Ẹ̀kọ́ 2
Ta Ni Ọlọrun?
Ta ni Ọlọrun tòótọ́ náà, kí sì ni orúkọ rẹ̀? (1, 2)
Irú ara wo ni òún ní? (3)
Àwọn ànímọ́ títa yọ wo ni òún ní? (4)
Ó ha yẹ kí á lo àwọn ère àti àmì ìjọsìn nínú ìjọsìn wa sí i bí? (5)
Àwọn ọ̀nà méjì wo ni a lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọrun? (6)
1. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn ènìyàn ń jọ́sìn. Ṣùgbọ́n, Bibeli sọ fún wa pé, Ọlọrun TÒÓTỌ́ kan ṣoṣo ni ó wà. Òun ni ó dá ohun gbogbo lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí pé òun ni ó fún wa ní ìwàláàyè, òun ni Ẹnì kan ṣoṣo tí a ní láti jọ́sìn.—1 Korinti 8:5, 6; Ìṣípayá 4:11.
2. Ọlọrun ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, ṣùgbọ́n orúkọ kan ṣoṣo ni ó ní. JEHOFA ni orúkọ yẹn. Nínú ọ̀pọ̀ Bibeli, a ti yọ orúkọ Ọlọrun kúrò, a sì ti fi orúkọ oyè bíi OLUWA tàbí ỌLỌRUN rọ́pò rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí a kọ Bibeli, orúkọ náà, Jehofa, fara hàn nínú rẹ̀ ní nǹkan bí ìgbà 7,000!—Eksodu 3:15; Orin Dafidi 83:18.
3. Jehofa ní ara, ṣùgbọ́n kì í ṣe bíi tiwa. Bibeli sọ pé: “Ọlọrun jẹ́ Ẹ̀mí.” (Johannu 4:24) Ẹ̀mí jẹ́ oríṣi ìwàláàyè kan, tí ó ga fíofío ju tiwa lọ. Kò sí ènìyàn kankan tí ó tí ì rí Ọlọrun rí. Ọ̀run ni Jehofa ń gbé, ṣùgbọ́n ó lè rí ohun gbogbo. (Orin Dafidi 11:4, 5; Johannu 1:18) Nígbà náà, kí ni ẹ̀mí mímọ́? Kì í ṣe ẹnì kan bí Ọlọrun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun.—Orin Dafidi 104:30.
4. Bibeli ṣí ànímọ́ Jehofa payá fún wa. Ó fi hàn pé ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, àti agbára jẹ́ àwọn ànímọ́ rẹ̀ títa yọ. (Deuteronomi 32:4; Jobu 12:13; Isaiah 40:26; 1 Johannu 4:8) Bibeli sọ fún wa pé, òún jẹ́ aláàánú, onínúure, olùdáríjini, ọ̀làwọ́, àti onísùúrù pẹ̀lú. Àwa, gẹ́gẹ́ bí ọmọ onígbọràn, gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti fara wé e.—Efesu 5:1, 2.
5. Ó ha yẹ kí á tẹrí ba tàbí gbàdúrà sí ère, àwòrán, tàbí àmì ìjọsìn nínú ìjọsìn wa bí? Rárá! (Eksodu 20:4, 5) Jehofa sọ pé òun nìkan ṣoṣo ni a gbọ́dọ̀ jọ́sìn. Òun kì yóò ṣàjọpín ògo rẹ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn tàbí ohun mìíràn. Ère kò ní agbára láti ràn wá lọ́wọ́.—Orin Dafidi 115:4-8; Isaiah 42:8.
6. Báwo ni a ṣe lè mọ Ọlọrun dáradára sí i? Ọ̀nà kan jẹ́ nípa wíwo àwọn ohun tí òún ti dá, àti ríronú jinlẹ̀ nípa ohun tí wọ́n ń sọ fún wa. Àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọrun ń fi hàn wá pé ó ní agbára àti ọgbọ́n gíga. A ń rí ìfẹ́ rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ti ṣe. (Orin Dafidi 19:1-6; Romu 1:20) Ọ̀nà míràn tí a lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọrun jẹ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Nínú rẹ̀, òún sọ púpọ̀ fún wa nípa irú Ọlọrun tí òún jẹ́. Ó tún sọ fún wa nípa ète rẹ̀ àti ohun tí òún fẹ́ kí a ṣe.—Amosi 3:7; 2 Timoteu 3:16, 17.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
A ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọrun láti ara ìṣẹ̀dá àti láti inú Bibeli