ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • dp orí 18 ojú ìwé 306-319
  • Jèhófà Ṣèlérí Èrè Àgbàyanu fún Dáníẹ́lì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Ṣèlérí Èrè Àgbàyanu fún Dáníẹ́lì
  • Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “MÁA LỌ SÍHÀ ÒPIN”
  • FÍFARADÀ Á GẸ́GẸ́ BÍ ÀKẸ́KỌ̀Ọ́ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
  • DÁNÍẸ́LÌ FORÍ TÌ Í NÍNÚ ÀDÚRÀ
  • FÍFARADÀ Á GẸ́GẸ́ BÍ OLÙKỌ́NI NÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
  • ‘ÌWỌ YÓÒ SINMI’
  • “ÌWỌ YÓÒ DÌDE”
  • ÌPÍN DÁNÍẸ́LÌ NÍNÚ PÁRÁDÍSÈ ÀTI ÌPÍN TÌRẸ!
  • Ońṣẹ́ kan Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún un Lókun
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Ìwé Dáníẹ́lì àti Ìwọ
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Dáníẹ́lì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Bìkítà Nípa Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
dp orí 18 ojú ìwé 306-319

Orí Kejìdínlógún

Jèhófà Ṣèlérí Èrè Àgbàyanu fún Dáníẹ́lì

1, 2. (a) Ànímọ́ pàtàkì wo ni eléré ìje kan nílò láti lè ṣàṣeyọrí? (b) Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìgbésí ayé oníṣòtítọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà wé eré ìje?

ELÉRÉ ìje kan ti fẹ́rẹ̀ẹ́ sáré rẹ̀ dópin. Okun rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán pátápátá, àmọ́, níwọ̀n bí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin eré ìje rẹ̀, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ dé góńgó lórí ìwọ̀nba díẹ̀ tó kù. Nípa sísakun tagbáratágbara, ó sá eré náà dópin! Ojú rẹ̀ wálẹ̀ wàyí, ó ti yege. Ìfaradà tó lò títí dópin já sí èrè fún un.

2 Ní òpin orí kejìlá ìwé Dáníẹ́lì, a rí i pé wòlíì olùfẹ́ náà ń sún mọ́ òpin “eré ìje” tirẹ̀, ìyẹn lílò tí ó ń lo ìgbésí ayé rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti tọ́ka sí onírúurú àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti wà ṣáájú àkókò àwọn Kristẹni, ó kọ̀wé pé: “Nípa báyìí, nítorí tí a ní àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yí wa ká, ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn, ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa, bí a ti tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù. Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.”—Hébérù 12:1, 2.

3. (a) Kí ní sún Dáníẹ́lì láti “fi ìfaradà sá eré ìje” rẹ̀? (b) Àwọn ohun mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wo ni áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Dáníẹ́lì?

3 Dáníẹ́lì wà lára “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” yẹn. Dájúdájú, ó jẹ́ ẹnì kan tí ó ní láti “fi ìfaradà sá eré ìje,” ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí ó ní fún Ọlọ́run ni ó sì sún un láti lè ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà ti ṣí ohun púpọ̀ payá fún Dáníẹ́lì nípa ọjọ́ iwájú àwọn ìjọba ayé, àmọ́, nísinsìnyí, Ó wá fi ọ̀rọ̀ ìṣírí ti Dáníẹ́lì fúnra rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, pé: “Ní ti ìwọ fúnra rẹ, máa lọ síhà òpin; ìwọ yóò sì sinmi, ṣùgbọ́n ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.” (Dáníẹ́lì 12:13) Ohun mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni áńgẹ́lì Jèhófà ń sọ fún Dáníẹ́lì: (1) pé kí Dáníẹ́lì “máa lọ síhà òpin,” (2) pé yóò “sinmi,” àti (3) pé “yóò dìde” lẹ́ẹ̀kan sí i lọ́jọ́ kan tí ń bọ̀ níwájú. Báwo ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yóò ṣe fún àwọn Kristẹni tòní níṣìírí láti forí tì í dópin eré ìje wọn fún ìyè?

“MÁA LỌ SÍHÀ ÒPIN”

4. Kí ni áńgẹ́lì Jèhófà ní lọ́kàn tí ó fi sọ pé “máa lọ síhà òpin,” èé sì ti ṣe tí ìyẹn fi ní láti jẹ́ ìpèníjà fún Dáníẹ́lì?

