Ẹ̀kọ́ 15
Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Ṣe Ìfẹ́ Ọlọrun
Èé ṣe tí ó fi yẹ kí o sọ nípa ohun tí o ń kọ́ fún àwọn ẹlòmíràn? (1)
Ta ni o lè bá ṣàjọpín ìhìn rere náà? (2)
Ipa wo ni ìwà rẹ lè ní lórí àwọn ẹlòmíràn? (2)
Nígbà wo ni o lè wàásù pẹ̀lú ìjọ? (3)
1. Ní báyìí, o ti kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀pọ̀ ohun rere láti inú Bibeli. Ìmọ̀ yìí yẹ kí ó sún ọ sí mímú àkópọ̀ ìwà Kristian dàgbà. (Efesu 4:22-24) Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe kókó, kí o lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. (Johannu 17:3) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn mìíràn pẹ̀lú ní láti gbọ́ ìhìn rere náà, kí àwọn pẹ̀lú lè rí ìgbàlà. Gbogbo Kristian tòótọ́ gbọ́dọ̀ wàásù fún àwọn ẹlòmíràn. Àṣẹ Ọlọrun ni.—Romu 10:10; 1 Korinti 9:16; 1 Timoteu 4:16.
2. O lè bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣàjọpín àwọn ohun rere tí o ń kọ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n sún mọ́ ọ. Sọ wọ́n fún ìdílé, ọ̀rẹ́, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́, àti àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ. Jẹ́ onínúure àti onísùúrù, bí o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. (2 Timoteu 2:24, 25) Máa fi í sọ́kàn pé, àwọn ènìyàn sábà máa ń wo ìwà ẹnì kan ju bí wọ́n ṣe ń fetí sí ohun tí ó ń sọ lọ. Nítorí náà, ìwà rere rẹ lè fa àwọn mìíràn mọ́ra láti tẹ́tí sí ìhìn iṣẹ́ tí o ń wàásù.—Matteu 5:16; 1 Peteru 3:1, 2, 16.
3. Bí àkókò ti ń lọ, o lè tóótun láti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pẹ̀lú ìjọ àdúgbò, ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Èyí jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì kan nínú ìtẹ̀síwájú rẹ. (Matteu 24:14) Wo irú ìdùnnú tí yóò jẹ́ bí o bá lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jehofa, kí ó sì jèrè ìyè ayérayé!—1 Tessalonika 2:19, 20.