Ẹ̀KỌ́ 12
Ìfaraṣàpèjúwe Àti Ìrísí Ojú
ÀWỌN ẹ̀yà kan sábà máa ń fara ṣàpèjúwe ju àwọn ẹ̀yà mìíràn lọ. Síbẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ tí ìrísí ojú rẹ̀ kì í fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí hàn tí kò sì ní máa fara ṣàpèjúwe lọ́nà kan ṣáá. Bó sì ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ nìyẹn nígbà tí a bá ń báni fọ̀rọ̀ wérọ̀ tàbí nígbà tí a bá ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀.
Ó mọ́ Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí lára láti máa fara ṣàpèjúwe. Ní àkókò kan, ẹnì kan sọ fún Jésù pé ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. Jésù fèsì pé: “Ta ni ìyá mi, ta sì ni àwọn arákùnrin mi?” Bíbélì wá fi kún un pé: “Ní nína ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé: ‘Wò ó! Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi!’” (Mát. 12:48, 49) Yàtọ̀ sí àwọn ìtọ́kasí mìíràn tó tún wà, Bíbélì fi hàn ní Ìṣe 12:17 àti 13:16 pé àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú fara ṣàpèjúwe láìsí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rò ó tẹ́lẹ̀.
Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan la fi í sọ èrò àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹni, a tún lè fara ṣàpèjúwe tàbí ká jẹ́ kí ìrísí ojú wa fi wọ́n hàn. Béèyàn ò bá lò wọ́n bó ṣe yẹ, ó lè jẹ́ kó dà bíi pé ẹni tó ń sọ̀rọ̀ náà kò bìkítà. Ṣùgbọ́n bí a bá lo ọ̀nà tí à ń gbà sọ̀rọ̀ yìí pa pọ̀ lọ́nà tó jíire, ó máa mú kí ọ̀rọ̀ túbọ̀ gbéṣẹ́. Kódà nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, bí o bá ń fara ṣàpèjúwe, tí ìrísí ojú rẹ sì bá ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ mu bó ṣe yẹ, ohùn rẹ yóò tètè máa fi bí ọ̀rọ̀ rẹ àti ohun tí ò ń sọ ṣe rí lára ìwọ fúnra rẹ hàn. Nítorí náà, ì báà jẹ́ pé ńṣe lò ń sọ̀rọ̀ láìlo àkọsílẹ̀ tàbí ò ń kàwé, bóyá àwọn olùgbọ́ rẹ ń wò ọ́ tàbí wọ́n ń wo Bíbélì wọn, fífara ṣàpèjúwe àti jíjẹ́ kí ìrísí ojú rẹ bá ọ̀rọ̀ mu wúlò.
Má ṣe wo aago aláago ṣiṣẹ́ bó bá di ti fífara ṣàpèjúwe àti mímú kí ìrísí ojú rẹ bá ọ̀rọ̀ mu. Ṣebí o kò kọ́ bí èèyàn ṣe ń rẹ́rìn-ín tàbí bí èèyàn ṣe ń bínú. Nítorí náà, ńṣe ló yẹ kí ìfaraṣàpèjúwe rẹ fi ohun tó wà nínú rẹ hàn. Ohun tó dára jù ni pé kí o lè fara ṣàpèjúwe láìsí pé ò ń rò ó tẹ́lẹ̀.
Ní pàtàkì, ọ̀nà méjì ni ìfaraṣàpèjúwe pín sí, àwọn ni: lílo ara láti fi ṣàpèjúwe àti fífi ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe. Lílo ara láti fi ṣàpèjúwe jẹ́ ọ̀nà kan tí a máa ń gbà fi ohun tí èèyàn ṣe hàn, ó sì lè fi gígùn, fífẹ̀ àti gíga nǹkan àti ibi tó wà hàn. Ní ilé ẹ̀kọ́, nígbà tí o bá ń ṣiṣẹ́ lórí ìfaraṣàpèjúwe, má ṣe fi mọ sí mímọ ẹyọ kan tàbí méjì péré. Gbìyànjú láti fara ṣàpèjúwe jálẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ, lọ́nà tó bá ìwà ẹ̀dá tìrẹ mu. Bí ó bá ṣòro fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè ṣèrànwọ́ bí o bá wá àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fi ìhà ibi tí nǹkan wà hàn, bí nǹkan náà ṣe jìnnà sí, bó ṣe tóbi tó, ọ̀gangan ibi tó wà, tàbí bí wọ́n ṣe wà síra wọn. Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí o ní láti ṣe ni pé kí o fọkàn sí ohun tí ò ń sọ, kí o má ṣe dààmú nípa ohun tí àwọn ẹlòmíràn yóò máa rò nípa rẹ, ṣùgbọ́n kí o máa sọ̀rọ̀ rẹ kí o sì máa ṣe nǹkan rẹ bí o ṣe máa ń ṣe wọ́n lójoojúmọ́. Bí èèyàn bá ti fara balẹ̀, ńṣe lá kàn rí i pé òun ń fára ṣàpèjúwe fàlàlà bó ṣe yẹ.