4 Kí ni áńgẹ́lì náà ní lọ́kàn tí ó fi sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ní ti ìwọ fúnra rẹ, máa lọ síhà òpin”? Òpin kí ni? Wàyí o, níwọ̀n bí Dáníẹ́lì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, ó jọ pé òpin ìgbésí ayé rẹ̀, tí ó dà bí pé ó kù sí dẹ̀dẹ̀, ni èyí ń tọ́ka sí.a Ṣe ni áńgẹ́lì yìí ń rọ Dáníẹ́lì láti fara dà á nínú ìṣòtítọ́ títí dójú ikú. Ṣùgbọ́n, èyí kò túmọ̀ sí pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò rọrùn. Dáníẹ́lì ti fojú rí i pé a gba ìjọba Bábílónì, àṣẹ́kù àwọn Júù tí ó wà nígbèkùn sì ti padà sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù. Ìyẹn ti ní láti fún wòlíì arúgbó náà láyọ̀. Àmọ́ ṣá, kò sí ẹ̀rí tí ó fi hàn pé ó bá wọn lọ. Ó ṣeé ṣe kí ó ti darúgbó kùjọ́kùjọ́ nígbà yẹn. Tàbí bóyá ńṣe ni Jèhófà fẹ́ kí ó ṣì wà ní Bábílónì. Bí ó ti wù kí ó jẹ́, a kò ní ṣàì máa dà á rò pé bóyá ni àárò kò ní máa sọ Dáníẹ́lì bákan ṣá, bí àwọn ará ìlú rẹ̀ ṣe ń lọ sí Júdà.

5. Ẹ̀rí wo ni ó fi hàn pé Dáníẹ́lì fara dà á dópin?

5 Ó dájú pé ńṣe ni eegun Dáníẹ́lì yóò tún le sí i látàrí ọ̀rọ̀ atura tí áńgẹ́lì yìí sọ fún un pé: “Máa lọ síhà òpin.” Ó lè mú wa rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi sọ ní nǹkan bí ọ̀rúndún mẹ́fà lẹ́yìn náà pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:13) Ó dájú pé ohun tí Dáníẹ́lì ṣe nìyẹn. Ó fara dà á dé òpin, ní fífi ìṣòtítọ́ sáré ìje ìyè náà dé ìparí rẹ̀ kokoko. Ìyẹn lè jẹ́ ìdí tí a fi sọ̀rọ̀ dáadáa nípa rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Hébérù 11:32, 33) Kí ní jẹ́ kí Dáníẹ́lì lè fara dà á dópin? Àkọsílẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ pèsè ìdáhùn fún wa.

FÍFARADÀ Á GẸ́GẸ́ BÍ ÀKẸ́KỌ̀Ọ́ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

6. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Dáníẹ́lì jẹ́ ẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójú méjèèjì?

6 Ní ti Dáníẹ́lì, fífara dà á dé òpin so pọ̀ mọ́ bíbá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣe àṣàrò jinlẹ̀jinlẹ̀ nínú àwọn ìlérí amárayágágá tí Ọlọ́run ṣe. A mọ̀ pé Dáníẹ́lì jẹ́ ẹni tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójú méjèèjì. Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, báwo ni òun ì bá ṣe mọ̀ pé Jèhófà ṣèlérí fún Jeremáyà pé àádọ́rin ọdún ni àwọn yóò lò ní ìgbèkùn? Dáníẹ́lì alára kọ̀wé pé: “Èmi . . . fi òye mọ̀ láti inú ìwé, iye ọdún [náà].” (Dáníẹ́lì 9:2; Jeremáyà 25:11, 12) Láìsí àní àní, ńṣe ni Dáníẹ́lì wá àwọn ìwé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó wà lọ́wọ́ nígbà náà kàn. Ó dájú pé àwọn ìwé Mósè, Dáfídì, Sólómọ́nì, Aísáyà, Jeremáyà, Ìsíkíẹ́lì—èyíkéyìí tọ́wọ́ Dáníẹ́lì bá sáà ti tẹ̀—àkàgbádùn ló máa ń kà á, tí á sì máa ṣàṣàrò lé e lórí fún ọ̀pọ̀ wákàtí.

7. Tí a bá fi ìgbà tiwa wé ìgbà ti Dáníẹ́lì, àwọn àǹfààní wo ni a ní nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

7 Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fífi ara wa fún un pátápátá, ṣe pàtàkì gidigidi kí a bàa lè ní ànímọ́ ìfaradà lónìí. (Róòmù 15:4-6; 1 Tímótì 4:15) A sì ní odindi Bíbélì lọ́wọ́, tí ó ní àkọsílẹ̀ tí ó sọ nípa bí àwọn kan lára àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣe ní ìmúṣẹ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn tí a ti kọ wọ́n. Síwájú sí i, ó tún jẹ́ ìbùkún fún wa pé a ń gbé ní “àkókò òpin,” tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 12:4. Lọ́jọ́ tiwa, a fi ìjìnlẹ̀ òye tẹ̀mí jíǹkí àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n fi ń tan iná òtítọ́ jáde yàà bí iná atọ́nisọ́nà nínú ayé tí ó ṣókùnkùn biribiri yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, púpọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ jíjinlẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì, tí díẹ̀ nínú wọn ta kókó lójú Dáníẹ́lì, kún fún ìtumọ̀ fún wa lónìí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kí a má fojú yẹpẹrẹ wo nǹkan wọ̀nyí láé. Ìyẹn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á.

DÁNÍẸ́LÌ FORÍ TÌ Í NÍNÚ ÀDÚRÀ

8. Àpẹẹrẹ wo ni Dáníẹ́lì fi lélẹ̀ ní ti àdúrà gbígbà?

