbogbo ìtàn. Èyí ń mú kí àwọn onírònú ènìyàn ṣe kàyéfì, gẹ́gẹ́ bí olóògbé òǹkọ̀wé alátùn-únṣe, David Lawrence ti ṣe nígbà tó sọ pé: “‘Àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé’—ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ní ń fẹ́ ẹ. ‘Ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn’—ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn ènìyàn ayé ni ó ní èrò rẹ̀ sí ọmọnìkejì wọn. Nígbà náà kí ló wá dé? Èé ṣe tí a fi ń halẹ̀ ogun láìka ìfẹ́-ọkàn tí a dá mọ́ àwọn ènìyàn sí?”
Ó dà bí ẹ̀dà ọ̀rọ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Nígbà tí ìfẹ́-ọkàn tí a dá mọ́ àwọn ènìyàn jẹ́ láti gbé ní àlàáfíà, wọ́n sábà máa ń kórìíra ara wọn, wọ́n sì ń pa ara wọn—pẹ̀lú ìwà òkúrorò sì ni. Gbé ìwà ìkà tó lékenkà táwọn èèyàn ń fi ìwà àìláàánú tó burú jáì hù, yẹ̀ wò. Àwọn ènìyàn ti lo àwọn ìyẹ̀wù aláfẹ́fẹ́ aséniléèémí, àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àwọn ohun ìjà afinásọ̀kò, àwọn bọ́ǹbù oníná, àti àwọn ọ̀nà oníkà tó burú jáì mìíràn láti dáni lóró àti láti pa ọmọnìkejì wọn ní ìpakúpa.
Ìwọ ha gbà gbọ́ pé àwọn ènìyàn, tí àlàáfíà àti ayọ̀ ń wù lè dá hu irú ìwà tó burú jáì bẹ́ẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn bí? Irú àwọn agbára wo ní ń ti àwọn ènìyàn sínú ṣíṣe irú àwọn nǹkan amúniwárìrì bẹ́ẹ̀ tàbí tí ń dọ́gbọ́n darí wọn sínú àwọn ipò tí wọn ó fi rò pé ó pọndandan fún wọn láti hu àwọn ìwà ìkà? Ìwọ ha ti fìgbà kan rí ṣe kàyéfì bóyá àwọn agbára ibi, tí a kò lè fojú rí, ní ń sún àwọn ènìyàn láti hu irú àwọn ìwà ipá bẹ́ẹ̀?
A Fi Àwọn Olùṣàkóso Ayé Hàn
Kò sí ìdí láti méfò lórí ọ̀ràn náà, nítorí Bíbélì fi hàn kedere pé ẹni àìrí, olóye kan ni ó ti ń darí àwọn ènìyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè. Ó wí pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Bíbélì sì fi í hàn, ní wíwí pé: “Ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, . . . ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.”—1 Jòhánù 5:19; Ìṣípayá 12:9.
Ní ìgbà kan tí “Èṣù . . . dẹ [Jésù] wò,” Jésù kò gbé ìbéèrè dìde sí ipa tí Sátánì ń kó gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso ayé yìí. Bíbélì ṣàlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ pé: “Èṣù . . . mú un lọ sí òkè ńlá kan tí ó ga lọ́nà kíkàmàmà, ó sì fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án, ó sì wí fún un pé: ‘Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú bí ìwọ bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.’ Nígbà náà ni Jésù wí fún un pé: ‘Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!’”—Mátíù 4:1, 8-10.
Ronú nípa èyí. Sátánì dẹ Jésù wò nípa fífi “gbogbo ìjọba ayé” lọ̀ ọ́. Síbẹ̀, ǹjẹ́ ìfilọni Sátánì yóò ha jẹ́ ìdẹwò gidi kan bí Sátánì kì í bá ṣe olùṣàkóso àwọn ìjọba wọ̀nyí ní ti tòótọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́, kì yóò jẹ́ bẹ́ẹ̀. Sì ṣàkíyèsí, Jésù kò jiyàn lórí pé gbogbo àwọn ìjọba ayé wọ̀nyí jẹ́ ti Sátánì, èyí tí òun ì bá ti ṣe ká ní pé Sátánì kò ní agbára lórí wọn ni. Nípa báyìí, Sátánì Èṣù ní ti gidi ni olùṣàkóso àìrí fún ayé! Ní ti tòótọ́, Bíbélì pè é ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́ríńtì 4:4) Síbẹ̀, báwo ni irú ẹni ibi kan bẹ́ẹ̀ ṣe lè dé ipò alágbára yìí?
