Ẹ̀kọ́ 16
Ìpinnu Rẹ Láti Sin Ọlọrun
Kí ni o gbọ́dọ̀ ṣe láti lè di ọ̀rẹ́ Ọlọrun? (1, 2)
Báwo ni o ṣe lè ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọrun? (1)
Nígbà wo ni ó yẹ kí o ṣe ìrìbọmi? (2)
Báwo ni o ṣe lè jèrè okun láti máa bá ìṣòtítọ́ sí Ọlọrun nìṣó? (3)
1. Láti lè di ọ̀rẹ́ Ọlọrun, o gbọ́dọ̀ jèrè ìmọ̀ òtítọ́ Bibeli dáradára (1 Timoteu 2:3, 4), lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́ (Heberu 11:6), ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ (Ìṣe 17:30, 31), kí o sì yí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ padà. (Ìṣe 3:19) Lẹ́yìn náà, ìfẹ́ rẹ fún Ọlọrun gbọ́dọ̀ sún ọ láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún un. Èyí túmọ̀ sí pé o ní láti sọ fún un nínú àdúrà ara ẹni rẹ, ní ìdákọ́ńkọ́ pé, o ń fi ara rẹ fún un láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Matteu 16:24; 22:37.
2. Lẹ́yìn tí o bá ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọrun, o gbọ́dọ̀ ṣe ìrìbọmi. (Matteu 28:19, 20) Ìrìbọmi ń jẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ̀ pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jehofa. Nítorí náà, ìrìbọmi wà fún kìkì àwọn tí wọ́n ti dàgbà tó láti pinnu láti sin Ọlọrun. Nígbà tí a bá ń batisí ẹnì kan, gbogbo ara rẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ rì bọ inú omi fún àkókò díẹ̀.a—Marku 1:9, 10; Ìṣe 8:36.
3. Lẹ́yìn tí o bá ti ṣe ìyàsímímọ́, Jehofa yóò retí pé kí o máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ. (Orin Dafidi 50:14; Oniwasu 5:4, 5) Eṣu yóò gbìyànjú láti dá ọ lọ́wọ́ kọ́ láti sin Jehofa. (1 Peteru 5:8) Ṣùgbọ́n, sún mọ́ Ọlọrun pẹ́kípẹ́kí nínú àdúrà. (Filippi 4:6, 7) Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójoojúmọ́. (Orin Dafidi 1:1-3) Rọ̀ mọ́ ìjọ tímọ́tímọ́. (Heberu 13:17) Nípa ṣíṣe gbogbo ìwọ̀nyí, ìwọ yóò jèrè okun láti máa bá ìṣòtítọ́ sí Ọlọrun nìṣó. O lè tipa báyìí máa ṣe àwọn ohun tí Ọlọrun ń béèrè lọ́wọ́ rẹ títí ayérayé!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A dámọ̀ràn kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tàbí irú ìwé bẹ́ẹ̀, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watch Tower Bible and Tract Society, ní ìmúra sílẹ̀ fún ìrìbọmi.