8 Àdúrà tún ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ pẹ̀lú láti fara dà á dé òpin. Ó máa ń yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run lójoojúmọ́, ó ń bá a sọ̀rọ̀ láti inú ọkàn tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti ìgbọ́kànlé. Ó mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2; fi wé Hébérù 11:6.) Nígbà tí ẹ̀dùn ọkàn bá Dáníẹ́lì nítorí bí Ísírẹ́lì ṣe ń bá ọ̀nà ìṣọ̀tẹ̀ lọ, ó sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ jáde fún Jèhófà. (Dáníẹ́lì 9:4-19) Kódà, nígbà tí Dáríúsì pàṣẹ pé òun nìkan ṣoṣo ni kí wọ́n máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí fún ọgbọ̀n ọjọ́, Dáníẹ́lì kò jẹ́ kí ìyẹn dá òun dúró lẹ́nu àdúrà gbígbà sí Jèhófà Ọlọ́run. (Dáníẹ́lì 6:10) Ara wa kò ha bù máṣọ bí a ṣe ń fojú inú wo arúgbó ọkùnrin náà tí ó gbà láti lọ sínú ihò kìnnìún dípò kí ó jáwọ́ nínú àdúrà gbígbà tí ó jẹ́ àǹfààní iyebíye? Kò sí iyèméjì rárá pé Dáníẹ́lì fi ìṣòtítọ́ lọ sí òpin rẹ̀, ní gbígba àdúrà kíkankíkan sí Jèhófà lójoojúmọ́.

9. Èé ṣe tí a kò fi gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àǹfààní àdúrà gbígbà?

9 Àdúrà gbígbà rọrùn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìgbàkigbà ni a lè gbàdúrà, níbikíbi, ìbáà jẹ́ sókè tàbí sínú. Ṣùgbọ́n, kí a má rí i láé pé a fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àǹfààní yìí. Bíbélì sọ pé àdúrà ní í ṣe pẹ̀lú ìfaradà, ìforítì, àti ìwàlójúfò nípa tẹ̀mí. (Lúùkù 18:1; Róòmù 12:12; Éfésù 6:18; Kólósè 4:2) Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun iyebíye ni pé a lè bá ẹni gíga jù lọ lágbàáyé sọ̀rọ̀ fàlàlà? Ó sì máa ń gbọ́ wa! Rántí ìgbà kan tí Dáníẹ́lì gbàdúrà tí Jèhófà sì dáhùn nípa rírán áńgẹ́lì sí i. Dáníẹ́lì ṣì ń gbàdúrà yẹn lọ́wọ́ ni áńgẹ́lì náà ti dé! (Dáníẹ́lì 9:20, 21) Áńgẹ́lì lè má yọ síni lọ́nà bẹ́ẹ̀ nígbà tiwa yìí, àmọ́ Jèhófà kò yí padà. (Málákì 3:6) Gan-an bí ó ṣe gbọ́ àdúrà Dáníẹ́lì, yóò gbọ́ tiwa náà. Bí a sì ṣe ń gbàdúrà, a óò túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́ sí i, ìdè ọ̀rẹ́ tí a óò ní pẹ̀lú rẹ̀ yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á dópin, gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì ti ṣe.

FÍFARADÀ Á GẸ́GẸ́ BÍ OLÙKỌ́NI NÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

10. Èé ṣe tí fífi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni fi ṣe pàtàkì fún Dáníẹ́lì?

10 Ní ìtumọ̀ mìíràn, Dáníẹ́lì ní láti “máa lọ síhà òpin.” Ó ní láti fara dà á gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní òtítọ́. Kò jẹ́ gbàgbé pé òun wà lára àwọn àyànfẹ́ ènìyàn tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa wọn pé: “‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn.’” (Aísáyà 43:10) Dáníẹ́lì sa gbogbo agbára rẹ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ nídìí iṣẹ́ tí a gbé lé wọn lọ́wọ́ yìí. Ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ rẹ̀ kan kíkọ́ àwọn ènìyàn tirẹ̀ tí wọ́n wà nígbèkùn ní Bábílónì. A kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, yàtọ̀ sí èyí tí ó kan àwọn mẹ́ta tí a pè ní “àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀,” ìyẹn Hananáyà, Míṣáẹ́lì, àti Asaráyà. (Dáníẹ́lì 1:7; 2:13, 17, 18) Ó dájú pé jíjẹ́ tí wọ́n jùmọ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ṣèrànwọ́ púpọ̀ fún olúkúlùkù wọn láti ní ìfaradà. (Òwe 17:17) Ohun púpọ̀ ni Dáníẹ́lì, tí Jèhófà fi àkànṣe ìjìnlẹ̀ òye jíǹkí, yóò ní láti fi kọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Dáníẹ́lì 1:17) Àmọ́, ohun mìíràn ń bẹ nílẹ̀ fún un láti tún fi kọ́ni.

11. (a) Kí ló jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú iṣẹ́ Dáníẹ́lì? (b) Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe ṣe dáadáa tó lẹ́nu iṣẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí a yàn fún un?