Fífi ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe jẹ́ ọ̀nà kan tí a máa ń gbà fi bí nǹkan ṣe rí lára àti bó ṣe dáni lójú tó hàn. Ńṣe ló máa ń gbé èrò ẹni yọ, á mú kí ó tani jí, kí ó sì túbọ̀ rinlẹ̀. Ó ṣe pàtàkì láti máa fi ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe nǹkan. Ṣùgbọ́n ṣọ́ra o! Nítorí kì í pẹ́ téèyàn fi ń sọ ọ́ di àṣà. Bí ó bá jẹ́ pé gbólóhùn ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ kan náà lo máa ń lò léraléra, gbólóhùn yẹn gan-an lè bẹ̀rẹ̀ sí gbàfiyèsí àwọn èèyàn dípò kí ó túbọ̀ gbé ọ̀rọ̀ rẹ yọ. Bí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ bá sọ pé o ní ìṣòro yìí, gbìyànjú láti fi mọ́ sórí kìkì fífi ara ṣàpèjúwe nǹkan. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, kó o wá tún bẹ̀rẹ̀ sí fi ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ rẹ.
Láti lè pinnu bí ó ṣe yẹ kí o fi ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe tó, àti irú ìfaraṣàpèjúwe tó yẹ, ńṣe ni kó o ronú nípa bí yóò ṣe rí lára àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀. Bí o bá ń nàka sí àwùjọ, ó lè máà bá wọn lára mu. Nínú àwọn ẹ̀yà kan, bí ọkùnrin bá fara ṣàpèjúwe láwọn ọ̀nà kan, irú bíi kó fi ọwọ́ bo ẹnu láti fi hàn pé nǹkan ya òun lẹ́nu, ńṣe ni wọ́n á wò ó pé ó ń ṣe bí obìnrin. Láwọn ibì kan láyé, wọ́n kà á sí ohun tí kò bá a mu pé kí obìnrin máa fi ọwọ́ ṣàpèjúwe ní fàlàlà. Nítorí náà, láwọn ibi wọ̀nyẹn, lọ́pọ̀ ìgbà, ojú làwọn arábìnrin máa ń lò ní pàtàkì láti fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí hàn. Ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé níbikíbi láyé yìí ni wọ́n ti máa ń ka fífara ṣàpèjúwe lọ́nà àṣerégèé níwájú àwùjọ kékeré sí ọ̀ràn ẹ̀fẹ̀.
Bí o ṣe ń ní ìrírí sí i tí ọ̀rọ̀ sì túbọ̀ ń rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti sọ, ọ̀nà yòówù kí o lò láti gbà fi ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe nǹkan yóò gbé ohun tí ó wà nínú rẹ lọ́hùn-ún yọ, yóò sì fi ìdánilójú àti òtítọ́ ọkàn tí o fi ń sọ ọ́ hàn. Wọ́n á jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ ní ìtumọ̀.
Ohun Tí Ìrísí Ojú Rẹ Ń Sọ. Ìrísí ojú rẹ sábà máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ gan-an ju bí ibòmíràn lára rẹ ṣe lè fi hàn. Ẹyinjú rẹ, bí ẹnu rẹ ṣe rí, àti ibi tí o bá tẹ orí sí ní ipa tí wọ́n ń kó. Láìsọ̀rọ̀ rárá, ìrísí ojú rẹ lè fi àìbìkítà, ìríra, ìpòrúùru ọkàn, ìyàlẹ́nu, tàbí ìdùnnú hàn. Nígbà tí irú ìrísí ojú bẹ́ẹ̀ bá bá ọ̀rọ̀ téèyàn ń sọ rìn, wọ́n máa ń jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ túbọ̀ róye ọ̀ràn ọ̀hún àti bó ṣe rí lára ẹni. Ẹlẹ́dàá dá ọ̀pọ̀ iṣan wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ síbi ojú rẹ, wọ́n sì ju ọgbọ̀n lọ lápapọ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì wọn tó máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ nígbà tí o bá rẹ́rìn-ín músẹ́.
Bóyá o wà lórí pèpéle tàbí ò ń wàásù lóde ẹ̀rí, ohun tí ò ń ṣakitiyan láti sọ fún àwọn èèyàn jẹ́ ìhìn kan tó lárinrin tí ó lè mú ọkàn wọn yọ̀. Ẹ̀rín músẹ́ pẹ̀lú ọ̀yàyà ń fi ìyẹn hàn. Ṣùgbọ́n, bí o bá kàn ṣojú fúrú, èyí lè mú kí àwọn èèyàn rò pé bóyá lohun tí ò ń sọ dé inú rẹ.
Ẹ̀wẹ̀, rírẹ́rìn-ín músẹ́ máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé inú rẹ yọ́ sí wọn. Ìyẹn ṣe pàtàkì, pàápàá lóde òní tí àwọn èèyàn sábà máa ń bẹ̀rù àjèjì. Ẹ̀rín músẹ́ rẹ lè fi àwọn èèyàn lọ́kàn balẹ̀ kí wọ́n sì túbọ̀ tẹ́tí sí ohun tí o bá sọ.