Àwọn Ọ̀nà Tí Wọ́n Ń Gbà Sọ Ìhìn Rere
ÀṢẸ tí àwọn Kristẹni gbà ni pé kí wọ́n “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kí wọ́n máa fínná mọ́ni tàbí kí wọ́n máa fi tipátipá yí àwọn èèyàn padà. Iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ ni pé kí wọ́n “sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù,” kí wọ́n “di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn,” kí wọ́n “tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.” (Mátíù 28:19; Aísáyà 61:1, 2; Lúùkù 4:18, 19) Ìyẹn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wá ọ̀nà àtiṣe nípa kíkéde ìhìn rere látinú Bíbélì. Bíi wòlíì Ìsíkíẹ́lì ayé àtijọ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ṣe ń gbìyànjú láti wá àwọn tí “ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí a ń ṣe.”—Ìsíkíẹ́lì 9:4.
Ọ̀nà tó hàn pé ó dára jù lọ tí wọ́n gbà ń wá àwọn tí ipò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ń bà nínú jẹ́ kàn ni láti máa lọ látilé délé. Wọ́n ń tipa báyìí ṣaápọn gidigidi láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́lẹ́ bí Jésù ti ṣe nígbà tó ‘ń rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, tó ń wàásù, tó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.’ Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí ṣe. (Lúùkù 8:1; 9:1-6; 10:1-9) Lóde òní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbìyànjú láti kàn sí ibùgbé kọ̀ọ̀kan lọ́pọ̀ ìgbà lọ́dún níbi tó bá ti ṣeé ṣe, tí wọ́n á máa wá ọ̀nà láti bá onílé jíròrò fún ìṣẹ́jú mélòó kan nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àdúgbò tàbí ní àgbáyé tí èèyàn bá nífẹ̀ẹ́ sí, tàbí téèyàn ń ṣàníyàn nípa rẹ̀. Wọ́n lè tọ́ka sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì fún àgbéyẹ̀wò, bí onílé bá sì fìfẹ́ hàn, Ẹlẹ́rìí yẹn lè ṣètò láti padà lọ síbẹ̀ lákòókò tó wọ̀, fún ìjíròrò síwájú sí i. Wọ́n máa ń fi Bíbélì àti ìwé tó ṣàlàyé lórí Bíbélì lọ onílé, wọ́n á sì kọ́ onílé lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ bó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tó wúlò yìí ni wọ́n ń ṣe déédéé káàkiri ayé yálà pẹ̀lú àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí àwọn ìdílé.
Ọ̀nà mìíràn tí wọ́n tún gbà ń sọ “ìhìn rere ìjọba” yìí fún ẹlòmíràn ni nínú àwọn ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń ṣe àwọn ìpàdé níbẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn ìpàdé yẹn jẹ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, ó sì máa ń dá lórí kókó ẹ̀kọ́ tí àwọn èèyàn ń fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀, lẹ́yìn náà, wọn yóò wá kẹ́kọ̀ọ́ lórí àkòrí ọ̀rọ̀ tàbí àsọtẹ́lẹ̀ kan látinú Bíbélì, inú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ni wọ́n ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́ ìyẹn. Ìpàdé mìíràn jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí ti ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ di ẹni tó ń kéde ìhìn rere náà lọ́nà tó já fáfá, lẹ́yìn èyí ni yóò kan apá tó dá lórí ìjíròrò nípa iṣẹ́ ìjẹ́rìí ládùúgbò. Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí tún ń pàdé pọ̀ ní àwùjọ kéékèèké lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ ní àwọn ilé àdáni, láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Gbogbo èèyàn ló lè wá sí àwọn ìpàdé wọ̀nyí. Wọn kì í dáwó igbá níbẹ̀ rárá. Gbogbo èèyàn ni àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn lè ṣe láǹfààní. Bíbélì sọ pé: “Ó yẹ kí á rí ọ̀nà tó dára jù lọ tí olúkúlùkù wa lè gbà ru ẹlòmíràn sókè sí ìfẹ́ àti iṣẹ́ rere ṣíṣe, kí a má máa pa ìpàdé jẹ, bí àwọn kan ti ń ṣe, kàkà bẹ́ẹ̀ kí á máa fún èkíní kejì wa níṣìírí, pàápàá bí ẹ ti rí i pé Ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣe ìwádìí fúnra ẹni ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n pípàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn a máa mórí yáni, nítorí: “Bí irin ṣe ń pọ́n irin mú féfé, bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ṣe máa pọ́n làákàyè ẹnì kejì rẹ̀ mú féfé.”—Hébérù 10:24, 25; Òwe 27:17, The New English Bible.