11 Iṣẹ́ Dáníẹ́lì ni láti jẹ́rìí fún àwọn ẹni jàǹkàn-jàǹkàn nínú àwọn Kèfèrí, lọ́nà tí ó tayọ ti àwọn wòlíì mìíràn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní láti jẹ́ àwọn iṣẹ́ kan tí kò báradé, kò hùwà sí àwọn aláṣẹ wọ̀nyí bíi pé wọ́n jẹ́ ẹni ìríra, kò sì fojú tín-ínrín wọn. Ó fi òye bá wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àwọn kan wá—irú bí àwọn òjòwú baálẹ̀ elétekéte—tí wọ́n fẹ́ gbẹ̀mí Dáníẹ́lì. Síbẹ̀, àwọn ẹni jàǹkàn-jàǹkàn mìíràn wá ń bọ̀wọ̀ fún Dáníẹ́lì. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ kí Dáníẹ́lì lè ṣàlàyé àwọn àṣírí tó jẹ́ àdììtú fún àwọn ọba àti àwọn ọlọ́gbọ́n, ni wòlíì yìí bá di olókìkí. (Dáníẹ́lì 2:47, 48; 5:29) Lóòótọ́, bí ó ṣe ń darúgbó sí i, ara rẹ̀ kò lè gbé kánkán bí ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó dájú pé, títí ó fi dé òpin ayé rẹ̀, kò yéé fi ìṣòtítọ́ wọ́nà láti sìn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí Ọlọ́run rẹ̀ tí ó fẹ́ràn gidigidi.

12. (a) Ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìkọ́ni wo ni àwa Kristẹni ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀ lónìí? (b) Báwo ni a ṣe lè fi ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tí ó sọ sílò pé kí a “máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n sí àwọn tí ń bẹ lóde”?

12 Nínú ìjọ Kristẹni lónìí, a lè rí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lè ní ìfaradà, gan-an bí Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe ran ara wọn lọ́wọ́ lẹ́nì kìíní-kejì. A sì tún ń kọ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, tí a ń fún ara wa ní “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.” (Róòmù 1:11, 12) Gẹ́gẹ́ bíi Dáníẹ́lì, a yanṣẹ́ fún wa pé kí a jẹ́rìí fún àwọn aláìgbàgbọ́. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Nítorí náà, a ní láti mú kí òye iṣẹ́ wa dán mọ́rán gidigidi kí a bàa lè “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́” nígbà tí a bá ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. (2 Tímótì 2:15) Yóò sì dára bí a bá ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí ó sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n sí àwọn tí ń bẹ lóde.” (Kólósè 4:5) Irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ kan níní ojú ìwòye tí ó tọ́ nípa àwọn tí kò fara mọ́ ẹ̀sìn tiwa. A kò ní fojú tín-ínrín irú àwọn bẹ́ẹ̀, kí a sì ka ara wa sí ẹni tí ó ṣe pàtàkì jù wọ́n lọ. (1 Pétérù 3:15) Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò wọ́nà láti fi ojú wọn mọ òtítọ́ nípa fífọgbọ́n lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà olóye láti lè dénú ọkàn wọn. Nígbà tí a bá sì lè dénú ọkàn ẹnì kan, ẹ wo bí ìdùnnú wa ṣe máa ń pọ̀ tó! Dájúdájú, irú ìdùnnú bẹ́ẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á dópin, gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì ti ṣe.

‘ÌWỌ YÓÒ SINMI’

13, 14. Èé ṣe tí èrò náà pé àwọn yóò kú fi lè kó jìnnìjìnnì bá ọ̀pọ̀ àwọn ará Bábílónì, báwo sì ni ojú ìwòye ti Dáníẹ́lì ṣe yàtọ̀?

13 Áńgẹ́lì náà wá mú un dá Dáníẹ́lì lójú pé: “Ìwọ yóò . . . sinmi.” (Dáníẹ́lì 12:13) Kí ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí? Tóò, Dáníẹ́lì mọ̀ pé ikú òun ti dé tán. Láti ìgbà Ádámù títí di ọjọ́ wa, kò sí ẹni tí ó tíì mú ikú jẹ rí. Lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú, Bíbélì pe ikú ní “ọ̀tá.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Àmọ́, ojú tí Dáníẹ́lì fi ń wo ọ̀ràn pé ikú dé tán yàtọ̀ pátápátá sí ojú tí gbogbo àwọn ará Bábílónì tí ó yí i ká fi ń wò ó. Lójú tiwọn, àwọn ẹni tó jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin èké ọlọ́run àjúbàfún ni wọ́n ń jọ́sìn lọ́nà ìjọsìn tí ó lọ́jú pọ̀, ikú jẹ́ àkókò láti fojú winá onírúurú ohun ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀. Wọ́n gbà gbọ́ pé lẹ́yìn ikú, ńṣe ni àwọn tí nǹkan kò bá fara rọ fún lọ́jọ́ ayé wọn tàbí àwọn tó bá kú ikú gbígbóná máa ń di àkúdàáyà tí wọn yóò sì máa kó àwọn alààyè sí ìyọnu. Àwọn ará Bábílónì sì gbà gbọ́ pé ayé àwọn òkú wà, níbi tí àwọn òǹrorò abàmì ẹ̀dá lónírúurú ń gbé, òmíràn á rí bí ènìyàn, òmíràn á dà bí ẹranko.

