ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ed ojú ìwé 31
  • Ìparí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìparí
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Kristẹni Tòótọ́ Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Fipá Mú Káwọn Ọmọ Wọn Ṣe Ẹ̀sìn Wọn?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ohun Tóo Gbà Gbọ́—Kí Nìdí Tóo Fi Gbà Á Gbọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́
ed ojú ìwé 31
Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31

Ìparí

A KÒ ṢE ìwé pẹlẹbẹ yìí láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ ìsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní kíkún. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ti sapá láti ṣàlàyé díẹ̀ nínú àwọn ìlànà tí àwọn Ẹlẹ́rìí gbà gbọ́, àti láti fi irú àwọn agbára ìdarí ìdílé tí ń nípa lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ, bí ọ̀kan tàbí àwọn òbí méjèèjì bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí, hàn kedere.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka ìdàgbàsókè tẹ̀mí àwọn ọmọ wọn sí gan-an. Wọ́n sì ní ìgbọ́kànlé pé èyí ń ṣèrànwọ́ fún ìdàgbàsókè àwọn ọmọ wọn ní àwọn agbègbè míràn. Èrò Ìgbàgbọ́ tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà, àti àwọn ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé mú kí ìgbésí ayé wọ́n nítumọ̀, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro wọn ojoojúmọ́. Ní àfikún sí i, àwọn èrò ìgbàgbọ́ àti ìlànà yẹn yẹ kí ó sún wọn láti gbìyànjú láti jẹ́ ògbóṣáṣá akẹ́kọ̀ọ́ àti ọmọ orílẹ̀-èdè rere jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn.

Àwọn Ẹlẹ́rìí ń sapá láti wo ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí gan-an, nítorí náà, wọ́n ka ìmọ̀ ẹ̀kọ́ sí pàtàkì gan-an. Nítorí èyí, ó jẹ́ àníyàn wọn láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ débi tí agbára wọ́n mọ. Ní ti wọn, ní ilé wọn àti ní àwọn ibi ìjọsìn wọn kárí ayé, wọn yóò máa bá a lọ láti fún àwọn ọmọ wọn níṣìírí láti ṣe ipa tiwọn nínú iṣẹ́ àjùmọ̀ṣe tí ń méso jáde yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́