Ẹ̀kọ́ 9
Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun Gbọ́dọ̀ Mọ́ Tónítóní
Èé ṣe tí a fi gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní ní gbogbo ọ̀nà? (1)
Kí ni ó túmọ̀ sí láti mọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí? (2) mọ́ tónítóní ní ti ìwà híhù? (3) mọ́ tónítóní ní ti èrò orí? (4) mọ́ tónítóní nípa ti ara? (5)
Irú àwọn èdè àìmọ́ wo ni ó yẹ kí a yẹra fún? (6)
1. Jehofa Ọlọrun mọ́ tónítóní, ó sì jẹ́ mímọ́. Ó retí pé kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní—nípa tẹ̀mí, ní ti ìwà híhù, ní ti èrò orí, àti nípa ti ara. (1 Peteru 1:16) Ó gba ìsapá gidigidi láti wà ní mímọ́ tónítóní ní ojú Ọlọrun. A ń gbé nínú ayé aláìmọ́. A tún ní ìjàkadì lòdì sí àwọn ìtẹ̀sí wa láti ṣe ohun tí kò tọ́. Ṣùgbọ́n a kò gbọdọ̀ juwọ́ sílẹ̀.
2. Ìmọ́tónítóní Nípa Tẹ̀mí: Bí a bá fẹ́ẹ́ sin Jehofa, a kò lè máa bá ẹ̀kọ́ tàbí àṣà ìsìn èké èyíkéyìí nìṣó. A gbọ́dọ̀ jáde kúrò nínú ìsìn èké, kí a má sì ṣe tì í lẹ́yìn lọ́nàkọnà. (2 Korinti 6:14-18; Ìṣípayá 18:4) Níwọ̀n bí a bá ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọrun, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí àwọn ènìyàn tí ń kọni ní ohun tí kì í ṣe òtítọ́, má baà ṣì wá lọ́nà.—2 Johannu 10, 11.
3. Ìmọ́tónítóní Ní Ti Ìwà Híhù: Jehofa ń fẹ́ kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ hùwà gẹ́gẹ́ bíi Kristian tòótọ́ ní gbogbo ìgbà. (1 Peteru 2:12) Ó ń rí gbogbo ohun tí a bá ṣe, kódà ní kọ́lọ́fín pàápàá. (Heberu 4:13) A gbọ́dọ̀ yẹra fún ìwà pálapàla àti àwọn àṣà àìmọ́ mìíràn ti ayé yìí.—1 Korinti 6:9-11.
4. Ìmọ́tónítóní Ní Ti Èrò Orí: Bí a bá fi àwọn èrò tí ó mọ́ tónítóní, tí ó dára kún èrò inú wa, ìwà wa pẹ̀lú yóò mọ́ tónítóní. (Filippi 4:8) Ṣùgbọ́n, bí a bá ń ronú lórí àwọn ohun tí kò mọ́, yóò yọrí sí àwọn ìṣe búburú. (Matteu 15:18-20) A gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn eré ìnàjú tí ó lè sọ èrò inú wa di ẹlẹ́gbin. A lè fi àwọn èrò tí ó mọ́ tónítóní kún èrò inú wa nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
5. Ìmọ́tónítóní Nípa Ti Ara: Nítorí pé wọ́n ń ṣojú fún Ọlọrun, àwọn Kristian ní láti mú kí ara àti aṣọ wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní. A gbọ́dọ̀ fọ ọwọ́ wa nígbà tí a bá lọ sí ilé ìyàgbẹ́, a sì gbọ́dọ̀ fọ̀ wọ́n kí á tó jẹun tàbí fọwọ́ kan oúnjẹ. Bí ẹ kò bá ní ilé ìyàgbẹ́ tí ó bójú mu, ẹ gbẹ́ kòtò bo ìgbẹ́ mọ́lẹ̀. (Deuteronomi 23:12, 13) Wíwà ní mímọ́ tónítóní nípa ti ara máa ń dá kún ìlera pípé. Ilé Kristian ní láti bójú mu, kí ó sì mọ́ tónítóní nínú àti lóde. Ó ní láti dá yàtọ̀ ní àdúgbò gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ rere.
6. Èdè Mímọ́ Tónítóní: Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo. Àwọn òpùrọ́ kì yóò wọ Ìjọba Ọlọrun. (Efesu 4:25; Ìṣípayá 21:8) Àwọn Kristian kì í lo èdè rírùn. Wọn kì í tẹ́tí sí tàbí sọ àwọn ọ̀rọ̀ àpárá rírùn tàbí ìtàn rírùn. Nítorí èdè mímọ́ tónítóní tí ń jáde lẹ́nu wọn, wọ́n dá yàtọ̀ ní ibi iṣẹ́ tàbí ní ilé ẹ̀kọ́ àti ládùúgbò.—Efesu 4:29, 31; 5:3.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní ní gbogbo ọ̀nà