14 Lójú Dáníẹ́lì, kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ nípa ikú. Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ọjọ́ Dáníẹ́lì, Ọlọ́run ti mí sí Sólómọ́nì Ọba láti sọ pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Ní ti àwọn tí wọ́n sì kú, onísáàmù ti kọ ọ́ lórin pé: “Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” (Sáàmù 146:4) Nítorí náà, Dáníẹ́lì mọ̀ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì náà ń bá òun sọ yóò já sí. Ìsinmi ni ikú jẹ́. Kò sí inú rírò, kò sí ti pé à ń kábàámọ̀ kíkorò, kò sí ìdálóró—ó sì dájú pé kò sí àwọn òǹrorò abàmì ẹ̀dá níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù Kristi ṣe sọ nígbà tí Lásárù kú. Ó sọ pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi.”—Jòhánù 11:11.

15. Báwo ni ọjọ́ ikú ṣe lè sàn ju ọjọ́ tí a bíni?

15 Gbé ìdí mìíràn yẹ̀ wò tí mímọ̀ pé ikú dé tán kò fi kó jìnnìjìnnì bá Dáníẹ́lì. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Orúkọ sàn ju òróró dáradára, ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.” (Oníwàásù 7:1) Báwo ni ọjọ́ ikú, tó jẹ́ ọjọ́ ọ̀fọ̀, bí a bá tilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ẹni yẹn rárá, ṣe lè sàn ju ọjọ́ ayọ̀ tí a bíni lọ? Orí “orúkọ” ni ọ̀ràn náà dá lé. “Òróró dáradára” lè wọ́n gógó. Owó òróró onílọ́fínńdà tí Màríà arábìnrin Lásárù fi kun ẹsẹ̀ Jésù nígbà kan rí tó owó iṣẹ́ ọdún kan! (Jòhánù 12:1-7) Báwo ni orúkọ kan lásán ṣe lè ṣeyebíye tó bẹ́ẹ̀? Nínú Oníwàásù 7:1, Bíbélì Septuagint ti Gíríìkì sọ pé, “orúkọ rere.” Kì í kàn í ṣe orúkọ yẹn bí kò ṣe ohun tí ó dúró fún, ni ó ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀. Lọ́jọ́ tí a bá bí ènìyàn, kò tí ì sí ohun òkìkí, kò sí àkọsílẹ̀ iṣẹ́ rere, kò sí ìwà tàbí ànímọ́ rere tí a tíì lè fi rántí ẹni náà. Ṣùgbọ́n nígbà ikú, gbogbo ìwọ̀nyí ni orúkọ yẹn máa dúró fún. Bó bá sì jẹ́ orúkọ rere lójú Ọlọ́run, ó tún ṣeyebíye gan-an ju bí ohun ìní èyíkéyìí ṣe lè jẹ́ lọ.

16. (a) Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe gbìyànjú láti ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run? (b) Èé ṣe tí Dáníẹ́lì fi lè lọ sinmi tòun ti ìdánilójú pé òun ti kẹ́sẹ járí ní ti níní orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà?

16 Dáníẹ́lì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣe orúkọ rere fún ara rẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, Jèhófà kò sì gbójú fo èyíkéyìí nínú wọn. Ó kíyè sí Dáníẹ́lì, ó sì yẹ ọkàn-àyà rẹ̀ wò. Bẹ́ẹ̀ gan-an náà ni Ọlọ́run ti ṣe fún Dáfídì Ọba, ẹni tí ó kọrin pé: “Jèhófà, ìwọ ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, ìwọ sì mọ̀ mí. Ìwọ alára ti wá mọ jíjókòó mi àti dídìde mi. Ìwọ ti gbé ìrònú mi yẹ̀ wò láti ibi jíjìnnàréré.” (Sáàmù 139:1, 2) Lóòótọ́, Dáníẹ́lì kì í ṣe ẹni pípé. Àtọmọdọ́mọ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀ ni, ó sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 3:23) Ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó ń gbìyànjú ní bíbá Ọlọ́run rìn lọ́nà ìwà títọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè dá wòlíì olùṣòtítọ́ náà lójú pé Jèhófà yóò dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ òun jì, kò sì ní kà wọ́n sí òun lọ́rùn láé. (Sáàmù 103:10-14; Aísáyà 1:18) Jèhófà yàn láti rántí àwọn iṣẹ́ rere àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́. (Hébérù 6:10) Nípa báyìí, ẹ̀ẹ̀mejì ni áńgẹ́lì Jèhófà pe Dáníẹ́lì ní “ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.” (Dáníẹ́lì 10:11, 19) Èyí túmọ̀ sí pé Dáníẹ́lì jẹ́ ààyò fún Ọlọ́run. Wàyí o, Dáníẹ́lì lè lọ fi ìfọ̀kànbalẹ̀ sinmi, ní mímọ̀ pé òun ti lórúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà.

17. Èé ṣe tí ó fi jẹ́ kánjúkánjú pé kí a ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà lónìí?

