ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ie ojú ìwé 17-18
  • Ibi Tí A Lè Yíjú sí fún Ìdáhùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibi Tí A Lè Yíjú sí fún Ìdáhùn
  • Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sáyẹ́ǹsì àti Ọgbọ́n Èrò Orí
  • Orísun Aláìlẹ́gbẹ́ fún Ìdáhùn
  • Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Ìgbàgbọ́ Àwọn Ènìyàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìwàláàyè Ha Wà Lẹ́yìn Ikú Bí?
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Orisun Àrà-ọ̀tọ̀ Ti Ọgbọn Ti O Ga Ju
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • Èrò Náà Wọnú Ẹ̀sìn Àwọn Júù, Kirisẹ́ńdọ̀mù, àti Ìsìláàmù
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
Àwọn Míì
Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
ie ojú ìwé 17-18

Ibi Tí A Lè Yíjú sí fún Ìdáhùn

“Àbá èrò orí ti ìjìyà àìnípẹ̀kun kò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tí ó dá. . . . Láti gbà gbọ́ pé ìjìyà ayérayé ń bẹ fún ọkàn tìtorí àwọn àṣìṣe ọdún mélòó kan, láìní fún un ní àyè láti ṣàtúnṣe, lòdì sí gbogbo ìrònú tí ó bọ́gbọ́n mu.”—NIKHILANANDA, ỌLỌ́GBỌ́N ÈRÒ ORÍ TI Ẹ̀SÌN HÍŃDÙ.

1, 2. Lójú ìwòye onírúurú ìgbàgbọ́ tí ó wà nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú, àwọn ìbéèrè wo ni ó jẹyọ?

Ọ̀PỌ̀ lónìí, bí ti ọlọ́gbọ́n èrò orí ti ẹ̀sìn Híńdù náà, Nikhilananda, ni ẹ̀kọ́ ìdálóró ayérayé kò bá lára dé. Bẹ́ẹ̀ gan-an náà ni ó ṣe ṣòro fún àwọn mìíràn láti lóye èrò ti dídé ipò Nirvana àti wíwà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Tao.

2 Síbẹ̀, nítorí èrò náà pé ọkàn jẹ́ aláìleèkú, àwọn ẹ̀sìn ní Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀-Oòrùn ti gbé ọ̀wọ́ ìgbàgbọ́ nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú kalẹ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà tí ó tojú súni. Ó ha ṣeé ṣe láti mọ òtítọ́ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tí a bá kú bí? Ọkàn ha jẹ́ aláìleèkú lóòótọ́ bí? Ibo ni a lè yíjú sí fún ìdáhùn?

Sáyẹ́ǹsì àti Ọgbọ́n Èrò Orí

3. Sáyẹ́ǹsì àti ọ̀nà ìgbàṣe àyẹ̀wò ti sáyẹ́ǹsì ha rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú bí?

3 Sáyẹ́ǹsì tàbí ọ̀nà ìgbàṣe àyẹ̀wò ti sáyẹ́ǹsì ha rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú bí? Ní tìtorí ìrírí tí àwọn ènìyàn tí wọ́n sún mọ́ bèbè ikú tàbí tí wọ́n dá kú sọ, àwọn olùṣèwádìí kan ti gbìyànjú láti sọ ojú ìwòye tiwọn nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú. Nígbà tí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì náà, Hans Küng, ń ṣàtúnyẹ̀wò díẹ̀ lára ohun tí wọ́n sọ, nínú àwíyé rẹ̀ “Ikú Ha Jẹ́ Ọ̀nà Àtiwọnú Ìmọ́lẹ̀ Bí?,” ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àwọn ìrírí bí irú èyí kò fi ẹ̀rí ohunkóhun múlẹ̀ nípa pé ìwàláàyè ṣeé ṣe lẹ́yìn ikú: ohun tí ó kàn ṣẹlẹ̀ ní ìṣẹ́jú márùn-ún ṣáájú kí ikú tó dé ni, kì í ṣe ìwàláàyè ayérayé lẹ́yìn ikú.” Ó fi kún un pé: “Ọ̀ràn pé ó ṣeé ṣe láti wà láàyè lẹ́yìn ikú ṣe kókó gidigidi fún ìwàláàyè ṣáájú kíkú. Ó ń béèrè ìdáhùn kan tí a ní láti wá lọ sí ibòmíràn bí àwọn oníṣègùn kò bá lè fi fúnni.”

4. Ǹjẹ́ ọgbọ́n èrò orí lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn láàárín onírúurú àlàyé tí àwọn ẹ̀sìn lónírúurú ti ṣe nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú bí?