Ẹni náà tí ó di Sátánì ti jẹ́ áńgẹ́lì kan rí, tí Ọlọ́run dá, ṣùgbọ́n òun wá ń ṣe ìlara ipò Ọlọ́run. Ó pe ìṣàkóso Ọlọ́run lọ́nà ẹ̀tọ́ níjà. Fún ète yìí, ó lo ejò kan gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ láti tan Éfà, obìnrin àkọ́kọ́, jẹ, tí ó sì tipa báyìí ṣeé ṣe fún un láti sún òun àti Ádámù, ọkọ rẹ̀, ṣe ohun tí ó fẹ́ dípò ṣíṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; 2 Kọ́ríńtì 11:3) Ó tún sọ pé òun lè yí gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà, tí a kò tíì bí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà Ọlọ́run yọ̀ọ̀da àkókò fún Sátánì kí ó gbìyànjú láti fi ẹ̀rí ohun tí ó sọ múlẹ̀, ṣùgbọ́n Sátánì kò tíì ṣàṣeyọrí.—Jóòbù 1:6-12; 2:1-10.
Lọ́nà tí ó gba àfiyèsí, Sátánì kò nìkan ṣàkóso lórí ayé. Ó rí àwọn áńgẹ́lì mìíràn yí lérò padà láti dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Àwọn wọ̀nyí wá di àwọn ẹ̀mí èṣù, àwọn ẹ̀mí tó dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ṣíṣe ibi. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí ó rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ . . . dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù; nítorí àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe . . . lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.”—Éfésù 6:11, 12.
Gbéjà Ko Àwọn Ẹ̀mí Burúkú
Àwọn òkúrorò olùṣàkóso ayé, tí a kò lè fojú rí wọ̀nyí, ti pinnu láti ṣi gbogbo aráyé lọ́nà, ní yíyí wọn kúrò nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ọ̀nà kan tí àwọn ẹ̀mí burúkú gbà ń ṣe èyí ni gbígbé èrò ìwàláàyè lẹ́yìn ikú lárugẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn kedere pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:19; Ìsíkíẹ́lì 18:4; Sáàmù 146:3, 4; Oníwàásù 9:5, 10) Nípa báyìí, ẹ̀mí burúkú kan, tí ó ṣàfarawé ohùn ẹni náà tí ó ti kú, lè bá àwọn ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ ẹni yẹn tí ó wà láàyè sọ̀rọ̀, bóyá nípasẹ̀ abẹ́mìílò kan tàbí nípasẹ̀ “ohùn” kan láti ilẹ̀ àìrí. “Ohùn” náà á díbọ́n bí ẹni náà tí ó ti ṣaláìsí, síbẹ̀ ẹ̀mí èṣù kan ni ó jẹ́ ní ti gidi!
Nítorí náà, bí ìwọ bá gbọ́ irú “ohùn” bẹ́ẹ̀ nígbàkigbà, má ṣe jẹ́ kó tàn ọ́ jẹ. Má ṣe tẹ́wọ́ gba ohunkóhun yòówù tí ó bá sọ, kí o sì tún àwọn ọ̀rọ̀ Jésù sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!” (Mátíù 4:10; Jákọ́bù 4:7) Má ṣe jẹ́ kí òfíntótó nípa ilẹ̀ ọba ẹ̀mí sún ọ láti ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù. Irú àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ ni a ń pè ní ìbẹ́mìílò, Ọlọ́run sì kìlọ̀ fún àwọn olùjọsìn rẹ̀ kí wọ́n má ṣe lọ́wọ́ nínú rẹ̀ rárá, irú èyí ó wù kó jẹ́. Bíbélì dẹ́bi fún “ẹnikẹ́ni tí ń woṣẹ́, . . . tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú.”—Diutarónómì 18:10-12; Gálátíà 5:19-21; Ìṣípayá 21:8.