17 Olúkúlùkù lè wá béèrè pé, ‘Mo ha ti lórúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà bí?’ Àkókò oníhílàhílo ni a ń gbé. Láti gbà pé ìgbàkigbà ni ikú lè pani kì í ṣe ìbẹ̀rùbojo bí kò ṣe pé ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. (Oníwàásù 9:11) Ó mà ṣe pàtàkì gan-an o, pé kí olúkúlùkù wa lórúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run nísinsìnyí gan-an, láìjáfara. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò tún sídìí fún wa láti bẹ̀rù ikú mọ́. Ìsinmi lásán ni—bí oorun sísùn. Bí ó sì ṣe máa ń rí ní ti oorun sísùn, ó dájú pé a óò jí!

“ÌWỌ YÓÒ DÌDE”

18, 19. (a) Kí ni áńgẹ́lì náà ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Dáníẹ́lì yóò “dìde” lọ́jọ́ iwájú? (b) Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé Dáníẹ́lì ti lè mọ̀ nípa ìrètí àjíǹde?

18 Ọ̀kan nínú àwọn ìlérí dídára jù lọ tí Ọlọ́run tíì ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn rí ni ó parí ìwé Dáníẹ́lì. Áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.” Kí ni áńgẹ́lì náà ní lọ́kàn? Ó dára, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ikú ni “ìsinmi” tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kàn tán yìí, ohun kan ṣoṣo ni ìlérí náà pé Dáníẹ́lì yóò “dìde” nígbà tí ó bá yá lè túmọ̀ sí—èyíinì ni àjíǹde!b Ní ti gidi, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan kéde pé inú ìwé Dáníẹ́lì orí kejìlá ni a ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde lọ́nà tí ó ṣe kedere nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. (Dáníẹ́lì 12:2) Àmọ́ ṣá, wọ́n kùnà ní ti èyí. Dáníẹ́lì mọ̀ nípa ìrètí àjíǹde dáadáa.

19 Bí àpẹẹrẹ, ó dájú pé Dáníẹ́lì mọ ọ̀rọ̀ Aísáyà yìí, tí ó ti kọ ní ọ̀rúndún méjì ṣáájú ìgbà yẹn, pé: “Àwọn òkú rẹ yóò wà láàyè. Òkú tèmi—wọn yóò dìde. Ẹ jí, ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin olùgbé inú ekuru! Nítorí pé . . . ilẹ̀ ayé pàápàá yóò sì jẹ́ kí àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú pàápàá jáde wá nínú ìbímọ.” (Aísáyà 26:19) Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà fún Èlíjà òun Èlíṣà lágbára láti mú kí àjíǹde gidi ṣẹlẹ̀. (1 Àwọn Ọba 17:17-24; 2 Àwọn Ọba 4:32-37) Kódà ṣáájú ìgbà yẹn, Hánà, ìyá Sámúẹ́lì wòlíì, gbà pé Jèhófà lè jí àwọn ènìyàn dìde kúrò nínú Ṣìọ́ọ̀lù tàbí sàréè. (1 Sámúẹ́lì 2:6) Àní ṣáájú ìyẹn pàápàá, Jóòbù olùṣòtítọ́ fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sọ ìrètí tirẹ̀ jáde pé: “Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí? Jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ òpò tí mo ní láti ṣe lápàpàǹdodo ni èmi yóò fi dúró, títí ìtura mi yóò fi dé. Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”—Jóòbù 14:14, 15.

20, 21. (a) Nínú àjíǹde wo ni ó dájú pé Dáníẹ́lì yóò ti nípìn-ín? (b) Ọ̀nà wo ni ó ṣeé ṣe kí àjíǹde gbà ṣẹlẹ̀ nínú Párádísè?

20 Bíi ti Jóòbù, ìdí wà fún Dáníẹ́lì láti ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò ṣàfẹ́rí òun ní ti gidi láti mú òun padà wá sí ìyè lọ́jọ́ kan lọ́jọ́ iwájú. Síbẹ̀ náà, ìtùnú ńláǹlà ni ó ti ní láti jẹ́ láti gbọ́ tí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára kan ń mú kí ìrètí yẹn túbọ̀ dájú sí i. Dájúdájú, Dáníẹ́lì yóò dìde dúró nígbà “àjíǹde àwọn olódodo” tí yóò ṣẹlẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. (Lúùkù 14:14) Báwo ni ìyẹn yóò ṣe rí fún Dáníẹ́lì? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nǹkan púpọ̀ fún wa nípa rẹ̀.

21 Jèhófà “kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.” (1 Kọ́ríńtì 14:33) Nígbà náà, ó dájú pé àjíǹde nínú Párádísè yóò ṣẹlẹ̀ létòlétò. Bóyá yóò jẹ́ ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16) A óò ti palẹ̀ gbogbo ràlẹ̀rálẹ̀ ètò ògbólógbòó yìí mọ́ kúrò, ó sì dájú pé a óò ti ṣe àwọn ètò tí a óò fi lè tẹ́wọ́ gba àwọn òkú tí a jí dìde. Ní ti bí a óò ṣe jí àwọn òkú dìde tẹ̀léra tẹ̀léra, Bíbélì ti fún wa ní àwòṣe pé: “Olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 15:23) Ó jọ pé ó ṣeé ṣe pé ní ti ọ̀ràn “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo,” àwọn olódodo ní a óò kọ́ jí dìde. (Ìṣe 24:15) Lọ́nà yìí, yóò lè ṣeé ṣe pé kí àwọn ẹni olùṣòtítọ́ ìgbàanì, bí Dáníẹ́lì, lè ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ àbójútó àlámọ̀rí ayé, títí kan pípèsè ìtọ́ni fún àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ “àwọn aláìṣòdodo” tí a óò mú padà wá sí ìyè.—Sáàmù 45:16.