4 Ọgbọ́n èrò orí ńkọ́? Ṣé ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn láàárín onírúurú àlàyé tí àwọn ẹ̀sìn lónírúurú ti ṣe nípa pé ìwàláàyè lẹ́yìn ikú ṣeé ṣe bí? Bertrand Russell, ọlọ́gbọ́n èrò orí ọmọ ilẹ̀ Britain, sọ pé “ọ̀ràn bí ká méfòó” máa ń wà nínú àwárí ti ọgbọ́n èrò orí. Ọgbọ́n èrò orí, gẹ́gẹ́ bí ìwé agbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣe wí, jẹ́ “irú ọ̀nà ìṣèwádìí kan—ọ̀nà ìgbàṣe àgbéyẹ̀wò, ká ṣe lámèyítọ́, kí a wá ìtumọ̀ sí i, kí a sì méfòó.” Lórí ọ̀ràn ti Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú, ìméfòó yàtọ̀ síra látorí ká pe àìleèkú ní ohun tí a kàn dàníyàn pé kó ṣẹ dórí pípè é ní ogún ìbí gbogbo ènìyàn.

Orísun Aláìlẹ́gbẹ́ fún Ìdáhùn

5. Ìwé wo ni ó lọ́jọ́ lórí jù lọ nínú gbogbo ìwé tí a tíì kọ rí?

5 Àmọ́ ṣá o, ìwé kan wà tí ìdáhùn tòótọ́ sí àwọn ìbéèrè nípa ìwàláàyè àti ikú wà nínú rẹ̀. Òun ni ìwé tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ nínú gbogbo ìwé tí a tíì kọ rí níwọ̀n bí a ti ṣàkójọ apá kan lára rẹ̀ ní nǹkan bí 3,500 ọdún sẹ́yìn. A ti kọ apá àkọ́kọ́ ìwé yìí ní ọ̀rúndún mélòó kan ṣáájú kí a tó gbé àkọ́kọ́ pàá nínú orin ìsìn ti ìwé mímọ́ Híńdù náà, Veda, kalẹ̀ àti ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí Búdà, Mahāvīra àti Confucius tó dé ayé. A parí ìwé yìí ní ọdún 98 Sànmánì Tiwa, tí ó ju 500 ọdún ṣáájú kí Mọ̀ọ́mọ́dù tó dá ẹ̀sìn Ìsìláàmù sílẹ̀. Orísun aláìlẹ́gbẹ́ fún ọgbọ́n gíga jù lọ yìí ni Bíbélì.a

6. Èé ṣe tí a fi lè retí pé kí Bíbélì sọ ohun tí ọkàn jẹ́ fún wa?

6 Nínú gbogbo ìwé tí ń bẹ láyé, Bíbélì ni ó ní ìtàn ìgbàanì tí ó péye jù lọ nínú. Ìtàn tí a kọ sínú Bíbélì lọ jìnnà sẹ́yìn sí ìbẹ̀rẹ̀ ìdílé ẹ̀dá ènìyàn, ó sì ṣàlàyé bí a ṣe dé ayé. Àkọsílẹ̀ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí a tó dá ènìyàn tilẹ̀ wà nínú rẹ̀. Ní tòótọ́, irú ìwé kan bẹ́ẹ̀ lè fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye nípa bí a ṣe dá ènìyàn àti ohun tí ọkàn jẹ́.

7, 8. Èé ṣe tí a fi lè fi ìdánilójú yíjú sí Bíbélì fún àwọn ìdáhùn tòótọ́ tí ó sì tẹ́ni lọ́rùn nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tí a bá kú?

7 Síwájú sí i, Bíbélì jẹ́ ìwé tí a kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ sí, tí wọ́n sì ṣẹ láìyingin. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ ìdìde àti ìṣubú ilẹ̀ ọba Médíà òun Páṣíà àti ti Gíríìsì. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àwọn aṣelámèyítọ́ kan fi gbìyànjú, lórí asán, láti fi hàn pé ṣe ni a kọ wọ́n lẹ́yìn tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn ti ṣẹlẹ̀. (Dáníẹ́lì 8:1-7, 20-22) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tí a kọ sínú Bíbélì ń ṣẹ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní àkókò tiwa yìí.b—Mátíù, orí 24; Máàkù, orí 13; Lúùkù, orí 21; 2 Tímótì 3:1-5, 13.

8 Kò sí ènìyàn náà, bí ó ti wù kí ó jẹ́ onílàákàyè tó, tí ó lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la lọ́nà pípéye bẹ́ẹ̀. Ẹlẹ́dàá àgbáyé, Olódùmarè àti ọlọ́gbọ́n gbogbo nìkan ni ó lè ṣe bẹ́ẹ̀. (2 Tímótì 3:16, 17; 2 Pétérù 1:20, 21) Ìwé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì jẹ́ lóòótọ́. Dájúdájú, irú ìwé bẹ́ẹ̀ lè fún wa ní àwọn ìdáhùn tòótọ́ tí ó sì tẹ́ni lọ́rùn, nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tí a bá kú. Ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ wo ohun tí ó sọ nípa ọkàn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

b Wo ìwé The Bible—God’s Word or Man’s?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ìwé tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ nínú gbogbo ìwé tí a tíì kọ rí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ìwé tí ó fúnni ní àwọn ìdáhùn tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀ tí ó sì tẹ́ni lọ́rùn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́