Àwọn Ẹlẹ́rìí tún máa ń lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti fi sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn pàdé lẹ́nu ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́. Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan ni àwọn àti aládùúgbò wọn jọ sọ, tàbí ẹni tí wọ́n jọ wọkọ̀ tàbí tí wọ́n jọ wọ ọkọ̀ òfuurufú pọ̀, tàbí kó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó gùn díẹ̀ ni wọ́n bá ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí sọ, tàbí kó jẹ́ ìjíròrò pẹ̀lú òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni nígbà ìjẹun. Ọ̀nà yìí ni Jésù gbà ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí rẹ̀ nígbà tó wà láyé, ìyẹn nínú bó ṣe ń rìn létíkun, tó bá ti jókòó sí ẹ̀gbẹ́ òkè, tó bá ń jẹun nínú ilé ẹnì kan, tó bá wà níbi ìgbéyàwó, tàbí tó bá wọ ọkọ̀ ojú omi àwọn apẹja láti rìnrìn àjò lójú Òkun Gálílì. Ó kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Ó máa ń wá àyè láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run níbikíbi tó bá wà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé ipasẹ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí kan náà.—1 Pétérù 2:21.
FÍFI ÌWÀ WỌN WÀÁSÙ
Èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sọ ìhìn rere yìí fún ọ kò ní já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ bí ẹni tó ń wàásù fún ọ kò bá fi àwọn ẹ̀kọ́ yẹn ṣèwà hù fúnra rẹ̀. Ká sọ ohun kan ká sì máa wá ṣe nǹkan mìíràn jẹ́ ìwà àgàbàgebè, àgàbàgebè inú ẹ̀sìn sì ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kẹ̀yìn sí Bíbélì. Bẹ́ẹ̀, Bíbélì kọ́ ló sì fà á. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ń bẹ lọ́wọ́ àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí, síbẹ̀ Jésù bẹnu àtẹ́ lù wọ́n, ó ní alágàbàgebè ni wọ́n. Ó sọ nípa bí wọ́n ṣe ń ka ìwé Òfin Mósè jáde, ó sì wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ síwájú sí i pé: “Gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún yín, ni kí ẹ ṣe kí ẹ sì pa mọ́, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣe wọn, nítorí wọn a máa wí, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe.” (Mátíù 23:3) Àpẹẹrẹ ìgbé ayé rere tí Kristẹni bá ń gbé máa ń yíni lọ́kàn padà ju ká máa da ìwàásù bolẹ̀ ṣáá. Wọ́n tọ́ka sí kókó yìí fún àwọn aya tó jẹ́ Kristẹni tí ọkọ wọ́n sì jẹ́ aláìgbàgbọ́, pé: “Kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pétérù 3:1, 2.
Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá láti lo ọ̀nà yìí láti fi mú kí àwọn ẹlòmíràn tẹ́wọ́ gba ìhìn rere pẹ̀lú: ìyẹn nípa jíjẹ́ àwòkọ́ṣe nínú ìwà Kristẹni tí wọ́n ń sọ pé kí àwọn ẹlòmíràn máa hù. Wọ́n ń sapá láti ‘ṣe ohun tí wọ́n ń fẹ́ kí èèyàn ṣe sí àwọn gẹ́lẹ́, sí ọmọnìkejì wọn pẹ̀lú.’ (Mátíù 7:12) Gbogbo èèyàn ni wọ́n ń gbìyànjú láti hu irú ìwà yìí sí, kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn, ọ̀rẹ́ wọn, aládùúgbò wọn, tàbí ẹbí wọn nìkan. Nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìpé, ìgbà gbogbo kọ́ ni wọ́n máa ń lè ṣe é tó bó ṣe yẹ. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ ọkàn wọn ni láti máa ṣe rere fún gbogbo èèyàn, kì í ṣe nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn nìkan, bí kò ṣe nípa ṣíṣèrànwọ́ fún wọn níbi tó bá ti ṣeé ṣe.—Jákọ́bù 2:14-17.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Hawaii
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Venezuela
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Yugoslavia
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́ ibi ìjíròrò Bíbélì, a kọ́ wọn lọ́nà tó mọ níwọ̀n
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Nínú ìgbésí ayé ìdílé wọn àti nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń fi tinútinú gbìyànjú láti ṣe àwọn ohun tí wọ́n ń wàásù pé kí àwọn ẹlòmíràn máa ṣe