22. Àwọn ìbéèrè wo ni ó dájú pé Dáníẹ́lì yóò hára gàgà láti gbọ́ ìdáhùn rẹ̀?

22 Ó dájú pé kí Dáníẹ́lì tó lè tẹ́wọ́ gba irú ẹrù iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, yóò ní àwọn ìbéèrè tí yóò fẹ́ béèrè. Ó ṣe tán, ó sọ nípa mélòó kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìjìnlẹ̀ tí a fi rán an pé: “Mo gbọ́, ṣùgbọ́n èmi kò lóye.” (Dáníẹ́lì 12:8) Ìwúrí ńláǹlà ni yóò jẹ́ fún un nígbà tí ó bá wá lóye àwọn àdììtú àtọ̀runwá náà nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín! Láìsí àní-àní, yóò fẹ́ láti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ nípa Mèsáyà. Yóò jẹ́ ìwúrí fún Dáníẹ́lì láti mọ̀ nípa bí àwọn agbára ayé ṣe ń dé ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ìgbà tirẹ̀ títí fi dé ìgbà tiwa, láti mọ àwọn olùṣòtítọ́ tí ó jẹ́ “àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ”—tí wọ́n forí tì í láìka inúnibíni sí ní “àkókò òpin”—àti láti mọ̀ nípa bí Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run ṣe pa gbogbo ìjọba ènìyàn run níkẹyìn.—Dáníẹ́lì 2:44; 7:22; 12:4.

ÌPÍN DÁNÍẸ́LÌ NÍNÚ PÁRÁDÍSÈ ÀTI ÌPÍN TÌRẸ!

23, 24. (a) Báwo ni ayé tí Dáníẹ́lì yóò rí pé a jí òun dìde sí yóò ṣe yàtọ̀ sí èyí tí ó mọ̀? (b) Dáníẹ́lì yóò ha ní àyè nínú Párádísè bí, báwo ni a sì ṣe mọ̀?

23 Dáníẹ́lì yóò fẹ́ láti mọ̀ nípa ayé tí yóò bá ara rẹ̀ nígbà náà—ayé kan tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ti ìgbà tirẹ̀. Àwọn ogun àti ìtẹ̀lóríba tí ó ba ayé tí ó mọ̀ jẹ́ yóò ti dàwátì. Kò ní sí ọ̀fọ̀, kò ní sí àìsàn, kò ní sí ikú. (Aísáyà 25:8; 33:24) Àmọ́, ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ, ilé gbígbé, àti iṣẹ́ tí ó máyọ̀ wá ni yóò wà fún gbogbo ènìyàn. (Sáàmù 72:16; Aísáyà 65:21, 22) Aráyé yóò jẹ́ ìdílé kan ṣoṣo tí ó wà níṣọ̀kan, tí ó sì láyọ̀.

24 Ó dájú pé Dáníẹ́lì yóò ní àyè kan nínú ayé yẹn. Áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “ìpín” níhìn-ín jẹ́ ọ̀rọ̀ kan náà tí a ń lò fún abá ilẹ̀ gidi.c Ó ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì ti mọ àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì dunjú nípa bí a óò ṣe pín ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí a mú bọ̀ sípò. (Ìsíkíẹ́lì 47:13–48:35) Ní ti ìmúṣẹ rẹ̀ nínú Párádísè, kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì fi hàn? Ìyẹn ni pé gbogbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run ni yóò ní àyè tiwọn nínú Párádísè, kódà a óò pín ilẹ̀ tìkára rẹ̀ létòlétò àti lọ́nà títọ́. Àmọ́ ṣá, ìpín Dáníẹ́lì nínú Párádísè yóò kan ohun tí ó ju ilẹ̀ nìkan lọ. Yóò kan àyè rẹ̀ nínú ète Ọlọ́run níbẹ̀. Èrè tí a ṣèlérí fún Dáníẹ́lì dájú.

25. (a) Àwọn ohun tí a lè wọ̀nà fún wo nípa ìgbésí ayé nínú Párádísè ni ó fà ọ́ mọ́ra? (b) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Párádísè gan-an ni ilé ènìyàn?

