Ẹ̀kọ́ 12
Fífọ̀wọ̀ Hàn fún Ìwàláàyè àti Ẹ̀jẹ̀
Ojú wo ni ó yẹ kí á fi wo ìwàláàyè? (1) ìṣẹ́yún? (1)
Báwo ni àwọn Kristian ṣe ń fi hàn pé ààbò jẹ wọ́n lọ́kàn? (2)
Ó ha lòdì láti pa ẹranko bí? (3)
Kí ni díẹ̀ lára àwọn àṣà tí kò fí ọ̀wọ̀ hàn fún ìwàláàyè? (4)
Kí ni òfin Ọlọrun lórí ẹ̀jẹ̀? (5)
Èyí ha kan ìfàjẹ̀sínilára bí? (6)
1. Jehofa ni Orísun ìwàláàyè. Gbogbo ohun abẹ̀mí jẹ Ọlọrun ní gbèsè ìwàláàyè wọn. (Orin Dafidi 36:9) Ìwàláàyè jẹ́ mímọ́ fún Ọlọrun. Ìwàláàyè ọmọ tí a kò tí ì bí, tí ó wà nínú ìyá rẹ̀ pàápàá, ṣeyebíye fún Jehofa. Láti mọ̀-ọ́nmọ̀ pa ọmọ inú jòjòló, tí ń dàgbà, lòdì lójú Ọlọrun.—Eksodu 21:22, 23; Orin Dafidi 127:3.
2. Àwọn Kristian tòótọ́ máa ń jẹ́ kí ààbò jẹ wọ́n lọ́kàn. Wọ́n ń rí i dájú pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ilé wọn kò fa ewu. (Deuteronomi 22:8) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun kì í fi ẹ̀mí wọn wewu láìnídìí nítorí ìgbádùn tàbí ìmóríyá lásán. Nítorí náà, wọn kì í lọ́wọ́ nínú àwọn eré ìdárayá oníwà ipá, tí ń mọ̀-ọ́nmọ̀ ṣe ìpalára fún àwọn ẹlòmíràn. Wọ́n ń yẹra fún eré ìnàjú tí ń fún ìwà ipá níṣìírí.—Orin Dafidi 11:5; Johannu 13:35.
3. Ìwàláàyè ẹranko pẹ̀lú jẹ́ mímọ́ fún Ẹlẹ́dàá. Kristian lè pa ẹranko láti pèsè oúnjẹ àti aṣọ tàbí láti dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àìsàn àti ewu. (Genesisi 3:21; 9:3; Eksodu 21:28) Ṣùgbọ́n, ó lòdì láti ṣe ẹranko níkà tàbí láti pa wọ́n fún eré ìdárayá tàbí ìgbádùn lásán.—Owe 12:10.
4. Mímu sìgá, jíjẹ ẹ̀pà beteli, àti lílo oògùn fún ìmóríyá kò yẹ fún Kristian. Àwọn àṣà wọ̀nyí lòdì nítorí pé (1) wọ́n ń sọ wá di ẹrú wọn, (2) wọ́n ń pa ara wa lára, àti pé (3) wọ́n jẹ́ aláìmọ́. (Romu 6:19; 12:1; 2 Korinti 7:1) Ó lè ṣòro gan-an láti fi àwọn ìwà wọ̀nyí sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ láti mú inú Jehofa dùn.
5. Ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọrun. Ọlọrun sọ pé ẹ̀mí, tàbí ìwàlááyè, ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀. Nítorí náà, ó lòdì láti jẹ ẹ̀jẹ̀. Ó lòdì pẹ̀lú láti jẹ ẹran tí a kò ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dànù dáradára. Bí a bá lọ́ ẹranko kan lọ́rùn pa tàbí bí ó bá kú sí ojú pàkúté, a kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Bí a bá gún un ní ọ̀kọ̀ tàbí bí a bá yin ìbọn pa á, a gbọ́dọ̀ dúńbú rẹ̀ kíákíá, bí a óò bá jẹ ẹ́.—Genesisi 9:3, 4; Lefitiku 17:13, 14; Ìṣe 15:28, 29.
6. Ó ha lòdì láti gba ẹ̀jẹ̀ sára? Rántí pé, Jehofa béèrè pé kí á ta kété sí ẹ̀jẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé, lọ́nàkọnà tí ó wù kí ó jẹ́, a kò gbọdọ̀ gba ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹ̀jẹ̀ ti àwa fúnra wa pàápàá, tí a tọ́jú pamọ́, sára. (Ìṣe 21:25) Nítorí náà, àwọn Kristian tòótọ́ kì yóò gba ẹ̀jẹ̀ sára. Wọn yóò gba oríṣi ìtọ́jú ìṣègùn míràn, irú bíi fífa àwọn èròjà tí kò ní ẹ̀jẹ̀ nínú sára. Wọ́n fẹ́ wà láàyè, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbìyànjú láti du ẹ̀mí wọn nípa rírú òfin Ọlọrun.—Matteu 16:25.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Láti mú inú Ọlọrun dùn, a gbọ́dọ̀ yẹra fún ìfàjẹ̀sínilára, àwọn àṣà àìmọ́, àti ìfẹ̀mí-ara-ẹni-wewu láìnídìí