Níwọ̀n bí ìbẹ́mìílò ti ń mú ẹnì kan wá sábẹ́ agbára ìdarí àwọn ẹ̀mí èṣù, yàgò fún gbogbo àṣà ìbẹ́mìílọ̀ láìka bí ó ti lè dà bí ohun tí ó gbádùn mọ́ni, tàbí mórí yá tó. Àwọn kan lára àṣà wọ̀nyí ni wíwo kírísítálì àfiwoṣẹ́, lílo àwọn ọpọ́n Ouija, ESP (wíwòye ìmọ̀lára ré kọjá òde ara), yíyẹ àwọn ilà ọwọ́ ẹni wò (wíwo àtẹ́lẹwọ́ sọ tẹ́lẹ̀), àti wíwo ìràwọ̀. Bákan náà àwọn ẹ̀mí èṣù ti fa àwọn ariwo àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì tí ó ṣeé fojú rí mìíràn nínú àwọn ilé tí wọ́n ti sọ di ibùwọ̀ wọn.
Ní àfikún sí i, àwọn ẹ̀mí burúkú ń lo ìtẹ̀sí tí ènìyàn ní láti máa dẹ́ṣẹ̀ fún yíyàn wọ́n jẹ nípa gbígbé àwọn ìwé, àwòrán sinimá, àti àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n tó jẹ́ ti ìbálòpọ̀ oníwà ìbàjẹ́ àti èyí tí kò bá ìwà ẹ̀dá mu lárugẹ. Àwọn ẹ̀mí èṣù mọ̀ pé ńṣe ni èrò tí kò tọ́ máa ń gbani lọ́kàn tí a kò bá lé e jáde kúrò lọ́kàn, àti pé yóò sún àwọn ènìyàn láti hùwà ìbàjẹ́—bíi ti àwọn ẹ̀mí èṣù fúnra wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2; 1 Tẹsalóníkà 4:3-8; Júúdà 6.
Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ lè yínmú sí èrò náà pé àwọn ẹ̀mí burúkú ni ó ń ṣàkóso ayé yìí. Ṣùgbọ́n àìgbàgbọ́ wọn kò yani lẹ́nu, níwọ̀n bí Bíbélì ti wí pé: “Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:14) Ìtànjẹ rẹ̀ tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ jù lọ ni fífọ́ tó fọ́ ọ̀pọ̀ lójú sí òtítọ́ náà pé òun àti àwọn ẹ̀mí èṣù òun wà ní ti gidi. Má ṣe jẹ́ kí a tàn ọ jẹ́ o! Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ wà lóòótọ́, o sì ní láti máa bá a lọ láti gbéjà kò wọ́n.—1 Pétérù 5:8, 9.
Ó mà dùn mọ́ni o pé, àkókò ti sún mọ́lé nísinsìnyí nígbà tí Sátánì àti àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ kì yóò sí mọ́! Bíbélì mú un dáni lójú pé, “Ayé [pa pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù olùṣàkóso rẹ̀] ń kọjá lọ . . . ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Ẹ wo irú ìtura tí yóò jẹ́ láti rí i pé a mú agbára búburú yìí tó ń darí ẹni kúrò! Ǹjẹ́ kí àwa, nígbà náà, wà lára àwọn tí wọ́n ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kí a sì gbádùn ìwàláàyè títí láé nínú ayé tuntun òdodo ti Ọlọ́run.—Sáàmù 37:9-11, 29; 2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.
Bí a kò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí a fà yọ wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Sátánì ha lè fi gbogbo ìjọba ayé wọ̀nyí lọ Jésù bí wọn kì í bá ṣe tirẹ̀ bí?