25 Ìpín tìrẹ wá ńkọ́? Ìlérí kan náà lè kàn ọ́. Ṣe ni Jèhófà ń fẹ́ kí àwọn ènìyàn onígbọràn “dìde” fún ìpín tiwọn, láti ní àyè tiwọn nínú Párádísè. Ṣá rò ó wò ná! Dájúdájú, yóò múni lórí yá gágá láti lọ pàdé Dáníẹ́lì fúnra rẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ mìíràn tí ń bẹ láyé nígbà tí a ń kọ Bíbélì. Bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òkú tí a ń jí dìde yóò wà tí wọ́n ń fẹ́ ìtọ́ni láti lè mọ Jèhófà Ọlọ́run kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Fojú inú wo ara rẹ̀ pé o ń ṣètọ́jú ilé ayé wa yìí, tí o ń ṣèrànwọ́ láti yí i padà di Párádísè tí ọ̀kẹ́ àìmọye onírúurú nǹkan ẹwà tí kì í ṣá láé yóò wà nínú rẹ̀. Ronú nípa bí o ṣe di ẹni tí Jèhófà ń kọ́, tí o ń kọ́ nípa ọ̀nà tí ó ń fẹ́ gan-an pé kí aráyé máa gbà gbé ìgbésí ayé. (Aísáyà 11:9; Jòhánù 6:45) Bẹ́ẹ̀ ni, àyè wà fún ọ nínú Párádísè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Párádísè lè jọ bí ohun àjèjì sí àwọn ènìyàn kan lónìí, rántí pé ńṣe ni Jèhófà ṣẹ̀dá aráyé láti gbé ní irú ibi bẹ́ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7-9) Nípa bẹ́ẹ̀, ibùgbé tí a dá fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ ẹ̀dá ènìyàn ni Párádísè jẹ́. Ibi tó jẹ́ tiwọn nìyẹn. Dídé inú Párádísè yóò dà bí ẹní lọ sílé.

26. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́rìí sí i pé dídúró de òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí kò rọrùn fún wa?

26 Ọkàn wa ń fi ìmọrírì yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bí a ṣe ń ronú nípa gbogbo èyí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? O kò ha ń hára gàgà láti wà níbẹ̀ bí? Abájọ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń hára gàgà láti mọ ìgbà tí òpin ètò àwọn nǹkan yìí yóò dé! Kò rọrùn láti kàn máa dúró dè é. Jèhófà pẹ̀lú jẹ́rìí sí i, nítorí ó rọ̀ wá pé kí a “máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà” fún àkókò òpin “bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀.” Ohun tí ó ń sọ ni pé, ó lè jọ pé ó falẹ̀ lójú tiwa, nítorí nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan náà, a mú un dá wa lójú pé: “Kì yóò pẹ́.” (Hábákúkù 2:3; fi wé Òwe 13:12.) Dájúdájú, òpin yóò dé lásìkò rẹ̀ gẹ́lẹ́.

27. Kí ni ó yẹ kí o ṣe láti lè dúró níwájú Ọlọ́run títí ayérayé?

27 Kí ló yẹ kí o ṣe bí òpin ṣe ń sún mọ́lé? Gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì, ààyò wòlíì Jèhófà, fi ìṣòtítọ́ fara dà á. Kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run taápọntaápọn. Gbàdúrà tìtaratìtara. Máa fi tìfẹ́tìfẹ́ bá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ kẹ́gbẹ́ pọ̀. Máa fi tìtaratìtara kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́. Bí òpin ètò àwọn nǹkan burúkú yìí ṣe ń sún mọ́lé lójoojúmọ́, rọ̀ mọ́ ìpinnu tí o ti ṣe láti jẹ́ olódodo ìránṣẹ́ Ọ̀gá Ògo, àti alágbàwí dídúróṣinṣin fún Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lọ́nàkọnà, kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! Ǹjẹ́ kí Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, sì fún ọ́ ní àǹfààní bíbá a lọ láti dúró níwájú rẹ̀ tayọ̀tayọ̀ títí láé fáàbàdà!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọdún 617 ṣááju Sànmánì Tiwa ni a mú Dáníẹ́lì lọ sígbèkùn ní Bábílónì, ó ṣeé ṣe kí ó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́langba nígbà náà. Ọdún kẹta ìjọba Kírúsì tàbí ọdún 536 ṣááju Sànmánì Tiwa ni a fi ìran yìí hàn án.—Dáníẹ́lì 10:1.

b Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Brown-Driver-Briggs Hebrew and English Lexicon ṣe wí, ọ̀rọ̀ Hébérù tí a lò fún “dìde” níhìn-ín ń tọ́ka sí “ìmúsọjí lẹ́yìn ikú.”

c Ọ̀rọ̀ Hébérù yẹn tan mọ́ “òkúta,” níwọ̀n bí a ti ń fi àwọn òkúta kéékèèké ṣẹ́ kèké. Nígbà mìíràn a máa ń lo ọ̀nà yìí láti fi pín ilẹ̀. (Númérì 26:55, 56) Ìwé Handbook on the Book of Daniel sọ pé níhìn-ín, ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí “ohun tí (Ọlọ́run) yàn sọ́tọ̀ fún ẹnì kan.”

KÍ LO LÓYE?

• Kí ló ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ láti fara dà á dópin?

• Èé ṣe tí èrò pé òun yóò kú kò fi ba Dáníẹ́lì lẹ́rù?

• Báwo ni a óò ṣe mú ìlérí áńgẹ́lì náà ṣẹ́ pé Dáníẹ́lì ‘yóò dìde fún ìpín tirẹ̀’?

• Báwo ni ìwọ alára ṣe jàǹfààní nípa kíkíyèsí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 307]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 318]

Ìwọ ha ń kíyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run bíi ti Dáníẹ́lì bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́